“Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo Láìsí Ìkùnsínú”
“Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú.”—FÍLÍPÌ 2:14.
1, 2. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì àti Kọ́ríńtì, kí sì nìdí tó fi fún wọn?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù yin àwọn ará ìjọ Fílípì gan-an nínú lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ sí wọn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ó yin àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ tó wà ní Fílípì torí pé wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́ àti onítara. Ó sọ bí inú rẹ̀ ṣe dùn tó nítorí iṣẹ́ rere wọn. Síbẹ̀, ó rán wọn létí pé kí wọ́n “máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú.” (Fílípì 2:14) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi gbà wọ́n nímọ̀ràn yìí?
2 Pọ́ọ̀lù mọ ohun tí ìkùnsínú lè fà. Ó ti kọ́kọ́ rán ìjọ Kọ́ríńtì létí lọ́dún mélòó kan ṣáájú pé ìkùnsínú léwu gan-an. Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó yé wọn pé nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà láginjù, wọ́n ṣe ohun tó bí Jèhófà nínú lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Lọ́nà wo? Ní ti pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun tí ń ṣeni léṣe, wọ́n ń bọ̀rìṣà, wọ́n ń ṣàgbèrè, wọ́n ń dán Jèhófà wò, wọ́n sì tún ń kùn. Pọ́ọ̀lù wá gba ìjọ Kọ́ríńtì níyànjú pé kí wọ́n fi tàwọn wọ̀nyí kọ́gbọ́n. Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe jẹ́ oníkùnsínú, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn kan nínú wọn ti kùn, kìkì láti ṣègbé láti ọwọ́ apanirun.”—1 Kọ́ríńtì 10:6-11.
3. Kí nìdí to fi yẹ ká kọbi ara sí ọ̀rọ̀ nípa ìkùnsínú lóde òní?
3 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní nírú ẹ̀mí táwọn ará ìjọ Fílípì ní. A nítara fún iṣẹ́ rere, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa. (Jòhánù 13:34, 35) Ṣùgbọ́n tá a bá wo àkóbá tí ìkùnsínú ṣe fún àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́, a óò rí i pé kò ní dára ká gbàgbé ìmọ̀ràn yìí: “Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú.” Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo àpẹẹrẹ àwọn kan tí Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kàn pé wọ́n kùn. Lẹ́yìn náà, a óò wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí a lè ṣe kí ìkùnsínú má bàa kó wa sí yọ́ọ́yọ́ọ́ lóde òní.
Àwùjọ Èèyàn Búburú Kan Kùn sí Jèhófà
4. Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kùn nípa rẹ̀ ní aginjù?
4 Bíbélì lo ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí ‘ìkùnsínú, ìráhùn tàbí àròyé ṣíṣe’ nígbà tó ń sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní aginjù fún ogójì ọdún. Láwọn ìgbà kan lákòókò náà, ẹ̀mí àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀sẹ̀ mélòó kan péré lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì ni “gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá . . . bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè àti Áárónì.” Tìtorí oúnjẹ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń ráhùn pé: “Àwa ì bá kúkú ti kú láti ọwọ́ Jèhófà ní ilẹ̀ Íjíbítì nígbà tí àwa jókòó ti ìkòkò ẹran, nígbà tí a ń jẹ oúnjẹ ní àjẹtẹ́rùn, nítorí ẹ̀yin ti mú wa jáde wá sínú aginjù yìí láti fi ìyàn pa gbogbo ìjọ yìí.”—Ẹ́kísódù 16:1-3.
5. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ráhùn, ta ni wọ́n ń ráhùn sí ní pàtàkì?
5 Bẹ́ẹ̀, Jèhófà ń tọ́jú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí nínú aginjù o, ó ń pèsè oúnjẹ àti omi tí ó tó fún wọn. Kò sídìí tó fi yẹ kí wọ́n bẹ̀rù pé ìyàn á pa àwọn láginjù. Àmọ́, ẹ̀mí àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn mú kí wọ́n sọ ohun tó ń ṣe wọ́n di bàbàrà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè àti Áárónì ni wọ́n dojú ìráhùn wọn kọ, Jèhófà wò ó pé òun Ọlọ́run gan-an ni wọ́n ń ráhùn sí. Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà ti gbọ́ ìkùnsínú yín tí ẹ ń kùn sí i. Kí sì ni àwa? Ìkùnsínú yín kì í ṣe sí wa, bí kò ṣe sí Jèhófà.”—Ẹ́kísódù 16:4-8.
