Jẹ́ Adúróṣinṣin Sí Kristi Àti Sí Ẹrú Rẹ̀ Olóòótọ́
“Ọ̀gá rẹ̀ . . . yóò yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.”—MÁTÍÙ 24:45-47.
1, 2. (a) Ta ni Ìwé Mímọ́ pè ní Aṣáájú wa? (b) Kí ló fi hàn pé Kristi ń darí ìjọ Kristẹni lójú méjèèjì?
“KÍ A má pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.” (Mátíù 23:10) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ló jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò jẹ́ aṣáájú wọn lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀run ni Aṣáájú kan ṣoṣo tí wọ́n ní wà, Jésù Kristi fúnra rẹ̀ sì ni. Ọlọ́run ló yan Jésù sípò yìí. Jèhófà “gbé e dìde kúrò nínú òkú . . . ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, èyí tí ó jẹ́ ara rẹ̀.”—Éfésù 1:20-23.
2 Níwọ̀n bí Kristi ti jẹ́ “orí lórí ohun gbogbo” tó jẹ mọ́ ìjọ Kristẹni, ó ní àṣẹ lórí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín ìjọ. Gbogbo ohun tó ń lọ nínú ìjọ pátá ló mọ̀. Ó ń kíyè sí i bóyá àwọn Kristẹni tàbí ìjọ kọ̀ọ̀kan ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Kristẹni àti bóyá wọ́n ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Èyí hàn kedere nínú ìṣípayá tó fún àpọ́sítélì Jòhánù ní òpin ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. Nígbà tí Jésù ń bá àwọn ìjọ méje sọ̀rọ̀, ìgbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sọ fún wọn pé òun mọ àwọn iṣẹ́ wọn, ìyẹn ni pé ó mọ àwọn ibi tí wọ́n ti ṣe dáadáa, ó sì mọ ibi tí wọ́n kù sí, ìyẹn ló mú kó bá wọn wí tó sì tún gbà wọ́n níyànjú bó ti tọ́ àti bó ti yẹ. (Ìṣípayá 2:2, 9, 13, 19; 3:1, 8, 15) Kò sídìí tí kò fi yẹ ká gbà gbọ́ pé Kristi tún mọ ohun tó ń lọ láwọn ìjọ mìíràn tó wà ní Éṣíà Kékeré, Palẹ́sìnì, Síríà, Babilóníà, Gíríìsì, Ítálì, àtàwọn ibòmíràn. (Ìṣe 1:8) Lóde òní náà ńkọ́?
Ẹrú Kan Tó Jẹ́ Olóòótọ́
3. Kí nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú láti fi Kristi wé orí àti láti fi ìjọ rẹ̀ wé ara?
3 Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde tó sì kù díẹ̀ kó gòkè lọ sọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ lọ́run, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” Ó tún sọ pé: “Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:18-20) Yóò máa wà pẹ̀lú wọn nígbà gbogbo gẹ́gẹ́ bí Orí wọn tó ń darí wọn lójú méjèèjì. “Ara” tí Kristi jẹ́ Orí fún ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìjọ Kristẹni wé nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù àti Kólósè. (Éfésù 1:22, 23; Kólósè 1:18) Ìwé The Cambridge Bible for Schools and Colleges sọ pé àfiwé yìí “fi hàn pé kì í ṣe pé ìṣọ̀kan wà láàárín ìjọ àti Orí ìjọ nìkan ni, àmọ́ ó tún fi hàn pé Orí ló ń darí ìjọ. Ohun èlò Rẹ̀ ni wọ́n.” Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ ohun èlò Kristi látìgbà tí Ọlọ́run ti sọ ọ́ di ọba lọ́dún 1914?—Dáníẹ́lì 7:13, 14.
4. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ Málákì wí, kí ni Jèhófà àti Kristi Jésù rí nígbà tí wọ́n wá sínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí fún ìbẹ̀wò?
