Tó O Bá Wà Nípò Àṣẹ, Máa Fara Wé Kristi
NÍ ÀWỌN ẹ̀wádún mélòó kan sẹ́yìn, àyẹ̀wò kan tí wọ́n ṣe nípa ìhùwàsí ẹ̀dá gbé àbájáde kan tó jọni lójú jáde. Wọ́n pín àwọn tó kópa nínú àyẹ̀wò náà sí àwùjọ méjì. Àwùjọ àkọ́kọ́ jẹ́ ẹ̀ṣọ́, wọ́n sì ní kí wọ́n máa ṣọ́ àwùjọ kejì tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n. Kí wá ni àbájáde àyẹ̀wò náà?
Ìròyìn náà sọ pé: “Láàárín ọjọ́ díẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn [ẹ̀ṣọ́ náà] ti dẹni tí ń tàbùkù àwọn tí wọ́n fi sábẹ́ wọn, wọ́n sì ti di òǹrorò èèyàn, tí wọ́n ń fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà nígbà gbogbo, tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní tiwọn sì wá di ojo àti dọ̀bọ̀sìyẹsà.” Ohun táwọn tó wà nídìí àyẹ̀wò náà wá sọ níkẹyìn ni pé: Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sẹ́ni tí àṣẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ tí kò ní lò ó nílòkulò.
Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Lo Ipò Àṣẹ àti Ọ̀nà Tí Kò Tọ́
Ó dájú pé lílo àṣẹ ẹni lọ́nà tó dára máa ń ṣàǹfààní. Ó lè mú kí àwọn tó wà lábẹ́ ẹni rí ìtọ́sọ́nà rere ó sì lè ṣe wọ́n láǹfààní nípa ti ara, ti èrò inú àti tẹ̀mí. (Òwe 1:5; Aísáyà 48:17, 18) Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àyẹ̀wò tá a sọ níṣàájú yẹn ti fi hàn, ìgbà gbogbo làwọn èèyàn tí àṣẹ wà níkàáwọ́ wọn lè lo àṣẹ náà nílòkulò. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ewu yìí, ó ní: “Nígbà tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn a máa mí ìmí ẹ̀dùn.”—Òwe 29:2; Oníwàásù 8:9.
Lílo àṣẹ ẹni nílòkulò léwu gan-an, àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dára léèyàn ní lọ́kàn tó fi ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ilé ẹ̀kọ́ ìsìn kan lórílẹ̀-èdè Ireland tọrọ àforíjì ní gbangba nítorí ọ̀nà tí kò dára táwọn kan lára àwọn olùkọ́ ibẹ̀ gbà lo àṣẹ lórí àwọn ọmọ tí wọ́n fi síkàáwọ́ wọn. Kò sí àní-àní pé ńṣe làwọn olùkọ́ yẹn fẹ́ kó dára fáwọn ọmọ náà, àmọ́ ọ̀nà táwọn kan lára wọn gbà ṣe é fa ìpalára púpọ̀. Ìwé ìròyìn kan sọ pé “ọ̀pọ̀ ọmọ ni wọ́n kó ìbànújẹ́ ńláǹlà bá nítorí ìwà ìkà àti ọwọ́ líle táwọn olùkọ́ yẹn fi mú àwọn ọmọ náà.” (Ìwé ìròyìn The Irish Times) Ọ̀nà wo lo lè gbà lo àṣẹ tó wà níkàáwọ́ rẹ láti fi mú káwọn èèyàn máa ṣe dáadáa dípò kí wọ́n máa sá fún ọ, tàbí kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ máa bà wọ́n nínú jẹ́?—Òwe 12:18.
