Kí Nìdí Tá a Fi Ń gbàdúrà Lórúkọ Jésù?
Ọ̀PỌ̀ ìgbà ni Jésù kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè máa gbàdúrà. Ńṣe làwọn aṣáájú ìsìn Júù ìgbà ayé rẹ̀ máa ń gbàdúrà ní “àwọn igun oríta.” Nítorí kí ni? Nítorí “kí àwọn ènìyàn bàa lè rí wọn” ni. Ńṣe ni wọ́n ń fẹ́ káwọn èèyàn máa kan sáárá sí wọn pé wọ́n ní ìtara ìsìn. Ọ̀pọ̀ máa ń gba àdúrà gígùn jàn-ànràn jan-anran, wọ́n á máa sọ ohun kan náà lásọtúnsọ, nítorí wọ́n rò pé “lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀” ló máa jẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wọn. (Mátíù 6:5-8) Jésù fi hàn pé asán ni ohun tí wọ́n ń ṣe, ìyẹn sì jẹ́ káwọn olóòótọ́ èèyàn mọ ohun tó yẹ kí wọ́n yàgò fún tí wọ́n bá ń gbàdúrà. Àmọ́, kì í ṣe ohun tó yẹ kéèyàn yàgò fún nínú àdúrà nìkan ni Jésù kọ́ni.
Jésù kọ́ni pé ó yẹ ká fi hàn nínú àdúrà wa pé a fẹ́ kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí ìfẹ́ Rẹ̀ sì ṣẹ. Ó tún kọ́ni pé, a lè bẹ Ọlọ́run pé kó ṣe àwọn nǹkan kan fún wa. (Mátíù 6:9-13; Lúùkù 11:2-4) Ó lo àpèjúwe láti fi jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà wa, a nílò ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà gbígbà. (Lúùkù 11:5-13; 18:1-14) Àpẹẹrẹ òun fúnra rẹ̀ sì tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tó gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.—Mátíù 14:23; Máàkù 1:35.
Ó dájú pé ìtọ́ni Jésù jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè gbàdúrà lọ́nà tó sunwọ̀n sí i. Àmọ́, alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé ló tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù nípa àdúrà gbígbà.
“Àyípadà Pàtàkì Nínú Àdúrà Gbígbà”
Jésù lo àkókò tó pọ̀ gan-an ní alẹ́ tó lò kẹ́yìn láyé láti fi gba àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ níyànjú. Ó sì rí i pé ìgbà yẹn gan-an ló dáa jù láti jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tuntun kan. Ó ní: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” Lẹ́yìn náà, ó wá ṣèlérí fún wọn pé: “Ohun yòówù kí ó jẹ́ tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe èyí dájúdájú, kí a lè yin Baba lógo ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọmọ. Bí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe é dájúdájú.” Nígbà tó kù díẹ̀ kó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Títí di ìsinsìnyí, ẹ kò tíì béèrè ẹyọ ohun kan ní orúkọ mi. Ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí a lè sọ ìdùnnú yín di kíkún.”—Jòhánù 14:6, 13, 14; 16:24.
Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an ni. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ Jésù yìí jẹ́ “àyípadà pàtàkì nínú àdúrà gbígbà.” Kì í ṣe pé Jésù ń fẹ́ ká máa gbàdúrà sóun dípò Ọlọ́run o. Ńṣe ló kàn ń jẹ́ ká mọ ọ̀nà tuntun tá a lè máa gbà bá Jèhófà Ọlọ́run sọ̀rọ̀.
Lóòótọ́, Ọlọ́run ti máa ń gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ látẹ̀yìnwá. (1 Sámúẹ́lì 1:9-19; Sáàmù 65:2) Àmọ́ látìgbà tí Ọlọ́run ti bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú, gbogbo àwọn tó bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wọn gbọ́dọ̀ gbà pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nìkan ni Ọlọ́run yàn. Lẹ́yìn náà, láti ìgbà ayé Sólómọ́nì, àwọn tó bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wọn gbọ́dọ̀ gbà pé tẹ́ńpìlì ni Ọlọ́run fọwọ́ sí pé káwọn èèyàn ti máa rúbọ. (Diutarónómì 9:29; 2 Kíróníkà 6:32, 33) Àmọ́, ọ̀nà ìjọsìn yẹn kò wà títí lọ gbére. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ẹbọ tí wọ́n ń rú nínú tẹ́ńpìlì jẹ́ “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe kókó inú àwọn ohun náà gan-an.” (Hébérù 10:1, 2) Nígbà tí Kristi tó jẹ́ ohun gidi sì dé, àwọn ohun tó jẹ́ òjìji yẹn ò wúlò mọ́. (Kólósè 2:17) Látọdún 33 Sànmánì Kristẹni ló ti di pé kò dìgbà téèyàn bá pa Òfin Mósè mọ́ kéèyàn tó lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tó bá máa ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà gbọ́dọ̀ máa ṣègbọ́ràn sí ẹni tí Òfin Mósè tọ́ka sí, ìyẹn Kristi Jésù.—Jòhánù 15:14-16; Gálátíà 3:24, 25.
