Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jòhánù
JÒHÁNÙ, “ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù ti máa ń nífẹ̀ẹ́,” lẹni tó gbẹ̀yìn nínú àwọn tó kọ àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí, èyí tó dá lórí ìgbésí ayé Kristi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Jòh. 21:20) Ọdún 98 Sànmánì Kristẹni ni Jòhánù kọ ìwé Ìhìn Rere yìí. Ọ̀pọ̀ jù lọ ohun tó wà nínu ìwé Ìhìn Rere Jòhánù la ò lè rí nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere tó kù.
Àpọ́sítélì Jòhánù ní ohun pàtó kan lọ́kàn tó fi kọ ìwé Ìhìn Rere yìí. Ohun tó sọ rèé nípa àwọn nǹkan tó kọ, ó ní: “Ìwọ̀nyí ni a ti kọ sílẹ̀ kí ẹ lè gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run, àti pé, nítorí gbígbàgbọ́, kí ẹ lè ní ìyè nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀.” (Jòh. 20:31) Láìsí àní-àní, ìwé Ìhìn Rere Jòhánù wúlò gan-an fún wa lónìí.—Héb. 4:12.
“WÒ Ó, Ọ̀DỌ́ ÀGÙNTÀN ỌLỌ́RUN”
Nígbà tí Jòhánù Olùbatisí rí Jésù, ó fi ìdánilójú kéde pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” (Jòh. 1:29) Bí Jésù ṣe ń rìnrìn-àjò gba ìlú Samáríà, Gálílì, Jùdíà àti apá ìlà oòrùn Jọ́dánì kọjá, ó ń wàásù, ó ń kọ́ni, ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára, ‘ọ̀pọ̀ èèyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.’—Jòh. 10:41, 42.
Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ta yọ jù lọ tí Jésù ṣe ni àjíǹde Lásárù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gba Jésù gbọ́ nígbà tí wọ́n rí ọkùnrin tó ti kú láti ọjọ́ mẹ́rin tó wá padà jíǹde. Àmọ́, ńṣe làwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù. Èyí ló mú kí Jésù fi ìlú yẹn sílẹ̀, ó sì lọ sí “ilẹ̀ tí ó wà nítòsí aginjù, sí ìlú ńlá tí a ń pè ní Éfúráímù.”—Jòh. 11:53, 54.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:35, 40—Yàtọ̀ sí Áńdérù, ọmọ ẹ̀yìn wo ló dúró ti Jòhánù Olùbatisí? Nígbà tẹ́ni tó kọ ìtàn yìí bá mẹ́nu ba “Jòhánù,” Jòhánù Olùbatisí ló ń tọ́ka sí, nítorí pé ẹni náà kò dárúkọ ará rẹ̀ rárá nínú ìwé Ìhìn Rere yìí. Nítorí náà, Jòhánù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere ni ọmọ ẹ̀yìn tí ìwé náà ò sọ orúkọ rẹ̀.
2:20—Tẹ́ńpìlì wo ni wọ́n fi “ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta” kọ́? Tẹ́ńpìlì Serubábélì tí Hẹ́rọ́dù Ọba Jùdíà ṣàtúnkọ́ rẹ̀ làwọn Júù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan tó ń jẹ́ Josephus ṣe sọ, iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì yẹn bẹ̀rẹ̀ ní ọdún kejìdínlógún ìgbà ìjọba Hẹ́rọ́dù, tàbí kó jẹ́ ọdún 18 tàbí ọdún 17 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọdún mẹ́jọ ni wọ́n fi kọ́ ibùjọsìn tẹ́ńpìlì náà àtàwọn ibi pàtàkì-pàtàkì lára rẹ̀. Àmọ́ ṣá, wọ́n ṣì ń kọ́ àwọn ilé kan nítòsí tẹ́ńpìlì náà títí dìgbà àjọyọ̀ Ìrékọjá ní ọdún 30 Sànmánì Kristẹni, ó sì tún ń bá a nìṣó lẹ́yìn àkókò yìí pàápàá, ìgbà yẹn làwọn Júù sọ pé iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì yẹn gba ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta.
5:14—Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn ń dá ló máa ń fa àìsàn ni? Ọ̀rọ̀ kì í fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀. Láti ọdún méjìdínlógójì sẹ́yìn ni ọkùnrin tí Jésù wò sàn yìí ti ń ṣàìsàn nítorí àìpé táwa èèyàn ti jogún. (Jòh. 5:1-9) Ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé, ní báyìí tí ọkùnrin náà ti rí àánú gbà, ó gbọ́dọ̀ máa rìn ní ọ̀nà ìgbàlà kó má sì dá ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá mọ́, kí nǹkan tó burú ju àìsàn lọ má bàa ṣe é. Ọkùnrin yẹn lè dẹni tó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì, èyí tá á mú kó kú, tí kò sì ní ní àjíǹde.—Mát. 12:31, 32; Lúùkù 12:10; Héb. 10:26, 27.
