Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Báwo ni òkun dídà tó wà nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ ṣe tóbi tó?
Àwọn Ọba Kìíní orí keje, ẹsẹ kẹrìndínlọ́gbọ̀n sọ pé òkun dídà náà gba “ẹgbàá òṣùwọ̀n báàfù” omi, èyí táwọn àlùfáà ń lò, nígbà tí ìwé 2 Kíróníkà 4:5 tóun náà sọ̀rọ̀ nípa òkun yìí kan náà sọ pé ó gba “ẹgbẹ̀ẹ́dógún òṣùwọ̀n báàfù” omi. Èyí ti mú káwọn kan sọ pé ẹni tó ṣe àdàkọ ìwé Kíróníkà Kejì ló ṣàṣìṣe tí àkọsílẹ̀ méjèèjì yìí kò fi bára mu.
Ṣùgbọ́n, Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jẹ́ ká rí ìdí tí ẹsẹ Bíbélì méjèèjì kò fi ta kora. Àwọn Ọba Kìíní orí keje, ẹsẹ kẹrìndínlọ́gbọ̀n kà pé: “Ẹgbàá òṣùwọ̀n báàfù ni ó ń gbà.” Ohun tí 2 Kíróníkà 4:5 sì sọ ni pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìkóhunsí, ẹgbẹ̀ẹ́dógún òṣùwọ̀n báàfù ni ó lè gbà.” Nítorí náà, ńṣe ni 2 Kíróníkà 4:5 ń sọ bí òkun náà ṣe tóbi tó, ìyẹn ìwọ̀n omi tí ó lè gbà. Nígbà tí 1 Àwọn Ọba 7:26 ń sọ iye báàfù omi tí wọ́n sàbá máa ń pọn sínú rẹ̀. Ìyẹn ni pé wọn kì í pọn omi kún inú òkun dídà náà. Ó jọ pé ẹgbàá òṣùwọ̀n báàfù omi ni wọ́n sábà máa ń pọn sí i.
Kí nìdí tó fi jẹ́ ẹyọ owó kan ṣoṣo ni Jésù àti Pétérù fi san owó orí tí wọ́n ń san ní tẹ́ńpìlì?
Nígbà tí Jésù wà láyé, gbogbo ọmọ Júù tó jẹ́ ọkùnrin tó ti lé lógún ọdún ló ní láti máa san owó dírákímà méjì alápapọ̀ tàbí ẹyọ dírákímà méjì lọ́dún, ìyẹn owó orí tí wọ́n ń san nínú tẹ́ńpìlì. Èyí sì tó nǹkan bí owó iṣẹ́ ọjọ́ méjì. Nígbà tí ọ̀rọ̀ owó orí sísan délẹ̀, Jésù sọ fún Pétérù pé: “Lọ sí òkun, ju ìwọ̀ ẹja kan, sì mú ẹja tí ó kọ́kọ́ jáde wá, nígbà tí o bá sì la ẹnu rẹ̀, ìwọ yóò rí ẹyọ owó sítátà kan. Mú ìyẹn, kí o sì fi í fún wọn fún èmi àti ìwọ.”—Mátíù 17:24-27.
Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé gbà pé owó dírákímà mẹ́rin alápapọ̀ ni ẹyọ owó sítátà kan tí ibí yìí ń sọ, èyí tó tó láti fi san owó orí ẹni méjì. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, owó dírákímà mẹ́rin alápapọ̀ wọ́pọ̀ ju owó dírákímà méjì alápapọ̀ lọ. Ìwé àtumọ̀ èdè náà The New Bible Dictionary, tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Ó jọ pé Júù méjì-méjì ló sábà máa ń pa pọ̀ san owó orí tí wọ́n ń san nínú Tẹ́ńpìlì.”
Yàtọ̀ síyẹn, tẹ́nì kan bá fẹ́ dá owó orí tara rẹ̀ san, yóò ní láti kọ́kọ́ ṣẹ́ owó, wọ́n sì máa gba iye kan lórí owó tó bá ṣẹ́ náà. Ká ní owó tónítọ̀hún fẹ́ ṣẹ́ jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún náírà, nígbà míì wọ́n á gbà tó náírà mẹ́jọ lọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́ táwọn méjì bá pa pọ̀ san owó orí yìí, wọn ò ní sanwó fẹ́nikẹ́ni láti bá wọn ṣẹ́ owó. Ẹ ò rí i pé kúlẹ̀kúlẹ̀ tó wà nínú ìwé Mátíù yìí bá ohun táwọn èèyàn sábà máa ń ṣe nígbà ayé Jésù mu gan-an!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Owó dírákímà mẹ́rin alápapọ̀ tá a sọ di ńlá