Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí nígbà tó o kà wọ́n? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó mú kí ìwà ibi pọ̀ gan-an lónìí?
Ọ̀kan lára àwọn ohun tó fà á ni pé ohun búburú lọkàn àwọn èèyàn máa ń fà sí. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Ohun mìíràn ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò ní ìmọ̀ pípéye nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, Sátánì, ẹni tó pilẹ̀ ibi ò yéé dá sí ọ̀rọ̀ aráyé.—1/1, ojú ìwé 4 sí 6.
• Àwọn àǹfààní wo ló lè jẹ yọ tá a bá sọ ọ̀rọ̀ rere tó bọ́ sákòókò? (Òwe 12:25)
Ó lè jẹ́ kẹ́ni tá a yìn túbọ̀ dáńgájíá, ó lè mú kẹ́ni náà fẹ́ láti ṣèmíì, ó tún lè mú kó mọ̀ pé àwọn èèyàn ka òun sí. Àti pé, tá a bá ń fẹ́ láti máa yin àwọn èèyàn, àá lè máa rí ànímọ́ rere tí wọ́n ní.—1/1, ojú ìwé 16 àti 17.
• Kí ló wà nínú àpótí májẹ̀mú?
Wàláà òkúta méjì tí wọ́n kọ Òfin Mósè sí àti mánà díẹ̀ ló wà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ Kórà, wọ́n fi ọ̀pá Áárónì sínú àpótí náà láti fi ṣe ẹ̀rí pé ohun tí ìran ọlọ̀tẹ̀ náà ṣe kò dára. (Hébérù 9:4) Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti kó ọ̀pá yẹn àti mánà náà kúrò nínú Àpótí náà kó tó dìgbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́.—1/15, ojú ìwé 31.
• Kí nìdí tí wọ́n fi ní káwọn Júù tó wà nígbà ayé Nehemáyà máa kó igi wá sí tẹ́ńpìlì?
Òfin Mósè kò sọ pé kí wọ́n máa fi igi rúbọ. Ṣùgbọ́n nígbà ayé Nehemáyà, wọ́n ní láti máa kó igi wá lóòrèkóòrè kí wọ́n lè máa rí nǹkan fi sun ẹbọ lórí pẹpẹ.—2/1, ojú ìwé 11.
• Kí ni Ìwé Muratori?
Ìwé náà jẹ́ ara ìwé àfọwọ́kọ tó jẹ́ alábala tí wọ́n fi èdè Látìn kọ. Èdè Gíríìkì ni wọ́n kọ́kọ́ fi kọ ìwé náà ní apá ìparí ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni. Òun ni ọjọ́ rẹ̀ tíì pẹ́ jù lọ nínú gbogbo ìwé tó mẹ́nu kan àwọn ìwé inú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí Ọlọ́run mí sí. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwé náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan àtàwọn tó kọ wọ́n.—2/15, ojú ìwé 13 àti 14.
• Kí nìdí tí Fáṣítì Ayaba Páṣíà fi ń kọ̀ ṣáá láti wá sọ́dọ̀ ọba? (Ẹ́sítérì 1:10-12)
Bíbélì ò sọ ohun tó fà á tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ohun tó mú kó kọ̀ ni pé kò fẹ́ fi ara rẹ̀ wọ́lẹ̀ níwájú àwọn àlejò ọba tí wọ́n ti mutí yó kẹ́ri. Tàbí kó jẹ́ pé ayaba tó lẹ́wà gan-an yìí kì í ṣe ẹni tó nítẹríba, àpẹẹrẹ búburú lèyí sì máa jẹ́ fún gbogbo àwọn aya tó wà ní Ilẹ̀ Páṣíà.—3/1, ojú ìwé 9.
• Báwo ni ìràpadà ṣe lè dá wa nídè?
Ẹbọ Jésù lè dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún, ó sì lè tú wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun ìbànújẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ ń fà. (Róòmù 6:23) Ẹbọ ìràpadà yìí kò ní jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn máa dá àwọn Kristẹni tòótọ́ lẹ́bi. Tá a bá sì ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà, a ò ní máa bẹ̀rù pé bóyá ni Ọlọ́run ń fojú rere wò wá. (1 Jòhánù 2:1)—3/15, ojú ìwé 8.
• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìkàléèwọ̀ tó wà nínú Òfin Mósè pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀? (Ẹ́kísódù 23:19)
Ó ṣeé ṣe kí síse ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀ jẹ́ ààtò kan táwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣe láti mú kí òjò rọ̀. (Léfítíkù 20:23) Ńṣe ni Ọlọ́run pèsè wàrà fún abo ewúrẹ́ kó lè fi bọ́ ọmọ rẹ̀ kí wàrà sì lè mú kó tètè dàgbà. Tẹ́nì kan bá wá ń se ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀, á jẹ́ pé onítọ̀hún ò bọ̀wọ̀ fún àjọṣe tí Ọlọ́run ti ní kó wà láàárín ìyá ẹran àti ọmọ rẹ̀. Òfin yìí jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run jẹ́ oníyọ̀ọ́nú.—4/1, ojú ìwé 31.