4 Àsọtẹ́lẹ̀ Málákì sọ pé Jèhófà, “Olúwa tòótọ́,” pẹ̀lú “ońṣẹ́ májẹ̀mú” rẹ̀, ìyẹn Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé gorí ìtẹ́, yóò wá láti ṣèdájọ́ àti láti ṣèbẹ̀wò sí “tẹ́ńpìlì,” tàbí ilé ìjọsìn Rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Ó hàn gbangba pé “àkókò tí a yàn kalẹ̀” fún ‘ìdájọ́ ilé Ọlọ́run láti bẹ̀rẹ̀’ dé ní ọdún 1918.a (Málákì 3:1; 1 Pétérù 4:17) Fínnífínní ni wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn tó sọ pé àwọn ń ṣojú fún Ọlọ́run àti ìjọsìn rẹ̀ tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Ó kọ àwọn tí wọ́n ń fẹnu lásán jẹ́ Kristẹni sílẹ̀ pátápátá, ìyẹn àwọn tó ti ń fi ẹ̀kọ́ tó tàbùkù sí Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn tí wọ́n sì tún lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn rẹpẹtẹ tó wáyé nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Ó wá dán àwọn olóòótọ́ tó ṣẹ́ kù lára àwọn Kristẹni wò, ìyẹn àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn, ó yọ́ wọn mọ́ bí ohun tí a fi iná yọ́, ó tẹ́wọ́ gbà wọ́n, wọ́n sì di “àwọn ènìyàn tí ń mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn wá fún Jèhófà nínú òdodo.”—Málákì 3:3.
5. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa “wíwàníhìn-ín” rẹ̀ ti wí, àwọn wo ló wá di olóòótọ́ “ẹrú” náà?
5 Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Málákì ti wí, dídá ẹgbẹ́ “ẹrú” kan mọ̀ wà lára àmì alápá púpọ̀ tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lè mọ àkókò ‘wíwàníhìn-ín òun àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan.’ Jésù sọ pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu? Aláyọ̀ ni ẹrú náà bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé, bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Òun yóò yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Mátíù 24:3, 45-47) Nígbà tí Kristi dé láti ṣàyẹ̀wò ẹgbẹ́ “ẹrú” náà lọ́dún 1918, ó rí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, ìyẹn àwọn tó jẹ́ pé láti ọdún 1879 ni wọ́n ti ń lo ìwé ìròyìn yìí àtàwọn ìwé mìíràn tá a gbé ka Bíbélì láti pèsè ‘oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.’ Ó sọ pé ohun èlò òun ni ẹgbẹ́ tàbí “ẹrú” náà jẹ́, nígbà tó sì di ọdún 1919, ó fi àbójútó àwọn ohun ìní rẹ̀ tí orí ilẹ̀ ayé síkàáwọ́ wọn.
Wọ́n Ń Bójú Tó Ohun Ìní Kristi Lórí Ilẹ̀ Ayé
6, 7. (a) Ọ̀nà mìíràn wo ni Jésù gbà sọ̀rọ̀ nípa “ẹrú” rẹ̀ olóòótọ́? (b) Kí ni lílò tí Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “ìríjú” túmọ̀ sí?
6 Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ẹrú” yìí lọ́nà kan tó yàtọ̀ lóṣù díẹ̀ ṣáájú ìgbà tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti nípa “ẹrú” kan tí yóò máa ṣojú fún un lórí ilẹ̀ ayé. Èyí ló jẹ́ ká mọ iṣẹ́ tí ẹrú náà yóò ṣe. Jésù sọ pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye, tí ọ̀gá rẹ̀ yóò yàn sípò lórí ẹgbẹ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ láti máa fún wọn ní ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu? Mo sọ fún yín lótìítọ́, Òun yóò yàn án sípò lórí gbogbo nǹkan ìní rẹ̀.”—Lúùkù 12:42, 44.
7 Níhìn-ín, a pe ẹrú náà ní ìríjú, ìyẹn ọ̀rọ̀ kan tó wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “alábòójútó agboolé tàbí dúkìá.” Ẹgbẹ́ ẹrú náà kì í wulẹ̀ ṣe àgbájọ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tí wọ́n máa ń ṣàlàyé àwọn ohun tó dùn mọ́ni nínú Bíbélì. Láfikún sí oúnjẹ tẹ̀mí tí “olóòótọ́ ìríjú náà” ń pèsè “ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” Jésù tún yàn án lé orí àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ó sì tún yàn án láti máa bójú tó gbogbo ohun tó jẹ́ ti Kristi lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn “gbogbo nǹkan ìní rẹ̀.” Kí ni gbogbo nǹkan ìní Kristi yìí?
8, 9. Àwọn “ohun ìní” wo la yan ẹrú náà láti máa bójú tó?
