Ìtọ́ni Jésù Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Jẹ́rìí Kúnnákúnná
“Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—ÌṢE 1:8.
1, 2. Iṣẹ́ wo ni Pétérù gbà, ta lo sì gbé iṣẹ́ náà lé e lọ́wọ́?
“JÉSÙ tí ó wá láti Násárétì . . . pa àṣẹ ìtọ́ni fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná pé Ẹni tí Ọlọ́run ti fàṣẹ gbé kalẹ̀ nìyí pé kí ó jẹ́ onídàájọ́ alààyè àti òkú.” (Ìṣe 10:38, 42) Àpọ́sítélì Pétérù ló sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Kọ̀nílíù àti ìdílé rẹ̀ kí wọ́n lè mọ̀ pé òun ti gba àṣẹ láti jẹ́ ajíhìnrere.
2 Ìgbà wo ni Jésù fún un níṣẹ́ yẹn? Ó lè jẹ́ ohun tí Jésù sọ lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ kó tó gòkè re ọ̀run ni Pétérù ronú kàn. Ní àkókò yẹn, Jésù sọ fáwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Àmọ́ ṣá o, ṣáájú àkókò yẹn ni Pétérù ti mọ̀ pé níwọ̀n bí òun ti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, òun ní láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tóun ní nínú Jésù.
Wọ́n Gba Ìtọ́ni fún Ọdún Mẹ́ta
3. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù ṣe, kí ló sì sọ pé kí Pétérù àti Áńdérù wá ṣe?
3 Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa, ó fi oṣù bíi mélòó kan wàásù níbi tí Pétérù àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ ẹja pípa ní Òkun Gálílì. Wọ́n ṣe làálàá ní gbogbo òru ọjọ́ kan, àmọ́ wọn ò rí ẹja kankan pa. Síbẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “[Ẹ] wa ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi tí ó jindò, kí ẹ sì rọ àwọn àwọ̀n yín sísàlẹ̀ fún àkópọ̀ ẹja.” Nígbà tí wọ́n ṣe ohun tí Jésù sọ yìí, “wọ́n kó ògìdìgbó ńlá ẹja. Ní ti tòótọ́, àwọn àwọ̀n wọn bẹ̀rẹ̀ sí fà ya sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.” Nígbà tí Pétérù rí iṣẹ́ ìyanu yìí, ẹ̀rú bà á, àmọ́ Jésù fi í lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Dẹ́kun fífòyà. Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.”—Lúùkù 5:4-10.
4. (a) Báwo ni Jésù ṣe múra àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ láti jẹ́rìí? (b) Báwo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe máa rí tá a bá fi wé tirẹ̀?
4 Ojú ẹsẹ̀ ni Pétérù àti Áńdérù, títí kan Jákọ́bù àti Jòhánù tí wọ́n jẹ́ ọmọ Sébédè fi ọkọ̀ wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù. Ó tó ọdún mẹ́ta tí wọ́n fi ń tẹ̀ lé Jésù lọ sáwọn ibi tó ti lọ ń wàásù, ó sì ń kọ́ wọn níṣẹ́ ìjíhìnrere. (Mátíù 10:7; Máàkù 1:16, 18, 20, 38; Lúùkù 4:43; 10:9) Nígbà tí ẹ̀kọ́ náà fẹ́ parí ní Nísàn 14 ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, ẹni yẹn pẹ̀lú yóò ṣe àwọn iṣẹ́ tí èmi ń ṣe; yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí.” (Jòhánù 14:12) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yóò jẹ́rìí kúnnákúnná bí Jésù ti ṣe, àmọ́ tiwọn á gbòòrò gan-an ju tiẹ̀ lọ. Kò pẹ́ tí wọ́n fi wá mọ̀ pé àwọn àti gbogbo àwọn tó máa di ọmọ ẹ̀yìn lọ́jọ́ iwájú yóò jẹ́rìí ní “gbogbo orílẹ̀-èdè,” títí dé “ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 28:19, 20.
5. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jàǹfààní látinú ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
5 Àkókò “ìparí ètò àwọn nǹkan” là ń gbé. (Mátíù 24:3) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí tẹ̀ lé Jésù káàkiri wọ́n sì ń wò ó bó ṣe ń wàásù, àmọ́ àwa ò láǹfààní yẹn. Síbẹ̀, a lè jàǹfààní látinú ìtọ́ni rẹ̀ tá a bá ń kà nípa ọ̀nà tó gbà wàásù tá a sì ń kà nípa ìtọ́ni tó fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú Bíbélì. (Lúùkù 10:1-11) Àmọ́, ohun mìíràn tó tún ṣe pàtàkì gan-an tí Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ la ó jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìyẹn ni kéèyàn ní ẹ̀mí tó dáa nípa iṣẹ́ ìwàásù náà.
Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Jésù Lọ́kàn
6, 7. Àwọn ànímọ́ wo ni Jésù ní tó jẹ́ kí ìwàásù rẹ̀ múná dóko, báwo la sì ṣe lè fara wé e?
6 Kí ló mú kí ìwàásù Jésù múná dóko? Ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn jinlẹ̀ ó sì bìkítà fún wọn. Onísáàmù náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Jésù yóò “káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì.” (Sáàmù 72:13) Jésù mú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ lóòótọ́. Bíbélì sọ nípa ohun tó ṣe nígbà kan pé: “Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:36) Kódà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn jẹ Jésù lọ́kàn, èyí sì mú kí wọ́n sún mọ́ ọn.—Mátíù 9:9-13; Lúùkù 7:36-38; 19:1-10.
7 Ìwàásù wa lè múná dóko lónìí táwa náà bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lọ́kàn. Kó o tó lọ sóde ẹ̀rí, o ò ṣe kọ́kọ́ ronú nípa bí àwọn èèyàn ṣe nílò ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ lọ sọ yẹn tó? Ronú nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n lè ní tó jẹ́ pé kìkì Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè bá wọn yanjú rẹ̀. Rí i dájú pé o ní èrò tó dáa nípa gbogbo èèyàn, nítorí pé o ò mọ ẹni tí ìhìn rere náà máa yí lọ́kàn padà. Bóyá ẹni tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ tiẹ̀ ti ń gbàdúrà pé kí òun rí ẹnì kan bíi tìrẹ tí yóò ran òun lọ́wọ́!
Ìfẹ́ Ló Mú Kó Máa Wàásù
8. Kí ló mú káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa wàásù ìhìn rere náà bíi tirẹ̀?
8 Bí ìfẹ́ Jèhófà ṣe máa di ṣíṣe, tí orúkọ Rẹ̀ yóò sì di mímọ́ àti bí a ó ṣe dá ipò Rẹ̀ láre gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, wà lára ìhìn rere tí Jésù wàásù rẹ̀, àwọn kókó wọ̀nyí ló sì ṣe pàtàkì jù nínú ọ̀ràn tó dojú kọ ìran ènìyàn. (Mátíù 6:9, 10) Ìfẹ́ tí Jésù ní sí Baba rẹ̀ ló mú kó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ títí dópin tó sì mú kó jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba tí yóò mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, tí yóò sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, tí yóò sì dá ipò rẹ̀ láre. (Jòhánù 14:31) Irú ìfẹ́ yìí kan náà làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù òde òní ní, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń wàásù lójú méjèèjì. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” Àṣẹ tí Jésù pa pé ká wàásù ìhìn rere náà ká sì tún sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn wà lára wọn.—1 Jòhánù 5:3; Mátíù 28:19, 20.
9, 10. Yàtọ̀ sí ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run, ìfẹ́ mìíràn wo ló tún ń mú ká máa jẹ́rìí kúnnákúnná?