“Gbogbo Ọlá Àṣẹ” Ni A Ti Fún Jésù Kristi
Gbé àpẹẹrẹ Jésù Kristi yẹ̀ wò. Kété kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 28:18) Ǹjẹ́ gbólóhùn yẹn kó ìpayà bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? Ǹjẹ́ wọ́n rò pé Jésù yóò máa ṣe bíi tàwọn Késárì ilẹ̀ Róòmù, tí gbogbo èèyàn mọ̀ wọ́n sẹ́ni tó máa ń fipá tẹ àwọn èèyàn lórí ba, ìyẹn àwọn tó bá ta ko ìjọba tàbí àwọn tó ń ṣọ̀tẹ̀ síjọba?
Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ọ̀rọ̀ ti Jésù kò rí bẹ́ẹ̀ o! Ọ̀nà tí Bàbá rẹ̀ gbà ń lo àṣẹ ni Jésù Kristi gbà lò ó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Olódùmarè àti Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run tí kò sì sẹ́ni tó lè bá a dù ú, síbẹ̀ iṣẹ́ ìsìn àtọkànwá ló fẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀, kò fẹ́ ìgbọràn tí kò tọkàn wọn wá tàbí tí wọ́n á máa gbọ̀n jìnnìjìnnì ṣe. (Mátíù 22:37) Jèhófà kò ṣi ọlá àṣẹ rẹ̀ lò rí. Àgbàyanu ìran tí Ọlọ́run fi han wòlíì Ísíkíẹ́lì fi èyí hàn.
Nínú ìran náà, Ísíkíẹ́lì rí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n ń gbé ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run ga. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin. Ísíkíẹ́lì kọ̀wé pé: “Ní ti ìrí ojú wọn, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú ènìyàn pẹ̀lú ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì ní ojú akọ màlúù ní ìhà òsì; àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tún ní ojú idì.” (Ísíkíẹ́lì 1:10) Àwọn ojú mẹ́rin wọ̀nyí dúró fáwọn ànímọ́ pàtàkì mẹ́rin tí Ọlọ́run ní, àwọn ànímọ́ náà sì jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ni. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pe àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ni: ìfẹ́, tí ojú èèyàn ń ṣàpẹẹrẹ rẹ̀; ìdájọ́ òdodo, tí ojú kìnnìún ń ṣàpẹẹrẹ rẹ̀; àti ọgbọ́n, tí ojú idì ń ṣàpẹẹrẹ rẹ̀. Àwọn ànímọ́ mẹ́ta yìí ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀kẹrin, ìyẹn agbára, tí ojú akọ màlúù ṣàpẹẹrẹ rẹ̀. Kí ni gbogbo èyí túmọ̀ sí? Ìran yìí fi hàn pé Jèhófà kì í lo agbára rẹ̀ tó bùáyà àti àṣẹ rẹ̀ lọ́nà tí kò bá àwọn ànímọ́ pàtàkì yòókù tó ní mu.
Ìgbà gbogbo ni Jésù Kristi ń fara wé Bàbá rẹ̀ nínú bó ṣe ń lo àṣẹ rẹ̀ lọ́nà tó bá ìfẹ́, ọgbọ́n, àti ìdájọ́ òdodo mu délẹ̀délẹ̀. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí ìtura ńláǹlà bí wọ́n ti ń sìn lábẹ́ àṣẹ rẹ̀. (Mátíù 11:28-30) Ìfẹ́ ni ànímọ́ pàtàkì tá a fi dá Jèhófà àti Jésù mọ̀ jù lọ, kì í ṣe agbára tàbí àṣẹ!—1 Kọ́ríńtì 13:13; 1 Jòhánù 4:8.
Báwo Lo Ṣe Máa Ń Lo Àṣẹ Tó Wà Níkàáwọ́ Rẹ?