6, 7. Gẹ́gẹ́ bí Númérì 14:1-3 ṣe fi hàn, báwo ni ìwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe yí padà?
6 Láìpẹ́ sígbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún kùn. Ó ṣẹlẹ̀ pé Mósè ní káwọn ọkùnrin méjìlá lọ ṣamí Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́ mẹ́wàá lára wọn mú ìròyìn burúkú wá. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ńṣe ni “gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì . . . bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè àti Áárónì, gbogbo àpéjọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí wọn pé: ‘Àwa ì bá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Íjíbítì, tàbí àwa ì bá kúkú ti kú ní aginjù yìí! Èé sì ti ṣe tí Jèhófà fi ń mú wa bọ̀ ní ilẹ̀ yìí [ìyẹn ilẹ̀ Kénáánì] láti tipa idà ṣubú? Àwọn aya wa àti àwọn ọmọ wa kéékèèké yóò di ohun tí a piyẹ́. Kò ha sàn fún wa láti padà sí Íjíbítì?’”—Númérì 14:1-3.
7 Áà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló wá dà báyìí! Tẹ́lẹ̀, ńṣe ni ìmọrírì nípa bí Jèhófà ṣe yọ wọ́n lóko ẹrú Íjíbítì tó sì mú wọn la Òkun Pupa kọjá mú kí wọ́n kọrin ìyìn sí Jèhófà o. (Ẹ́kísódù 15:1-21) Àmọ́ nígbà tí nǹkan ò rọrùn fún wọn nínú aginjù tí ẹ̀rù sì ń bà wọ́n nítorí àwọn ọmọ Kénáánì, ẹ̀mí ìmọrírì wọn pòórá, wọ́n wá di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Dípò kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó dá àwọn nídè kúrò lóko ẹrú, wọ́n ń dá a lẹ́bi nítorí wọ́n rò pé ńṣe ló ń fi ìyà jẹ àwọn. Èyí jẹ́ ká rí i pé ohun tó ń fa ìkùnsínú àwọn èèyàn ni àìmọrírì àwọn ìpèsè Jèhófà. Abájọ tí Jèhófà fi sọ pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí àpéjọ yìí tí ó jẹ́ ti ibi yóò máa ṣe ìkùnsínú yìí tí wọ́n ń bá nìṣó sí mi?”—Númérì 14:27; 21:5.
Àwọn Tó Kùn ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Kìíní
8, 9. Mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ pé wọ́n kùn.
8 Àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu kàn yìí jẹ́ ti àwùjọ èèyàn kan tó sọ àwọn nǹkan tí kò dùn mọ́ wọn nínú síta. Àmọ́, nígbà tí Jésù Kristi wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà lọ́dún 32 Sànmánì Kristẹni, “ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ [ló] wà nípa rẹ̀ láàárín àwọn ogunlọ́gọ̀” tó wà níbẹ̀. (Jòhánù 7:12, 13, 32) Wọ́n ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nípa rẹ̀, àwọn kan ní èèyàn rere ni, àwọn míì sì ní kì í ṣèèyàn rere.
9 Ní àsìkò mìíràn, Léfì, ìyẹn Mátíù agbowó orí, gba Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lálejò nílé rẹ̀. “Àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin wọn [wá] bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, pé: ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé ẹ ń jẹ, ẹ sì ń mu pẹ̀lú àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀?’” (Lúùkù 5:27-30) Nígbà kan lẹ́yìn náà, nílùú Gálílì, “àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí [Jésù] nítorí ó wí pé: ‘Èmi ni oúnjẹ tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.’” Kódà inú àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò dùn sóhun tí Jésù sọ, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn.—Jòhánù 6:41, 60, 61.
10, 11. Kí nìdí táwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì fi ń kùn, ẹ̀kọ́ wo làwọn alàgbà ìjọ sì lè rí kọ́ látinú bí àwọn àpọ́sítélì ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ náà?
10 Ní ti kíkùn táwọn kan kùn nígbà díẹ̀ lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nǹkan dáadáa ló tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà yẹn, àwọn onígbàgbọ́ tó wà ní Jùdíà ń pèsè oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì fáwọn Júù tí wọ́n wá láti ilẹ̀ ibòmíì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn, àmọ́ ìṣòro wáyé nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà ń pín àwọn nǹkan yẹn láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn lápapọ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ìkùnsínú dìde níhà ọ̀dọ̀ àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì lòdì sí àwọn Júù tí ń sọ èdè Hébérù, nítorí pé àwọn opó wọn ni a ń gbójú fò dá nínú ìpín-fúnni ojoojúmọ́.”—Ìṣe 6:1.