9 Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, ẹ ó pa àwọn àṣẹ mi mọ́. Ẹni tí ó bá ní àwọn àṣẹ mi, tí ó sì ń pa wọ́n mọ́, ẹni yẹn ni ó nífẹ̀ẹ́ mi.” (Jòhánù 14:15, 21) Nítorí náà, ìfẹ́ tá a ní sí Jésù yẹ kó mú wa máa jẹ́rìí nípa òtítọ́ ká sì máa pa àwọn àṣẹ mìíràn tí Jésù fún wa mọ́. Nígbà kan tí Jésù fara hàn lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, ó rọ Pétérù pé: “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn mi. . . . Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn àgùntàn mi kéékèèké. . . . Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” Kí ló máa mú kí Pétérù ṣe ìyẹn? Ìbéèrè tí Jésù bi Pétérù léraléra jẹ́ ká mọ ohun tó máa mú un ṣe é. Jésù bí i pé: ‘Ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi bí? . . . Ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi bí? . . . Ìwọ ha ní ìfẹ́ni fún mi bí?’ Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfẹ́ tí Pétérù ní sí Jésù ló máa mú kó jẹ́rìí kúnnákúnná, á sì mú kó wá “àwọn àgùntàn kéékèèké” tí Jésù ní kàn, lẹ́yìn ìyẹn, á wá di olùṣọ́ àgùntàn wọn nípa tẹ̀mí.—Jòhánù 21:15-17.
10 Àwa tá a wà láyé lónìí ò rí Jésù sójú rí a ò sì bá a rìn bíi ti Pétérù. Síbẹ̀, a ní òye tó jinlẹ̀ nípa ohun tí Jésù ṣe fún wa. Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tó mú kó “tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn” wú wa lórí gan-an ni. (Hébérù 2:9; Jòhánù 15:13) Bọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gẹ́ẹ́ ló rí lára àwa náà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa . . . Ó kú fún gbogbo wa kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn.’ (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Tá a bá fi gbogbo ọkàn wa tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa pé ká jẹ́rìí kúnnákúnná, èyí á fi hàn pé a mọrírì ìfẹ́ tí Jésù ní sí wa yìí gan-an, á sì tún fi hàn pé àwa náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Jòhánù 2:3-5) A ò ní dágunlá sí iṣẹ́ ìwàásù náà láé, nítorí ìyẹn á túmọ̀ sí pé a fọwọ́ yẹpẹrẹ mu ẹbọ Jésù.—Hébérù 10:29.
Pọkàn Pọ̀ Sórí Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù
11, 12. Torí kí ni Jésù ṣe wá sáyé, báwo ló sì ṣe fi hàn pé iṣẹ́ tóun kà sí pàtàkì jù nìyẹn?
11 Nígbà tí Jésù wà níwájú Pọ́ńtíù Pílátù, ó sọ pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Jésù ò jẹ́ kí ohunkóhun gbàfiyèsí òun bó ṣe ń jẹ́rìí sí òtítọ́. Ohun tí Ọlọ́run sì fẹ́ kó ṣe nìyẹn.
12 Ó hàn gbangba pé Sátánì dán Jésù wò lórí èyí. Kété lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi ni Sátánì fẹ́ sọ ọ́ dẹni ńlá nínú ayé, ó fẹ́ fún un ní “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn.” (Mátíù 4:8, 9) Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn Júù tún fẹ́ fi Jésù jọba. (Jòhánù 6:15) Àwọn kan lónìí lè máa rò pé bóyá nǹkan ì bá tiẹ̀ ṣẹnuure fáwọn èèyàn ká ní Jésù gba àwọn nǹkan tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ yìí, wọ́n lè máa rò pé tí Jésù bá jẹ́ ọba ayé, ì bá ti ṣe ọ̀pọ̀ ohun tó dáa gan-an fọ́mọ aráyé. Àmọ́, Jésù ò fara mọ́ irú èrò yẹn o. Ohun tó gbà pé ó ṣe pàtàkì jù ni kóun máa jẹ́rìí sí òtítọ́.
13, 14. (a) Kí ni ohun tí Jésù ò jẹ́ kó gbàfiyèsí òun bó ṣe ń ṣiṣẹ́ tó wá ṣe láyé? (b) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò ní ọrọ̀ nípa tara, kí lohun tó gbé ṣe?
13 Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jésù ò lé ọ̀rọ̀ kiri tá á fi wá gbà gbé ohun tó torí ẹ̀ wá sáyé. Ìdí nìyẹn tí kò fi ní ọrọ̀. Kò tiẹ̀ nílé tara ẹ̀ pàápàá. Ìgbà kan wà tó sọ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Mátíù 8:20) Nígbà tí Jésù kú, ohun kan ṣoṣo tó ṣeyebíye tí Bíbélì sọ pé ó ní kò ju ẹ̀wù rẹ̀ táwọn sójà Róòmù ṣẹ́ kèké lé. (Jòhánù 19:23, 24) Ṣé ó wá túmọ̀ sí pé ìgbésí ayé rádaràda ni Jésù gbé ni? Rárá o!
14 Ohun tí Jésù gbélé ayé ṣe ju ohun tí olówó ayé èyíkéyìí ṣe lọ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ mọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wa, pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun jẹ́ ọlọ́rọ̀, ó di òtòṣì nítorí yín, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ipò òṣì rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 8:9; Fílípì 2:5-8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò ní ọrọ̀ nípa tara, síbẹ̀ ó ṣílẹ̀kùn àǹfààní sílẹ̀ fáwọn onírẹ̀lẹ̀ láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun kí wọ́n sì di ẹni pípé. A mọrírì ohun tó ṣe yìí gan-an ni! Inú wa sì dùn púpọ̀ sí èrè tó rí gbà nítorí pé ó fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ṣáájú nínú ìgbésí ayé rẹ̀!—Sáàmù 40:8; Ìṣe 2:32, 33, 36.
15. Kí ló níye lórí ju ọrọ̀ lọ?
15 Àwọn Kristẹni tó ń sapá láti fara wé Jésù lóde òní ò jẹ́ kí wíwá ọrọ̀ gbàfiyèsí àwọn náà. (1 Tímótì 6:9, 10) Wọ́n gbà pé ọrọ̀ lè mú káwọn jẹ̀gbádùn ayé nísinsìnyí, àmọ́ wọ́n mọ̀ pé ọrọ̀ ò lè fáwọn ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Nígbà tí Kristẹni kan bá kú, àwọn nǹkan ìní rẹ̀ kò lè wúlò fún un bí ẹ̀wù Jésù ò ṣe wúlò fún Jésù nígbà tó kú. (Oníwàásù 2:10, 11, 17-19; 7:12) Nígbà tí Kristẹni kan bá kú, ohun iyebíye kan ṣoṣo tó lè ní ò ju àjọṣe tó wà láàárín òun àti Jèhófà àti Jésù Kristi.—Mátíù 6:19-21; Lúùkù 16:9.
Àtakò Ò Dí Jésù Lọ́wọ́
16. Báwo ni Jésù ṣe kojú àtakò?
16 Àtakò ò dí Jésù lọ́wọ́ kó má jẹ́rìí sí òtítọ́. Kódà, mímọ̀ tó mọ̀ pé ikú ìrúbọ lóun máa fi kẹ́yìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun lórí ilẹ̀ ayé ò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jésù pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” (Hébérù 12:2) Kíyè sí i pé Jésù “tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú.” Kò jẹ́ kí ohun táwọn alátakò ń rò nípa òun kó ìdààmú bá òun. Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló gbájú mọ́.
17. Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ nínú ìfaradà Jésù?
