A ó Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Wa
“Àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—MÍKÀ 4:5.
1. Báwo ni ìwà àwọn èèyàn ṣe rí nígbà ayé Nóà, báwo ni Nóà sì ṣe yàtọ̀ sáwọn tó kù?
ÉNỌ́KÙ lẹni àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ pé ó bá Ọlọ́run rìn. Nóà sì ni ẹnì kejì. Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé: “Nóà jẹ́ olódodo. Ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀. Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9) Gbogbo èèyàn ti yapa kúrò nínú ìjọsìn mímọ́ nígbà ayé Nóà. Ohun tó túbọ̀ wá mú kí nǹkan burú sí i lákòókò yẹn ni àwọn áńgẹ́lì aláìṣòótọ́ tí wọ́n ṣe ohun tí kò bójú mu rárá ní ti pé wọ́n wá fẹ́ àwọn ọmọbìnrin èèyàn. Wọ́n bí àwọn ọmọ tá a pè ní Néfílímù, “àwọn ni alágbára ńlá” tàbí “àwọn ọkùnrin olókìkí,” láyé ìgbàanì. Abájọ tí ìwà ipá fi kún orí ilẹ̀ ayé! (Jẹ́nẹ́sísì 6:2, 4, 11) Síbẹ̀, Nóà fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́bi àti “oníwàásù òdodo.” (2 Pétérù 2:5) Nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ áàkì láti fi gba ẹ̀mí là, ó ṣègbọràn ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:22) Láìsí àní-àní, Nóà bá Ọlọ́run rìn.
2, 3. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Nóà fi lélẹ̀ fún wa lónìí?
2 Nóà wà lára àwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́ tí Pọ́ọ̀lù to orúkọ wọn lẹ́sẹẹsẹ nígbà tó kọ̀wé pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà, lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí, fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀; àti nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí, ó dá ayé lẹ́bi, ó sì di ajogún òdodo tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́.” (Hébérù 11:7) Àpẹẹrẹ títayọ gbáà lèyí mà jẹ́ o! Ó dá Nóà lójú gan-an pé ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò ṣẹ, débi pé ó lo ọ̀pọ̀ àkókò, okun àti ohun ìní rẹ̀ láti fi ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ. Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ ló kọ àwọn àǹfààní ńlá tí ì bá jẹ́ tiwọn nínú ayé sílẹ̀, tí wọ́n ń lo àkókò wọn, agbára wọn àti ohun ìní wọn láti ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ. Ìgbàgbọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ jọni lójú gan-an, yóò sì yọrí sí ìgbàlà wọn àti tàwọn ẹlòmíràn.—Lúùkù 16:9; 1 Tímótì 4:16.
3 Kò rọrùn rárá fún Nóà àti ìdílé rẹ̀ láti fi ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní ṣèwà hù bí kò ṣe rọrùn fún Énọ́kù tó jẹ́ baba ńlá Nóà, bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Bó ṣe rí nígbà ayé Énọ́kù náà ló rí nígbà ayé Nóà, àwọn olùjọsìn tòótọ́ kéré níye gan-an, ẹni mẹ́jọ péré ló jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n sì la Ìkún Omi náà já. Nóà wàásù òdodo nínú ayé tó kún fún ìwà ipá àti ìṣekúṣe. Yàtọ̀ síyẹn, òun àti ìdílé rẹ̀ tún kan ọkọ̀ áàkì onígi kan tó rí gìrìwò. Wọ́n múra sílẹ̀ de ìkún omi kan tó máa kárí ayé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó rí irú ìkún omi bẹ́ẹ̀ rí ṣáájú àkókò yẹn. Ìyẹn ti ní láti jẹ́ nǹkan àjèjì lójú àwọn tó ń wò wọ́n.
