Máa Bá a Lọ Ní Títẹ̀lé Ìṣísẹ̀ Jésù Kristi
“Ẹni tí ó bá sọ pé òun dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Ọlọ́run] wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe pẹ̀lú láti máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ẹni yẹn [Jésù] ti rìn.”—1 JÒHÁNÙ 2:6.
1, 2. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ máa tẹjú mọ́ Jésù?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa, bí a ti tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù.” (Hébérù 12:1, 2) Tá a bá fẹ́ máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó, a ní láti tẹjú mọ́ Jésù Kristi.
2 Ohun tí ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a tú sí “tẹjú mọ́” gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe lò ó nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì túmọ̀ sí ni pé “kéèyàn gbájú mọ́ nǹkan kan láìsí ìpínyà ọkàn,” tàbí “kéèyàn máa wo nǹkan kan láìgbójú kúrò lára rẹ̀ rárá,” tàbí “kéèyàn gbé ojú kúrò lára ohun kan kó bàa lè máa wo nǹkan míì.” Ìwé kan sọ pé: “Tí sárésáré ọmọ Gíríìkì kan tó ń sáré ní pápá ìṣeré bá bẹ̀rẹ̀ sí wo ibòmíì bó ṣe ń sáré lọ, tí kò fọkàn sí ìdí tó fi ń sáré, tó lọ ń wo àwọn òǹwòran, kò ní lè sáré dáadáa. Bí ọ̀rọ̀ àwa Kristẹni ṣe rí gan-an nìyẹn.” Tá a bá ní ìpínyà ọkàn, èyí lè ṣèdíwọ́ fún ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí. Torí náà, a ní láti máa tẹjú mọ́ Jésù Kristi. Àmọ́, kí ni ká máa wò lára Olórí Aṣojú yìí? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tá a tú sí “olórí aṣojú” túmọ̀ sí “aṣáájú pàtàkì, ìyẹn ẹni tó ń mú ipò iwájú nínú gbogbo nǹkan, tó sì ń fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn míì láti tẹ̀ lé.” Láti fi hàn pé à ń tẹjú mọ́ Jésù, a ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.
3, 4. (a) Kí ló yẹ ká máa ṣe tá a bá fẹ́ máa rìn bí Jésù Kristi ṣe rìn? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká ronú lé lórí?
3 Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá sọ pé òun dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Ọlọ́run] wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe pẹ̀lú láti máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ẹni yẹn [Jésù] ti rìn.” (1 Jòhánù 2:6) Èyí fi hàn pé a ní láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọ̀nà tá a sì lè gbà ṣe èyí ni pé ká máa pa àwọn òfin Jésù mọ́ bó ṣe pa àwọn òfin Baba rẹ̀ mọ́.—Jòhánù 15:10.
4 Nítorí náà, tá a bá fẹ́ máa rìn bí Jésù ṣe rìn, ó gba pé ká fara balẹ̀ máa wo Aṣáájú Pàtàkì yìí ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ohun gbogbo. Àwọn ìbéèrè pàtàkì tó wá yẹ ká gbé yẹ̀ wò lórí ọ̀rọ̀ yìí rèé: Báwo ni Kristi ṣe ń darí wa lónìí? Ipa wo ló yẹ kí títẹ̀lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ ní lórí wa? Àwọn àǹfààní wo la máa jẹ tá ò bá yà kúrò ní ipa ọ̀nà tí Jésù Kristi fi lélẹ̀ fún wa?
Bí Kristi Ṣe Ń Darí Àwọn Ọmọlẹ́yìn Rẹ̀
5. Kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ìlérí wo ló ṣe fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
5 Lẹ́yìn tí Jésù Kristi jíǹde, kó tó di pé ó gòkè re ọ̀run, ó fara han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sì gbé iṣẹ́ pàtàkì kan lé wọn lọ́wọ́. Ó ní: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Lákòókò kan náà, Aṣáájú Pàtàkì yìí tún ṣèlérí fún wọn pé òun yóò wà pẹ̀lú wọn bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà, ó ní: “Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:19, 20) Báwo ni Jésù Kristi ṣe wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìparí ètò àwọn nǹkan yìí?
