Orí 8
Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègba Ìjìyà?
1, 2. Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe sábà máa ń hùwàpadà sí ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn?
NÍGBÀ tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀, tí ó ba dúkìá jẹ́ tí ó sì mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lọ, ọ̀pọ̀ kò lè lóye ìdí tí àwọn nǹkan bíbanilẹ́rù bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀. Bí ìwà ìkà, àti ìwà-ọ̀daràn, àti ìwà-ipá ṣe pọ̀ tó tí ó sì rékọjá àkóso ń kó ìdààmú bá àwọn mìíràn. Ìwọ pẹ̀lú lè ti ṣe kàyéfì pé, ‘Èéṣe tí Ọlọrun fi fàyègba ìjìyà?’
2 Nítorí àìrí ìdáhùn tí ó tẹ́nilọ́rùn sí ìbéèrè yìí, ọ̀pọ̀ ti pàdánù ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun. Wọ́n nímọ̀lára pé kò nífẹ̀ẹ́-ọkàn nínú aráyé. Àwọn mìíràn tí wọ́n gba ìjìyà bí ìrírí ojoojúmọ́ di ẹni tí a mú bínú wọ́n sì di ẹ̀bi gbogbo ibi tí ó wà nínú àwùjọ aráyé ru Ọlọrun. Bí o bá ti ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí o lọ́kàn-ìfẹ́ nínú àwọn gbólóhùn inú Bibeli lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí.
ÌJÌYÀ KÒ WÁ LÁTI Ọ̀DỌ̀ ỌLỌRUN
3, 4. Ìdánilójú wo ni a ní pé ibi àti ìjìyà kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ Jehofa?
3 Bibeli mú un dá wa lójú pé Jehofa Ọlọrun kọ́ ni ó fa ìjìyà tí a rí ní àyíká wa. Fún àpẹẹrẹ, Kristian ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu kọ̀wé pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó máṣe wí pé: ‘Ọlọrun ni ó ń dán mi wò.’ Nitori a kò lè fi awọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọrun wò bẹ́ẹ̀ ni oun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jakọbu 1:13) Bí ìyẹn bá rí bẹ́ẹ̀, kò lè jẹ́ Ọlọrun ni ó ṣokùnfà ọ̀pọ̀ àwọn ìnira tí ń dààmú aráyé. Kì í mú àdánwò wá sórí ènìyàn láti mú kí wọ́n yẹ fún ìyè ní ọ̀run, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í mú kí ènìyàn jìyà fún láburú tí a lérò pé wọ́n ṣe nígbà ìwàláàyè wọn tí ó ti kọjá.—Romu 6:7.
4 Ní àfikún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ohun bíbanilẹ́rù ni a ti ṣe ní orúkọ Ọlọrun tàbí ti Kristi, kò sí ohunkóhun nínú Bibeli tí ó fi hàn pé èyíkéyìí nínú wọn fìgbà kan fọwọ́sí irú àwọn ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ọlọrun àti Kristi kò ní ohunkóhun láti ṣe pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn ń jọ́sìn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n ń rẹ́nijẹ tí wọ́n sì ń jẹ hàrámù, tí wọ́n ń pànìyàn tí wọ́n sì ń kóni nífà, tí wọ́n sì ń ṣe ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan mìíràn tí ń fa ìjìyà fún ẹ̀dá ènìyàn. Nítòótọ́, “ọ̀nà ènìyàn búburú, ìríra ni lójú Oluwa.” Ọlọrun “jìnnà sí àwọn ènìyàn búburú.”—Owe 15:9, 29.
5. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ Jehofa, báwo ni ó sì ṣe ń nímọ̀lára nípa àwọn ẹ̀dá rẹ̀?