4. Kí ni Jésù sọ pé àwọn tó gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú Nóà kùnà láti ṣe?
4 Ohun kan tó yẹ ká kíyè sí ni pé, nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ Nóà, kò sọ̀rọ̀ nípa ìwà ipá, ìsìn èké, tàbí ìṣekúṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan wọ̀nyí náà burú jáì. Ohun tí Jésù dá àwọn èèyàn náà lẹ́bi fún ni pé wọ́n kọ̀ láti kọbi ara sí ìkìlọ̀ tí wọ́n gbọ́. Ó sọ pé wọ́n “ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì.” Kí ló burú nínú kéèyàn máa jẹ, kó máa mu, kó gbéyàwó, kó sì fa ìyàwó fúnni? Lójú tiwọn, ohun tó yẹ kéèyàn ṣe láyé ni wọ́n ń ṣe yẹn! Àmọ́, ìkún omi ń bọ̀, Nóà sì ń wàásù òdodo. Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ tó ń sọ àti ìwà rẹ̀ ti jẹ́ ìkìlọ̀ fún wọn. Síbẹ̀, wọn “kò . . . fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—Mátíù 24:38, 39.
5. Àwọn ànímọ́ wo ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ nílò?
5 Tá a bá fojú inú wo bí nǹkan ṣe rí lákòókò yẹn, a óò rí ọgbọ́n tó wà nínú ọ̀nà tí Nóà gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, láwọn ọjọ́ tó ṣáájú ìkún omi yẹn, ó gba ìgboyà gan-an kéèyàn tó lè máa ṣe ohun tó yàtọ̀ sóhun tí gbogbo èèyàn yòókù ń ṣe. Ó gba ìgbàgbọ́ tó lágbára gan-an kí Nóà àti ìdílé rẹ̀ tó lè kan ọkọ̀ áàkì gìrìwò náà kí wọ́n sì kó onírúurú ẹranko sínú rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn kan lára àwọn kéréje tó jẹ́ olóòótọ́ èèyàn yẹn tiẹ̀ fìgbà kan sọ pé ó wu àwọn káwọn má ṣe dá yàtọ̀, káwọn sì máa gbé irú ìgbésí ayé táwọn èèyàn yòókù ń gbé? Kódà, bí irú èrò bẹ́ẹ̀ bá tiẹ̀ ṣèèṣì wá sí wọn lọ́kàn, wọn ò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn yẹ̀. Ẹ̀yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìgbàgbọ́ Nóà tó yọrí sí ìgbàlà fún un nígbà tí Ìkún Omi náà dé, ìyẹn sì ju iye ọdún tí èyíkéyìí lára wa ní láti fara da ètò nǹkan ìsinsìnyí. Àmọ́, Jèhófà mú ìdájọ́ ṣẹ sórí gbogbo àwọn tó ń gbé ìgbésí ayé tó dára lójú ara wọn yẹn tí wọn ò sì fiyè sí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò tí wọ́n ń gbé náà.
Ìwà Ipá Tún Gbayé Kan
6. Báwo ni ipò nǹkan tún ṣe rí lẹ́yìn Ìkún Omi?
6 Lẹ́yìn tí Ìkún Omi náà fà tán lórí ilẹ̀, àwọn èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbé ayé tuntun. Àmọ́, ẹ̀dá èèyàn ṣì jẹ́ aláìpé síbẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni “ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn” ń bá a lọ ní jíjẹ́ “búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Yàtọ̀ síyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù ò lè gbé ara èèyàn wọ̀ mọ́, síbẹ̀ wọ́n ń bá iṣẹ́ ibi wọn lọ lójú méjèèjì. Kò pẹ́ rárá tó hàn kedere pé ‘abẹ́ agbára ẹni burúkú náà’ ni àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run wà. Àwọn olùjọsìn tòótọ́ sì ní láti gbógun ti “àwọn ètekéte Èṣù” nígbà yẹn bíi ti ọjọ́ òní.—1 Jòhánù 5:19; Éfésù 6:11, 12.
