Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń jẹ Aráyé?
Ọlọ́run kọ́ ló ń fìyà jẹ aráyé. Bíbélì sọ pé: “Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú!” (Jóòbù 34:10) Ta wá lẹni tó ń fa ìyà ọ̀hún gan-an?
Jésù pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé.” (Jòhánù 14:30) Lóòótọ́, Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Kò sì ní gbé ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn. Àmọ́, ó fàyè gba Sátánì láti máa ṣàkóso èyí tó pọ̀ jù nínú ìran èèyàn fún àkókò kan.—1 Jòhánù 5:19.
Irú alákòóso wo la ti wá rí i pé Sátánì jẹ́ báyìí? Látìgbà tí Sátánì ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sọ́ràn aráyé la ti rí i pé apààyàn àti atannijẹ ni. Sátánì ń ṣe àwọn ọmọ aráyé ní jàǹbá lọ́pọ̀ ọ̀nà. Jésù sọ irú ẹni tó jẹ́, ó ní: “Apànìyàn ni ẹni yẹn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀, kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) Jésù tún sọ pé àwọn tó fẹ́ pa òun jẹ́ ọmọ Sátánì tó jẹ́ olórí apààyàn. Bí wọ́n ṣe sọ ara wọn di ọmọ rẹ̀ ni pé wọ́n ń ṣe bíi tiẹ̀. Ṣé ẹ sì mọ̀ pé ẹni bíni làájọ.
Sátánì ṣì ń gbin ẹ̀mí ìpànìyàn sọ́kàn àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àgbà ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ R. J. Rummel nílé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Hawaii, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, fojú bù ú pé láàárín ọdún 1900 sí 1987, iye èèyàn tí onírúurú ìjọba ti pa tó mílíọ̀nù mọ́kàndínláàádọ́sàn-án ó lé ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [169,198,000], látàrí pé àwọn èèyàn yìí fẹ́ lé ìjọba tí wọn ò fẹ́ wọlé tàbí látàrí pé àwọn ìjọba yẹn fẹ́ pa ẹ̀yà kan run àti látàrí pípa èèyàn nípakúpa. Àwọn tá a sọ yìí kò sí lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó kú sójú ogun láàárín àkókò kan náà yìí.
Tí kì í bá ṣe Ọlọ́run ló ń fa ìjìyà, kí wá ló dé tó fi fàyè gbà á? Ìdí tó fi fàyè gbà á ni pé àwọn ọ̀ràn méjì kan jẹ yọ, ó sì kan gbogbo ẹ̀dá alààyè. Ọ̀ràn yìí dá lórí ìbéèrè nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ó sì pọn dandan pé ká wá ojútùú sí i. Jẹ́ ká wo ọ̀kan péré lára wọn.
Níbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé àwọn èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, Ádámù àti Éfà lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Sátánì. Wọ́n kọ ìṣàkóso Ọlọ́run, wọ́n yàn láti máa ṣàkóso ara wọn, wọ́n sì tipa báyìí fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Èṣù.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Ìṣípayá 12:9.
Nítorí Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ó fàyè sílẹ̀ kí ẹ̀rí tó pọ̀ tó lè wà ká fi lè mọ irú ìṣàkóso tó tọ́. Kí wá làwọn ẹ̀rí kedere tá a rí yìí ti fi hàn? Wọ́n fi hàn pé Sátánì ló ń darí àwọn tó ń ṣàkóso ayé, kò sì sóhun tí èyí ń fa ju ìjìyà lọ. A ti wá rí i kedere báyìí pé àǹfààní ló jẹ́ fáwa èèyàn bí Ọlọ́run ṣe fún Èṣù láyè láti ṣàkóso ayé. Lọ́nà wo? Àǹfààní ló jẹ́ fáwọn tó ti kíyè sí àwọn ẹ̀rí tá a rí yìí tí wọ́n sì gbà pé òótọ́ ni, nítorí pé wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ìṣàkóso Ọlọ́run làwọn fara mọ́. Àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlànà Ọlọ́run tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé e ní ìrètí àtiwàláàyè títí láé.—Jòhánù 17:3; 1 Jòhánù 2:17.
Lóòótọ́, ìkáwọ́ Sátánì ni ayé yìí ṣì wà báyìí. Àmọ́ kò ní pẹ́ mọ́ tó fi máa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Láìpẹ́ láìjìnnà, Jèhófà máa lo Ọmọ rẹ̀ láti “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) Ọlọ́run máa darí Jésù láti tu àwọn tí ọkàn wọn gbọgbẹ́ nínú, á sì tún ìgbésí ayé àwọn táyé wọn ti bà jẹ́ ṣe. Ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn tó jìyà títí tí wọ́n fi kú láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún wá ni Jésù máa jí dìde padà sórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 11:25.
Jíjí tí Ọlọ́run jí Jésù dìde jẹ́ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé Ọlọ́run lágbára láti fọ́ iṣẹ́ Èṣù túútúú, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí ohun rere tó ń bọ̀ wá fáwọn èèyàn tó bá fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. (Ìṣe 17:31) Ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Bíbélì sọ jẹ́ ká lóye bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí, ó ní: “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú [aráyé]. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.