5 Bibeli ṣàpèjúwe Jehofa gẹ́gẹ́ bí “oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jakọbu 5:11) Ó kéde pé “Oluwa fẹ́ ìdájọ́.” (Orin Dafidi 37:28; Isaiah 61:8) Kò ní ẹ̀mí ìforóyáró. Ó ń fi ìyọ́nú bójútó àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ ó sì ń fún gbogbo wọn ní ohun tí ó dára jùlọ fún ire aásìkí wọn. (Ìṣe 14:16, 17) Jehofa ti ṣe ìyẹn bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìwàláàyè lórí ilẹ̀-ayé.
ÌBẸ̀RẸ̀ PÍPÉ KAN
6. Báwo ni àwọn ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ díẹ̀ ṣe mẹ́nukan ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn aráyé?
6 Gbogbo wa ni rírí àti níní ìmọ̀lára ìrora àti ìjìyà kò ṣàjèjì sí. Nígbà náà ó lè ṣòro fún wa láti ronú ìgbà kan tí kò sí ìjìyà, ṣùgbọ́n bí àwọn nǹkan ti rí gan-an nìyẹn ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Kódà àwọn ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ ti àwọn orílẹ̀-èdè kan sọ nípa irú ìbẹ̀rẹ̀ aláyọ̀ kan bẹ́ẹ̀. Nínú ìtàn àròsọ àwọn Griki, àkọ́kọ́ nínú àwọn “Sànmánì Márùn-ún ti Ènìyàn” ni a pè ní “Sànmánì Oníwúrà.” Nínú rẹ̀, àwọn ènìyàn ń gbé ìgbésí-ayé aláyọ̀, tí kò ní làálàá, ìrora, àti ìyọrísí búburú ti ọjọ́ ogbó. Àwọn ará China sọ pé nínú ìtàn àròsọ lákòókò ìṣàkóso Olú-Ọba Yellow (Huang-Ti), àwọn ènìyàn ń gbé ní àlàáfíà, wọ́n ń gbádùn ìbáramuṣọ̀kan kódà pẹ̀lú ipò ojú-ọjọ́ àti àwọn ẹranko ẹhànnà. Àwọn ará Persia, Egipti, Tibet, Peru, àti Mexico ni gbogbo wọn ní àwọn ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ nípa àkókò kan tí ayọ̀ àti ìjẹ́pípé wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn aráyé.
7. Èéṣe tí Ọlọrun fi dá ilẹ̀-ayé àti ìran aráyé?
7 Àwọn ìtàn àròsọ àwọn orílẹ̀-èdè wulẹ̀ sọ àkọsílẹ̀ ọlọ́jọ́lórí ti ẹ̀dá ènìyàn, Bibeli, ní àsọtúnsọ ni. Ó sọ fún wa pé Ọlọrun fi ẹ̀dá ènìyàn méjì àkọ́kọ́, Adamu àti Efa, sínú paradise kan tí a pè ní ọgbà Edeni tí ó sì pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa rẹ̀, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀.” (Genesisi 1:28) Àwọn òbí wa àkọ́kọ́ gbádùn ìjẹ́pípé wọ́n sì ní ìrètí rírí gbogbo ilẹ̀-ayé tí ó di paradise tí àwọn ìdílé ẹ̀dá ènìyàn pípé yóò máa gbé inú rẹ̀ ní àlàáfíà àti ayọ̀ àìlópin. Ìyẹn jẹ́ ète Ọlọrun ní dídá ilẹ̀-ayé àti ìran aráyé.—Isaiah 45:18.
ÌPÈNÍJÀ ONÍNÚ-BURÚKÚ
8. Àṣẹ wo ni a retí pé kí Adamu àti Efa ṣègbọràn sí, ṣùgbọ́n kí ni ó ṣẹlẹ̀?