8 Iṣẹ́ ẹrú náà kan bíbójútó àwọn ibi táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi máa ń lò fún ìgbòkègbodò wọn, àwọn bí orílé iṣẹ́ wa lágbàáyé, àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, títí kan àwọn ibi ìjọsìn wa, ìyẹn àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ jákèjádò ayé. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ẹrú náà tún ń bójú tó àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, èyí tó máa ń wáyé láwọn ìpàdé wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ àti ní ìpàdé àyíká, ti àkànṣe àti ti àgbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. A máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì láwọn ibi tá a ti máa ń pàdé pọ̀ yìí, a sì tún máa ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó bọ́ sákòókò nípa bó ṣe yẹ ká máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wa.
9 Iṣẹ́ ìríjú náà tún kan bíbójú tó iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run àti sísọ “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Èyí sì kan kíkọ́ àwọn èèyàn láti kíyè sí gbogbo ohun tí Kristi, tó jẹ́ Orí ìjọ, ti pa láṣẹ pé ká ṣe ní àkókò òpin yìí. (Mátíù 24:14; 28:19, 20; Ìṣípayá 12:17) Iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni yìí ti mú káwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” èèyàn jáde wá látinú aráyé, àwọn wọ̀nyí sì jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ tó dúró ṣinṣin ti àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró. Ó dájú pé “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” wọ̀nyí wà lára “ohun ìní” ṣíṣeyebíye tó jẹ́ ti Kristi, èyí táwọn ẹrú olóòótọ́ náà ń bójú tó.—Ìṣípayá 7:9; Hágáì 2:7.
Ìgbìmọ̀ Olùdarí Tó Ń Ṣojú fún Ẹgbẹ́ Ẹrú Náà
10. Ìgbìmọ̀ wo ló ń ṣèpinnu ní ọ̀rúndún kìíní, ipa wo nìyẹn sì ní lórí àwọn ìjọ?
10 Ṣíṣe ọ̀pọ̀ ìpinnu wà lára iṣẹ́ bàǹtàbanta tó já lé ẹrú olóòótọ́ náà léjìká. Nínú ìjọ Kristẹni ìjímìjí, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù ló ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ẹrú náà, tí wọ́n sì máa ń pinnu ohun tó yẹ kí gbogbo ìjọ Kristẹni ṣe. (Ìṣe 15:1, 2) Ìpinnu tí ìgbìmọ̀ olùdarí ọ̀rúndún kìíní yìí bá ṣe sì máa ń dé ọ̀dọ̀ àwọn ará nínú ìjọ nípasẹ̀ lẹ́tà àti nípasẹ̀ àwọn aṣojú tó máa ń rìnrìn àjò. Inú àwọn Kristẹni ìjímìjí máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá gba ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere yìí, bí wọ́n sì ti ń ṣètìlẹ́yìn tinútinú fún ìgbìmọ̀ olùdarí náà mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà.—Ìṣe 15:22-31; 16:4, 5; Fílípì 2:2.
11. Àwọn wo ni Kristi ń lò láti darí ìjọ rẹ̀ lónìí, ojú wo ló sì yẹ ká máa fi wo àwùjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí?
11 Gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò àwọn Kristẹni ìjímìjí, àwùjọ kékeré tí wọ́n jẹ́ alábòójútó tá a fi ẹ̀mí yàn ló para pọ̀ jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Nípasẹ̀ “ọwọ́ ọ̀tún” rẹ̀ tó lágbára, Kristi tó jẹ́ Orí ìjọ ń darí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ wọ̀nyí bí wọ́n ti ń bójú tó iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣípayá 1:16, 20) Nígbà tí Albert Schroeder, tó ti wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí tipẹ́, tó sì parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ń sọ ìtàn ìgbésí ayé ara rẹ̀, ó sọ pé: ‘Gbogbo ọjọ́ Wednesday ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń ṣèpàdé, àdúrà ni wọ́n máa ń fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé náà, tí wọ́n á bẹ Jèhófà pé kó fi ẹ̀mí rẹ̀ darí àwọn. Wọ́n máa ń sapá gidigidi láti rí i dájú pé gbogbo ọ̀ràn tí wọ́n bá bójú tó àti gbogbo ìpinnu tí wọ́n bá ṣe jẹ́ èyí tó wà níbàámu pẹ̀lú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’b Ó yẹ ká fọkàn tán àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ yìí. Àwọn gan-an ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tó gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín.”—Hébérù 13:17.
