Èdìdì ‘Júkálì’
NÍ Ọ̀RÚNDÚN keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Nebukadinésárì ọba àwọn ará Kálídíà, ìyẹn Bábílónì, ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, ó dáná sun ìlú náà ó sì wó odi rẹ̀ palẹ̀. Ó mú Sedekáyà ọba Júdà nígbèkùn ó sì fọ́ ọ lójú. Kódà “gbogbo ọ̀tọ̀kùlú Júdà . . . ni ọba Bábílónì pa.”—Jeremáyà 39:1-8.
Ó jọ pé Júkálì ọmọ Ṣelemáyà, ọ̀kan lára àwọn ọ̀tọ̀kùlú Júdà, wà lára àwọn táwọn ará Bábílónì pa nígbà náà. Àwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí ohun kan nípa Júkálì yìí. Àmọ́ ká tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n rí yìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Júkálì àti ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀.
“Wọn Kì Yóò Borí Rẹ”
Jèhófà rán wòlíì Jeremáyà pé kó máa kéde ìdájọ́ tóun máa ṣe fún àwọn èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run sọ fún un pé àwọn ọba Júdà, àwọn ọmọ aládé rẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ àtàwọn èèyàn rẹ̀ ‘yóò bá Jeremáyà jà.’ Ṣùgbọ́n Jèhófà ní: “Wọn kì yóò borí rẹ, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ.’”—Jeremáyà 1:17-19.
Nígbà táwọn ará Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù olú ìlú Júdà, ẹ̀ẹ̀mejì ni Sedekáyà Ọba rán àwọn èèyàn sí Jeremáyà láti wádìí bóyá Nebukadinésárì yóò fi ìlú yẹn sílẹ̀ kí wọ́n sì sọ fún Jeremáyà pé kó gbàdúrà pé kó fi ìlú náà sílẹ̀. Júkálì tí Bíbélì tún pè ní Jéhúkálì wà lára àwọn tí ọba yìí rán. Ọlọ́run ní kí Jeremáyà sọ fún wọn pé pípa làwọn ará Bábílónì yóò pa Jerúsálẹ́mù run. Àti pé aráàlú tí kò bá kúrò níbẹ̀, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa á tàbí kí wọ́n fi idà pa á. Àmọ́ ẹni tó bá lọ fi ara rẹ̀ lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́ yóò wà láàyè. Ọ̀rọ̀ Jeremáyà yìí bí àwọn ọmọ aládé Júdà nínú gan-an ni!—Jeremáyà 21:1-10; 37:3-10; 38:1-3.
Júkálì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tó rọ Sedekáyà pé: ‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a fi ikú pa ọkùnrin yìí [ìyẹn Jeremáyà], nítorí ó ń sọ ọwọ́ àwọn ọkùnrin ogun tí wọ́n ṣẹ́ kù nínú ìlú ńlá yìí àti ọwọ́ gbogbo ènìyàn di aláìlera.’ Júkálì ẹni ibi yìí sì tún wà lára àwọn tó ju Jeremáyà sínú ìkùdu tó ní ẹrẹ̀ kó tó di pé àwọn kan wá fà á yọ níbẹ̀. (Jeremáyà 37:15; 38:4-6) Nítorí pé Jeremáyà ṣègbọràn sí Jèhófà, kò bá ìparun Jerúsálẹ́mù lọ, ṣùgbọ́n ní ti Júkálì tó gbẹ́kẹ̀ lé orílẹ̀-èdè Júdà, ó jọ pé ó wà lára àwọn tí wọ́n pa nígbà ìparun náà.
Ohun Pàtàkì Tí Wọ́n Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ṣàwárí
Wọ́n rí ohun pàtàkì kan nípa Júkálì ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 2005. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn awalẹ̀pìtàn kan ń gbẹ́ ibì kan tí wọ́n rò pé ààfin Dáfídì Ọba wà. Wọ́n wá rí àwókù ògiri òkúta kan tó gbalẹ̀ lọ rẹrẹẹrẹ, tí wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ará Bábílónì wó palẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Jeremáyà.
Lóòótọ́, kò sóhun tó tíì fi hàn dájú pé àwókù ààfin Dáfídì ni wọ́n rí. Ṣùgbọ́n àwọn awalẹ̀pìtàn yìí rí ohun kan tí kò fẹ̀ ju ìdajì ìdérí ìgò bíà lọ. Ohun náà ni èdìdì amọ̀ kan tí wọ́n lù lóǹtẹ̀, èyí tí àwòrán rẹ̀ wà lójú èwé kẹrìnlá. Ìwé àkọsílẹ̀ kan ni wọ́n fi èdìdì náà dì, àmọ́ ìwé náà ti jẹrà tipẹ́tipẹ́. Ọ̀rọ̀ tó wà lára èdìdì náà ni: “Èyí jẹ́ ti Yéhúkálì ọmọ Ṣelemiyáhù ọmọ Ṣófì.” Ó dájú pé òǹtẹ̀ Jéhúkálì, ìyẹn Júkálì ọmọ Ṣelemáyà tó jẹ́ alátakò Jeremáyà, ni wọ́n fi lu èdìdì amọ̀ náà.
Awalẹ̀pìtàn tó ń jẹ́ Eilat Mazar tó ka ohun tó wà lára èdìdì náà sọ pé, yàtọ̀ sí Gemaráyà ọmọ Ṣáfánì tó jẹ́ ìjòyè tórúkọ rẹ̀ hàn lára èdìdì kan tí wọ́n rí nínú Ìlú Dáfídì, Jéhúkálì tún ni “ìjòyè tá a rí ṣìkejì.”a
Kì í ṣe ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tí wọ́n ń rí ló ń mú ká nígbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí tó ń ṣẹ ni ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká gba Bíbélì gbọ́. Ìtàn fi hàn pé gbogbo ohun tí Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù ló ṣẹ pátá láìyẹ̀. Ikú ẹ̀tẹ́ táwọn ọ̀tá Jeremáyà sì kú nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín yẹ kó mú un dá wa lójú pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́ bíi ti Jeremáyà, àwọn ọ̀tá wa ‘kì yóò borí wa, nítorí pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa.’
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa Gemaráyà àti Ṣáfánì, wo àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ǹjẹ́ O Mọ Ṣáfánì àti Ìdílé Rẹ̀?” nínú Ilé Ìṣọ́ December 15, 2002, ojú ìwé 19 sí 22.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jeremáyà kò torí ìbẹ̀rù àwọn tó fúngun mọ́ ọn bomi la iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 14]
Gabi Laron/Institute of Archaeology/ Hebrew University ©Eilat Mazar