8 Láti máa ní ojúrere Ọlọrun nìṣó, Adamu àti Efa níláti fàsẹ́yìn kúrò nínú jíjẹ nínú “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” (Genesisi 2:16, 17) Kání wọ́n ti ṣègbọràn sí òfin Jehofa ni, kì bá tí sí ìjìyà tí ó dápàá sí ìgbésí-ayé ẹ̀dá ènìyàn. Nípa ṣíṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọrun, wọ́n ìbá ti fi ìfẹ́ wọn fún Jehofa àti ìdúróṣinṣin wọn sí i hàn. (1 Johannu 5:3) Ṣùgbọ́n bí a ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Orí 6, àwọn nǹkan kò ṣẹlẹ̀ ní ọ̀nà yẹn. Bí Satani ti rọ̀ ọ́, Efa jẹ èso igi yẹn. Lẹ́yìn náà, Adamu pẹ̀lú nípìn-ín nínú èso tí a kà léèwọ̀ náà.
9. Ọ̀ràn àríyànjiyàn wo nípa Jehofa ni Satani gbé dìde?
9 Ìwọ ha rí bí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ti wúwo tó bí? Satani ń gbéjàko ipò Jehofa bí Ẹni Gíga Jùlọ. Ní sísọ pé, “Ẹ̀yin kì yóò kú ikú kíkú kan,” Èṣù tako ọ̀rọ̀ Ọlọrun pé, “Kíkú ni ìwọ óò kú.” Ọ̀rọ̀ Satani síwájú síi dọ́gbọ́n sọ pé Jehofa kò fẹ́ kí Adamu àti Efa mọ̀ nípa ṣíṣeéṣe náà láti dàbí Ọlọrun, tí wọn kò sì tipa bẹ́ẹ̀ nílò Rẹ̀ láti pinnu ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú. Ìpèníjà Satani tipa báyìí gbé ìbéèrè dìde sí ẹ̀tọ́ àti ìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ ipò Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé.—Genesisi 2:17; 3:1-6.
10. Kí ni Satani dọ́gbọ́n sọ nípa àwọn ẹ̀dá ènìyàn?
10 Satani Èṣù tún dọ́gbọ́n sọ pé ènìyàn yóò jẹ́ onígbọràn sí Jehofa síbẹ̀ kìkì bí ṣíṣègbọràn sí Ọlọrun yóò bá mú àǹfààní wá fún wọn. Ní èdè mìíràn, ìwàtítọ́ ẹ̀dá ènìyàn ní a gbé ìbéèrè dìde sí. Satani fi ẹ̀sùn kàn pé kò sí ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí tí yóò fínnúfíndọ̀ dúróṣinṣin ti Ọlọrun. Ọ̀rọ̀ onínú-burúkú tí Satani sọ yìí ni a ṣípayá kedere nínú àkọsílẹ̀ Bibeli nípa Jobu, olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jehofa tí ó faragbá ìdánwò púpọ̀ ṣáájú 1600 B.C.E. Nígbà tí o bá ka orí méjì àkọ́kọ́ nínú ìwé Jobu, o lè jèrè ìjìnlẹ̀ òye fún ìdí tí ẹ̀dá ènìyàn fi ń jìyà àti ìdí tí Ọlọrun fi fàyègbà á.
11. Irú ẹni wo ni Jobu jẹ́, ṣùgbọ́n ẹ̀sùn wo ni Satani fi kàn án?
11 Jobu, “ọkùnrin tí í ṣe olóòótọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin,” wá sábẹ́ ìkọlù Satani. Lákọ̀ọ́kọ́, Satani jẹ́wọ́ èrò búburú nípa Jobu nípa gbígbé ìbéèrè náà dìde pé, “Jobu ha bẹ̀rù Oluwa ní asán bí?” Lẹ́yìn náà, Èṣù lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti fi kèéta ọkàn hàn sí Ọlọrun àti Jobu ní fífẹ̀sùnkàn pé Jehofa ti ra ìdúróṣinṣin Jobu nípa dídáàbòbò ó tí ó sì bùkún un. Satani pe Jehofa níjà pé: “Ǹjẹ́ nawọ́ rẹ nísinsìnyí, kí o sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ní; bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.”—Jobu 1:8-11.
