“Àwa Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso Dípò Àwọn Ènìyàn”
‘A Ò Lè Dẹ́kun Sísọ̀rọ̀ Nípa Jésù’
NÍ ỌDÚN 33 Sànmánì Kristẹni, ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn pàdé nínú gbọ̀ngàn ńlá ti ilé ẹjọ́ gíga jù lọ àwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n fẹ́ ṣe ìgbẹ́jọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi méjìlá. Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n ṣẹ̀? Wọ́n ní wọ́n ń wàásù nípa Jésù. Ìgbà kejì nìyí tí àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù máa wá jẹ́jọ́ níwájú ìgbìmọ̀ náà. Èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ fún àwọn àpọ́sítélì mẹ́wàá yòókù.
Àlùfáà àgbà rán àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà létí àṣẹ tí ilé ẹjọ́ náà pa níṣàájú. Nígbà yẹn, wọ́n sọ fún àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù pé kí wọ́n má ṣe kọ́ àwọn èèyàn nípa Jésù mọ́, àmọ́ ohun táwọn méjèèjì fi fèsì ni pé: “Bí ó bá jẹ́ òdodo lójú Ọlọ́run láti fetí sí yín dípò Ọlọ́run, ẹ fúnra yín ṣèdájọ́. Ṣùgbọ́n ní tiwa, àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” Lẹ́yìn táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún àwọn ní ìgboyà, ńṣe ni wọ́n ń bá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere lọ.—Ìṣe 4:18-31.
Nígbà tí àlùfáà àgbà ti wá rí i báyìí pé gbogbo ìkìlọ̀ òun tẹ́lẹ̀ ò pa àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lẹ́nu mọ́, ó sọ níbi ìgbẹ́jọ́ ẹlẹ́ẹ̀kejì yìí pé: “A pa àṣẹ fún yín ní pàtó láti má ṣe máa kọ́ni nípa orúkọ yìí, síbẹ̀, sì wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù, ẹ sì pinnu láti mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sórí wa.”— Ìṣe 5:28.
Wọ́n Dúró Lórí Ìpinnu Wọn
Tìgboyà-tìgboyà ni Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù fi dáhùn pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Bẹ́ẹ̀ ni o, bí ohun táwọn èèyàn ní ká ṣe bá ta ko àṣẹ Ọlọ́run, Jèhófà ló yẹ ká ṣègbọràn sí dípò tí a ó fi ṣègbọràn sí ẹ̀dá èèyàn lásán-làsàn.a
Ó ti yẹ kí ọ̀rọ̀ táwọn àpọ́sítélì sọ pé ti Ọlọ́run làwọn máa ṣe mú kí ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn rí i pé ó yẹ káwọn jáwọ́ nínú ọ̀rọ̀ yìí. Bí wọ́n bá bi àwọn aṣáájú Júù yìí bóyá Ọlọ́run ló yẹ kéèyàn ṣègbọràn sí àbí òun kọ́, ohun tó yẹ kí gbogbo wọn lápapọ̀ fi fèsì ni pé: ‘Ọlọ́run ló yẹ kéèyàn ṣègbọràn sí.’ Ṣebí wọ́n ṣáà gbà pé Ọlọ́run ni Ọba Aláṣẹ ayé àti ọ̀run.
Ó jọ pé ńṣe ni Pétérù ń gbẹnu sọ fún gbogbo àwọn àpọ́sítélì náà nígbà tó sọ pé tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù tí àwọn ń ṣe ni, Ọlọ́run làwọn ń ṣègbọràn sí kì í ṣe èèyàn. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn àpọ́sítélì náà pé aláìgbọràn ni wọ́n kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Nítorí pé ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn mọ ìtàn orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n mọ̀ pé àwọn ìgbà kan wà tó jẹ́ pé ó tọ́ kéèyàn pa òfin Ọlọ́run mọ́ dípò òfin èèyàn. Nílẹ̀ Íjíbítì, Ọlọ́run làwọn agbẹ̀bí méjì kan bẹ̀rù kì í ṣe Fáráò, ìyẹn ni wọn ò ṣe fikú pa èyíkéyìí nínú àwọn ọmọkùnrin táwọn obìnrin Hébérù bá bí. (Ẹ́kísódù 1:15-17) Bákan náà, nígbà tí Senakéríbù Ọba ń fòòró Hesekáyà Ọba kó lè juwọ́ sílẹ̀, ti Jèhófà ni Hesekáyà ṣe. (2 Ọba 19:14-37) Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn mọ̀ dáadáa fi hàn gbangba pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn òun máa ṣègbọràn sí òun.—1 Sámúẹ́lì 15:22, 23.
Ọlọ́run San Wọ́n Lẹ́san fún Ìgbọràn Wọn
Ó jọ pé ọ̀rọ̀ táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù sọ pé, “àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn,” wọ ọ̀kan lára àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga náà lọ́kàn. Gàmálíẹ́lì lorúkọ adájọ́ náà, wọn kò sì kóyán rẹ̀ kéré nínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn. Nígbà tó ku ìgbìmọ̀ yẹn nìkan, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n gbọ́ ohun tóun fẹ́ sọ, ó sì fún wọn ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n kan. Ó mẹ́nu kan àpẹẹrẹ àwọn èèyàn kan tí wọ́n ti wà ṣáájú ìgbà yẹn, ó wá lo ìyẹn láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu rárá láti ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ táwọn àpọ́sítélì náà ń ṣe. Ohun tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: “Ẹ má tojú bọ ọ̀ràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ wọn jẹ́ẹ́; . . . bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè wá rí yín ní ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gidi.”—Ìṣe 5:34-39.
Ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí Gàmálíẹ́lì sọ yìí mú kí ilé ẹjọ́ gíga náà pinnu pé àwọn yóò fi àwọn àpọ́sítélì ọ̀hún sílẹ̀. Wọ́n na àwọn àpọ́sítélì náà lẹ́gba, àmọ́ ìyà tó jẹ wọ́n yìí kò dẹ́rù bà wọ́n rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.”—Ìṣe 5:42.
Ọlọ́run bù kún àwọn àpọ́sítélì wọ̀nyí gan-an nítorí pé wọ́n dúró lórí ìpinnu wọn pé àṣẹ Ọlọ́run tó ga jù lọ làwọn máa tẹ̀ lé! Ìpinnu àwa Kristẹni òde òní náà nìyẹn. Jèhófà làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ó jẹ́ Alákòóso Gíga Jù Lọ. Bí ẹnikẹ́ni bá pàṣẹ fún wa pé ká ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ Ọlọ́run, ohun táwọn àpọ́sítélì wọ̀nyẹn sọ làwa náà máa sọ, ìyẹn ni pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo oṣù September àti October nínú kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2006.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
ǸJẸ́ O TI RONÚ NÍPA Ọ̀RỌ̀ YÌÍ RÍ?
Báwo ni Lúùkù tó kọ ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe mọ ohun tí Gàmálíẹ́lì sọ láàárín ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn nígbà tó jẹ́ pé ìgbìmọ̀ yẹn nìkan ló wà níbẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ọlọ́run ló fúnra rẹ̀ sọ fún Lúùkù. Ó sì lè jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù (ẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Gàmálíẹ́lì nígbà kan) ló sọ fún Lúùkù. Tàbí kẹ̀, ó lè jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga náà tó gbà pé òótọ́ lohun táwọn àpọ́sítélì náà ń sọ ni Lúùkù lọ bá.