Ìtàn Ìgbésí Ayé
À Ń Tukọ̀ Lọ Sí Ayé Tuntun
Gẹ́gẹ́ Bí Jack Pramberg Ṣe Sọ Ọ́
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ kan sítòsí ìlú Arboga, ìyẹn ìlú kékeré kan tó lẹ́wà gan-an ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Sweden. Àwa tá a yọ̀ǹda ara wa, tá à ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lé lọ́gọ́rin. Ibí yìí lèmi àti Karin, ìyàwó mi ń gbé, ibẹ̀ la sì ti ń ṣiṣẹ́. Báwo la ṣe dé ibí yìí?
NÍ NǸKAN bí àádọ́fà ọdún sẹ́yìn, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tó tún jẹ́ ará Sweden lọ ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ibì kan tí wọ́n máa ń fi àwọn àjèjì sí nílùú New York City lòun àti atukọ̀ ojú omi kan tó jẹ́ ará Sweden ti pàdé ara wọn. Àwọn méjèèjì wá nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an, wọ́n ṣègbéyàwó, wọ́n sì bí ọmọkùnrin kan. Èmi ni ọmọkùnrin náà. Ìlú Bronx, tó wà ní New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1916, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ń lọ lọ́wọ́.
Kété lẹ́yìn ìyẹn la kó lọ sílùú Brooklyn, a sì ń gbé ibì kan tí kò jìnnà rárá sí àdúgbò Brooklyn Heights. Bàbá mi sọ fún mi nígbà kan pé a gba itòsí afárá Brooklyn kọjá nígbà tóun mú mi lọ tukọ̀ ojú omi kan tí wọ́n ní kí wọ́n dán wò. Téèyàn bá wà ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó lè máa wo ibi tó sọ yẹn kedere. Mi ò mọ̀ nígbà yẹn pé ohun tí wọ́n ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì máa wá nípa tó lágbára gan-an lórí ìgbésí ayé mi.
Ogun Àgbáyé Kìíní parí lọ́dún 1918, pípa tí wọ́n ń pa àwọn èèyàn nípakúpa nílẹ̀ Yúróòpù sì dáwọ́ dúró fúngbà díẹ̀. Àwọn sójà wá padà sílùú wọn, àmọ́ ńṣe ni wọ́n lọ dojú kọ ìṣòro mìíràn, ìyẹn ni àìríṣẹ́ṣe àti àìlówólọ́wọ́. Bàbá mi rí i pé ohun tó dára jù lọ ni pé ká padà sí orílẹ̀-èdè Sweden, a sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dún 1923. Abúlé kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Erikstad tó wà nítòsí ibùdó ọkọ̀ ojú irin kan lágbègbè Dalsland la wá fìdí kalẹ̀ sí. Ibẹ̀ ni bàbá mi ṣí ṣọ́ọ̀bù kan sí tó ti ń tún ẹ̀rọ ṣe, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti tọ́ mi dàgbà tí mo sì ti lọ sílé ìwé.
Irúgbìn Kan Ń Dàgbà Nínú Ọkàn Mi
Iṣẹ́ tí bàbá mi ń ṣe ò fi bẹ́ẹ̀ mówó wọlé. Ó sì padà sídìí iṣẹ́ atukọ̀ ojú omi ní nǹkan bí ọdún 1932. Ó wá ku èmi àti màmá mi nìkan nílé. Màmá mi ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń dà á lọ́kàn rú, èmi sì ń bójú tó ṣọ́ọ̀bù bàbá mi. Lọ́jọ́ kan, màmá mi lọ sọ́dọ̀ àna rẹ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johan. Nítorí pé gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ láyé tójú sú màmá mi, ó bi àna rẹ̀ yìí pé: “Johan, ṣé báyé á ṣe máa rí lọ nìyí?”
Ìyẹn fèsì pé: “Rárá o Ruth.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa fòpin sí ìwà ibi, òun á mú Ìjọba òdodo tó máa ṣàkóso lórí ayé wá, Jésù Kristi ni yóò sì jẹ́ Ọba. (Aísáyà 9:6, 7; Dáníẹ́lì 2:44) Ó ṣàlàyé pé Ìjọba tí Jésù ní ká máa gbàdúrà fún ni ìṣàkóso tàbí ìjọba òdodo tó máa sọ ayé di Párádísè.—Mátíù 6:9, 10; Ìṣípayá 21:3, 4.
