Sún Mọ́ Ọlọ́run
Jèhófà Ṣàpèjúwe Irú Ẹni Tóun Jẹ́
BÁWO lo ṣe máa ṣàpèjúwe irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, àwọn ànímọ́ rẹ̀ àti bó ṣe máa ń ṣe nǹkan? Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ ká ló ṣeé ṣe fún ẹ láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fúnra rẹ̀, kó o sì wá fetí ara ẹ gbọ́ bó ṣe máa ṣàpèjúwe ara rẹ̀? Ohun tí wòlíì Mósè ṣe gan-an nìyẹn. Inú wa dùn pé Ọlọ́run mí sí i láti ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀.
Mósè bẹ Jèhófà lórí Òkè Sínáì pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n rí ògo rẹ.” (Ẹ́kísódù 33:18) Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, Ọlọ́run fún wòlíì yìí láǹfààní láti kófìrí ògo òun.a Gbogbo ohun tí Mósè rí nínú ìran àgbàyanu yẹn kọ́ ló ṣàlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, nǹkan tó ṣe pàtàkì jù ló kọ sílẹ̀, ìyẹn sì ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Jèhófà sọ bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Ẹ́kísódù 34:6, 7.
Ohun àkọ́kọ́ tí Jèhófà sọ nípa ara rẹ̀ ni pé òún jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́.” (Ẹsẹ 6) Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tá a tú sí “aláàánú” jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe máa ń “ṣàánú lọ́nà tó tuni lára, bí ìgbà tí bàbá kan ń ṣàánú àwọn ọmọ ẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tá a tú sí ‘oore ọ̀fẹ́’ sì ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣe tí wọ́n fi ń “ṣàpèjúwe ẹni tó ṣe tán láti ran aláìní lọ́wọ́ tọkàntọkàn.” Kò sí àní-àní pé Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé báwọn òbí ṣe máa ń tọ́jú àwọn ọmọ wọn lòun náà ṣe máa ń tọ́jú àwọn tó bá ń sin òun, ó fẹ́ràn wọn dénú, àwọn ohun tí wọ́n nílò sì jẹ ẹ́ lógún.—Sáàmù 103:8, 13.
Jèhófà wá sọ tẹ̀ lé e pé òun máa “ń lọ́ra láti bínú.” (Ẹsẹ 6) Kì í tètè bínú sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ní sùúrù fún wa, ó máa ń ro ti pé a jẹ́ aláìpé mọ́ wa lára bó ṣe ń fún wa lákòókò tó pọ̀ tó láti fìwà ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀.—2 Pétérù 3:9.
Ọlọ́run tún sọ pé òún “pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹsẹ 6) Inú rere onífẹ̀ẹ́ tàbí ìfẹ́ àtọkànwá ni ànímọ́ àtàtà tí Jèhófà fi ń mú kí ìdè ìṣọ̀kan tó wà láàárín òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ lágbára. (Diutarónómì 7:9) Jèhófà náà tún ni orísun òtítọ́ gbogbo. Kò sẹ́ni tó lè tàn án jẹ, bẹ́ẹ̀ lòun náà ò sì ní tan ẹnikẹ́ni jẹ. Torí pé òun ni “Ọlọ́run òtítọ́,” tọkàntọkàn la fi gba gbogbo ohun tó sọ gbọ́, títí kan àwọn ìlérí tó ṣe fún wa nípa ọjọ́ iwájú.—Sáàmù 31:5.
Òtítọ́ míì tó ṣe pàtàkì tí Jèhófà tún fẹ́ ká mọ̀ nípa òun ni pé òún máa “ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.” (Ẹsẹ 7) ‘Ó ṣe tán láti dárí ji’ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. (Sáàmù 86:5) Àmọ́, Jèhófà kì í fàyè gba ìwàkiwà. Ó ṣàlàyé pé “lọ́nàkọnà” òun “kì í dáni sí láìjẹni-níyà.” (Ẹsẹ 7) Ọlọ́run mímọ́ tó ń ṣèdájọ́ òdodo ò ní fàwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Bó pẹ́ bó yá, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ máa jèrè iṣẹ́ burúkú ọwọ́ wọn.
Bí Jèhófà ṣe ṣàpèjúwe irú ẹni tóun jẹ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere pé ó fẹ́ ká mọ òun dáadáa, ó sì fẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ òun àti bóun ṣe máa ń ṣe nǹkan. Ó yẹ káwọn ohun tí Jèhófà sọ nípa ara ẹ̀ yìí mú kó o fẹ́ láti túbọ̀ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ànímọ́ àtàtà tó ní.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Mósè ò rí Ọlórun lójúkojú torí pé kò séèyàn tó lè rí Ọlọ́run kónítọ̀hún sì wà láàyè. (Ẹ́kísódù 33:20) Ó ṣe kedere nígbà náà pé ìran nípa ògo Ọlọ́run ni Mósè rí, ańgẹ́lì kan sì ni Jèhófà lò láti bá Mósè sọ̀rọ̀.