Báwo ló ṣe ń ṣe sí nínú ọ̀ràn yìí? Bí àpẹẹrẹ, ṣé bó ṣe wù ọ́ lo ṣe máa ń lo àṣẹ tó wà níkàáwọ́ rẹ nígbà tó o bá ń darí ìdílé rẹ? Ṣé nítorí ìbẹ̀rù làwọn tó wà nínú ìdílé rẹ ṣe máa ń fara mọ́ ìpinnu rẹ àbí nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ? Ṣé nítorí pé o lágbára jù wọ́n lọ ni ìdílé rẹ ṣe máa ń ṣègbọràn sí ọ? Ó yẹ káwọn olórí ìdílé gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò kí wọ́n bàa lè máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run nínú ìdílé wọn.—1 Kọ́ríńtì 11:3.
Bó o bá wà nípò àṣẹ nínú ìjọ Kristẹni ńkọ́? Láti mọ̀ bóyá ò ń lo àṣẹ tó wà níkàáwọ́ rẹ lọ́nà tó dára, ó yẹ kó o bi ara rẹ léèrè bóyá ò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nísàlẹ̀ yìí, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run mí sí, tí Jésù Kristi sì fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lélẹ̀.
“Kí ẹrú Olúwa . . . jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, . . . tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi, kí ó máa fún àwọn tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere ní ìtọ́ni pẹ̀lú ìwà tútù.”—2 Tímótì 2:24, 25.
Àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni ìjímìjí wà nípò tí wọ́n fi lè pàṣẹ fún àwọn mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, Tímótì tiẹ̀ lè “pàṣẹ fún àwọn kan láti má ṣe fi ẹ̀kọ́ tí ó yàtọ̀ kọ́ni.” (1 Tímótì 1:3) Síbẹ̀, ó dá wa lójú pé Tímótì fi ànímọ́ Ọlọ́run hàn nínú gbogbo ohun tó ṣe, kò sì sí àní-àní pé ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún un pé kó máa kọ́ni “pẹ̀lú ìwà tútù” kó sì “jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn” nínú bó ṣe ń bójú tó ìjọ Kristẹni. Nítorí pé ó kéré sáwọn alàgbà mìíràn, ó ní láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn àgbà kó sì máa ṣe bí ẹ̀gbọ́n tó nífẹ̀ẹ́ sáwọn tó kéré sí i lọ́jọ́ orí. (1 Tímótì 5:1, 2) Nígbà tí irú ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ bá wà, ẹ̀mí ọ̀yàyà àti ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín ìdílé yóò wà nínú ìjọ Kristẹni, kò ní jẹ́ ẹ̀mí àìnífẹ̀ẹ́ àti ti òǹrorò tó máa ń wà níbi iṣẹ́ ajé.—1 Kọ́ríńtì 4:14; 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.
“Àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ènìyàn ńlá a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn. Báyìí kọ́ ni láàárín yín; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín.”—Mátíù 20:25, 26.
Àwọn alágbára nínú ayé máa ń “jẹ olúwa lé [àwọn èèyàn] lórí” nípa mímú àwọn èèyàn lọ́ranyàn pé kí wọ́n tẹ̀ lé ohun táwọn fẹ́. Wọ́n tún máa ń sọ pé kí wọ́n ṣe nǹkan lọ́nà táwọn fẹ́ àti pé tí wọn ò bá ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn á fìyà jẹ wọ́n. Àmọ́ ohun tí Jésù Kristi sọ pé ó ṣe kókó ni pé ká máa lo ara wa fáwọn èèyàn dípò ká máa ni wọ́n lára. (Mátíù 20:27, 28) Kò sígbà tí Jésù kì í fìfẹ́ bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Tó o bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, yóò túbọ̀ rọrùn fáwọn mìíràn láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ. (Hébérù 13:7, 17) Bákan náà, yóò túbọ̀ rọrùn fáwọn ẹlòmíràn láti tẹ̀ lé àṣẹ rẹ, àní tí wọ́n á tún ṣe ju ohun tó o fẹ́ kí wọ́n ṣe lọ. Gbogbo ọkàn wọn ni wọ́n á sì fi ṣe é, kò ní jẹ́ tipátipá.—Mátíù 5:41.
“Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe . . . bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.”—1 Pétérù 5:2, 3.