Orúkọ Kan “Tí Ó Lékè Gbogbo Orúkọ Mìíràn”
Jésù jẹ́ ká mọ ọ̀nà pàtàkì tá a óò máa gbà bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé òun ni ọ̀rẹ́ wa àtàtà, ẹni tí Ọlọ́run ń tipasẹ̀ rẹ̀ gbọ́ àdúrà wa. Kí ló jẹ́ kí Jésù lè ṣe nǹkan yìí fún wa?
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo wa ni wọ́n bí ní ẹlẹ́ṣẹ̀, kò sírú iṣẹ́ ìsìn tá a lè ṣe, bẹ́ẹ̀ ni kò sírú ẹbọ tá a lè rú tó lè wẹ̀ wá mọ́ nínú àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún tàbí tó lè mú ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, Ọlọ́run wa mímọ́. (Róòmù 3:20, 24; Hébérù 1:3, 4) Àmọ́ Jésù tó jẹ́ èèyàn pípé fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ, ó fi ṣe ìràpadà gbogbo aráyé tó ń fẹ́ ìràpadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 5:12, 18, 19) Ní báyìí, àǹfààní ti ṣí sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tó ń fẹ́ kí Ọlọ́run wẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn mọ́ láti dẹni tó mọ́ lójú Jèhófà, kí wọ́n sì “ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ” lọ́dọ̀ rẹ̀, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù kí wọ́n sì máa gbàdúrà ní orúkọ rẹ̀.—Éfésù 3:11, 12.
Tá a bá ń gbàdúrà lórúkọ Jésù, ńṣe là ń fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú ọ̀nà mẹ́ta ó kéré tán, lára àwọn ọ̀nà tí Jésù gbà kópa nínú ìmúṣẹ àwọn ohun tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe. Àwọn ọ̀nà náà ni: (1) Òun ni “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run,” tí ẹbọ ìràpadà rẹ̀ jẹ́ ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (2) Jèhófà jí i dìde, ó sì ti wá di “àlùfáà àgbà” tó ń jẹ́ ká lè máa jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà náà. (3) Ipasẹ̀ rẹ̀ nìkan ni “ọ̀nà” tí àdúrà wa lè gbà dé ọ̀dọ̀ Jèhófà.—Jòhánù 1:29; 14:6; Hébérù 4:14, 15.
Tá a bá ń gbàdúrà lórúkọ Jésù, ńṣe là ń bọlá fún un. Kò sì burú pé ká bọlá fún un lọ́nà yẹn, nítorí ńṣe ni Jèhófà fẹ́ kó jẹ́ pé, “ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba . . . kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.” (Fílípì 2:10, 11) Èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù ni pé, tá a bá ń gbàdúrà lórúkọ Jésù ńṣe là ń fìyẹn yin Jèhófà lógo, ẹni tó fi Ọmọ rẹ̀ ṣe ìràpadà fún wa.—Jòhánù 3:16.
Bíbélì lo oríṣiríṣi orúkọ àti orúkọ òye láti fi ṣàpèjúwe Jésù ká bàa lè mọ bí ipa tó kó ti ṣe pàtàkì tó. Èyí ń jẹ́ ká lè mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní tá à ń jẹ nítorí ohun tí Jésù ti ṣe fún wa, àtàwọn ohun tó ń ṣe lọ́wọ́ àtèyí tó ṣì máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. (Wo àpótí náà “Ipa Pàtàkì Tí Jésù Kó,” ní ojú ìwé 14.) Dájúdájú, Ọlọ́run ti fún Jésù ní “orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.”a Gbogbo ọlá àṣẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ni Ọlọ́run sì ti fún un.—Fílípì 2:9; Mátíù 28:18.
Kì Í Ṣe Àṣà Kan Lásán
Lóòótọ́, tá a bá fẹ́ kí Jèhófà gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ máa gbà á ní orúkọ Jésù. (Jòhánù 14:13, 14) Àmọ́ kò yẹ ká wá máa lo gbólóhùn náà “ní orúkọ Jésù” lọ́nà wọ̀ǹdùrùkù bí àṣà kan lásán. Kí nìdí?
Wo àpèjúwe kan. Jẹ́ ká sọ pé oníṣòwò kan kọ lẹ́tà sí ọ, tó sì fi “èmi ni tiyín ní tòótọ́” parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń kọ lẹ́tà ìṣòwò. Ǹjẹ́ wàá rò pé oníṣòwò náà dìídì fẹ́ràn rẹ ni àbí ó kàn ń tẹ̀ lé ìlànà lẹ́tà kíkọ? Nítorí náà, tá a bá ń gbàdúrà kò yẹ ká kàn máa lo orúkọ Jésù ní ìlò wọ̀ǹdùrùkù lásán, bí ìgbà téèyàn kàn fi gbólóhùn ìkíni parí lẹ́tà ìṣòwò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ ká “máa gbàdúrà láìdabọ̀,” “gbogbo ọkàn-àyà” wa ló yẹ ká máa fi gbà á, kó má ṣe jẹ́ àdúrà tá à ń gbà láìfọkàn sí i.—1 Tẹsalóníkà 5:17; Sáàmù 119:145.
Báwo lo ṣe lè yàgò fún lílo gbólóhùn náà “ní orúkọ Jésù” lọ́nà àṣà lásán? Ńṣe ni wàá ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ àtàtà tí Jésù ní. Ronú lórí ohun tó ti ṣe àtohun tó fẹ́ ṣe fún ọ. Nígbà tó o bá ń gbàdúrà, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, kó o sì máa yìn ín fún ọ̀nà àgbàyanu tó gbà lo Ọmọ rẹ̀. Tó o bá ṣe èyí, ìlérí tí Jésù ṣe á túbọ̀ dá ọ lójú. Ó sọ pé: “Bí ẹ bá béèrè fún ohunkóhun lọ́wọ́ Baba, yóò fi í fún yín ní orúkọ mi.”—Jòhánù 16:23.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words, èyí tó ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “orúkọ” níhìn-ín lè tọ́ka sí “gbogbo ohun tó rọ̀ mọ́ orúkọ náà, ìyẹn àṣẹ, ìwà, ipò, ọlá ńlá, agbára [àti] ìtayọlọ́lá orúkọ náà.”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]
“Gbogbo ọkàn-àyà” wa ló yẹ ká máa fi gbàdúrà, ká má máa gbàdúrà láìfọkàn sí i
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
IPA PÀTÀKÌ TÍ JÉSÙ KÓ
Ká lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa ipa tí Jésù kó, wo àwọn orúkọ oyè, àpèjúwe, àtàwọn orúkọ míì tí Bíbélì lò fún un.
Ádámù Ìkẹyìn.—1 Kọ́ríńtì 15:45.
Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn.—Aísáyà 9:6.
Alárinà.—1 Tímótì 2:5.
Àlùfáà Àgbà.—Hébérù 4:14, 15.
Àmín.—2 Kọ́ríńtì 1:19, 20; Ìṣípayá 3:14.
Àpọ́sítélì.—Hébérù 3:1.
Aṣáájú.—Mátíù 23:10.
Baba Ayérayé.—Aísáyà 9:6.
Ẹlẹ́rìí Aṣeégbíyèlé.—Ìṣípayá 1:5.
Ìmánúẹ́lì.—Mátíù 1:23.
Kristi/Mèsáyà.—Mátíù 16:16; Jòhánù 1:41.
Máíkẹ́lì Olú-áńgẹ́lì.—1 Tẹsalóníkà 4:16; Júúdà 9.
Olórí Aṣojú Ìyè.—Ìṣe 3:15.
Olùgbàlà.—Lúùkù 2:11.
Olùkọ́.—Jòhánù 13:13.
Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà.—Jòhánù 10:11.
Olúwa.—Jòhánù 13:13.
Onídàájọ́.—Ìṣe 10:42.
Orí Ìjọ.—Éfésù 5:23.
Ọba.—Ìṣípayá 11:15.
Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run.—Jòhánù 1:29.
Ọlọ́run Alágbára Ńlá.—Aísáyà 9:6.
Ọmọ Aládé Àlàáfíà.—Aísáyà 9:6.
Ọmọ Ènìyàn.—Mátíù 8:20.
Ọmọ Ọlọ́run.—Jòhánù 1:34.
Ọ̀rọ̀.—Jòhánù 1:1.