Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jòhánù Kìíní, Jòhánù Kejì, Jòhánù Kẹta àti Ìwé Júúdà
ÓṢEÉ ṢE kó jẹ́ pé ìlú Éfésù ni àpọ́sítélì Jòhánù ti kọ àwọn ìwé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó kọ lọ́dún 98 Sànmánì Kristẹni, àwọn ìwé wọ̀nyí sì wà lára àwọn ìwé tó kẹ́yìn nínú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí. Ìwé Jòhánù Kìíní àti Jòhánù Kejì gba àwọn Kristẹni níyànjú láti máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀, kí wọ́n má sì fàyè gba ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà. Jòhánù sọ nínú ìwé rẹ̀ kẹta pé káwọn Kristẹni máa rìn nínú òtítọ́, ó sì tún gbà wọ́n níyànjú láti máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọdún 65 Sànmánì Kristẹni ni Júúdà ọbàkan Jésù kọ ìwé rẹ̀ nílẹ̀ Palẹ́sínì, ó kìlọ̀ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni nípa àwọn èèyàn búburú tí wọ́n ti yọ́ wọnú ìjọ, ó sì tún gbà wọ́n nímọ̀ràn nípa bí wọ́n ṣe lè yẹra fáwọn ìwà búburú tó lè ranni. Tá a bá fiyè sáwọn ìwé Jòhánù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí àtèyí tí Júúdà kọ, àwọn ọ̀rọ̀ inú wọn máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i láìka àtakò èyíkéyìí sí.—Héb. 4:12.
MÁA RÌN NÍNÚ ÌMỌ́LẸ̀ NÍNÚ ÌFẸ́ ÀTI NÍPA ÌGBÀGBỌ́
Ìwé Jòhánù Kìíní tí Jòhánù kọ sí gbogbo ìjọ fún àwa Kristẹni ní ìtọ́ni tó lágbára tó máa jẹ́ ká máa ṣọ́ra fún ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà, ká lè dúró gbọin nínú òtítọ́ ká sì jẹ́ olódodo. Ó tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀, nínú ìfẹ́ àti nípa ìgbàgbọ́.
Jòhánù kọ̀wé pé: “Bí a bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí [Ọlọ́run] fúnra rẹ̀ ti wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní àjọpín pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Ọlọ́run ni Orísun ìfẹ́, àpọ́sítélì náà sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” Bí “ìfẹ́ fún Ọlọ́run” ṣe ń jẹ́ ká lè “pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,” “ìgbàgbọ́ wa” nínú Jèhófà Ọlọ́run, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti Ọmọ rẹ̀ á jẹ́ ká lè máa ṣẹ́gun ayé.—1 Jòh. 1:7; 4:7; 5:3, 4.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:2; 4:10—Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ẹbọ ìpẹ̀tù”? Kéèyàn tó lè pẹ̀tù sọ́rọ̀, ó ní láti “bẹ̀bẹ̀,” tàbí kó “pàrọwà.” Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ ṣe ẹbọ ìpẹ̀tù ní ti pé ó bẹ̀bẹ̀ fún ìdájọ́ òdodo tàbí ká sọ pé ó ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu. Nítorí ẹbọ yẹn, Ọlọ́run máa lè fàánú hàn sáwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, á sì tún dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.—Jòh. 3:16; Róòmù 6:23.
2:7, 8—Àṣẹ wo ni Jòhánù sọ pó jẹ́ “láéláé,” tó sì tún jẹ́ “tuntun”? Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ náà pé ká ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ fún àwọn ará wa, ìyẹn ni pé ká nífẹ̀ẹ́ wọn débi tá a máa fi lè yááfì àwọn nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí nítorí wọn. (Jòh. 13:34) Ó pè é ní àṣẹ “láéláé” torí pé ó ti ju ọgọ́ta [60] ọdún lọ tí Jésù ti pa àṣẹ yìí kí Jòhánù tó kọ ìwé Jòhánù Kìíní tó jẹ́ ara Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí. Èyí fi hàn pé àwọn onígbàgbọ́ ti mọ òfin yìí “láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” ìgbésí ayé wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Àṣẹ yìí tún jẹ́ “tuntun” ní ti pé ó kọjá kéèyàn kàn ‘nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì bíi tara ẹ̀,’ àmọ́ ó gba pé kéèyàn ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan tó nífẹ̀ẹ́ sí nítorí àwọn ẹlòmíì.—Léf. 19:18; Jòh. 15:12, 13.
3:2—Kí ni “a kò tíì fi hàn kedere” sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ta sì ni wọ́n máa rí “gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí”? Ohun tí kò tíì hàn kedere sí wọn ni bí wọ́n ṣe máa rí nígbà tí wọ́n bá jíǹde sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. (Fílí. 3:20, 21) Àmọ́, wọ́n “mọ̀ pé nígbàkigbà tí a bá fi [Ọlọ́run] hàn kedere [wọn] ó dà bí rẹ̀, nítorí [wọn] óò rí i gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí,” ìyẹn “Ẹ̀mí náà.”—2 Kọ́r. 3:17, 18.