6, 7. Báwo ni Jésù ṣe ń fi ẹ̀mí mímọ́ darí wa?
6 Jésù sọ pé: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.” (Jòhánù 14:26) Lónìí, ẹ̀mí mímọ́ tí Ọlọ́run rán ní orúkọ Jésù ń tọ́ wa sọ́nà, ó sì ń fún wa lókun. Ó ń là wá lóye nípa tẹ̀mí, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye “àní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 2:10) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ànímọ́ Ọlọ́run bíi “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu” jẹ́ “èso ti ẹ̀mí.” (Gálátíà 5:22, 23) Ẹ̀mí mímọ́ ló ń jẹ́ ká lè ní àwọn ànímọ́ wọ̀nyí.
7 Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ tá a sì ń gbìyànjú láti fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ ṣèwà hù, ẹ̀mí Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ọgbọ́n, ìfòyemọ̀, òye, ìmọ̀, ìdájọ́, àti agbára láti ronú. (Òwe 2:1-11) Ẹ̀mí mímọ́ tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìdẹwò àti àdánwò. (1 Kọ́ríńtì 10:13; 2 Kọ́ríńtì 4:7; Fílípì 4:13) Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “wẹ ara [wọn] mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí [wọ́n] máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ǹjẹ́ a lè tẹ̀ lé gbogbo òfin Ọlọ́run tó jẹ mọ́ ìwà mímọ́ láìjẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́? Ẹ̀mí mímọ́ wà lára ohun tí Jésù fi ń darí wa lónìí. Jèhófà ló sì fún Ọmọ rẹ̀ láṣẹ pé kó máa lò ó.—Mátíù 28:18.
8, 9. Báwo ni Kristi ṣe ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti darí ìjọ?
8 Tún wo ọ̀nà mìíràn tí Kristi gbà ń darí ìjọ lónìí. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ìparí ètò àwọn nǹkan, ó ní: “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu? Aláyọ̀ ni ẹrú náà bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé, bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Òun yóò yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.”—Mátíù 24:3, 45-47.
9 Jésù Kristi ni “ọ̀gá” yìí. Gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lápapọ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé sì ni “ẹrú” yẹn. Iṣẹ́ tí Jésù gbé lé ẹgbẹ́ ẹrú yìí lọ́wọ́ ni pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn ohun tó jẹ́ ti Jésù lórí ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lákòókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. Àwọn alábòójútó mélòó kan tó tóótun lára ẹgbẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ló para pọ̀ di Ìgbìmọ̀ Olùdarí, àwọn ló sì ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ẹrú yìí. Wọ́n ń darí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé, wọ́n sì tún ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tó yẹ. Nípa báyìí, Kristi ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú fún ẹrú yìí láti darí ìjọ.
10. Báwo ló ṣe yẹ ká máa hùwà sáwọn alàgbà, kí sì nìdí rẹ̀?
10 Kò tán síbẹ̀ o, Kristi tún ń lo “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” ìyẹn àwọn alàgbà tàbí alábòójútó láti darí ìjọ. Ó fi wọ́n fúnni “láti lè ṣe ìtọ́sọ́nàpadà àwọn ẹni mímọ́, fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, fún gbígbé ara Kristi ró.” (Éfésù 4:8, 11, 12) Hébérù orí kẹtàlá ẹsẹ ìkeje sọ nípa wọn pé: “Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.” Àwọn alàgbà ló ń mú ipò iwájú nínú ìjọ. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé àpẹẹrẹ Kristi Jésù ni wọ́n ń tẹ̀ lé, ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn. (1 Kọ́ríńtì 11:1) Tá a bá ń ṣègbọràn sí àwọn alàgbà tá a sì ń tẹrí ba fún “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” yìí, ìyẹn á fi hàn pé a mọyì wọn.—Hébérù 13:17.
11. Àwọn ọ̀nà wo ni Kristi gbà ń darí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lónìí, kí ló sì yẹ ká ṣe ká lè máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀?
11 Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀mí mímọ́, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àtàwọn alàgbà ìjọ ni Jésù Kristi ń lò láti darí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lónìí. Ká tó lè máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Kristi, a ní láti lóye ọ̀nà tó gbà ń darí wa ká sì fi ara wa sábẹ́ ètò náà. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ní láti máa tẹ̀ lé ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Ipa wo ló yẹ kí títẹ̀lé àpẹẹrẹ pípé tí Jésù fi lélẹ̀ ní lórí wa?