12. (a) Àwọn ìbéèrè wo ni a óò dáhùn kìkì bí Ọlọrun bá yọ̀ǹda fún Satani láti dán Jobu wò? (b) Kí ni ìdánwò Jobu yọrí sí?
12 Jobu ha ń jọ́sìn Jehofa kìkì nítorí gbogbo àwọn ohun tí ó rí gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun? Ìwàtítọ́ Jobu ha lè dúró láìyingin lábẹ́ ìdánwò? Ní ìdàkejì, Jehofa ha ní ìgbọ́kànlé tí ó pọ̀ tó nínú ìránṣẹ́ rẹ̀ láti yọ̀ǹda kí a dán an wò? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yóò rí ìdáhùn bí Jehofa bá gba Satani láyè láti mú àwọn ìdánwò rírorò wá sórí Jobu. Ipa-ọ̀nà ìṣòtítọ́ Jobu lábẹ́ ìdánwò tí Ọlọrun yọ̀ǹda, gẹ́gẹ́ bí a ti ròyìn rẹ̀ nínú ìwé Jobu, jẹ́ ẹ̀rí délẹ̀délẹ̀ nípa ìdáláre òdodo Jehofa àti ìwàtítọ́ ènìyàn.—Jobu 42:1, 2, 12.
13. Báwo ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Edeni àti sí Jobu ṣe kàn wá?
13 Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Edeni àti sí ọkùnrin náà Jobu, ní ìjẹ́pàtàkì jíjinlẹ̀. Àwọn ọ̀ràn àríyànjiyàn tí Satani gbé dìde ní gbogbo aráyé nínú, títí kan awa náà lónìí. Orúkọ Ọlọrun ni a fi kèéta ọkàn hàn sí, ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ ni a sì pèníjà. Ìdúróṣánṣán ènìyàn, ìṣẹ̀dá Ọlọrun, ni a gbé ìbéèrè dìde sí. A gbọ́dọ̀ yanjú àwọn ọ̀ràn àríyànjiyàn náà.
BÍ A ṢE LÈ YANJÚ ÀWỌN Ọ̀RÀN ÀRÍYÀNJIYÀN NÁÀ
14. Bí a bá gbé ìpèníjà onínú burúkú síwájú ẹnì kan, kí ni ó ṣeé ṣe kí ẹni tí a fẹ̀sùn kàn náà ṣe?
14 Bí àkàwé kan, jẹ́ kí á sọ pé o jẹ́ òbí onífẹ̀ẹ́ kan tí o ní àwọn ọmọ mélòó kan nínú ìdílé kan tí ó jẹ́ aláyọ̀. Kí a sọ pé ọ̀kan lára àwọn aládùúgbò rẹ tan irọ́ kálẹ̀, ní fífi ẹ̀sùn kàn ọ́ pé o jẹ́ òbí búburú. Kí ni bí aládùúgbò náà bá sọ pé àwọn ọmọ rẹ kò nífẹ̀ẹ́ rẹ, pé wọ́n ń gbé pẹ̀lú rẹ kìkì nítorí pé wọn kò ní yíyàn mìíràn, pé wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ bí ẹnì kan bá fi ọ̀nà mìíràn hàn wọ́n. Ìwọ lè wí pé, ‘Ìsọkúsọ nìyẹn!’ Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n báwo ni o ṣe lè fi ẹ̀rí ìyẹn hàn? Àwọn òbí kan lè hùwàpadà pẹ̀lú ìhónú. Yàtọ̀ sí pé ìyẹn yóò túbọ̀ dá ìṣòro sílẹ̀, ìhùwàpadà oníwà-ipá bẹ́ẹ̀ yóò ṣe ìtìlẹyìn fún irọ́ náà ni. Ọ̀nà tí ó tẹ́nilọ́rùn láti kojú irú ìṣòro kan bẹ́ẹ̀ ni láti yọ̀ǹda àǹfààní fún ẹni tí ó fẹ̀sùn kàn ọ́ láti fi ẹ̀rí ohun tí ó sọ múlẹ̀ kí àwọn ọmọ rẹ sì fi òtítọ́-inú fi ẹ̀rí hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ.
