Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kó Lè Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ikú Fà
ÌYÁ kan wo inú ilé ìtàwé kan títí, bóyá á lè rí ìwé tó ní ìmọ̀ràn tí yóò fi tu ọmọ rẹ̀ kékeré nínú nítorí èèyàn wọn tímọ́tímọ́ kan tó kú lójijì. Nígbà tó sú u, ó ráhùn sétígbọ̀ọ́ ẹni tó ń tàwé níbẹ̀ pé: “Ó ga o! Ìwé pọ̀ tó báyìí nínú ṣọ́ọ̀bù yín, ẹ ò sì léyìí tó lè ran ọmọ mi lọ́wọ́!”
Ọ̀rọ̀ náà kò ní ṣàì dun ìyá yìí. Kékeré kọ́ ni ìbànújẹ́ tí ọmọdé máa ń ní tẹ́ni tó fẹ́ràn gan-an bá kú! Òótọ́ ni pé òbí máa ń kópa pàtàkì lára ọmọ, síbẹ̀ ikú lè pa ojúlùmọ̀ tọ́mọ fẹ́ràn gan-an. Báwo ni ìwọ òbí ṣe máa wá ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ tó bá di pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fẹ́ ṣẹlẹ̀ tàbí pé ó ti ṣẹlẹ̀?
Lóòótọ́, téèyàn rẹ bá kú o lè wà nínú ìbànújẹ́, kí ọkàn rẹ gbọgbẹ́, kó o sì máa ronú nípa àdánù tó bá ọ. Bó ti wù kó rí, má gbàgbé pé ọmọ rẹ náà nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ. Ìwé kan tílé ìwòsàn kan ní ìpínlẹ̀ Minnesota, lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, ń pín fáwọn èèyàn sọ pé: “Ìwọ̀nba díẹ̀ ló máa ń ta sáwọn ọmọdé létí nípa ọ̀rọ̀ ikú ẹnì kan, nítorí náà wọ́n kì í sábà mọ bọ́rọ̀ ikú onítọ̀hún ṣe jẹ́ gan-an tàbí kí wọ́n ṣi ọ̀rọ̀ ikú ẹni náà lóye.” Ìwé náà tún sọ pé: “Ó yẹ ká máa sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn ọmọ.” Nítorí náà, ó lè bọ́gbọ́n mu pé kó o sọ kókó ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọmọ rẹ, níwọ̀nba tí òye rẹ̀ lè gbé. Èyí lè má rọrùn láti ṣe ṣá o, torí agbára òye àwọn ọmọ yàtọ̀ síra.—1 Kọ́ríńtì 13:11.
Bó O Ṣe Lè Ṣàlàyé Ikú Ẹnì Kan
Àwọn aṣèwádìí kan sọ pé táwọn òbí bá fẹ́ sọ̀rọ̀ ikú ẹnì kan fún ọmọ, kí wọ́n má kàn lo ọ̀rọ̀ bíi “lágbájá ń sùn,” “a pàdánù rẹ̀,” tàbí “lágbájá ti lọ.” Lílo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láìṣe àfikún àlàyé fọ́mọ, lè má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yé e dáadáa. Lóòótọ́, Jésù lo oorun láti fi ṣàpèjúwe ikú, ó sì bá a mu bẹ́ẹ̀ fáwọn tó ń bá sọ̀rọ̀. Ẹ sáà rántí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kì í ṣe ọmọdé. Síbẹ̀ náà, Jésù ṣàlàyé àpèjúwe yẹn. Ó sọ fún wọn pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àgbàlagbà làwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ṣì “lérò pé [Jésù] ń sọ̀rọ̀ nípa sísinmi nínú oorun.” Jésù wá ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún wọn pé: “Lásárù ti kú.” (Jòhánù 11:11-14) Táwọn àgbàlagbà yẹn bá nílò irú àlàyé bẹ́ẹ̀, mélòómélòó wá làwọn ọmọ wa!
Òǹkọ̀wé méjì kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Mary Ann Emswiler àti James P. Emswiler sọ pé: “Òbí lè fẹ́ máa pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ tó bá ń ṣàlàyé ikú ẹnì kan fọ́mọ, àmọ́ òbí lè tipa bẹ́ẹ̀ gbin èrò tọ́mọ ò ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ sí i lọ́kàn, ìyẹn sì lè jẹ́ èrò tó léwu tàbí èyí tó ń dẹ́rù ba ọmọ.” Bí àpẹẹrẹ, tí òbí bá kàn sọ fún ọmọ rẹ̀ pé èèyàn wọn tó kú kàn ń sùn ni, láìṣe àlàyé míì, ìyẹn lè mú kí ọmọ náà máa bẹ̀rù pé tóun bá sún lálẹ́, òun lè má jí mọ́. Tóhun tí òbí sọ fọ́mọ nípa èèyàn wọn tó kú ò bá sì ju pé ẹni náà “ti lọ,” ọmọ náà lè rò pé ṣe lonítọ̀hún kọ òun sílẹ̀ tàbí pé ó pa òun tì.
Ọ̀pọ̀ òbí ti rí i pé tó bá di pé ká ṣàlàyé ohun tí ikú jẹ́ fọ́mọ, ọ̀rọ̀ tó rọrùn tó sì sọ ojú abẹ níkòó ló máa ń tètè yé ọmọdé ju kéèyàn lo àkànlò èdè tàbí àdàpè. (1 Kọ́ríńtì 14:9) Àwọn aṣèwádìí dá a lábàá pé, kí ìwọ òbí gba ọmọ rẹ níyànjú pé kó béèrè àwọn ìbéèrè tó ní, kó sì máa sọ àwọn nǹkan tó bá ń jà gùdù lọ́kàn rẹ̀. Bíbá a fọ̀rọ̀ wérọ̀ déédéé yóò jẹ́ kó o lè yanjú àwọn àṣìlóye yòówù kó ní, wàá sì tún lè mọ àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà ràn án lọ́wọ́.
Ibi Tá A Ti Lè Rí Ìtọ́sọ́nà Tó Ṣeé Gbára Lé
Lákòókò ọ̀fọ̀, ọmọ rẹ máa gbára lé ọ fún ìtọ́sọ́nà, ìtìlẹyìn àti ìdáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀. Ibo lo ti wá lè rí ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé nípa ikú? Ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí i pé inú Bíbélì la ti lè rí ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ìrètí tó ṣeé gbára lé. Ó sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìdí téèyàn fi ń kú, ipò táwọn òkú wà, àti ìrètí tó ń bẹ fáwọn tó ti kú. Òótọ́ pọ́ńbélé kan tí Bíbélì sọ, pé “àwọn òkú . . . kò mọ nǹkan kan rárá” yẹ kó mú kí ọmọ rẹ mọ̀ pé kì í ṣe pé èèyàn rẹ̀ tó kú yẹn lọ ń jìyà níbì kan. (Oníwàásù 9:5) Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run fi hàn nínú Bíbélì pé a óò tún rí àwọn èèyàn wa tó ti kú padà nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 5:28, 29.
Tó o bá ń wá ìtọ́sọ́nà lọ sínú Bíbélì, wàá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé Bíbélì máa ń fúnni ní ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé, tó sì ń tuni nínú nígbàkigbà téèyàn bá wà nínú ìdààmú. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ọmọ rẹ yóò rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ òbí òun fi ń ṣe atọ́nà nínú àwọn ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì.—Òwe 22:6; 2 Tímótì 3:15.
Ìdáhùn Àwọn Ohun Tó Lè Jẹ́ Ìbéèrè Rẹ
O lè bá àwọn ohun tó rúni lójú pàdé nígbà tó o bá ń tu ọmọ rẹ nínú lórí ikú èèyàn yín kan. Kí lo lè ṣe?a Jẹ́ ká wo àwọn ìbéèrè kan tó sábà máa ń jẹ yọ.
• Ṣé kí n pa ìbànújẹ́ mi mọ́ra lójú ọmọ mi? Gẹ́gẹ́ bí òbí, o kò ní fẹ́ kó ìdààmú bá ọmọ rẹ. Àmọ́ ṣé ó burú ni kí ọmọ rẹ rí i pé inú rẹ bà jẹ́? Ọ̀pọ̀ òbí rí i pé ohun tó dára jù ni pé káwọn má ṣe pa ẹ̀dùn ọkàn wọn mọ́ra. Wọ́n wá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ọmọ wọn rí i pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn kẹ́dùn. Ọ̀pọ̀ ló ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn inú Bíbélì tó banú jẹ́ lójú àwọn èèyàn, fún ọmọ wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jésù da omijé lójú nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kú. Jésù kò pa ẹdùn ọkàn rẹ̀ mọ́ra.—Jòhánù 11:35.
• Ǹjẹ́ ó yẹ kí ọmọ mi kékeré wà níbi ètò ìsìnkú nílé olókùú tàbí níbi sàréè tàbí ibi tí wọ́n kàn ti máa sọ àsọyé lórí ìsìnkú? Tí ọmọdé kan bá máa wà nírú ibi bẹ́ẹ̀, ó dáa láti jẹ́ kó mọ ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, títí kan ìdí tí wọ́n fi ń sọ àsọyé ìsìnkú. Àmọ́ ṣá o, fáwọn ìdí kan, òbí lè pinnu pé á dáa kí ọmọ òun má sí níbi apá kan tàbí gbogbo ètò ìsìnkú tí wọ́n máa ṣe. Tí ọmọ kan bá wà níbi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bójú tó ètò ìsìnkú, ó lè jàǹfààní gan-an nínú àsọyé inú Bíbélì tí wọ́n máa sọ níbẹ̀. Bákan náà, ẹ̀mí “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” àti ìfẹ́ tó máa ń hàn láàárín àwọn tó wà níbẹ̀ lè ní ipa tó dáa lórí ẹni, kó sì jẹ́ ìtùnú fúnni, títí kan ọmọdé pàápàá.—Róòmù 12:10, 15; Jòhánù 13:34, 35.
• Ǹjẹ́ ó yẹ kí n sọ̀rọ̀ nípa èèyàn wa tó kú fún ọmọ mi? Àwọn aṣèwádìí kan sọ pé, tí o kò bá sọ̀rọ̀ nípa ẹni yẹn mọ́ rárá, ọmọ rẹ lè rò pé àṣírí kan wà nípa ẹni tó kú náà tí o kò fẹ́ kó hàn tàbí pé ńṣe lo tiẹ̀ fẹ́ gbàgbé nípa onítọ̀hún pátápátá. Òǹṣèwé kan tó ń jẹ́ Julia Rathkey sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì pé kó o ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa rántí ẹni náà láìsí pé wọ́n ń bẹ̀rù.” Tó o bá ń sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa ẹni tó kú náà, títí kan ìwà àti ìgbé ayé rere rẹ̀, ìyẹn náà lè máa tù wọ́n nínú. Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ nípa àjíǹde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, níbi tí kò ti ní sí àìsàn àti ikú mọ́, tu ọmọ wọn nínú.—Ìṣípayá 21:4.
• Báwo ni mo ṣe lè ran ọmọ mi tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́? Lákòókò ọ̀fọ̀ náà, àwọn nǹkan kan lè máa ṣe ọmọ náà, irú bí àìsàn. Ọmọ náà lè máa bínú tàbí kó máa dààmú nítorí bí nǹkan ṣe sú u tàbí torí pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kọjá agbára rẹ̀. Má ṣe jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu tọ́mọ náà bá ń rò ó lọ́kàn pé ó lè ní nǹkan kan tóun ṣe tó fa ikú ẹni náà, kí ìyẹn sì jẹ́ kó máa wá dì mọ́ ọ, tàbí kó máa jáyà tó o bá pẹ́ délé látòde tàbí tó o bá ṣàìsàn. Kí lo lè ṣe nípa ìdààmú ọmọ rẹ yìí? Má ṣe jẹ́ kí ọmọ rẹ ní èrò pé o ò mọ̀ pé òun wà nínú ìdààmú. Ńṣe ni kó o wà lójúfò, kó o máa kíyè sí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀. Má kàn gbà lọ́kàn rẹ pé ọmọ rẹ ò ní pẹ́ gbàgbé nípa ikú ẹni náà. Máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un déédéé, kó o sì gbà á níyànjú láti máa béèrè àwọn ìbéèrè tó wà lọ́kàn rẹ̀, kó sì máa bá ọ sọ̀rọ̀ fàlàlà. O tún lè fi ọ̀rọ̀ “ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́” mú kí ìrètí tí ọmọ rẹ àti ìwọ fúnra rẹ ní, túbọ̀ lágbára sí i.—Róòmù 15:4.
• Báwo ló ṣe yẹ kí n jẹ́ kó pẹ́ tó ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í máa bá ìgbòkègbodò wa nínú ìdílé àti láwọn ọ̀nà míì lọ? Àwọn ògbógi sọ pé ńṣe ni kẹ́ ẹ máa bá gbogbo ìgbòkègbodò tó bá ṣeé ṣe nìṣó bó ṣe yẹ. Wọ́n ní bíbá àwọn ìgbòkègbodò dáadáa nìṣó jẹ́ ọ̀nà kan láti tètè borí ẹ̀dùn ọkàn. Ọ̀pọ̀ òbí láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti rí i pé, bíbá àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ti ìjọsìn wọn lọ, títí kan ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé déédéé àti lílọ sípàdé ìjọ, máa ń gbé ìdílé ró, ó sì máa ń tù wọ́n nínú.—Diutarónómì 6:4-9; Hébérù 10:24, 25.
Ìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run bá tó fòpin sí àìsàn àti ikú nìkan ni ìbànújẹ́ tí ikú máa ń fà bá àwọn ọmọ kò ní sí mọ́. (Aísáyà 25:8) Ṣùgbọ́n tí ọmọ bá ń rí ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ tó jíire gbà, yóò lè borí ẹ̀dùn ọkàn nípa ikú èèyàn rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn nǹkan tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí kì í ṣe ohun tó di dandan gbọ̀n pé ká tẹ̀ lé. Ká sì máa rántí pé ipò àwọn nǹkan àti àṣà ìbílẹ̀ máa ń yàtọ̀ síra gan-an láti orílẹ̀-èdè kan síkejì àti láti ẹ̀yà kan sí òmíràn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
Gba ọmọ rẹ níyànjú pé kó béèrè àwọn ìbéèrè tó bá ní, kó sì máa sọ àwọn nǹkan tó bá ń jà gùdù lọ́kàn rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ẹ máa bá àwọn ìgbòkègbodò yín lọ, títí kan ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé