Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Bí ẹ̀mí èṣù bá ń da ẹnì kan láàmú, kí ni ẹni náà lè ṣe láti bọ́ lọ́wọ́ wọn?
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń pọ́n lójú lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ kí ẹ̀mí èṣù fi àwọn sílẹ̀, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa gbàdúrà. (Máàkù 9:25-29) Àmọ́, àwọn ohun pàtàkì mìíràn tún wà tí ẹni tí ẹ̀mí èṣù ń dà láàmú ní láti ṣe. Ìtàn àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní fi ohun tó tún yẹ kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe hàn.
Àwọn kan ní Éfésù ìgbàanì ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò kí wọ́n tó di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí wọ́n pinnu pé Ọlọ́run làwọn fẹ́ máa sìn, “àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn.” (Ìṣe 19:19) Bí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ní Éfésù ṣe dáná sun àwọn ìwé idán wọn jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀mí èṣù lóde òní. Wọ́n ní láti kó gbogbo nǹkan tó bá jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò dà nù tàbí kí wọ́n dáná sun wọ́n. Ì báà jẹ́ ìwé ńlá, ìwé ìròyìn, fíìmù, orin tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò, àwọn ohun tí wọ́n tẹ̀ jáde látinú Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ mìíràn, ìfúnpá, ońdè, òòka ẹ̀rẹ, owó ẹyọ, tírà tàbí àwọn nǹkan míì tí wọ́n ń fi sára tí wọ́n gbà gbọ́ pé ó lè dáàbò bò àwọn.—Diutarónómì 7:25, 26; 1 Kọ́ríńtì 10:21.
Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn táwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ti dáná sun gbogbo ìwé idán wọn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn pé: “Àwa ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú.” (Éfésù 6:12) Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11) Ìmọ̀ràn yẹn ṣì wúlò lónìí. Àwọn Kristẹni ní láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára gan-an kí ọwọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù má bàa tẹ̀ wọ́n. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí ẹ ó lè fi paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà.” (Éfésù 6:16) Béèyàn sì ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára sí i ni pé kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Róòmù 10:17; Kólósè 2:6, 7) Torí náà, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ìgbàgbọ́ wa yóò lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ táwọn ẹ̀mí èṣù ò fi ní lè rí wa gbéṣe.—Sáàmù 91:4; 1 Jòhánù 5:5.
Síbẹ̀, ohun pàtàkì mìíràn tún wà táwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ní láti ṣe. Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Pẹ̀lú gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ . . . ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.” (Éfésù 6:18) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn tó bá fẹ́ kí ẹ̀mí èṣù dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn lóde òní ní láti máa gbàdúrà tọkàntọkàn pé kí Jèhófà dáàbò bo àwọn. (Òwe 18:10; Mátíù 6:13; 1 Jòhánù 5:18, 19) Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Jákọ́bù 4:7.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ẹni tí àwọn ẹ̀mí èṣù ń dà láàmú máa fi tọkàntọkàn gbàdúrà kó lè bọ́ lọ́wọ́ wọn, síbẹ̀ àwọn Kristẹni tòótọ́ yòókù lè máa bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbàdúrà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo ọkàn ni onítọ̀hún fẹ́ fi sin Jèhófà, tó sì ń sapá lójú méjèèjì láti dènà àwọn ẹ̀mí èṣù. Wọ́n lè máa bá a gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún un ní okun nípa tẹ̀mí tó máa lè fi gbéjà ko àwọn ẹ̀mí èṣù. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé “ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo, nígbà tí ó bá wà lẹ́nu iṣẹ́, ní ipá púpọ̀.” Torí náà, àdúrà tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá ń gbà yóò ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń dà láàmù tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti “kọ ojú ìjà sí Èṣù.”—Jákọ́bù 5:16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn tó di onígbàgbọ́ ní Éfésù dáná sun gbogbo ìwé idán wọn