Àwọn ìlérí inú Bíbélì wọ̀nyẹn wọ màmá mi lọ́kàn gan-an. Bó ṣe ń padà bọ̀ nílé nìyẹn, gbogbo bó ṣe ń rìn bọ̀ lọ́nà ló ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Àmọ́, inú èmi àti bàbá mi ò dùn sí bí màmá mi ṣe wá dẹni tó gbé ọ̀ràn ẹ̀sìn karí. Àárín àkókò yìí, ìyẹn ní nǹkan bí ọdún 1935 ni mo lọ ń gbé nílùú Trollhättan ní ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Sweden, níbi tí mo ti wá ríṣẹ́ sí iléeṣẹ́ ńlá kan tí wọ́n ti ń tún ẹ̀rọ ṣe. Kò pẹ́ sí àkókò yẹn tí màmá mi àti bàbá mi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fi iṣẹ́ atukọ̀ òkun sílẹ̀ fi kó wá síbi tí mo wà. Bí ìdílé wa tún ṣe wà pa pọ̀ nìyẹn.
Màmá mi fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa Ọlọ́run, ó wá wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè yẹn kàn. Ilé ẹnì kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ti máa ń ṣèpàdé lákòókò yẹn, bíi tàwọn Kristẹni ìjímìjí. (Fílémónì 1, 2) Lọ́jọ́ kan, ilé màmá mi ló kàn táwọn Ẹlẹ́rìí ti máa wá ṣèpàdé. Tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù ni màmá mi fi bi bàbá mi bóyá òun lè pe àwọn ọ̀rẹ́ òun wá sílé wa. Bàbá mi fún un lésì pé, “Ọ̀rẹ́ tèmi náà làwọn ọ̀rẹ́ rẹ.”
Báwọn èèyàn ṣe wá sílé wa nìyẹn. Bí wọ́n ṣe ń wọlé lèmi ń jáde. Àmọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá wá ṣèpàdé. Ọ̀yàyà àwọn Ẹlẹ́rìí náà àti bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu wá mú gbogbo ẹ̀tanú tó wà lọ́kàn mi kúrò pátá. Irúgbìn kan wá bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, ìyẹn ni ìrètí pé ọ̀la á dára.
Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Atukọ̀ Òkun
Ó ní láti jẹ́ pé iṣẹ́ atukọ̀ òkun tí bàbá mi ṣe ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ mi, nítorí pé èmi náà lọ ṣe iṣẹ́ atukọ̀ òkun. Àmọ́, mo tún rí i pé ó yẹ kí n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Nígbà tí ọkọ̀ wa bá gúnlẹ̀ sí èbúté, mo máa ń gbìyànjú láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn. Kódà, nígbà tá a wà nílùú Amsterdam, nílẹ̀ Holland (tó ti di Netherlands báyìí), ilé ìfìwéránṣẹ́ ni mo lọ láti lọ béèrè ibi tí mo ti lè rí wọn. Lẹ́yìn témi pẹ̀lú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ jọ jíròrò fúngbà díẹ̀, wọ́n fún mi ní àdírẹ́sì kan, mo sì lọ síbẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá ló ṣílẹ̀kùn fún mi tó sì kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Àjèjì ni mo jẹ́ níbẹ̀ o, àmọ́ ojú ẹsẹ̀ ni èmi àti ọmọbìnrin náà àti ìdílé rẹ̀ dọ̀rẹ́, mo wá rí i pé àwọn èèyàn wọ̀nyí ṣọ̀kan kárí ayé!