Àwọn alábòójútó lónìí mọ̀ pé àwọn yóò jíhìn fún Ọlọ́run lórí bí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ṣe ń ṣe sí nípa tẹ̀mí. Ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n fi mú iṣẹ́ tó wà níkàáwọ́ wọn yìí. Wọ́n ń bójú tó agbo Ọlọ́run tọkàntọkàn, pẹ̀lú ìtara, àti tìfẹ́tìfẹ́. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti mú kí ìgbàgbọ́ àwọn tí wọ́n ń bójú tó lágbára, wọn kò sì jẹ ọ̀gá lé ìgbàgbọ́ wọn lórí.—2 Kọ́ríńtì 1:24.
Nígbà tó bá pọn dandan láti fúnni nímọ̀ràn tó yẹ, àwọn alàgbà máa ń fi ẹ̀mí tútù tọ́ àwọn tó bá ṣàṣìṣe sọ́nà, wọ́n sì tún máa ń ran àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ ìránnilétí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ sọ́kàn pé: “Ẹ̀yin ará, bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù, bí olúkúlùkù yín ti ń ṣọ́ ara rẹ̀ lójú méjèèjì, kí a má bàa dẹ ìwọ náà wò.”—Gálátíà 6:1; Hébérù 6:1, 9-12.
“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà . . . Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:13, 14.
Kí lo máa ṣe tí ẹnì kan ò bá tẹ̀ lé ìlànà Kristẹni délẹ̀délẹ̀? Ǹjẹ́ ó máa ń ro ti jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ aláìpé gẹ́gẹ́ bí Jèhófà àti Jésù Kristi ti máa ń ṣe? (Aísáyà 42:2-4) Àbí ńṣe lo máa ń rin kinkin mọ́ òfin ju bó ṣe yẹ lọ nínú gbogbo ọ̀ràn? (Sáàmù 130:3) Rántí pé ó dára láti fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́ mú nǹkan níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ká má sì gba gbẹ̀rẹ́ fóhun tí kò dáa. Fífi ìfẹ́ ṣe gbogbo ohun tó o bá ń ṣe á jẹ́ kí ìwọ àtàwọn tó wà lábẹ́ àṣẹ rẹ lè fọkàn tán ara yín kẹ́ ẹ sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara yín.
Bí wọ́n bá gbé àṣẹ lé ọ lọ́wọ́, sa gbogbo ipá rẹ̀ láti fara wé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi nínú bí wàá ṣe máa lo àṣẹ náà. Rántí ọ̀nà àgbàyanu tí onísáàmù gbà ṣàpèjúwe ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń lo àṣẹ rẹ̀ lórí àwọn èèyàn rẹ̀. Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan. Ó ń mú mi dùbúlẹ̀ ní pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko; ó ń darí mi lẹ́bàá àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa. Ó ń tu ọkàn mi lára. Ó ń ṣamọ̀nà mi ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.” Bákan náà, a tún kà nípa Jésù pé: “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà, mo sì mọ àwọn àgùntàn mi, àwọn àgùntàn mi sì mọ̀ mí, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí mo sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.” Ǹjẹ́ àwọn àpẹẹrẹ rere mìíràn wà tó tún lè dára ju ìwọ̀nyí lọ tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ká máa fìfẹ́ lo àṣẹ?—Sáàmù 23:1-3; John 10:14, 15.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 18]
Jèhófà máa ń fi ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́ hàn nígbà tó bá ń lo agbára rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Nígbà mìíràn, àwọn alàgbà ní láti fún àwọn tó ṣàṣìṣe ní ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Pọ́ọ̀lù fún Tímótì nímọ̀ràn láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn àgbà kó sì máa ṣe bí ẹ̀gbọ́n tó nífẹ̀ẹ́ sáwọn tó kéré sí i
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Jésù Kristi máa ń fi ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ hàn nígbà tó bá ń lo àṣẹ rẹ̀