7. Báwo ni ìwà ipá tún ṣe gbòde kan lẹ́yìn Ìkún Omi?
7 Tá a bá fojú bù ú, láti àkókò Nímírọ́dù ni ayé tó wà lẹ́yìn Ìkún Omi ti tún padà di èyí táwọn èèyàn fi ìwà ipá kún inú rẹ̀. Nítorí pé àwọn èèyàn túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tí ìmọ̀ ẹ̀rọ sì ń tẹ̀ síwájú, ìwà ipá ti wá gbòde kan gan-an báyìí. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, idà, ọ̀kọ̀, ọrun àti ọfà pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun ni aráyé ń lò. Àmọ́ nígbà tó yá, ìbọn ṣakabùlà àti ìbọn arọ̀jò ọta dé, lẹ́yìn náà ni ìbọn jagamù àtàwọn ohun ìjà mìíràn tó lágbára gan-an wá dé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún. Ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní ni wọ́n tiẹ̀ wá lo ọ̀pọ̀ ohun ìjà mìíràn tó bani lẹ́rù jù, irú bí ọkọ̀ òfuurufú, ọkọ̀ afọ́nta, ọkọ̀ ogun abẹ́ omi àti afẹ́fẹ́ olóró. Nígbà ogun yẹn, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn làwọn ohun ìjà ìgbàlódé yẹn pa. Ṣé ohun téèyàn ò retí lohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Rárá o.
8. Báwo ni Ìṣípayá 6:1-4 ṣe ń nímùúṣẹ?
8 Ọlọ́run gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run lọ́dún 1914, ìgbà yẹn ni “ọjọ́ Olúwa” sì bẹ̀rẹ̀. (Ìṣípayá 1:10) Nínú ìran kan tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú ìwé Ìṣípayá, a rí Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba níbẹ̀, tó ń gun ẹṣin funfun kan tó sì ń ṣẹ́gun lọ. Bẹ́ẹ̀ làwọn ẹlẹ́ṣin mìíràn tí wọ́n dúró fún oríṣiríṣi ìyọnu tó máa bá ìran ènìyàn ń gẹṣin tẹ̀ lé e lẹ́yìn. Ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́ṣin náà gun ẹṣin aláwọ̀ iná. A sì yọ̀ǹda fún un pé kó “mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé kí wọ́n lè máa fikú pa ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì; a sì fún un ní idà ńlá kan.” (Ìṣípayá 6:1-4) Ẹṣin yìí pẹ̀lú ẹni tó gùn ún dúró fún ogun, idà ńlá tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ sì dúró fún bí ogun ayé ìsinsìnyí àtàwọn ohun ìjà olóró tí wọ́n ń lò ṣe ń pa àwọn èèyàn nípakúpa lọ́nà tá ò rírú rẹ̀ rí. Lára àwọn ohun ìjà wọ̀nyẹn làwọn ohun ìjà ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, àtàwọn ẹ̀rọ ajubọ́ǹbù tí wọ́n lè rán lọ síbi tó jìnnà tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà láti ju bọ́ǹbù, títí kan àwọn ohun ìjà oníkẹ́míkà àtàwọn ohun ìjà tó máa ń mú káwọn èèyàn ṣàìsàn, èyí tí wọ́n fi ń pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn.
À Ń Kọbi Ara Sáwọn Ìkìlọ̀ Jèhófà
9. Báwo ni ayé òde òní ṣe jọ ayé tó wà ṣáájú Ìkún Omi?
9 Nígbà ayé Nóà, Jèhófà pa àwọn èèyàn run torí ìwà ipá bíburú jáì táwọn olubi èèyàn àtàwọn Néfílímù ń hù. Òde òní wá ńkọ́? Ǹjẹ́ ìwà ipá inú ayé ìsinsìnyí dín kù sí tìgbà ayé Nóà? Rárá o! Láfikún sí i, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà làwọn èèyàn òde òní ṣe ń bá iṣẹ́ wọn ojoojúmọ́ lọ, tí wọ́n ń gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó tọ́ lójú ara wọn, tí wọn kò sì kọbi ara sí ìkìlọ̀ tí wọ́n ń gbọ́. (Lúùkù 17:26, 27) Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ ká ṣiyèméjì pé Jèhófà yóò tún pa àwọn ẹni ibi run? Ó tì o.