Máa Fi Òye Lo Ọlá Àṣẹ Tó O Ní
12. Àpẹẹrẹ wo ni Kristi fi lélẹ̀ tó yẹ káwọn alàgbà máa tẹ̀ lé?
12 Bo tilẹ̀ jẹ́ pé ọlá àṣẹ tí Jèhófà fún Jésù ju ti ẹnikẹ́ni lọ, síbẹ̀ kò ṣàṣejù nínú bó ṣe lò ó, ńṣe ló fòye lò ó. Torí náà, ó yẹ kí gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ, pàápàá àwọn alábòójútó, jẹ́ kí ‘ìfòyebánilò wa di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.’ (Fílípì 4:5; 1 Tímótì 3:2, 3) Níwọ̀n bí àwọn alàgbà ti ní ọlá àṣẹ dé ìwọ̀n àyè kan nínú ìjọ, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa tẹ̀ lẹ́ àpẹẹrẹ Kristi nínú bí wọ́n ṣe ń lò ó.
13, 14. Ọ̀nà wo làwọn alàgbà lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi bí wọ́n ṣe ń fún àwọn ẹlòmíì níṣìírí láti sin Ọlọ́run?
13 Jésù mọ ìkùdíẹ̀-káàtó àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, òye yẹn ló sì fi ń bá wọn lò. Kò ní kí wọ́n ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ. (Jòhánù 16:12) Jésù ò fagídí mú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti “tiraka tokuntokun” nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ńṣe ló gbà wọ́n níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 13:24) Ó sì ṣe èyí nípa fífi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wọn àti nípa sísọ ọ̀rọ̀ ìṣírí fún wọn tó ń mú kí wọ́n máa ṣe nǹkan látọkànwá. Bákan náà lónìí, àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni kì í sọ ọ̀rọ̀ tó lè kó ìtìjú bá àwọn ará débi pé ẹ̀rí ọkàn wọn á máa dà wọ́n láàmú bí wọ́n ṣe ń sin Ọlọ́run. Dípò ìyẹn, ńṣe ni wọ́n máa ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa sin Jèhófà nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí òun àti Jésù àtàwọn ọmọnìkejì wọn.—Mátíù 22:37-39.
14 Jésù ò ṣi ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún un lò, kó wá máa darí àwọn èèyàn bó ṣe wù ú. Kò gbé ìlànà tó ṣòro fáwọn èèyàn láti tẹ̀ lé kalẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣòfin má-ṣu-má-tọ̀ fún wọn. Ńṣe ló máa ń ṣàlàyé àwọn ìlànà tó wà nínú Òfin Mósè láti fi mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dénú ọkàn àwọn èèyàn kí wọ́n lè túbọ̀ fẹ́ràn ṣíṣe ohun tó dara. (Mátíù 5:27, 28) Àwọn alàgbà máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi, wọ́n kì í gbé òfin ti ara wọn kalẹ̀ tàbí kí wọ́n máa rin kinkin mọ́ èrò ti ara wọn. Tó bá sì dọ̀rọ̀ aṣọ wíwọ̀ àti ìmúra tàbí eré àṣenajú àti fàájì, wọ́n máa ń gbìyànjú láti sọ ọ̀rọ̀ tó máa wọ àwọn ará lọ́kàn nípa lílo àwọn ìlànà Ọlọ́run, irú èyí tó wà nínú Míkà 6:8, 1 Kọ́ríńtì 10:31-33 àti 1 Tímótì 2:9, 10.