5:5-8—Báwo ni omi, ẹ̀jẹ̀ àti ẹ̀mí ṣe ń jẹ́rìí pé “Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run”? Omi jẹ́rìí ní ti pé nígbà tí Jésù ṣe batisí nínú omi, Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ pé òun tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí Ọmọ òun. (Mát. 3:17) Ẹ̀jẹ̀ Jésù, ìyẹn ẹ̀mí rẹ̀, tó fi fúnni gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn,” tún jẹ́rìí pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù. (1 Tím. 2:5, 6) Ẹ̀mí mímọ́ sì tún jẹ́rìí pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù nígbà tó bà lé e nígbà ìbatisí rẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kó lè “la ilẹ̀ náà kọjá, ó ń ṣe rere, ó sì ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù ni lára.”—Jòh. 1:29-34; Ìṣe 10:38.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
2:9-11; 3:15. Tí Kristẹni kan bá jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni paná ìfẹ́ tóun ní sáwọn ará, ńṣe lonítọ̀hún ń rìn nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí, kò sì mọ ibi tó dorí kọ.
MÁA “RÌN NÍNÚ ÒTÍTỌ́”
Nígbà tí Jòhánù máa bẹ̀rẹ̀ ìwé Jòhánù Kejì, ohun tó kọ́kọ́ sọ ni pé: “Àgbà ọkùnrin sí àyànfẹ́ ìyáàfin àti sí àwọn ọmọ rẹ̀.” Ó sọ pé inú òun dùn gan-an bí òun ṣe rí “àwọn kan lára àwọn ọmọ [ìyáàfin náà] tí [wọ́n] ń rìn nínú òtítọ́.”—2 Jòh. 1, 4.
Lẹ́yìn tí Jòhánù ti gbani níyànjú láti nífẹ̀ẹ́, ó sọ pé: “Èyí sì ni ohun tí ìfẹ́ túmọ̀ sí, pé kí a máa bá a lọ ní rírìn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àṣẹ rẹ̀.” Jòhánù tún kìlọ̀ nípa “ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.”—2 Jòh. 5-7.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1, 13—Ta ni “àyànfẹ́ ìyáàfin” náà? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé obìnrin èyíkéyìí tí wọ́n bá ti lè pè ní Kyria lédè Gíríìkì, ìyẹn “ìyáàfin” lédè Yorùbá, ni Jòhánù ní lọ́kàn. Ó sì lè jẹ́ pé àkànlò èdè ló lò láti bá ìjọ kan ní pàtó sọ̀rọ̀ káwọn tó ń ṣenúnibíni sí wọn má bàa lóye ohun tó ń sọ. Tó bá jẹ́ pé àkànlò èdè ni Jòhánù lò lóòótọ́, a jẹ́ pé àwọn ará tó wà nínú ìjọ yẹn làwọn ọmọ ìyáàfin náà, àwọn ará tó wà nínú ìjọ míì ló sì máa wá jẹ́ “àwọn ọmọ arábìnrin [rẹ̀]”.
7—Wíwá Jésù wo ni Jòhánù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Jésù “wá,” báwo sì làwọn ẹlẹ̀tàn ṣe kọ̀ láti “jẹ́wọ́” èyí? Wíwá tí Jòhánù sọ pé Jésù “wá” yìí kì í ṣe wíwá rẹ̀ tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú nígbà tí kò séèyàn kankan tó máa rí i. Àmọ́, wíwá nínú ẹran ara àti bí Ọlọ́run ṣe yàn án gẹ́gẹ́ bíi Kristi ni Jòhánù ń sọ. (1 Jòh. 4:2) Àwọn ẹlẹ̀tàn ò gbà gbọ́ pé Jésù wá nínú ẹran ara. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n má gbà pé Jésù ti gbé láyé rí tàbí kí wọ́n kọ̀ jálẹ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ yàn án.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
2, 4. Bá a ṣe mọ “òtítọ́,” ìyẹn gbogbo ẹ̀kọ́ Kristẹni lódindi tó wà nínú Bíbélì, tá a sì fi ń ṣèwà hù ṣe pàtàkì ká bàa lè nígbàlà.—3 Jòh. 3, 4.
8-11. Tá ò bá fẹ́ pàdánù “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, àánú àti àlàáfíà . . . láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi,” tá ò sì tún fẹ́ pàdánù ìbákẹ́gbẹ́ onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, a ní láti máa “ṣọ́ ara” wa nípa tẹ̀mí, ká rí i dájú pé a ò ṣe kọjá àwọn ohun tí Kristi fi kọ́ni, ká sì máà ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn tí ò “dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi.”—2 Jòh. 3.
Ẹ DI “ALÁBÀÁṢIṢẸ́PỌ̀ NÍNÚ ÒTÍTỌ́”
Gáyọ́sì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jòhánù tímọ́tímọ́ ni Jòhánù kọ ìwé Jòhánù Kẹta sí. Ó kọ̀wé pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”—3 Jòh. 4.
Jòhánù gbóríyìn fún Gáyọ́sì fún “iṣẹ́ ìṣòtítọ́” tó ń ṣe nípa ríran òun lọ́wọ́ láti máa bẹ àwọn ará wò. Àpọ́sítélì náà sọ pé: “A wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti gba irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, kí a lè di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.”—3 Jòh. 5-8.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
11—Kí nìdí táwọn èèyàn kan fi máa ń hùwà búburú? Torí pé àwọn kan ò fi gbogbo ara dúró nínú òtítọ́, wọn ò rí Ọlọ́run pẹ̀lú ojú tẹ̀mí. Torí pé wọn ò lè rí Ọlọ́run lójúkojú, wọ́n wá ń hùwà bíi pé Ọlọ́run ò rí wọn.—Ìsík. 9:9.
14—Àwọn wo ni Jòhánù pè ní “àwọn ọ̀rẹ́”? “Àwọn ọ̀rẹ́” tí Jòhánù ń sọ níbí kì í wulẹ̀ ṣe àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe wọléwọ̀de lásán. Gbogbo àwọn onígbàgbọ́ lápapọ̀ ni Jòhánù lo ọ̀rọ̀ náà fún.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
4. Inú àwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí nínú ìjọ máa ń dùn tí wọ́n bá rí i pé àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ “ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” Ẹ sì wo bínú àwọn òbí ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá kẹ́sẹ járí ní ríran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà!
5-8. Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn míṣọ́nnárì, àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà wà lára àwọn tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run torí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àtàwọn ará. Ó yẹ ká fara wé ìgbàgbọ́ wọn ká sì máa tì wọ́n lẹ́yìn kí wọ́n lè mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.
9-12. Ẹ jẹ́ ká máa fara wé Dímẹ́tíríù tó jẹ́ olóòótọ́ èèyàn, ká má sì fara wé Dìótíréfè ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́ àti ọ̀dàlẹ̀.
“Ẹ PA ARA YÍN MỌ́ NÍNÚ ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN”
Júúdà pe àwọn tó ń dá rúgúdù sílẹ̀ nínú ìjọ ní “oníkùnsínú, àwọn olùráhùn nípa ìpín wọn nínú ìgbésí ayé, wọ́n ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn.” Wọ́n “ń sọ ohun kàǹkà-kàǹkà, nígbà tí wọ́n ń kan sáárá sí àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn.”—Júúdà 4, 16.
Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè yẹra fáwọn ẹgbẹ́ búburú? Júúdà kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ rántí àwọn àsọjáde tí àwọn àpọ́sítélì Olúwa wa Jésù Kristi ti sọ ní ìṣáájú.” Ó wá fi kún un pé: “Ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Júúdà 17-21.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
3, 4—Kí nìdí tí Júúdà fi gba àwa Kristẹni níyànjú láti “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́”? Ìdí ni pé ‘àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti yọ́ wọ inú ìjọ.’ Àwọn wọ̀nyí “ń sọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run . . . di àwáwí fún ìwà àìníjàánu.”
20, 21—Báwo la ṣe lè “pa ara [wa] mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run”? Ọ̀nà mẹ́ta la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀: (1) Nípa gbígbé ara wa ró nínú “ìgbàgbọ́” wa “mímọ́ jù lọ.” Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀-jinlẹ̀ àti fífìtara wàásù ìhìn rere náà sì máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí; (2) nípa gbígbàdúrà “pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́” tàbí jíjẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa tá a bá ń gbàdúrà àti (3) nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, torí ìyẹn ló máa jẹ́ ká lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 3:16, 36.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
5-7. Ṣáwọn èèyàn búburú lè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Jèhófà? Àpẹẹrẹ mẹ́ta tí Júúdà fi ṣèkìlọ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé wọn ò lè bọ́.
8-10. Ẹ jẹ́ ká máa fara wé Máíkẹ́lì, olú-áńgẹ́lì, ká sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn tí Jèhófà fi ṣe olórí.
12. Àwọn apẹ̀yìndà tí wọ́n ń díbọ́n pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wa léwu fún ìgbàgbọ́ wa bí òkúta tó fara sin sábẹ́ omi ṣe léwu fún ọkọ̀ òkun àtàwọn òmùwẹ̀. Àwọn olùkọ́ èké lè ṣe bíi pé àwọn fẹ́ ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ àgbá òfìfo ni wọ́n, wọn ò nímọ̀ kankan tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ò já mọ́ nǹkan kan, ńṣe ni wọ́n dà bí igi gbígbẹ nígbà ẹ̀rùn. Ìparun ló máa gbẹ̀yìn wọn bí igi téèyàn hú tigbòǹgbò tigbòǹgbò. Tá a bá ń yẹra fáwọn apẹ̀yìndà, a máa fi hàn pé a jẹ́ ọlọgbọ́n.
22, 23. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kórìíra ohun búburú. Káwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí nínú ìjọ, pàápàá jù lọ àwọn alábòójútó, lè fi àánú hàn sí “àwọn kan tí wọ́n ní iyèméjì” kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ má bàa lọ sínú ìná ìparun ayérayé, àwọn alábòójútó máa ń sapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tún ní ìgbàgbọ́ bíi tàtẹ̀yìnwá.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Omi, ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀ ń jẹ́rìí pé “Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run”