10. (a) Ìkìlọ̀ wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń sọ ní àsọtúnsọ? (b) Kí lohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ láti ṣe lónìí?
10 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú Ìkún Omi ni Énọ́kù ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò tiwa yìí. (Júúdà 14, 15) Jésù náà sọ̀rọ̀ nípa “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀. (Mátíù 24:21) Àwọn wòlíì mìíràn náà sì tún kìlọ̀ nípa àkókò yẹn. (Ìsíkíẹ́lì 38:18-23; Dáníẹ́lì 12:1; Jóẹ́lì 2:31, 32) Bákan náà la tún kà á nínú ìwé Ìṣípayá nípa bí ìparun ìkẹyìn yẹn ṣe máa ṣẹlẹ̀ gan-an. (Ìṣípayá 19:11-21) Àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń fara wé Nóà, a sì ń sa gbogbo ipá wa gẹ́gẹ́ bí oníwàásù òdodo. À ń kọbi ara sáwọn ìkìlọ̀ Jèhófà, a sì ń fìfẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe bákan náà. Fún ìdí yìí, à ń bá Ọlọ́run rìn bí Nóà ṣe bá a rìn. Láìsí àní-àní, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ wà láàyè máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó. Báwo la óò ṣe ṣèyẹn lójú gbogbo wàhálà tá à ń dojú kọ lójoojúmọ́? A ní láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára pé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe yóò ṣẹ.—Hébérù 11:6.
Máa Bá Ọlọ́run Rìn Nìṣó Láwọn Àkókò Hílàhílo Yìí
11. Ọ̀nà wo la gbà ń fara wé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?
11 Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn èèyàn máa ń sọ pé àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró jẹ́ ti “Ọ̀nà Náà.” (Ìṣe 9:2) Gbogbo ìgbésí ayé wọn ni wọ́n gbé ka ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Jésù Kristi. Wọ́n sì tẹ̀ lé ipasẹ̀ Ọ̀gá wọn. Bákan náà gẹ́lẹ́ làwọn Kristẹni olóòótọ́ ń ṣe lóde òní.
12. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu?
12 Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù jẹ́ ká mọ bí ìgbàgbọ́ ti ṣe pàtàkì tó. Ní àkókò kan, Jésù foúnjẹ bọ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin lọ́nà ìyanu. Ẹnu ya àwọn èèyàn náà, inú wọn sì dùn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà. A kà á pé: “Nígbà tí àwọn ènìyàn rí àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: ‘Dájúdájú, èyí ni wòlíì tí ń bọ̀ wá sí ayé.’ Nítorí náà, Jésù, ní mímọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun láti fi òun jẹ ọba, tún fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí òkè ńlá ní òun nìkan.” (Jòhánù 6:10-15) Òru ọjọ́ yẹn ló lọ́ sí ibòmíràn. Ó jọ pé bí Jésù ṣe kọ̀ láti jẹ ọba yìí kò dùn mọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn náà nínú. Ṣebí ó ti fi hàn pé òun lọ́gbọ́n tó láti jẹ́ ọba, àti pé gbogbo ìṣòro àwọn èèyàn lòun lágbára láti yanjú. Ṣùgbọ́n, kò tíì tó àsìkò tí Jèhófà fẹ́ kó di Ọba. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀run ni ibùjókòó Ìjọba Jésù, kì í ṣe ayé.
13, 14. Kí ni ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ sí, báwo la sì ṣe dán ìgbàgbọ́ wọn wò?