5:24, 25—Àwọn wo ló ń “ré kọjá láti inú ikú sínú ìyè”? Àwọn tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn ni àwọn tí wọ́n ti fi gbà kan rí kú nípa tẹ̀mí, àmọ́ tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n gbà á gbọ́, wọ́n sì jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ń dá. Wọ́n “ré kọjá láti inú ikú sínú ìyè,” ní ti pé ẹ̀bi ikú ti kúrò lórí wọn, wọ́n sì ti dẹni tó nírètí ìyè àìnípẹ̀kun nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run.—1 Pét. 4:3-6.
5:26; 6:53—Kí ló túmọ̀ sí láti ní ‘ìyè nínú ara ẹni’? Ohun tí níní tí Jésù Kristi “ní ìyè nínú ara rẹ̀” túmọ̀ sí ni fífún tí Ọlọ́run fún un ní agbára méjì kan. Àkọ́kọ́ ni bó ṣe lè mú kí àwa èèyàn ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà. Èkejì sì ni bó ṣe lágbára láti fúnni ní ìyè, ìyẹn agbára tó ní láti jí òkú dìde. Ní ti àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù, níní tá a ‘ní ìyè nínú ara wa’ túmọ̀ sí pé a ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gba ìyè yìí nígbà tí wọ́n jíǹde sí ìyè ti ọ̀run. Àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé yóò ní ìyè tí ó kún rẹ́rẹ́ kìkì tí wọ́n bá yege ìdánwò ìkẹyìn tó máa wáyé ní kété lẹ́yìn òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi.—1 Kọ́r. 15:52, 53; Ìṣí. 20:5, 7-10.
6:64—Ṣé látìgbà tí Jésù ti yan Júdásì Ísíkáríótù láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni Jésù ti mọ̀ pé ó máa da òun? Ó jọ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, nígbà kan, lọ́dún 32 Sànmánì Kristẹni, Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ọ̀kan nínú yín jẹ́ afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, nígbà yẹn, ńṣe ni Jésù kíyè sí i pé Júdásì Ísíkáríótù ti “bẹ̀rẹ̀” sí í hu àwọn ìwà àìtọ́ kan.—Jòh. 6:66-71
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
2:4. Ohun tí Jésù ń sọ fún Màríà ni pé, gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tó ti ṣe batisí tí Ọlọ́run sì ti fàmì òróró yàn gẹ́gẹ́ bí Ọmọ rẹ̀, òun ní láti gba ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Bàbá òun tó ń bẹ lọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni, ó ti mọ wákàtí tàbí àkókò tó máa fi ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, ó sì ti mọ̀ pé ikú ìrúbọ lòun máa kú. Ẹnikẹ́ni ò lè dí i lọ́wọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ì báà jẹ́ Màríà ìyá rẹ̀ tàbí mọ̀lẹ́bí èyíkéyìí tó sún mọ́ ọn. Irú ìpinnu tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn bá a ti ń sin Jèhófà Ọlọ́run.
3:1-9. Ẹ̀kọ́ méjì la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Nikodémù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùṣàkóso àwọn Júù. Àkọ́kọ́, Nikodémù fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye hàn, nǹkan tẹ̀mí jẹ ẹ́ lọ́kàn, ó sì gba ẹni tó jẹ́ ọmọ káfíńtà lásán-làsàn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ tó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwa Kristẹni lóde òní gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Èkejì, Nikodémù ò fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà tí Jésù wà láyé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí ìbẹ̀rù èèyàn, ìfẹ́ tó ní sí ipò rẹ̀ nínú Sànhẹ́dírìn, tàbí ìfẹ́ tó ní fún ọrọ̀ tó kó jọ ni kò ṣe fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a lè rí kọ́ nínú èyí ni pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ fún irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ dí wa lọ́wọ́ láti máa ‘gbé òpó igi oró wa ká sì máa tọ Jésù lẹ́yìn nígbà gbogbo.’—Lúùkù 9:23.
4:23, 24. Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run fojú rere wo ìjọsìn wa, ó gbọ́dọ̀ bá òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì mu, ẹ̀mí mímọ́ ló sì gbọ́dọ̀ máa darí rẹ̀.
6:27. Ohun tó túmọ̀ sí láti ṣiṣẹ́ fún “oúnjẹ tí ó wà títí ìyè àìnípẹ̀kun” ni pé ká sapá láti máa bójú tó àwọn ohun tẹ̀mí tá a nílò. A óò láyọ̀ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀.—Mát. 5:3.
6:44. Jèhófà bìkítà nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Ó ń fà wá sún mọ́ Ọmọ rẹ̀ nípa mímú kí iṣẹ́ ìwàásù dé ọ̀dọ̀ wa àti nípa bó ṣe ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ mú ká lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́.
11:33-36. Fifi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára ẹni hàn kì í ṣe àléébù.
