Kọ́ Ọmọ Rẹ
Jòsáyà Pinnu Láti Ṣohun Tó Tọ́
ṢÓ O rò pé kò rọrùn láti ṣohun tó tọ́?a— Tó o bá rò bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gbà pé òótọ́ lo sọ. Kì í rọrùn fáwọn àgbàlagbà pàápàá láti ṣohun tí wọ́n mọ̀ pó tọ́. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí tí kò fi rọrùn fún Jòsáyà láti ṣohun tó tọ́. Ṣó o tiẹ̀ mọ Jòsáyà?—
Ọmọkùnrin Ámọ́nì tó jẹ́ ọba Júdà ni Jòsáyà. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] péré sì ni Ámọ́nì nígbà tó bí Jòsáyà. Èèyàn burúkú ni Ámọ́nì, Ọba Mánásè tó jẹ́ bàbá ẹ̀ ló sì fìyẹn jọ. Kódà, ọ̀pọ̀ ọdún ni Mánásè fi ń hùwà ibi tí kò sì jáwọ́. Àmọ́, nígbà tọ́wọ́ àwọn ọmọ Ásíríà tẹ̀ ẹ́, tí wọ́n sì lọ jù ú sẹ́wọ̀n nílùú Bábílónì tó jìnnà gan-an sí Jerúsálẹ́mù, Mánásè bẹ Jèhófà pé kó dárí ji òun, Jèhófà sì dárí jì í lóòótọ́.
Wọ́n dá Mánásè sílẹ̀ lómìnira, ó pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ó sì tún pa dà sórí àlééfà gẹ́gẹ́ bí ọba. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló fàwọn ìwà burúkú tó ń hù tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa sin Jèhófà. Ó dájú pé inú ẹ̀ ò ní dùn nígbà tó rí i pé Ámọ́nì ọmọ òun ò fara wé àpẹẹrẹ rere tóun fi lélẹ̀. Àsìkò yìí ni Ámọ́nì bí Jòsáyà. Bíbélì ò sọ bí Mánásè ṣe sún mọ́ Jòsáyà ọmọ-ọmọ ẹ̀ tó. Àmọ́, ṣó o rò pó ṣeé ṣe kí Mánásè ti gbìyànjú láti ran Jòsáyà lọ́wọ́ kó lè sin Jèhófà?—
Jòsáyà ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́fà lọ nígbà tí Mánásè kú, tí Ámọ́nì bàbá Jòsáyà sì gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba. Ọdún méjì péré ni Ámọ́nì fi jọba káwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó pa á. Torí náà Jòsáyà ò ju ọmọ ọdún mẹ́jọ lọ nígbà tó jọba ní Júdà. (2 Kíróníkà, orí 33) Kí lo rò pó ṣẹlẹ̀ lásìkò yẹn? Ṣé Ámọ́nì bàbá Jòsáyà tí ò fàpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ni Jòsáyà máa fìwà jọ ni, àbí Mánásè bàbá-bàbá ẹ̀ tó ronú pìwà dà tó sì wá ṣe rere?—
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jòsáyà kéré lọ́jọ́ orí, ó mọ̀ pé Jèhófà lòún fẹ́ sìn. Torí náà, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló tẹ́tí sí, kò fetí sáwọn ọ̀rẹ́ bàbá ẹ̀. Jòsáyà ò ju ọmọ ọdún mẹ́jọ lọ, àmọ́ ó mọ̀ pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ló yẹ kéèyàn máa fetí sí. (2 Kíróníkà 34:1, 2) Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn tó gba Jòsáyà nímọ̀ràn tí wọ́n sì wá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwòkọ́ṣe fún un?—
Wòlíì Sefanáyà làkọ́kọ́, ó fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún Jòsáyà. Mọ̀lẹ́bí Jòsáyà ni Sefanáyà, torí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Hesekáyà, ọba rere tó bí Mánásè. Kò pẹ́ tí Jòsáyà jọba ni Sefanáyà kọ ìwé tí wọ́n ń forúkọ ẹ̀ pè tó wà lára àwọn ìwé tó para pọ̀ di Bíbélì. Sefanáyà kìlọ̀ nípa àwọn àjálù tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò bá ṣohun tó tọ́, ó sì dájú pé Jòsáyà fetí sáwọn ìkìlọ̀ wọ̀nyẹn.
Ẹlòmíì ni Jeremáyà, ó sì ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ nípa ẹ̀ rí. Ọ̀dọ́ ni Jeremáyà àti Jòsáyà, àdúgbò kan náà làwọn méjèèjì sì ti dàgbà. Jèhófà mí sí Jeremáyà láti kọ ìwé kan tí wọ́n forúkọ ẹ̀ pè tó wà lára àwọn ìwé tó para pọ̀ di Bíbélì. Nígbà tí Jòsáyà kú sójú ogun, Jeremáyà kọ orin arò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti fi hàn pé ikú ẹ̀ dùn òun gan-an. (2 Kíróníkà 35:25) Ó dájú pé wọ́n á ti ran ara wọn lọ́wọ́ láti jólóòótọ́ sí Jèhófà!
Kí lo rò pó o lè rí kọ́ tó o bá ṣàyẹ̀wò ìgbésí ayé Jòsáyà?— Bíi ti Jòsáyà, tí bàbá tó bí ẹ lọ́mọ kì í bá ṣe olùjọ́sìn Jèhófà, ṣó o lè ronú kan ẹnì kan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run? Ó ṣeé ṣe kónítọ̀hún jẹ́ màmá ẹ, màmá ẹ àgbà tàbí bàbá ẹ àgbà, ó sì lè jẹ́ ìbátan ẹ kan. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ ẹlòmíì tó ń jọ́sìn Jèhófà, àmọ́ tí màmá ẹ fọwọ́ sí i pé kó máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Èyí ó wù kó jẹ́, má gbàgbé pé ọmọ kékeré ni Jòsáyà lóòótọ́, àmọ́ kò kéré jù láti mọ̀ pé àwọn tó ń sin Jèhófà ló yẹ kóun máa bá ṣọ̀rẹ́. A gbà á ládùúrà pé kiyẹn jẹ́ ìpinnu tìẹ náà, kó o sì yàn láti máa ṣohun tó tọ́!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó bá jẹ́ pé ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kọ́mọ náà sọ tinú ẹ̀.
Ìbéèrè:
○ Kí lorúkọ bàbá Jòsáyà, ta ni bàbá tó bí bàbá ẹ̀, irú èèyàn wo sì ni wọ́n?
○ Àyípadà wo ni bàbá tó bí bàbá Jòsáyà ṣe nígbèésí ayé ẹ̀?
○ Àwọn wòlíì méjì wo ló fàpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún Jòsáyà, kí sì nìdí tó o fi rò pó ṣe pàtàkì pé káwa náà nírú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Kí ni Sefanáyà àti Jeremáyà ṣe láti ran Jòsáyà lọ́wọ́ kó lè ṣohun tó tọ́?