13 Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn èèyàn náà pinnu pé àwọn gbọ́dọ̀ wá Jésù rí. Ìwé Jòhánù sì sọ pé wọ́n rí i ní “òdì-kejì òkun.” Kí nìdí tí wọ́n fi ń wá Jésù kiri nígbà tó jẹ́ pé kò fẹ́ kí wọ́n fi òun jọba? Ohun tó ń da ọ̀pọ̀ wọn láàmú ni pé ojú ẹ̀dá èèyàn ni wọ́n fi ń wo ọ̀ràn náà, wọ́n ń tẹnu mọ́ àwọn nǹkan tara tí Jèhófà pèsè nínú aginjù nígbà ayé Mósè. Ohun tí wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ ni pé kí Jésù ṣáà máa pèsè oúnjẹ fáwọn ní gbogbo ìgbà. Jésù mọ ohun tí kò tọ́ tó wà lọ́kàn wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní àwọn ohun tó jẹ́ òtítọ́ tẹ̀mí tó lè mú kí wọ́n tún inú wọn rò. (Jòhánù 6:17, 24, 25, 30, 31, 35-40) Àmọ́, ńṣe làwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí i, pàápàá nígbà tó sọ àkàwé kan pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò ní ìyè kankan nínú ara yín. Ẹni tí ó bá ń fi ẹran ara mi ṣe oúnjẹ jẹ, tí ó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi ní ìyè àìnípẹ̀kun, èmi yóò sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”—Jòhánù 6:53, 54.
14 Àwọn àkàwé Jésù sábà máa ń mú káwọn èèyàn fi hàn bóyá wọ́n fẹ́ láti bá Ọlọ́run rìn lóòótọ́ tàbí wọn ò fẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni àkàwé rẹ̀ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ yìí ṣe rí. Ó mú káwọn èèyàn fi bí wọ́n ṣe jẹ́ hàn. A kà á pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wí pé: ‘Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?’” Ni Jésù bá ṣàlàyé pé ó yẹ kí ìtumọ̀ tẹ̀mí tí ọ̀rọ̀ òun ní yé wọn. Ó ní: “Ẹ̀mí ni ó ń fúnni ní ìyè; ẹran ara kò wúlò rárá. Àwọn àsọjáde tí mo ti sọ fún yín, ẹ̀mí ni wọ́n, ìyè sì ni wọ́n.” Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ò fẹ́ gbọ́yẹn rárá. Ìtàn náà sọ pé: “Ní tìtorí èyí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sídìí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, wọn kò sì jẹ́ bá a rìn mọ́.”—Jòhánù 6:60, 63, 66.
15. Èrò rere wo làwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní?
15 Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló ṣe bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, kì í ṣe pé òye ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn ò yẹ̀ nínú Jésù rárá. Pétérù, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn yìí sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára àwọn tí kò fi Jésù sílẹ̀, ó ní: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 6:68) Ẹ̀mí tí wọ́n fi hàn yìí má dára gan-an o, àpẹẹrẹ àtàtà gbáà lèyí sì jẹ́!
16. Àwọn nǹkan wo ló lè dán wa wò, irú ojú wo ló sì yẹ ká máa fi wo nǹkan?
16 Lóde òní, àwọn nǹkan kan lè dán wa wò lọ́nà tó jọ tàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìjímìjí yẹn. Ó lè má dùn mọ́ wa pé àwọn ìlérí Jèhófà ò tètè ṣẹ bá a ṣe fẹ́. A lè máa wò ó pé àlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àwọn ìwé wa tá a gbé karí Bíbélì ṣòro yéni. Ìwà tí ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni hù lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Ṣé ó dára ká wá torí ìwọ̀nyí tàbí àwọn ìdí mìíràn tó jọ ìyẹn ṣàìbá Ọlọ́run rìn mọ́? Àgbẹdọ̀! Ńṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kọ Jésù sílẹ̀ fi hàn pé ojú ẹ̀dá èèyàn làwọn fi wo ọ̀ràn. A gbọ́dọ̀ yẹra fún irú ìwà bẹ́ẹ̀.