‘Ẹ MÁA TỌ̀ Ọ́ LẸ́YÌN’
Nígbà tí àjọyọ̀ Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Kristẹni kù díẹ̀, Jésù padà sí Bẹ́tánì. Ní Nísàn 9, ó gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù. Ní Nísàn 10, Jésù wá sí tẹ́ńpìlì lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbà tí Jésù gbàdúrà pé kí Bàbá òun ṣe orúkọ ara rẹ̀ lógo, ohùn kan látọ̀run wá sọ pé: “Èmi ti ṣe é lógo, èmi yóò sì tún ṣe é lógo dájúdájú.”—Jòh. 12:28.
Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń jẹ oúnjẹ Ìrékọjá lọ́wọ́, ó sọ̀rọ̀ ìdágbére fún wọn, ó sì gbàdúrà fún wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n mú Jésù, tí wọ́n dájọ́ ikú fún un tí wọ́n sì kàn án mọ́gi, Ọlọ́run jí i dìde.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
14:2—Báwo ni Jésù ṣe máa “pèsè ibì kan sílẹ̀” ní ọ̀run fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́? Èyí túmọ̀ sí bí Jésù ṣe máa fìdí májẹ̀mú tuntun náà múlẹ̀ àti bó ṣe gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Pípèsè ibì kan sílẹ̀ tún kan bí Kristi ṣe máa gba agbára ìjọba, lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró máa bẹ̀rẹ̀ sí í jíǹde sí ìyè ti ọ̀run.—1 Tẹs. 4:14-17; Héb. 9:12, 24-28; 1 Pét. 1:19; Ìṣí. 11:15.
19:11—Ṣé Júdásì Ísíkáríótù ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó sọ fún Pílátù nípa ọkùnrin náà tó fa òun lé Pílátù lọ́wọ́? Ó jọ pé kì í ṣe Júdásì tàbí ọkùnrin èyíkéyìí ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ sí ikú rẹ̀ ló ní lọ́kàn. Lára wọn ni, Júdásì, “àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sànhẹ́dírìn pátá,” títí kan “àwọn ogunlọ́gọ̀” tí wọ́n yí lọ́kàn padà, tí wọ́n sì gbà pé kí wọ́n dá Bárábà sílẹ̀.—Mát. 26:59-65; 27:1, 2, 20-22.
20:17—Kí nìdí tí Jésù fi sọ fún Màríà Magidalénì pé kó dẹ́kun dídìrọ̀ mọ́ òun? Ó jọ pé ìdí tí Màríà fi dìrọ̀ mọ́ Jésù ni pé ó rò pé Jésù ti fẹ́ gòkè re ọ̀run, pé òun ò sì ní rí i mọ́. Kí Jésù lè mú un dá Màríà lójú pé kò tíì yá tóun máa gòkè re ọ̀run, ó sọ fún un pé kó dẹ́kun dídìrọ̀ mọ́ òun, àmọ́ kó lọ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun pé òun ti jíǹde.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
12:36. Tá a bá fẹ́ jẹ́ “ọmọ ìmọ́lẹ̀” tàbí ẹni tó ń tàn bí ìmọ́lẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí í ṣe Bíbélì. A sì gbọ́dọ̀ lo ìmọ̀ tá a ní yìí láti yọ àwọn èèyàn kúrò nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí, ká sì mú wọn wá sínú ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run.
14:6. Kò sọ́nà míì tá a lè gbà rí ojú rere Ọlọ́run, àyàfi nípasẹ̀ Jésù Kristi. Kìkì ìgbàgbọ́ nínú Jésù àti títẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀ ló lè mú wa sún mọ́ Jèhófà.—1 Pét. 2:21.
14:15, 21, 23, 24; 15:10. Tá a bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, èyí á mú ká dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọmọ rẹ̀.—1 Jòh. 5:3.
14:26; 16:13. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, ó sì máa ń rán wa létí àwọn nǹkan tá a ti kọ́. Ó tún máa ń mú káwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣe kedere. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè mú kí ìmọ̀ wa, ọgbọ́n wa àti òye wa máa pọ̀ sí i, á sì mú ká túbọ̀ lè ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ká sì ní agbára láti ronú. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà gbígbà, ká máa bẹ Ọlọ́run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—Lúùkù 11:5-13.
21:15, 19. Jésù bi Pétérù bóyá ó nífẹ̀ẹ́ òun ju “ìwọ̀nyí,” ìyẹn àwọn ẹja tó wà níwájú wọn. Ńṣe ni Jésù ń tipa báyìí tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kí Pétérù máa fi gbogbo ọjọ́ ayé ẹ̀ tẹ̀ lé òun, dípò kó máa bá iṣẹ́ ẹja pípa lọ. Ǹjẹ́ kí àwọn nǹkan tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mú kí ìpinnu wa túbọ̀ lágbára sí i láti nífẹ̀ẹ́ Jésù ju ohunkóhun mìíràn tó lè fà wá mọ́ra lọ. Àní sẹ, ẹ jẹ́ ká máa tẹ̀ lé e nìṣó tọkàntọkàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Kí la lè rí kọ́ látara Nikodémù?