Bá A Ṣe Lè Fi Ọ̀wọ̀ Tó Yẹ Hàn fún Ẹrú Olóòótọ́ Náà
12, 13. Àwọn ìdí wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún ẹgbẹ́ ẹrú náà?
12 Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká fi ọ̀wọ̀ tó yẹ hàn fún ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ yìí ni pé tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jésù Kristi tó jẹ́ Ọ̀gá. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn ẹni àmì òróró pé: “Ẹni tí a pè nígbà tí ó jẹ́ òmìnira jẹ́ ẹrú Kristi. A rà yín ní iye kan.” (1 Kọ́ríńtì 7:22, 23; Éfésù 6:6) Nítorí náà, nígbà tá a bá ń fi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹrú olóòótọ́ náà àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú rẹ̀, Kristi fúnra rẹ̀ tó jẹ́ Ọ̀gá ẹrú náà là ń tẹ̀ lé yẹn. Fífi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn fún ohun èlò tí Kristi ń lò láti bójú tó ohun ìní rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé jẹ́ ọ̀nà kan tá a gbà ń fi hàn pé à ń “jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.”—Fílípì 2:11.
13 Ìdí mìíràn tí Ìwé Mímọ́ fi sọ pé ká fi ọ̀wọ̀ hàn fún ẹrú olóòótọ́ yìí ni pé, Bíbélì pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé ní “tẹ́ńpìlì” tí Jèhófà ń gbé inú rẹ̀ “nípasẹ̀ ẹ̀mí.” Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ “mímọ́.” (1 Kọ́ríńtì 3:16, 17; Éfésù 2:19-22) Ẹgbẹ́ tá a pè ní tẹ́ńpìlì mímọ́ yìí ni Jésù fi ohun ìní rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé síkàáwọ́ rẹ̀, tó túmọ̀ sí pé àwọn ẹ̀tọ́ kan àtàwọn ẹrù iṣẹ́ kan wà nínú ìjọ Kristẹni tó jẹ́ pé ìkáwọ́ ẹgbẹ́ ẹrú yìí nìkan ló wà. Nítorí ìdí yìí, gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ló kà á sí ojúṣe wọn láti fara mọ́ ìtọ́sọ́nà tó ń wá látọ̀dọ̀ ẹrú olóòótọ́ àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú rẹ̀. Láìsí àní-àní, àwọn “àgùntàn mìíràn” kà á sí àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti ṣètìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ ẹrú yìí nínú bíbójú tó àwọn ohun tó jẹ́ ti Ọ̀gá náà.—Jòhánù 10:16.
Bá A Ṣe Lè Gbárùkù Ti Ẹgbẹ́ Ẹrú Náà
14. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ọ̀nà wo làwọn àgùntàn mìíràn gbà ń tẹ̀ lé ẹgbẹ́ ẹrú tá a fòróró yàn náà tí wọn sì ń sìn gẹ́gẹ́ bíi ‘lébìrà tí a kò sanwó fún’?
14 Wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn àgùntàn mìíràn ṣe ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tẹrí ba fún Ísírẹ́lì tẹ̀mí tá a fòróró yàn, ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Àwọn lébìrà Íjíbítì tí a kò sanwó fún àti àwọn olówò Etiópíà àti àwọn Sábéà, àwọn ọkùnrin gíga, àní wọn yóò wá bá ìwọ, tìrẹ ni wọn yóò sì dà. Wọn yóò máa rìn lẹ́yìn rẹ; nínú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ni wọn yóò wá, ìwọ ni wọn yóò sì máa tẹrí ba fún. Ìwọ ni wọn yóò máa gbàdúrà sí, pé, “Ní tòótọ́, Ọlọ́run wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹlòmíràn; kò sí Ọlọ́run mìíràn.”’” (Aísáyà 45:14) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn àgùntàn mìíràn ń tẹ̀ lé àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹgbẹ́ ẹrú náà àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí rẹ̀ lóde òní, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà wọn. Gẹ́gẹ́ bí ‘àwọn lébìrà tí a kò sanwó fún,’ tinútinú ni àwọn àgùntàn mìíràn ń lo okun wọn àtàwọn ohun ìní wọn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé, ìyẹn iṣẹ́ tí Kristi yàn fún àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣe 1:8; Ìṣípayá 12:17.
15. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 61:5, 6 ṣe sọ̀rọ̀ nípa àjọṣe tó wà láàárín àwọn àgùntàn mìíràn àti Ísírẹ́lì tẹ̀mí?
15 Inú àwọn àgùntàn mìíràn ń dùn, wọ́n sì mọrírì àǹfààní tí wọ́n ní láti sin Jèhófà lábẹ́ ìdarí ẹgbẹ́ ẹrú náà àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú rẹ̀. Wọ́n gbà pé àwọn ẹni àmì òróró yẹn jẹ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16) Bíbélì pe àwọn àgùntàn mìíràn ní “àjèjì” àti “ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” tó ń dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí, wọ́n ń fi tayọ̀tayọ̀ sìn gẹ́gẹ́ bí “àgbẹ̀” àti “olùrẹ́wọ́ àjàrà” lábẹ́ ìdarí àwọn ẹni àmì òróró, tí wọ́n jẹ́ “àlùfáà Jèhófà” àti “òjíṣẹ́ Ọlọ́run.” (Aísáyà 61:5, 6) Tìtaratìtara ni wọ́n fi ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà àti nínú iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. Gbogbo ọkàn ni wọ́n fi ń ti ẹgbẹ́ ẹrú náà lẹ́yìn nínú ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn àti bíbójú tó àwọn ẹni bí àgùntàn tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bá pàdé.
16. Kí ló mú káwọn àgùntàn mìíràn máa gbárùkù ti ẹrú olóòótọ́ àti olóye?
16 Àwọn àgùntàn mìíràn mọ̀ pé àwọn ti jàǹfààní tó pọ̀ gan-an látinú ìsapá ẹrú olóòótọ́ náà bó ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fún wọn. Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi gbà pé tí kì í bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ni, àwọn ì bá má mọ ohunkóhun nípa àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Bíbélì, irú bí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, ìsọdimímọ́ orúkọ rẹ̀, Ìjọba Ọlọ́run, ọrún tuntun àti ayé tuntun, ọkàn, ipò táwọn òkú wà, ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an, ẹni tí Ọmọ rẹ̀ jẹ́, àti ohun tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ pẹ̀lú. Nítorí pé àwọn àgùntàn mìíràn moore tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́, tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n ń gbárùkù ti àwọn ẹni àmì òróró “arákùnrin” Kristi lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò òpin yìí.—Mátíù 25:40.
17. Kí ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti rí i pé ó yẹ káwọn ṣe, kí la sì máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Nítorí pé àwọn ẹni àmì òróró ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ mọ́ lórí ilẹ̀ ayé, kò sí bí wọ́n ṣe lè wà nínú gbogbo ìjọ láti bójú tó àwọn ohun ìní Kristi. Ìdí nìyẹn tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi ní láti yan àwọn ọkùnrin kan lára àwọn àgùntàn mìíràn láti máa bójú tó àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́, àwọn iṣẹ́ àgbègbè, iṣẹ́ àyíká, àtàwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ǹjẹ́ bá a ṣe ń ṣe sáwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń sìn lábẹ́ Kristi yìí ń fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi àti ẹrú rẹ̀ olóòótọ́? Èyí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti rí àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ lórí kókó yìí, wo Ilé Ìṣọ́ March 1, 2004, ojú ìwé 13 sí 18, àti December 1, 1992, ojú ìwé 13.
b A tẹ ìrírí rẹ̀ jáde nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti March 1, 1988, ojú ìwé 10 sí 17.
Àtúnyẹ̀wò
• Ta ni Aṣáájú wa, kí ló sì fi hàn pé ó mọ ohun tó ń lọ nínú àwọn ìjọ?
• Nígbà ìbẹ̀wò sí “tẹ́ńpìlì,” àwọn wo ló ń ṣe iṣẹ́ wọn bí ẹrú olóòótọ́, àwọn ohun ìní wo la sì fi síkàáwọ́ wọn?
• Àwọn ìdí wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fi yẹ ká máa gbárùkù ti ẹrú olóòótọ́ náà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Àwọn ohun ìní” tí “ìríjú” náà ń bójú tó kan àwọn ilé tí à ń lò, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, àti iṣẹ́ ìwàásù wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn àgùntàn mìíràn ń gbárùkù ti ẹrú olóòótọ́ náà nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe tọkàntọkàn