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò sọ èdè kan náà, síbẹ̀ nígbà tí ìdílé náà mú kàlẹ́ńdà kan jáde tí wọ́n sì fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbà táwọn ọkọ ojú irin máa ń gbéra hàn mí, tí wọ́n tún ń yàwòrán ibi tí ọkọ̀ náà máa gbà, mo wá lóye pé àpéjọ kan máa wáyé nílùú Haarlem tí kò jìnnà síbẹ̀. Mo lọ sí àpéjọ náà, mo sì gbádùn rẹ̀ gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò gbọ́ nǹkan kan nínú gbogbo ohun tí wọ́n sọ. Nígbà tí mo rí àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń pín ìwé ìkésíni tí wọ́n fi ń pe àwọn èèyàn wá síbi àsọyé tó máa wáyé lọ́jọ́ Sunday, ó ṣe mí bíi pé kémi náà bá wọn pín ìwé ìkésíni náà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣa èyí táwọn èèyàn jù dànù mo sì ń tún wọn pín fáwọn ẹlòmíì.
Nígbà kan, ọkọ̀ ojú omi wa gúnlẹ̀ sílùú Buenos Aires, nílẹ̀ Ajẹntínà, mo sì rí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀. Ọ́fíìsì kan àti yàrá ìkẹ́rùsí kan wà nínú ilé náà. Mo rí obìnrin kan tó ń hun aṣọ nídìí tábìlì kan níbẹ̀, ọmọbìnrin kékeré kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọmọ rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tó ń fi bèbí ṣeré. Ilẹ̀ ti ṣú gan-an lọ́jọ́ yẹn, mo sì rí ọkùnrin kan tó ń mú àwọn ìwé kan níbi tí wọ́n ń to ìwé sí. Ìwé Creation lédè Sweden wà lára àwọn ìwé náà. Nígbà tí mo rí ayọ̀ tí wọ́n ní àti bí wọ́n ṣe kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà, ojú ẹsẹ̀ yẹn ló ti wù mí kémi náà jẹ́ ọ̀kan lára wọn.
Nígbà tá à ń padà bọ̀ wálé, ọkọ̀ ojú omi wa gbé àwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ òfuurufú kan tó já lulẹ̀ létíkun Newfoundland. Ọkọ̀ òfuurufú àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Kánádà ni ọkọ̀ náà. Lọ́jọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, a wà nítòsí ilẹ̀ Scotland, níbi táwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi kan tó jẹ́ tàwọn ọmọ ogun ojú omi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti mú wa. Wọ́n mú wa lọ sílùú Kirkwall tó wà ní erékùṣù Orkney láti fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò. Ogun Àgbáyé Kejì ti bẹ̀rẹ̀ nígbà yẹn, àwọn ọmọ ogun Hitler lábẹ́ ìjọba Násì sì ti gbogun wọ ilẹ̀ Poland lóṣù September ọdún 1939. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n dá wa sílẹ̀, a sì padà sílẹ̀ Sweden láìsí ìṣòro kankan.
Mo wá dé sílé lọ̀nà méjì wàyí, yàtọ̀ sí pé mo délé láyọ̀, mo tún ti múra tán láti sin Ọlọ́run. Ní báyìí, mo múra tán láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run, mo sì fẹ́ máa bá wọn ṣèpàdé déédéé. (Hébérù 10:24, 25) Inú mi dùn pé nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ atukọ̀ òkun, mo máa ń jẹ́rìí fáwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, mo sì mọ̀ pé ọ̀kan lára wọn di Ẹlẹ́rìí.
Iṣẹ́ Ìsìn Kan Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀
Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1940, mo lọ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Stockholm. Arákùnrin Johan H. Eneroth, tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù nílẹ̀ Sweden lákòókò yẹn sì kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Nígbà tí mo sọ fún un pé mo fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà, kí n máa wàásù ní gbogbo ìgbà, ó tẹjú mọ́ mi, ó wá bi mí pé, “Ǹjẹ́ o gbà pé ètò Ọlọ́run lèyí?”
Mo fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Ìyẹn ló mú kí n ṣèrìbọmi ní June 22, ọdún 1940, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ yìí tó wà ní àyíká kan tó lẹ́wà gan-an. Àwòfiṣàpẹẹrẹ làwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Ẹnu iṣẹ́ ìwàásù la ti máa ń lo àwọn òpin ọ̀sẹ̀ wa. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, a máa ń gun kẹ̀kẹ́ lọ sáwọn ìpínlẹ̀ tó jìnnà gan-an, a ó fi gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ náà wàásù, orí koríko tí wọ́n kó jọ la sì máa ń sùn lálẹ́.
Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé inú ìlú Stockholm àtàwọn àgbègbè rẹ̀ la ti máa ń wàásù láti ilé dé ilé. Nígbà kan, mo rí ọkùnrin kan ní àjà ilẹ̀ ilé rẹ̀, tó ń fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ lórí àgbá omi gbígbóná rẹ̀ tó ń jò. Mo wá ká apá aṣọ mi sókè, mo sì ràn án lọ́wọ́. Nígbà tí ibi tó ń jò náà dí, ọkùnrin náà wo ojú mi, ó fi ìmọrírì hàn, ó sì sọ pé: “Mo mọ̀ pé nǹkan mìíràn lo bá wá. Jẹ́ ká gòkè, ká lọ fọwọ́ wa ká sì mu kọfí.” A ṣe bẹ́ẹ̀, ibi tá a sì ti ń mu kọfí yẹn lọ́wọ́ ni mo ti jẹ́rìí fún un. Láìpẹ́, òun náà di Kristẹni bíi tèmi.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Sweden sọ pé òun ò lọ́wọ́ nínú ogun tó ń lọ lọ́wọ́ nígbà yẹn, síbẹ̀ ogun náà nípa lórí àwọn ará Sweden. Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin ni wọ́n ní kó wá wọṣẹ́ ológun, wọ́n sì pe èmi náà pẹ̀lú. Nígbà tí mo kọ̀ láti lọ kọ́ṣẹ́ ogun jíjà, wọ́n fi mí sẹ́wọ̀n láwọn ìgbà kan, àmọ́ mi ò pẹ́ níbẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n mú mi lọ sí àgọ́ tí wọ́n ti máa ń mú àwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sábà máa ń mú àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọ̀dọ́ lọ síwájú àwọn adájọ́, ìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ pé: “Wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.”—Mátíù 10:18.
Ìgbésí Ayé Mi Yí Padà
Lọ́dún 1945, ogun parí nílẹ̀ Yúróòpù. Nígbà tí ọdún yẹn ń lọ sópin, Arákùnrin Nathan H. Knorr, tó ń bójú tó iṣẹ́ wa jákèjádò ayé nígbà yẹn wá sọ́dọ̀ wa láti Brooklyn, Arákùnrin Milton Henschel tó jẹ́ akọ̀wé rẹ̀ sì bá a wá. Wíwá tí wọ́n wá yẹn jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì gan-an fún àtúntò iṣẹ́ ìwàásù nílẹ̀ Sweden, ó sì tún ṣe èmi alára pàápàá láǹfààní tó ga. Nígbà tí mo gbọ́ pé mo lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, kíá ni mo forúkọ sílẹ̀.
Ọdún tó tẹ̀ lé e ni mo lọ sílé ẹ̀kọ́ náà, tó wà nítòsí ìlú South Lansing ní New York nígbà yẹn. Láàárín oṣù márùn-ún tá a fi gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yẹn, mo kọ́ ẹ̀kọ́ tó túbọ̀ jẹ́ kí n mọrírì Bíbélì àti ètò Ọlọ́run sí i. Mo rí i pé àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù náà kárí ayé jẹ́ àwọn tára wọn yọ̀ mọ́ọ̀yàn tí wọ́n sì máa ń gba tẹni rò. Ńṣe làwọn àtàwa jọ máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. (Mátíù 24:14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èyí ò yà mí lẹ́nu, inú mi dùn pé mo fojú ara mi rí i.
Kò pẹ́ rárá tí February 9, ọdún 1947 fi pé, tí àwa tá a wà ní kíláàsì kẹjọ ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sì ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege. Arákùnrin Knorr kéde orílẹ̀-èdè tí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan máa lọ. Nígbà tó kàn mí, ó ní, “Arákùnrin Pramberg yóò padà sí orílẹ̀-èdè Sweden láti lọ ran àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́ níbẹ̀.” Kí n sòótọ́, inú mi ò fi bẹ́ẹ̀ dùn pé mò ń padà sílé.