17 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú ìfaradà Jésù, ó gba àwọn Kristẹni níyànjú, ó ní: “Ẹ ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀ nípa ẹni tí ó ti fara da irúfẹ́ òdì ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lòdì sí ire ara wọn, kí ó má bàa rẹ̀ yín, kí ẹ sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn yín.” (Hébérù 12:3) Lóòótọ́, ó lè má rọrùn láti máa kojú àtakò àti ìfiniṣẹ̀sín ní gbogbo ìgbà. Téèyàn bá sì ń fi gbogbo ìgbà kọ àwọn nǹkan tó ń fani mọ́ra nínú ayé, ó lè káàárẹ̀ ọkàn báni, ó tiẹ̀ lè mú kínú máa bí àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ tí wọ́n ń gbà wá níyànjú pé “ká wá náà wá nǹkan ṣe” ká lè dèèyàn gidi. Àmọ́, bíi ti Jésù, ojú Jèhófà là ń wò pé yóò tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń fi Ìjọba náà ṣáájú ohun gbogbo nínú ìgbésí ayé wa.—Mátíù 6:33; Róòmù 15:13; 1 Kọ́ríńtì 2:4.
18. Ẹ̀kọ́ àtàtà wo la lè rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sí Pétérù?
18 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ikú tó máa kú láìpẹ́ sí àkókò yẹn fi hàn pé kó jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn òun níyà. Pétérù gba Jésù níyànjú pé kó “ṣàánú” ara rẹ̀, ó sì tún mú un dá a lójú pé kò ní “ní ìpín yìí rárá.” Jésù kọ̀ láti fetí sí ohunkóhun tó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a nínú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ó kẹ̀yìn sí Pétérù, ó sọ fún un pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.” (Mátíù 16:21-23) Ẹ jẹ́ kí àwa náà múra tán láti kọ èrò òdì èyíkéyìí táwọn èèyàn lè ní. Dípò ìyẹn, èrò Ọlọ́run ni ká jẹ́ kó máa tọ́ wa sọ́nà nígbà gbogbo.
Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣeni Láǹfààní Ayérayé
19. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu, kí ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
19 Jésù ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu láti fi hàn pé òun ni Mèsáyà. Ó tiẹ̀ jí òkú dìde pàápàá. Àwọn iṣẹ́ wọ̀nyẹn múnú àwọn èèyàn dùn lóòótọ́, àmọ́ Jésù ò wá sáyé láti wá ṣe kìkì iṣẹ́ afẹ́nifẹ́re. Ńṣe ló wá jẹ́rìí sí òtítọ́. Ó mọ̀ pé nǹkan tara èyíkéyìí tóun bá ṣe fáwọn èèyàn ò lè wà títí ayé. Kódà, àwọn tí Jésù jí dìde tún padà kú. Nípa jíjẹ́rìí sí òtítọ́ nìkan ló fi lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—Lúùkù 18:28-30.
20, 21. Báwo làwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe ń ṣe ohun rere tí wọn ò sì jẹ́ kíyẹn pa iṣẹ́ ìwàásù wọn lára?
20 Lónìí, àwọn kan ń gbìyànjú láti ṣe irú iṣẹ́ rere tí Jésù ṣe nípa kíkọ́ ilé ìwòsàn tàbí kí wọ́n máa ṣe àwọn iṣẹ́ afẹ́nifẹ́re fún àwọn òtòṣì. Èyí máa ń ná wọn lówó gan-an nígbà míì, a sì mọrírì inú rere tí wọ́n ní yìí; àmọ́ ohun yòówù kí wọ́n ṣe láti dín ìṣòro àwọn èèyàn kù kò lè wà títí lọ. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè ṣeni láǹfààní tó máa wà títí láé. Ìdí nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbájú mọ́ jíjẹ́rìí sí òtítọ́ nípa Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe.
21 Lóòótọ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń ṣe nǹkan tó dáa fáwọn èèyàn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Lákòókò ìṣòro tàbí nígbà tẹ́nì kan bá nílò ìrànlọ́wọ́, a kì í lọ́ tìkọ̀ láti “ṣe ohun rere” fáwọn aládùúgbò wa tàbí àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Síbẹ̀, ohun tó ṣe pàtàkì jù lójú Jésù làwa náà gbájú mọ́, ìyẹn ni jíjẹ́rìí sí òtítọ́.
Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Jésù
22. Kí nìdí táwọn Kristẹni fi ń wàásù fáwọn èèyàn?
22 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní ti gidi, mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!” (1 Kọ́ríńtì 9:16) Kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìhìn rere náà rárá nítorí ó mọ̀ pé wíwàásù nípa rẹ̀ yóò jẹ́ kí òun àtàwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ òun ní ìyè. (1 Tímótì 4:16) Ojú táwa náà fi ń wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nìyẹn. A fẹ́ ran àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́. A fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. A fẹ́ jẹ́ kí Jésù mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun a sì fẹ́ fi hàn pé a mọrírì ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tó ní sí wa. Ìdí nìyẹn tá a fi ń wàásù ìhìn rere náà tá a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a ò wà “fún ìfẹ́-ọkàn ènìyàn mọ́, bí kò ṣe fún ìfẹ́ Ọlọ́run.”—1 Pétérù 4:1, 2.
23, 24. (a) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe? (b) Àwọn wo ló ń jẹ́rìí kúnnákúnná lóde òní?
23 Bíi ti Jésù, a kì í jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà nídìí iṣẹ́ ìwàásù wa nígbà táwọn èèyàn bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí tí wọ́n bá ń bínú tí wọn ò sì fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa. A rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tó pe Pétérù àti Áńdérù pé kí wọ́n tẹ̀ lé òun. A rí i pé tá a bá ṣe ohun tí Jésù ní ká ṣe, tá a sì ju àwọ̀n wa sínú odò tó dà bíi pé kò tiẹ̀ ní ẹja kankan, ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ ẹja pípa wa, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù tá a ń ṣe, so èso. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ti wá rí ẹja pa lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tó dà bíi pé kò sí ẹja kankan. Àwọn mìíràn ti ṣí lọ síbi tí wọ́n mọ̀ pé àwọn á ti rí ẹja pa dáadáa, wọ́n sì ti rí ọ̀pọ̀ ẹja kó níbẹ̀. Ohun yòówù tá à báà ṣe, a ò ní yéé ju àwọ̀n wa sínú odò. A mọ̀ pé Jésù ò tíì sọ pé iṣẹ́ ìwàásù náà ti parí níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 24:14.
24 Ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà lójú méjèèjì ní igba ó lé ọgbọ̀n [230] orílẹ̀-èdè. Ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ti February 1, 2005 yóò gbé ìròyìn ọdọọdún nípa iṣẹ́ tí wọ́n ṣe jákèjádò ayé láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn ti 2004 jáde. Ìròyìn yẹn yóò jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe bù kún iṣẹ́ ìwàásù náà lọ́nà tó bùáyà. Níwọ̀nba àkókò tó kù kí ètò nǹkan ìsinsìnyí parí, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ láti fi ọ̀rọ̀ ìwúrí tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹn sọ́kàn, ó sọ pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú.” (2 Tímótì 4:2) Ẹ jẹ́ ká máa jẹ́rìí kúnnákúnná nìṣó títí Jèhófà á fi sọ pé iṣẹ́ náà ti parí.
Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún yìí, a ò ní máa tẹ Ìròyìn Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé sínú Ilé Ìṣọ́ ti January 1 mọ́. Inú Ilé Ìṣọ́ ti February 1 la óò máa tẹ̀ ẹ́ sí.
Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn?
• Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
• Báwo lọ̀rọ̀ àwọn tí Jésù wàásù fún ṣe rí lára rẹ̀?
• Kí ló ń mú ká máa jẹ́rìí kúnnákúnná?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gba pọkàn pọ̀ sórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bíi ti Jésù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
A óò túbọ̀ kẹ́sẹ̀ járí nínú iṣẹ́ ìwàásù wa tí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn bá jẹ wá lọ́kàn bíi ti Jésù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Iṣẹ́ jíjẹ́rìí sí òtítọ́ ni olórí ohun tí Jésù wá ṣe láyé
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Iṣẹ́ tó jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lógún jù lọ ni pé kí wọ́n jẹ́rìí kúnnákúnná