Ní Ẹ̀mí Ìgbatẹnirò àti Ẹ̀mí Ìdáríjini
15. Kí ni Jésù ṣe nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe àwọn ohun tó kù díẹ̀ káàtó?
15 Kristi fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún wa nínú ọ̀nà tó gbà bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò nígbà tí wọ́n bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó. Ẹ jẹ́ ká wo ìṣẹ̀lẹ̀ méjì kan tó wáyé lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Nígbà tí Jésù dénú ọgbà Gẹtisémánì, ó “mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù lọ pẹ̀lú rẹ̀,” ó sì sọ fún wọn pé ‘kí wọ́n máa ṣọ́nà.’ Lẹ́yìn ìyẹn, “bí ó sì ti lọ síwájú díẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀, ó sì ń gbàdúrà.” Nígbà tó fi máa padà sọ́dọ̀ wọn, “ó . . . bá wọn tí wọ́n ń sùn.” Kí ni Jésù ṣe? Ó ní: “Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.” (Máàkù 14:32-38) Dípò tí Jésù á fi sọ̀rọ̀ sí Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù, ṣe ló káàánú wọn! Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù rí. (Máàkù 14:66-72) Kí ni Jésù ṣe fún Pétérù lẹ́yìn ìyẹn? Bíbélì sọ pé: “A gbé Olúwa dìde, ó sì fara han Símónì [Pétérù].” (Lúùkù 24:34) Bíbélì tún sọ pé: “Ó fara han Kéfà, lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà.” (1 Kọ́ríńtì 15:5) Jésù ò di àpọ́sítélì Pétérù sínú, dípò ìyẹn ńṣe ló dárí jì í nítorí pé ó ti ronú pìwà dà, ó sì tún fún un lókun. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jésù gbé àwọn iṣẹ́ ńlá kan lé Pétérù lọ́wọ́.—Ìṣe 2:14; 8:14-17; 10:44, 45.
16. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù nígbà tí ẹnì kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá ṣe ohun tó bí wa nínú tàbí tó ṣẹ̀ wá?
16 Nígbà táwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá ṣe ohun kan tó bí wa nínú tàbí tí wọ́n ṣẹ̀ wá nítorí àìpé tá a ti jogún, ǹjẹ́ kò yẹ ká káàánú wọn ká sì dárí jì wọ́n bíi ti Jésù? Pétérù gba àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ níyànjú pé: “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú, kí ẹ má ṣe máa fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe tàbí ìkẹ́gàn san ìkẹ́gàn, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre.” (1 Pétérù 3:8, 9) Ká lẹ́nì kan ò wá lo irú ẹ̀mí tí Jésù ní yìí láti fi bá wa lò ńkọ́, tí kò gba tiwa rò tàbí tó lóun ò dárí jì wá? Síbẹ̀ náà, a ṣì gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ká sì ṣe ohun tí Jésù ì bá ṣe ká lóun ló wà nírú ipò yẹn.—1 Jòhánù 3:16.
Máa Fi Ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run Ṣáájú Nígbèésí Ayé Rẹ
17. Kí ló fi hàn pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni Jésù fi ṣáájú nígbèésí ayé rẹ̀?
17 Ọ̀nà mìíràn ṣì tún wà tá a lè gbà tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù Kristi. Iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé Jésù. Lẹ́yìn tó wàásù fún obìnrin ará Samáríà kan nítòsí ìlú Síkárì ní Samáríà, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 4:34) Ṣíṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ ló ń gbé ẹ̀mí Jésù rò, bí oúnjẹ tó ń ṣara lóore tó sì ń gbádùn mọ́ni ló rí fún un. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa fífi ìfẹ́ Ọlọ́run ṣáájú nínú ayé wa, ǹjẹ́ ìgbésí ayé wa ò ní nítumọ̀ kí ayé wa sì dára?
18. Àwọn ìbùkún wo ló wà nínú gbígba àwọn ọmọ ẹni níyànjú láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún?
18 Táwọn òbí bá gba àwọn ọmọ wọn níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún, àwọn àtàwọn ọmọ wọn ló máa jọ jèrè rẹ̀. Láti kékeré ni bàbá ìbejì kan ti ń gba àwọn ọmọ náà níyànjú pé kí wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n bá dàgbà. Lẹ́yìn táwọn ọmọkùnrin ìbejì náà parí ilé ìwé, àwọn méjèèjì di aṣáájú ọ̀nà lóòótọ́. Nígbà tí bàbá wọn ronú nípa ayọ̀ tó ti rí bí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ó kọ̀wé pé: “Àwọn ọmọ wa ò já wa kulẹ̀ rárá. A lè fi ìdùnnú sọ ọ́ pé, ‘Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’” (Sáàmù 127:3) Àmọ́, báwo làwọn ọmọ ṣe ń jàǹfààní ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún? Obìnrin kan tó lọ́mọ márùn-ún sọ pé: “Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ti jẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ mi túbọ̀ ní àjọṣe tó ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó ti jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ máa dá kẹ́kọ̀ọ́, ó ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n lo àkókò wọn, ó sì ti jẹ́ kí wọ́n fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú nígbèésí ayé wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wọn ló ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nígbèésí ayé wọn, kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó kábàámọ̀ ṣíṣe tí wọ́n ń ṣe aṣáájú ọ̀nà.”