15. Báwo ni Jehofa ṣe yàn láti bójútó ìpènijà Satani?
15 Jehofa dàbí òbí onífẹ̀ẹ́ náà. Adamu àti Efa ni a lè fiwé àwọn ọmọ, Satani sì bá ipò aládùúgbò onírọ́ náà mu. Ó bọ́gbọ́nmu pé Ọlọrun kò pa Satani, Adamu, àti Efa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ṣùgbọ́n ó gba àwọn oníwà àìtọ́ náà láyè láti máa gbé nìṣó fún àkókò kan. Èyí yọ̀ǹda àkókò fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ láti mú ọmọ-inú jáde kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìdílé ẹ̀dá ènìyàn, èyí sì ti fún Èṣù ní àyè láti fi ẹ̀rí hàn bóyá ohun tí ó sọ jẹ́ òtítọ́ kí a ba lè yanjú ọ̀ràn àríyànjiyàn náà. Bí ó ti wù kí ó rí, láti ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọrun mọ̀ pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn kan yóò jẹ́ adúróṣinṣin sí òun tí wọ́n yóò sì fi Satani hàn bí òpùrọ́ kan. Ó tọ́pẹ́ pé Jehofa ti ń bá a nìṣó láti bùkún àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́!—2 Kronika 16:9; Owe 15:3.
KÍ NI A TI FI Ẹ̀RÍ RẸ̀ HÀN?
16. Báwo ni ayé ṣe di èyí tí ó wà ní agbára Satani?
16 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ jálẹ̀ gbogbo ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, Satani ti ní òmìnira láti gbèrò ìhùmọ̀ ìjẹgàba lórí aráyé. Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan mìíràn, ó ti fagbára lo ìdarí lórí àwọn agbára ìṣèlú ó sì ti gbé ìsìn tí ń fi ọgbọ́n àyínìke darí ìjọsìn síi ga dípò kí ó jẹ́ sí Jehofa. Nípa báyìí Èṣù ti di “ọlọrun ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii,” a sì pè é ní “olùṣàkóso ayé yii.” (2 Korinti 4:4; Johannu 12:31) Nítòótọ́, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” (1 Johannu 5:19) Èyí ha túmọ̀ sí pé Satani ti fi ẹ̀rí ohun tí ó sọ hàn pé òun yóò fa gbogbo aráyé lọ kúrò lọ́dọ̀ Jehofa Ọlọrun? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba Satani láyè láti máa wàláàyè nìṣó, Jehofa ti ń bá a lọ láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Nígbà náà, kí ni Bibeli ṣípayá nípa fífi tí Ọlọrun fààyè gba ìwà búburú?
17. Kí ni a níláti fi sọ́kàn nípa okùnfà ìwà búburú àti ìjìyà?
17 Jehofa kọ́ ni ó fa ìwà búburú àti ìjìyà. Níwọ̀n bí Satani ti jẹ́ alákòóso ayé yìí àti ọlọrun ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, òun àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ni ó fa bí ipò àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn ti rí lónìí àti gbogbo ìṣẹ́ tí aráyé ti jìyà rẹ̀. Kò sí ẹnì kan tí ó lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ sọ pé Ọlọrun ni ó fa irú àwọn ìnira bẹ́ẹ̀.—Romu 9:14.
18. Bí Jehofa ṣe yọ̀ǹda ìwà búburú àti ìjìyà ti fi ẹ̀rí kí ni hàn níti èrò nípa òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun?