11 Ìkùnsínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí kò dà bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì láginjù o. Kì í ṣe ẹ̀mí àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún wọn ló ń bá àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì jà. Ohun tí wọ́n ń pàfiyèsí sí ni pé wọn ò bójú tó àwọn opó kan bó ṣe yẹ. Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe pé àwọn tó kùn yẹn fẹ́ fa wàhálà kí wọ́n wá máa ráhùn sí Jèhófà. Àwọn àpọ́sítélì ni wọ́n lọ bá, àwọn àpọ́sítélì sì ṣètò pé kí wọ́n bójú tó ọ̀rọ̀ wọn láìfi falẹ̀ torí pé òótọ́ lohun tí wọ́n ń tìtorí ẹ̀ ṣàròyé. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dáa gan-an làwọn àpọ́sítélì yìí fi lélẹ̀ fáwọn alàgbà ìjọ lónìí! Àwọn alàgbà tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí yìí máa ń rí i dájú pé àwọn ò ‘di etí wọn sí igbe ìráhùn ẹni rírẹlẹ̀.’—Òwe 21:13; Ìṣe 6:2-6.
Ṣọ́ra fún Ìkùnsínú, Ó Máa Ń Ba Nǹkan Jẹ́
12, 13. (a) Ṣàpèjúwe àkóbá tí ìkùnsínú lè ṣe. (b) Kí ló lè mú kí ẹnì kan máa kùn?
12 Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn àpẹẹrẹ tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ìkùnsínú kó àwọn èèyàn Ọlọ́run sí yọ́ọ́yọ́ọ́ láyé àtijọ́. Nítorí náà, kò yẹ ká fojú kékeré wo ìbàjẹ́ tí ìkùnsínú lè ṣe lónìí. Ẹ wo àpèjúwe kan tí yóò jẹ́ ká rí bó ṣe léwu tó. Àwọn irin kan sábà máa ń dógùn-ún. Téèyàn ò bá wá nǹkan ṣe sírú irin bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í dógùn-ún, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ irin náà lè bà jẹ́ débi pé kò ní wúlò mọ́. Àìmọye ọkọ̀ tí ẹ́ńjìnnì rẹ̀ ṣì ń ṣiṣẹ́ làwọn èèyàn ti pa tì tìtorí pé gbogbo ara ọkọ̀ náà ti dógùn-ún tó sì ti bà jẹ́ kọjá bó ṣe yẹ. Báwo ni àpèjúwe yìí ṣe bá ọ̀rọ̀ ìkùnsínú mu?
13 Bí àwọn irin kan ṣe sábà máa ń dógùn-ún náà ló ṣe wà nínú ẹ̀jẹ̀ ọmọ èèyàn láti máa ráhùn. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ dẹni tó ń ráhùn. Bí ọ̀rinrin àti afẹ́fẹ́ ṣe máa ń jẹ́ kí irin tètè dógùn-ún, bẹ́ẹ̀ ni ìpọ́njú ṣe lè mú kéèyàn máa ráhùn. Ìnira lè mú kéèyàn fẹ́ fara ya tí nǹkan kékeré kan lásán bá gani lára. Bí ipò nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan yìí, bẹ́ẹ̀ làwọn ohun tó lè fa ìráhùn yóò máa pọ̀ sí i. (2 Tímótì 3:1-5) Èyí lè mú kí ìránṣẹ́ Jèhófà kan bẹ̀rẹ̀ sí í kùn nípa ìránṣẹ́ Jèhófà míì. Ó lè jẹ́ ọ̀ràn kékeré kan ló fa kíkùn yẹn, irú bíi kùdìẹ̀-kudiẹ ẹnì kan, tàbí nítorí ohun tẹ́nì kan mọ̀ ọ́n ṣe tàbí nítorí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tẹ́nì kan ní.
14, 15. Tó bá ti ń mọ́ wa lára láti máa ráhùn, kí nìdí tó fi yẹ ká wá nǹkan ṣe sí i?
14 Béèyàn ò bá tètè wá nǹkan ṣe sí ẹ̀mí ìráhùn, yálà ìráhùn náà tọ́ tàbí kò tọ́, ó lè sọni di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ẹni tó jẹ́ pé kó lè ṣe kó má kùn. Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀mí ìkùnsínú lè ṣàkóbá fún wa, kó bá àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ pátápátá. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ráhùn nípa bí nǹkan ṣe rí fún wọn nínú aginjù, wọ́n bá a débi pé wọ́n ń dá Jèhófà lẹ́bi. (Ẹ́kísódù 16:8) Ǹjẹ́ ká má ṣe dán irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wò ní tiwa!
15 Irin máa ń pẹ́ kó tó dógùn-ún téèyàn bá fi ọ̀dà tí kì í jẹ́ kí irin dógùn-ún kùn ún tó sì tètè wá nǹkan ṣe sí ojú ibi tó bá rí pé ó fẹ́ máa dógùn-ún. Bákan náà, tá a bá rí i pé ó ti fẹ́ mọ́ wa lára láti máa ráhùn, a lè káwọ́ ẹ̀mí yẹn tá a bá fi ọ̀rọ̀ yẹn sí àdúrà tá a sì tètè sapá láti borí rẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe é?
Máa Fojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Nǹkan Wò Ó
16. Báwo la ṣe lè borí ẹ̀mí ìráhùn?
16 Téèyàn bá ń ráhùn, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ àti ìṣòro rẹ̀ ló máa gbà á lọ́kàn, kò ní fọkàn sí àwọn ìbùkún tá à ń ní bá a ṣe jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tá a bá fẹ́ borí ẹ̀mí ìráhùn, àwọn ìbùkún wọ̀nyí ló yẹ ká jẹ́ kó gbawájú lọ́kàn wa. Bí àpẹẹrẹ, olúkúlùkù wa ni Jèhófà dá lọ́lá, tó jẹ́ ká máa bá òun jẹ́ orúkọ pọ̀. (Aísáyà 43:10) A lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, a sì lè bá òun, “Olùgbọ́ àdúrà” sọ̀rọ̀ nígbàkigbà. (Sáàmù 65:2; Jákọ́bù 4:8) À ń gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀ torí a mọ̀ nípa ọ̀ràn tó ńbẹ nílẹ̀, ìyẹn ọ̀rọ̀ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. A sì tún mọ̀ pé àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. (Òwe 27:11) A láǹfààní láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. (Mátíù 24:14) Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi sì ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Jòhánù 3:16) Gbogbo wa ló ní àwọn ìbùkún yìí yálà ìṣòro wa pọ̀ tàbí ó kéré.
17. Ká tiẹ̀ sọ pé òótọ́ ni pé nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ la fi ń ráhùn, kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbìyànjú láti fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn wò ó?
17 Ẹ jẹ́ ká máa gbìyànjú láti fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn wò ó, dípò tá ó fi máa ka èrò tiwa sí pàtàkì. Onísáàmù náà Dáfídì kọrin pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.” (Sáàmù 25:4) Tó bá ṣe pé òótọ́ ni pé nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ la fi ń ráhùn, Jèhófà á kúkú ti rí nǹkan ọ̀hún. Ó sì lè wá nǹkan ṣe sí i lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́ kí nìdí tó fi ń jẹ́ kí ìnira kan máa bá a nìṣó láìfòpin sí i? Ó lè jẹ́ pé ńṣe ló fẹ́ ká dẹni tó láwọn ànímọ́ dáadáa kan, irú bíi sùúrù, ìfaradà, ìgbàgbọ́ àti ìpamọ́ra.—Jákọ́bù 1:2-4.
18, 19. Mú àpẹẹrẹ kan wá nípa ohun tó lè jẹ́ àbájáde fífarada ìnira láìsí ìráhùn.
18 Bá a bá lè máa fara da àwọn ìnira kéékèèké láìráhùn, a óò ní ànímọ́ tó túbọ̀ dára, ìwà wa yóò sì máa wú àwọn tó ń kíyè sí wa lórí. Lọ́dún 2003, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wọ bọ́ọ̀sì láti ilẹ̀ Jámánì lọ sí ilẹ̀ Hungary láti lọ ṣèpàdé. Awakọ̀ bọ́ọ̀sì náà kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, kò sì dún mọ́ ọn nínú bó ṣe fẹ́ gbé àwọn Ẹlẹ́rìí yìí lọ kó sì wà pẹ̀lú wọn fún odidi ọjọ́ mẹ́wàá. Ṣùgbọ́n lópin ìrìn àjò náà, ọkàn rẹ̀ ti yí padà. Kí nìdí rẹ̀?