“Àwa Kì Í Ṣe Irú Àwọn Tí Ń Fà Sẹ́yìn”
17. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó?
17 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Jèhófà ń lo ọ̀rọ̀ inú Bíbélì láti sọ fún wa ní kedere pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísáyà 30:21) Ṣíṣe ìgbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ‘máa ṣọ́ra lójú méjèèjì nípa bí a ṣe ń rìn.’ (Éfésù 5:15) Bí a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà, a ó máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 3) Bí Jésù ṣe sọ lọ́rọ̀ rí pé “ẹ̀mí ni ó ń fúnni ní ìyè; ẹran ara kò wúlò rárá.” Ìtọ́sọ́nà kan ṣoṣo tó ṣeé gbára lé, tá a lè máa fi tọ́ ìṣísẹ̀ wa ni ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí, èyí tá a máa ń rí nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Jèhófà, nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ àti nípasẹ̀ ètò rẹ̀.
18. (a) Kí làwọn kan ń ṣe tí kò bọ́gbọ́n mu? (b) Irú ìgbàgbọ́ wo ló yẹ ká ní?
18 Lóde òní, àwọn tó ń bínú nítorí pé wọ́n ń fi ojú ẹ̀dá èèyàn wo ọ̀ràn tàbí nítorí pé ibi tí wọ́n fojú sí kọ́ lọ̀nà gbà sábà máa ń padà lọ lo ayé yìí lẹ́kún-únrẹ́rẹ́. Nítorí pé wọ́n dẹra nù, wọn ò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà,” wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn nǹkan tó fẹ̀mí ìmọtara ẹni hàn dípò kí wọ́n fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò kìíní. (Mátíù 24:42) Ìwà òmùgọ̀ gbáà lèyí! Ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun, ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.” (Hébérù 10:39) Bíi ti Énọ́kù àti Nóà ni ọ̀rọ̀ tiwa náà ṣe rí, àkókò hílàhílo là ń gbé, àmọ́ a láǹfààní àtibá Ọlọ́run rìn bíi tiwọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fojú sọ́nà pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn ohun tí Jèhófà pinnu láti ṣe yóò ṣẹ, pé ìwà ibi yóò pa rẹ́ àti pé ayé tuntun níbi tí òdodo yóò wà máa dé. Ìrètí wa yìí mà ga lọ́lá o!
19. Báwo ni Míkà ṣe ṣàpèjúwe ipa ọ̀nà àwọn olùjọsìn tòótọ́?
19 Wòlíì Míkà tí Ọlọ́run mí sí sọ nípa àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè ayé pé wọn yóò “máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó wá sọ nípa ara rẹ̀ àtàwọn olóòótọ́ olùjọsìn yòókù pé: “Àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Míkà 4:5) Tó bá jẹ́ pé ohun tí Míkà ṣe ni ìwọ náà pinnu láti ṣe, má ṣe jáwọ́ nínú bíbá Jèhófà rìn bó ti wù kí hílàhílo ayé wa yìí pọ̀ tó. (Jákọ́bù 4:8) Ẹ jẹ́ kó jẹ́ ìfẹ́ àtọkànwá olúkúlùkù wa nísinsìnyí pé a óò máa bá Jèhófà Ọlọ́run wa rìn fún àkókò tó lọ kánrin, àní títí láé!
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni ọjọ́ Nóà àti ọjọ́ òní fi jọra?
• Ọ̀nà wo ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ tọ̀, báwo la sì ṣe lè fara wé ìgbàgbọ́ wọn?
• Èrò tí kò dára wo làwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní?
• Kí làwọn Kristẹni tòótọ́ pinnu láti ṣe?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Bíi ti ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ ṣe gba àwọn èèyàn lọ́kàn lóde òní
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Níwọ̀n bí a ti jẹ́ oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run, a “kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn”