Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ń Mú Ìtẹ̀síwájú Wá
Ẹ̀MÍ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ṣe pàtàkì fáwọn tó bá fẹ́ ní ìdílé tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí. Nígbà tí Jèhófà dá tọkọtaya àkọ́kọ́, ó sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀. “Àṣekún” ni Éfà jẹ́ fún Ádámù ọkọ rẹ̀. (Jẹ́n. 2:18) Ó yẹ kí tọkọtaya máa ṣe nǹkan pa pọ̀, kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́. (Oníw. 4:9-12) Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tún ṣe pàtàkì báwọn òbí àtàwọn ọmọ bá fẹ́ ṣe ojúṣe tí Jèhófà gbé lé wọn lọ́wọ́ láṣeyọrí.
Ìjọsìn Ìdílé
Ọmọ márùn-ún ni Arákùnrin Barry àti Heidi ìyàwó ẹ̀ bí. Wọ́n rí i pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo wọn ló mú kí wọ́n lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nínú ìdílé wọn, èyí sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Arákùnrin Barry sọ pé: “Látìgbàdégbà, mo máa ń ní káwọn ọmọ múra àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe ṣókí tí wọ́n máa sọ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé sílẹ̀. Mo lè ní kí wọ́n mú ọ̀rọ̀ wọn látinú àpilẹ̀kọ kan nínú ìtẹ̀jáde Jí! A tún ní àkókò tá a fi máa ń ṣe ìdánrawò ohun tá a máa sọ lóde ẹ̀rí, kí ọmọ kọ̀ọ̀kan lè mọ bó ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀.” Heidi ìyàwó ẹ̀ fi kún un pé: “Gbogbo wa la ní nǹkan tẹ̀mí tá a ń fojú sùn, látìgbàdégbà, a máa ń ṣàgbéyẹ̀wò bá a ṣe tẹ̀ síwájú sí nígbà tá a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé.” Àwọn tọkọtaya yìí tún rí i pé, bí wọ́n ṣe ṣètò pé àwọn ò ní máa wo tẹlifíṣọ̀n láwọn alẹ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀ ti ran àwọn lọ́wọ́ láti máa ráyè kàwé.
Àwọn Ìpàdé Ìjọ
Ọmọ mẹ́rin ni Arákùnrin Mike àti Denise ìyàwó rẹ̀ bí. Báwo ni ìdílé wọn ṣe jàǹfààní nínú ṣíṣe nǹkan pọ̀? Arákùnrin Mike sọ pé: “Ìgbà míì wà tí ètò tá a ṣe dáadáa kì í lọ bá a ṣe rò, àmọ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa dé ìpàdé lákòókò.” Denise ìyàwó ẹ̀ sọ pé: “Gbogbo àwọn ọmọ wa ló ní iṣẹ́ ilé tí wọ́n ń bójú tó nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà. Ọmọbìnrin wa tó ń jẹ́ Kim, máa ń gbọ́únjẹ, á sì tún tẹ́ tábìlì.” Ọmọ wọn ọkùnrin tó ń jẹ́ Michael sọ pé: “A máa ń ṣe ọ̀kan lára àwọn ìpàdé ìjọ nílé wa lálẹ́ Tuesday. Torí náà, a máa ń tún ilé ṣe, a máa ń gbálẹ̀, a sì máa ń to àga táwọn ará máa fi jókòó.” Matthew ọmọ wọn míì fi kún un pé: “Dádì máa ń rí i pé àwọn tètè dé láwọn ọjọ́ ìpàdé, kí wọ́n lè rí i pé gbogbo wa tètè múra sílẹ̀ fún ìpàdé.” Kí ló wá jẹ́ àbájáde rẹ̀?
Ó Tó Bẹ́ẹ̀ Ó Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ
Arákùnrin Mike sọ pé: “Lọ́dún 1987, èmi àtìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà yẹn mẹ́ta lára àwọn ọmọ wa ló ṣì wà nílé. Méjì lára wọn di aṣáájú-ọ̀nà, àwọn tó kù sì báwọn ṣiṣẹ́ ilé kíkọ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Ohun tó mú kí ayọ̀ wa túbọ̀ kún ni pé, ó ti ṣeé ṣe fún ìdílé wa láti ran àwọn èèyàn tó tó ogójì lọ́wọ́ láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, tí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Ìdílé wa tún láǹfààní láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ilé kíkọ́, kódà nílẹ̀ òkèèrè.”
Ká sòótọ́, ìsapá tí ìdílé bá ṣe láti wà ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ǹjẹ́ o lè wá àwọn ọ̀nà míì tó o tún lè gbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó kù nínú ìdílé yín? Ó dájú pé tẹ́ ẹ bá lẹ́mìí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nínú ìdílé yín, ẹ ó máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Fífi ohun tẹ́ ẹ máa sọ lóde ẹ̀rí dánra wò máa jẹ́ kí ìṣẹ́ òjíṣẹ́ yín sunwọ̀n sí i