Mo Gba Iṣẹ́ Ìsìn Kan Tó Nira
Nígbà tí mo padà dé orílẹ̀-èdè Sweden, mo gbọ́ nípa iṣẹ́ ìsìn tuntun kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè jákèjádò ayé, ìyẹn ni iṣẹ́ àbójútó àgbègbè. Èmi ni wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè àkọ́kọ́ nílẹ̀ Sweden, iṣẹ́ mi sì gba pé kí n bójú tó bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń lọ ní gbogbo orílẹ̀-èdè Sweden. Èmi ni mo ṣètò àwọn àpéjọ tá a wá mọ̀ sí ìpàdé àyíká lónìí, tí mo sì bójú tó gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. A ṣe àpéjọ yìí láwọn ìlú ńlá àtàwọn ìlú kéékèèké jákèjádò ilẹ̀ Sweden. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé a ò ṣe irú ètò yìí rí, ìwọ̀nba ìtọ́ni díẹ̀ ni mo rí gbà. Èmi àti Arákùnrin Eneroth jọ jókòó, a sì ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan bí òye wa ṣe mọ. Iṣẹ́ yìí ṣẹ̀rùbà mí gan-an, àìmọye ìgbà ni mo sì gbàdúrà sí Jèhófà. Odindi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún gbáko ni mo fi ṣe iṣẹ́ alábòójútó àgbègbè.
Láyé ìgbà yẹn, kò rọrùn rárá láti ríbi tó bójú mu tá a lè lò fún àpéjọ. A ní láti máa lo àwọn ilé ijó àtàwọn ibòmíràn bẹ́ẹ̀, àwọn ohun ìmúlé-móoru tó máa ń wà níbẹ̀ kì í tó, ibẹ̀ kì í sì í bójú mu. Àpẹẹrẹ irú èyí ni àpéjọ kan tá a ṣe lábúlé kan tó ń jẹ́ Rökiö, ní Finland. Ògbólógbòó gbọ̀ngàn kan táwọn èèyàn ti pa tì fúngbà díẹ̀ la lò. Yìnyín ń wọ̀, òtútù sì mú gan-an. A wá dáná sínú àwọn àgbá ńláńlá méjì. A ò mọ̀ pé àwọn ẹyẹ ti kọ́lé sójú ihò tí èéfín máa ń gbà jáde. Bí èéfín ṣe bò wá mọ́lẹ̀ nìyẹn! Síbẹ̀, pẹ̀lú bá a ṣe yí aṣọ òtútù mọ́ra tójú sì ń ta wá fòò, ńṣe ni gbogbo wa jókòó síbẹ̀. Ó wá jẹ́ kí àpéjọ yẹn jẹ́ mánigbàgbé lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.
Lára ohun tí wọ́n ní ká ṣe láti múra àwọn ìpàdé àyíká ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí sílẹ̀ ni pé ká ṣètò oúnjẹ fáwọn tó máa wá sípàdé náà. Lákọ̀ọ́kọ́, a ò ní ohun èlò, a ò sì ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rí. Àmọ́, a láwọn arákùnrin àti arábìnrin àtàtà tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yìí. Lọ́jọ́ tó ku ọ̀la kí ìpàdé àyíká náà bẹ̀rẹ̀, ńṣe ni wọ́n kóra jọ sídìí ọpọ́n ńlá kan tí wọ́n ń bẹ ànàmọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọ ìrírí, tínú wọn sì ń dùn. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n wá dọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nígbà tó yá ló jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yẹn lọ̀rẹ́ wọn ti bẹ̀rẹ̀.
Ká máa yan kiri pẹ̀lú àkọlé gàdàgbà tá a fi ń polongo ìpàdé àyíká jẹ́ ara nǹkan tá a máa ń ṣe nígbà yẹn lọ́hùn-ún. A ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ gba àárín ìlú tàbí abúlé kan kọjá, a ó sì máa pe àwọn tó ń gbé níbẹ̀ pé kí wọ́n wá síbi àsọyé fún gbogbo èèyàn. Àwọn èèyàn lápapọ̀ sábà máa ń fìfẹ́ hàn sí wa, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wa. Nígbà kan tá a wà nílùú Finspång, àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń rọ́ jáde látinú ilé iṣẹ́ ńlá kan kún gbogbo ojú pópó. Ọ̀kan lára wọn ṣàdédé pariwo pé: “Ẹ̀yìn èèyàn mi, ẹ wo àwọn èèyàn tí Hitler ò lè borí!”
Ohun Ńlá Kan Ṣẹlẹ̀ Nígbèésí Ayé Mi
Ìgbésí ayé tí mo ti ń gbé bọ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò yí padà kété lẹ́yìn tí mo pàdé Karin, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ gidi. Àwa méjèèjì ni wọ́n pè sí ìpàdé àgbáyé tó wáyé ní Yankee Stadium, New York City, lóṣù July, ọdún 1953. Ibi ìpàdé àgbáyé yẹn gan-an ni Arákùnrin Milton Henschel ti darí ètò ìgbéyàwó wa lákòókò ìsinmi ọ̀sán lọ́jọ́ Monday, tó jẹ́ ogúnjọ́ oṣù náà. Ó jẹ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ kan tí kì í sábà wáyé ní pápá ìṣeré tó lókìkí gan-an yìí. Lẹ́yìn témi àti Karin ti jọ ṣiṣẹ́ arìnrìn-àjò títí di ọdún 1962, wọ́n ní ká wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílẹ̀ Sweden. Mo kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìwé Ìròyìn. Lẹ́yìn ìyẹn, nítorí pé mo kọ́ iṣẹ́ títún ẹ̀rọ ṣe, wọ́n ní kí n máa bójú tó àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àtàwọn ẹ̀rọ mìíràn tó wà ní ẹ̀ka náà. Karin ṣiṣẹ́ fún ọdún bíi mélòó kan níbi aṣọ fífọ̀. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ló ti wá ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń kàwé láti ṣàtúnṣe sáwọn àṣìṣe tó bá wà níbẹ̀.
Àwa méjèèjì ti jọ gbádùn ìgbésí ayé tó lárinrin tó sì láyọ̀ gan-an látohun tó lé lọ́dún mẹ́rìnléláàádọ́ta tá a ti jọ ń ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya! Láìsí àní-àní, Jèhófà ti bù kún ètò rẹ̀ tó kún fún àwọn òjíṣẹ́ onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára. Lọ́dún 1940, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] Ẹlẹ́rìí péré ló wà nílẹ̀ Sweden nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Àmọ́ a ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìlélógún [22,000] báyìí. A tiẹ̀ tún pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ láwọn apá ibòmíràn láyé, débi pé a ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àtààbọ̀ jákèjádò ayé báyìí.
Ẹ̀mí Jèhófà ń ti iṣẹ́ wa lẹ́yìn, gbogbo ìgbà ló sì ń mú ká tẹ̀ síwájú bí ìgbòkun ṣe ń mú kí ọkọ̀ òkun tẹ̀ síwájú. A ò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa yẹ̀ bá a ti ń wo ọmọ aráyé tí wọ́n ń ru gùdù bí òkun, ẹ̀rù ò sì bà wá. Bá a ṣe ń tukọ̀ lọ, à ń wo ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí lọ́ọ̀ọ́kán. Èmi àti Karin dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí gbogbo oore rẹ̀, ojoojúmọ́ la sì ń gbàdúrà pé kó fún wa lókun ká lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ lọ láìyẹsẹ̀, kí ọwọ́ wa sì tẹ ohun tá à ń lé, ìyẹn ojú rere Ọlọ́run àti ìyè ayérayé!—Mátíù 24:13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Màmá mi gbé mi lẹ́sẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1920, ibí yìí lèmi àti bàbá mi ti lọ tu ọkọ ojú omi tí wọ́n ní kí wọ́n dán wò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Èmi àti Herman Henschel (bàbá Milton) ní Gílíádì, lọ́dún 1946
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
A ṣègbéyàwó ní Pápá Ìṣeré Yankee ní July 20, ọdún 1953