19. Kí làwọn ohun tó bọ́gbọ́n mu tó yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa ronú àtiṣe lọ́jọ́ iwájú?
19 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, kí lẹ̀ ń ronú àtiṣe lọ́jọ́ iwájú? Ṣé bẹ́ ẹ ṣe máa ta yọ nínú àwọn iṣẹ́ kan lẹ̀ ń lé ni? Àbí bẹ́ ẹ ṣe máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún? Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ní tìtorí èyí, ẹ ṣíwọ́ dídi aláìlọ́gbọ́n-nínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.”—Éfésù 5:15-17.
Jẹ́ Adúróṣinṣin
20, 21. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ adúróṣinṣin, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin rẹ̀?
20 Ká lè máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ adúróṣinṣin bíi tirẹ̀. Lórí ọ̀rọ̀ ìdúróṣinṣin Jésù, Bíbélì sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run, kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba. Ó tì o, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn. Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” Jésù fara mọ́ ọn délẹ̀délẹ̀ pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ, ó sì fi èyí hàn nípa fífara mọ́ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí i. Ó ṣègbọràn débi pé ó kú lórí òpó igi oró. Ó yẹ ká “pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́,” ká sì máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo.—Fílípì 2:5-8.
21 Jésù tún jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní kùdìẹ̀-kudiẹ tiwọn, tí wọ́n sì jẹ́ aláìpé, síbẹ̀ Jésù nífẹ̀ẹ́ wọn “dé òpin.” (Jòhánù 13:1) Bákan náà, kò yẹ ká jẹ́ kí àìpé àwọn arákùnrin wa mú ká bẹ̀rẹ̀ sí ṣàríwísí wọn.
Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Nígbà Gbogbo
22, 23. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nígbà gbogbo, àwọn àǹfààní wo la máa jẹ?
22 Torí pé aláìpé ni wá, kò sí bá a ṣe lè tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Ẹni pípé tó fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lélẹ̀ fún wa tá ò ní máa kọsẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, a lè gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. Ká sì tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti lóye ètò tí Kristi ṣe láti máa darí wa, ká fi ara wa sábẹ́ ètò náà, ká sì tún máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nígbà gbogbo.
23 Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, ọ̀pọ̀ ìbùkún la óò rí gbà. Ìgbésí ayé wa yóò túbọ̀ nítumọ̀, ayé wa yóò sì túbọ̀ dára nítorí pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló jẹ wá lógún dípò ìfẹ́ ti ara wa. (Jòhánù 5:30; 6:38) Ẹ̀rí ọkàn wa á mọ́, a ó sì jẹ́ àwòkọ́ṣe fáwọn ẹlòmíràn. Jésù pe gbogbo àwọn tó ń ṣe làálàá, tí wọ́n sì ti di ẹrù wọ̀ lọ́rùn pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ òun kí wọ́n sì rí ìtura fún ọkàn wọn. (Mátíù 11:28-30) Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, àwa náà yóò jẹ́ orísun ìtura fáwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká dẹ́kun títẹ̀lé ìṣísẹ̀ Jésù.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo ni Kristi ṣe ń darí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lónìí?
• Báwo làwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi nínú bí wọ́n ṣe ń lo ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn?
• Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nígbà táwọn ẹlòmíì bá ṣe ohun tó bí wa nínú?
• Ọ̀nà wo làwọn èwe lè gbà fi ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú nígbèésí ayé wọn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn alàgbà ìjọ ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìdarí Kristi
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Kristẹni, kí lẹ̀ ń ronú àtiṣe kí ìgbésí ayé yín lè dára?