19 Nígbà ìrìn àjò náà, ọ̀pọ̀ nǹkan ni ò lọ bó ṣe yẹ, ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí náà kò ráhùn rárá. Awakọ̀ náà sọ pé nínú gbogbo àwọn tóun ti ń gbé lọ sí ìrìn àjò, àwọn Ẹlẹ́rìí nìwà wọn dára jù! Kódà ó ní nígbàkigbà táwọn Ẹlẹ́rìí bá tún wàásù délé òun, òun yóò pè wọ́n wọlé láti fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ wọn. Ẹ ò rí i báwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣe lórúkọ rere nítorí pé wọ́n “ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú”!
Ẹ̀mí Ìdáríjì Máa Ń Jẹ́ Kí Ìṣọ̀kan Wà
20. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dárí ji ara wa?
20 Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣẹ̀ wá ńkọ́? Bí ẹ̀ṣẹ̀ náà bá burú gan-an, ńṣe ni ká tẹ̀ lé ìlànà inú ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 18:15-17. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló pọn dandan ká máa ṣe gbogbo ìyẹn níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èdèkòyédè pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ló sábà máa ń wáyé. O ò ṣe wo ohun tó ṣẹlẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti fi hàn pé o lẹ́mìí ìdáríjì? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:13, 14) Ǹjẹ́ a ṣe tán láti dárí ji ẹni tó bá ṣẹ̀ wá? Ǹjẹ́ àwa náà kì í ṣẹ Jèhófà? Síbẹ̀, àìmọye ìgbà ló ń ṣàánú wa tó ń dárí jì wá.
21. Ipa wo ni ìkùnsínú máa ń ní lórí àwọn tó ń gbọ́ ọ?
21 Ohun yòówù kó máa bí wa nínú, ìkùnsínú ò lè yanjú ẹ̀. Ọ̀rọ̀ táwọn Hébérù máa ń lò fún ìkùnsínú tún lè túmọ̀ sí ríráhùn. Ó ṣeé ṣe kí ara má máa tù wá tẹ́nì kan bá ń kún nítòsí wa, àá sì fẹ́ jìnnà sírú ẹni bẹ́ẹ̀. Táwa náà bá sì ń kùn, ara lè má tu àwọn tó ń gbọ́ wa. Kódà, ìnira yẹn lè pọ̀ débi pé wọ́n á jìnnà sí wa! Ó ṣeé ṣe kí kíkùn tẹ́nì kan ń kùn mú kó rẹ́ni dá sí ọ̀rọ̀ ẹ̀ o, àmọ́ ńṣe làwọn èèyàn á máa sára fún un.
22. Kí ni ọ̀dọ́mọbìnrin kan sọ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
22 Ẹ̀mí ìdáríjì máa ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà, ìyẹn gan-an sì làwọn èèyàn Jèhófà ń fẹ́. (Sáàmù 133:1-3) Níbì kan nílẹ̀ Yúróòpù, ọ̀dọ́mọbìnrin ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀ láti sọ bó ṣe mọyì àwa Ẹlẹ́rìí tó. Ó ní: “Ìjọ yín nìkan ṣoṣo ni mo rí pé gbogbo àwọn ọmọ ìjọ wọn wà níṣọ̀kan, kò sí ẹ̀mí ìkórìíra, ìwọra, àìrára-gba-nǹkan-sí àti ìmọtara-ẹni-nìkan láàárín yín.”
23. Kí la máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
23 Tá a bá mọrírì àwọn ìbùkún tẹ̀mí tí àwa olùjọsìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, ń rí gbà, a óò máa sa ipa tiwa láti rí i pé ìṣọ̀kan wà, a ò sì ní jẹ́ kí nǹkan kan mú wa máa kùn nípa àwọn ẹlòmíì. Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò jẹ́ ká rí bí àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fi ń kọ́ wa kò ṣe ní jẹ́ ká máa kùn láwọn ọ̀nà míì tó burú jáì, irú bíi kéèyàn máa kùn nípa bí nǹkan ṣe ń lọ nínú apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ló máa ń fa ìkùnsínú?
• Kí lo lè fi ṣe àpẹẹrẹ àkóbá tí ìkùnsínú máa ń ṣe?
• Kí ló lè jẹ́ ká borí ẹ̀mí ìkùnsínú?
• Báwo ni níní ẹ̀mí ìdáríjì kò ṣe ní jẹ́ ká gba ìkùnsínú láyè?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Jèhófà gan-an làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kùn sí!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ǹjẹ́ o máa ń gbìyànjú láti fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn wò ó?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹ̀mí ìdáríjì máa ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn ará