18 Bí Jehofa ti fàyègba ìwà búburú àti ìjìyà ti fi ẹ̀rí hàn pé òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun kò tí ì mú ayé tí ó sàn jù wá. Láìsí iyèméjì, ìjábá kan tẹ̀lé òmíràn ti sàmì sí ọ̀rọ̀-ìtàn. Ìdí èyí ni pé àwọn ènìyàn ti yàn láti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà olómìnira tiwọn wọn kò sì ka ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti ìfẹ́-inú rẹ̀ sí níti gidi. Nígbà tí àwọn ènìyàn Jehofa ìgbàanì àti àwọn aṣáájú wọn fi àìṣòótọ́ tẹ̀lé ‘ọ̀nà gbígbajúmọ̀’ tí wọ́n sì kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó yọrí sí ìjábá. Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Jeremiah, Ọlọrun sọ fún wọn pé: “Ojú ti àwọn ọlọgbọ́n, ìdààmú bá wọn a sì mú wọn: sá wò ó, wọn ti kọ ọ̀rọ̀ Oluwa! ọgbọ́n wo ni ó wà nínú wọn?” (Jeremiah 8:5, 6, 9) Bí wọ́n ti kùnà láti tẹ̀lé ọ̀pá-ìdiwọ̀n Jehofa, aráyé lápapọ̀ ti dàbí ọkọ̀ òkun kan tí kò ní ìtukọ̀, tí ìrugùdù òkun ń bì síwá sẹ́yìn.
19. Kí ní fi ẹ̀rí hàn pé Satani kò lè yí gbogbo ẹ̀dá ènìyàn padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun?
19 Yíyọ̀ọ̀da tí Ọlọrun yọ̀ọ̀da ìwà búburú àti ìjìyà tún ti fi ẹ̀rí hàn pé kò tí ì ṣeé ṣe fún Satani láti yí gbogbo aráyé padà kúrò lọ́dọ̀ Jehofa. Ìtàn fi hàn pé àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan ti fìgbà gbogbo wà tí wọ́n dúró ní olùṣòtítọ́ ti Ọlọrun láìka àdánwò tàbí ìdààmú yòówù tí ó wá sórí wọn sí. Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyí, agbára Jehofa ti hàn níhà ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, orúkọ rẹ̀ ni a sì ti polongo káàkiri gbogbo ilẹ̀-ayé. (Eksodu 9:16; 1 Samueli 12:22) Heberu orí 11 sọ fún wa nípa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ẹni olùṣòtítọ́, títí kan Abeli, Enoku, Noah, Abrahamu, àti Mose. Heberu 12:1 pè wọ́n ní “àwọsánmà awọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀.” Wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ aláìyẹsẹ̀ nínú Jehofa. Lóde òní pẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi ìwàláàyè wọn sílẹ̀ nínú ìwàtítọ́ aláìṣeébàjẹ́ sí Ọlọrun. Nípa ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọn, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti fi ẹ̀rí hàn láìṣeéjáníkoro pé Satani kò lè yí gbogbo ẹ̀dá ènìyàn padà lòdì sí Ọlọrun.
20. Bí Jehofa ti yọ̀ǹda fún ìwà búburú àti ìjìyà láti máa bá a nìṣó ti fi ẹ̀rí kí ni hàn nípa Ọlọrun àti aráyé?
20 Lákòótán, bí Jehofa ṣe yọ̀ǹda ìwà búburú àti ìjìyà láti máa báa nìṣó ti pèsè ẹ̀rí pé Jehofa Ẹlẹ́dàá, nìkan ṣoṣo, ni ó ní agbára àti ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso lórí aráyé fún ìbùkún àti ayọ̀ wọn ayérayé. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, aráyé ti gbìyànjú oríṣiríṣi ìjọba. Ṣùgbọ́n kí ni ó ti jẹ́ ìyọrísí rẹ̀? Àwọn ìṣòro dídíjúpọ̀ àti àwọn yánpọnyánrin tí ó dojúkọ àwọn orílẹ̀-èdè lónìí jẹ́ ẹ̀rí tí ó pọ̀ tó pé nítòótọ́, bí Bibeli ti fi hàn, “ẹnì kan ń ṣe olórí ẹnì kejì fún ìfarapa rẹ̀.” (Oniwasu 8:9) Jehofa nìkan ṣoṣo ni ó lè gbà wá sílẹ̀ kí ó sì mú ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ. Báwo ni yóò ṣe ṣe èyí, ìgbà wo sì ni?
21. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Satani, ta ni a óò sì lò láti ṣàṣeparí èyí?
21 Kété lẹ́yìn tí Adamu àti Efa ti gba ìpètepèrò Satani láyè, Ọlọrun ṣèfilọ̀ ète Rẹ̀ nípa ọ̀nà kan sí ìgbàlà. Ohun tí Jehofa pòkìkí nípa Satani nìyí: “Èmi óò sì fi ọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀: òun óò fọ́ ọ ní orí, ìwọ óò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Genesisi 3:15) Ìpòkìkí yẹn jẹ́ ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà pé a kì yóò yọ̀ǹda fún Èṣù láti máa ṣe iṣẹ́ ibi rẹ̀ títí láé. Bí Ọba Ìjọba Messia náà, Irú-Ọmọ tí a ṣèlérí náà, Jesu Kristi, yóò ‘fọ Satani ní orí.’ Bẹ́ẹ̀ni, “láìpẹ́,” Jesu yóò tẹ Satani ọlọ̀tẹ̀ náà rẹ́!—Romu 16:20.
KÍ NI ÌWỌ YÓÒ ṢE?
22. (a) Àwọn ìbéèrè wo ni o níláti dojúkọ? (b) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Satani ń tú ìrunú rẹ̀ jáde sórí àwọn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun, kí ni ohun tí ó lè dá wọn lójú?
22 Lẹ́yìn tí o ti mọ àwọn ọ̀ràn àríyànjiyàn tí ó ní nínú, ìhà ọ̀dọ̀ ta ni ìwọ yóò dúró sí? Ìwọ yóò ha fi ẹ̀rí hàn nípa àwọn ìgbésẹ̀ rẹ pé o jẹ́ adúróṣinṣin alátìlẹyìn fún Jehofa? Níwọ̀n bí Satani ti mọ̀ pé àkókò òun kúrú, òun yóò ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láti fi ìrunú rẹ̀ hàn lórí àwọn tí wọ́n fẹ́ láti pa ìwàtítọ́ wọn mọ́ sí Ọlọrun. (Ìṣípayá 12:12) Ṣùgbọ́n o lè yíjú sí Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́ nítorí pé “Jehofa mọ bí a ti í dá awọn ènìyàn tí wọ́n ní ìfọkànsin Ọlọrun nídè kúrò ninu àdánwò.” (2 Peteru 2:9) Òun kì yóò jẹ́ kí a dẹ ọ́ wò rékọjá ohun tí o lè múmọ́ra, òun yóò sì tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí o baà lè farada ìdẹwò.—1 Korinti 10:13.
23. Kí ni a lè fojúsọ́nà fún pẹ̀lú ìgbọ́kànlé?
23 Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé, ẹ jẹ́ kí a máa fojúsọ́nà fún àkókò náà nígbà tí Ọba náà Jesu Kristi yóò gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí Satani àti gbogbo àwọn tí ó bá tẹ̀lé é. (Ìṣípayá 20:1-3) Jesu yóò mú àfẹ́kù débá gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n lọ́wọ́ nínú mímú ègbé àti ìrúkèrudò tí aráyé ti jìyà rẹ̀ wá. Títí di ìgbà náà, irú ìjìyà kan tí ń kánilára jù ni àdánù olólùfẹ́ wa nínú ikú. Kà orí tí ó tẹ̀lé e láti rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wọn.
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jehofa kọ́ ni ó fa ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn?
Àwọn ọ̀ràn àríyànjiyàn wo ni Satani gbé dìde ní Edeni tí a sì mú ṣe kedere ní ọjọ́ Jobu?
Kí ni bí Ọlọrun ṣe yọ̀ọ̀da ìjìyà fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn?