Bá A Ṣe Lè Máa Hùwà Tó Bójú Mu Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́ Ọlọ́run
“Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run.”—ÉFÉ. 5:1.
1, 2. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa hùwà tó bójú mu? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
NÍGBÀ tí òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Sue Fox ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà tó fi ọ̀wọ̀ hàn, ó ní: “Kò sígbà kankan tó yẹ kéèyàn ṣíwọ́ híhùwà tó bójú mu. Ìwà ọmọlúwàbí máa ń ṣàǹfààní níbi gbogbo, nígbà gbogbo.” Téèyàn bá ti fi kọ́ra láti máa hu ìwà tó bójú mu, kò ní máa fi bẹ́ẹ̀ níṣòro pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Àmọ́ téèyàn bá ń hùwà tí kò bójú mu sáwọn èèyàn, ohun tó máa ń bí ni ìjà, ìkórìíra àti ìbínú.
2 Àwọn ọmọlúwàbí èèyàn ló kún inú ìjọ Kristẹni. Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ìwà burúkú tó kún inú ayé òde òní má bàa ràn wá. Ẹ jẹ́ ká wo bí ìlànà Bíbélì lórí ọ̀ràn ìwà ọmọlúwàbí ṣe lè dáàbò bò wá, tí ìwà ìbàjẹ́ inú ayé yìí ò fi ní ràn wá àti bí ìwà tó bójú mu ṣe lè fa àwọn èèyàn wá sínú ìjọsìn tòótọ́. Láti lè mọ bó ṣe yẹ ká máa hùwà tó bójú mu, ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀.
Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀ Fi Àpẹẹrẹ Ìwà Tó Bójú Mu Lélẹ̀
3. Irú àpẹẹrẹ wo ni Jèhófà Ọlọ́run fi lélẹ̀ lórí bá a ṣe lè máa hùwà tó bójú mu?
3 Jèhófà Ọlọ́run fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ lórí ọ̀ràn ìwà tó bójú mu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, inú rere rẹ̀ sí ẹ̀dá èèyàn pọ̀ gan-an, ó sì ń yẹ́ wọn sí. Nígbà tí Jèhófà ń bá Ábúráhámù àti Mósè sọ̀rọ̀, ó lo ọ̀rọ̀ èdè Hébérù kan tá a sábà máa ń túmọ̀ sí “jọ̀wọ́.” (Jẹ́n. 13:14; Ẹ́kís. 4:6) Nígbà táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá ṣàṣìṣe, ó máa ń fi hàn pé òun ni “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, tí ń lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ yanturu nínú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́.” (Sm. 86:15) Ó yàtọ̀ gédégbé sáwọn èèyàn kan tó máa ń gbaná jẹ́ nígbà táwọn èèyàn ò bá ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́.
4. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà nígbà táwọn èèyàn bá ń bá wa sọ̀rọ̀?
4 Nínú bí Ọlọ́run ṣe ń tẹ́tí gbọ́ ẹ̀dá èèyàn, a tún rí àpẹẹrẹ ìwà tó bójú mu tó yẹ ká máa hù. Nígbà tí Ábúráhámù ń béèrè àwọn ìbéèrè kan nípa àwọn ará Sódómù, Jèhófà fi sùúrù dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. (Jẹ́n. 18:23-32) Kò sọ pé ṣe ni Ábúráhámù kàn ń fi àkókò Òun ṣòfò. Jèhófà máa ń tẹ́tí gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì máa ń fetí sí ẹkún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà. (Ka Sáàmù 51:11, 17.) Ṣé kò yẹ káwa náà fara wé Jèhófà, ká máa fetí sílẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá ń bá wa sọ̀rọ̀?
5. Àǹfààní wo ló wà nínú híhùwà tó bójú mu bíi ti Jésù?
5 Lára àwọn nǹkan púpọ̀ tí Jésù kọ́ lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ ni ìwà tó bójú mu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò rẹ̀ àti okun rẹ̀, síbẹ̀ gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń lo sùúrù tó sì máa ń ṣàánú. Jésù múra tán láti ṣàánú àwọn adẹ́tẹ̀, àwọn afọ́jú tó ń tọrọ báárà àtàwọn míì tó nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò sọ fún un tẹ́lẹ̀ pé àwọn ń bọ̀ wá rí i, síbẹ̀ ó dá wọn lóhùn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ṣíwọ́ ohun tó ń ṣe lọ́wọ́ kó lè ráyè dá àwọn tí ìdààmú bá lóhùn. Ìgbatẹnirò tí Jésù máa ń lò fún àwọn tó gbà á gbọ́ pọ̀ kọjá sísọ. (Máàkù 5:30-34; Lúùkù 18:35-41) Àwa Kristẹni náà máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa jíjẹ́ onínúure, tá a sì máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn aládùúgbò wa àtàwọn míì kò ṣàìrí oore tá à ń ṣe yẹn. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ ń fògo fún Jèhófà, ó sì ń fún wa láyọ̀.
6. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn fífi ọ̀yàyà hàn àti híhùwà bí ọ̀rẹ́?
6 Jésù tún fi ọ̀wọ̀ hàn fáwọn èèyàn nípa fífi orúkọ wọn gan-gan pè wọ́n. Ṣé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù máa ń fọ̀wọ̀ hàn fáwọn èèyàn lọ́nà yẹn? Rárá o. “Ẹni ègún” ni wọ́n ka àwọn tí kò mọ Òfin sí, wọ́n sì ń ṣe wọ́n bí ẹni ègún. (Jòh. 7:49) Ti Ọmọ Ọlọ́run kò rí bẹ́ẹ̀. Orúkọ àwọn èèyàn bíi Màtá, Màríà, Sákéù, àti ọ̀pọ̀ àwọn míì ló fi ń pè wọ́n. (Lúùkù 10:41, 42; 19:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà àti ipò nǹkan ló máa ń sọ bá a ṣe máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, síbẹ̀ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń ṣe ọ̀yàyà sáwọn èèyàn.a A kì í fàyè gba ẹ̀mí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ láti dín ọ̀wọ́ tó yẹ ká máa fi wọ àwọn ará wa àtàwọn míì kù.—Ka Jákọ́bù 2:1-4.
7. Báwo làwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lórí ọ̀ràn híhùwà tó bójú mu sáwọn èèyàn níbikíbi tá a bá wà?
7 Bí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ ṣe ń ṣàpọ́nlé àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà ń buyì kún àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ó sì ń fa àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òótọ́ wá sínú òtítọ́. Àmọ́, lórí ọ̀ràn ìwà tó bójú mu, báyìí làá ṣe nílẹ̀ wa, èèwọ̀ ibòmíì ni. Ìdí rèé tá ò fi gbọ́dọ̀ ṣe òfin má-ṣu-má-tọ̀ lórí ọ̀ràn ìwà híhù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa jẹ́ kí ìlànà Bíbélì darí wa lórí bó ṣe yẹ ká máa buyì kún àwọn èèyàn bíi tiwa níbikíbi tá a bá wà. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí híhùwà tó bójú mu sáwọn èèyàn ṣe lè mú kí iṣẹ́ ìwàásù wa túbọ̀ máa sèso rere.
Kíkí Àwọn Èèyàn àti Bíbá Wọn Sọ̀rọ̀
8, 9. (a) Irú ìṣe wo làwọn èèyàn lè kà sí ìwà tí kò bójú mu? (b) Kí nìdí tá a fi ní láti máa tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 5:47 nínú bá a ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn?
8 Torí kòókòó jàn-ánjàn-án táráyé ń bá kiri níbi púpọ̀ lóde òní, ẹni méjì sábà máa ń kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn láìlanu kí ara wọn. Lóòótọ́, a ò retí pé ká máa kí gbogbo ẹni tó bá ń kọjá lọ lọ́nà tí èrò ti ń wọ́ tìrítìrí. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ipò míì ló wà tó ti yẹ ká máa kí àwọn èèyàn táwọn náà á sì dáhùn. Ṣé o máa ń kí àwọn èèyàn? Àbí ńṣe lo kàn máa ń kọjá lára wọn láìkí wọn pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ àti ọ̀rọ̀ tó yááyì? Téèyàn ò bá ṣọ́ra, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tí kò yẹ ọmọlúwàbí, láìfi ṣe ìkà.
9 Jésù sọ̀rọ̀ kan tó yẹ kó máa ró gbọnmọgbọnmọ lọ́kàn wa, ó ní: “Bí ẹ bá sì kí àwọn arákùnrin yín nìkan, ohun àrà ọ̀tọ̀ wo ni ẹ ń ṣe? Àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú kò ha ń ṣe ohun kan náà bí?” (Mát. 5:47) Lórí kókó yìí, agbaninímọ̀ràn kan tó ń jẹ́ Donald Weiss sọ nínú ìwé kan tó kọ, pé: “Ó máa ń dun àwọn èèyàn tẹ́nì kan bá fojú pa wọ́n rẹ́. Kò sí àwíjàre kankan tó o lè wí tó máa pẹ̀tù sí wọn lọ́kàn. Ohun tí kò ní jẹ́ kírú rẹ̀ máa wáyé ò ṣòro, òun ni pé kó o máa kí àwọn èèyàn, kó o sì máa bá wọn sọ̀rọ̀.” Tí a kì í bá ta kété sáwọn èèyàn, tá a sì jẹ́ ẹni tí ara rẹ̀ yọ̀ mọ́ èèyàn, wọn yóò máa sún mọ́ wa.
10. Báwo ni ìwà tó bójú mu ṣe lè mú kí ìwàásù wa so èso rere? (Wo àpótí náà, “Fi Ẹ̀rín Músẹ́ Bẹ̀rẹ̀.”)
10 Jẹ́ ká wo ọ̀ràn tọkọtaya Kristẹni kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Tom àti Carol, tí wọ́n ń gbé ní ìlú ńlá kan ní Amẹ́ríkà ti Àríwá. Wọ́n fi bíbá àwọn aládùúgbò wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó yááyì kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Tom sọ pé ohun tó wà ní Jákọ́bù 3:18 làwọn ń tẹ̀ lé, ó ní: “A máa ń gbìyànjú láti ṣe bí ọ̀rẹ́ wọn, a sì ń bá wọn lò lọ́nà àlàáfíà. Tá a bá rí àwọn tó wà níwájú ilé wọn tàbí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láyìíká, a máa ń lọ bá wọn. A ó rẹ́rìn-ín múṣẹ́ bá a ṣe ń kí wọn. A ó bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, bí àwọn ọmọ wọn, ajá wọn, ilé wọn tàbí iṣẹ́ wọn. Tó bá yá, wọ́n á kà wá sí ọ̀rẹ́ wọn.” Carol ìyàwó rẹ̀ fi kún un pé: “Tá a bá tún pa dà lọ sọ́dọ̀ wọn, a máa ń sọ orúkọ wa fún wọn a ó sì béèrè tiwọn náà. A ó sọ ohun tá à ń ṣe ládùúgbò wọn fún wọn, àmọ́ ọ̀rọ̀ ṣókí la máa ń bá wọn sọ. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó máa ń ṣeé ṣe láti wàásù fún wọn.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn aládùúgbò Tom àti Carol ló ti fọkàn tán wọn. A sì tún rí púpọ̀ lára wọn tó ti gba ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, àwọn díẹ̀ sì ti fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Híhùwà Tó Bójú Mu Nígbà Tí Nǹkan Bá Nira
11, 12. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa retí pé wọ́n lè rí wa fín nígbà tá a bá ń wàásù ìhìn rere, kí ló sì yẹ ká ṣe tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀?
11 Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń rí wa fín nígbà tá a bá lọ wàásù ìhìn rere fún wọn. Èyí kò yà wá lẹ́nu torí pé Kristi Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòh. 15:20) Àmọ́ tá a bá fi èébú dá ẹni tó bú wa lóhùn, ìyẹn kì í bímọ rere. Kí ló wá yẹ ká ṣe? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín, kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pét. 3:15) Tá a bá ń hùwà tó yẹ ọmọlúwàbí, tá à ń fi inú tútù àti ọ̀wọ̀ dá àwọn tó ń bú wa lóhùn, ó lè yí wọn lérò pa dà.—Títù 2:7, 8.
12 Ṣé a lè múra sílẹ̀ láti fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tí kò bára dé lọ́nà tí inú Ọlọ́run dùn sí? A lè ṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù dá a lábàá pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kól. 4:6) Tá a bá sọ ọ́ di àṣà wa láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn ọmọ ilé ìwé wa, àwọn tá a jọ ń ṣíṣẹ́, àwọn ará ìjọ wa àtàwọn tó wà ládùúgbò wa, ó máa rọrùn fún wa láti fara da yẹ̀yẹ́ àti àbùkù lọ́nà tó yẹ Kristẹni.—Ka Róòmù 12:17-21.
13. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé téèyàn bá hùwà tó yẹ ọmọlúwàbí, ó lè mú kí ọkàn àwọn alátakò yí pa dà.
13 Híhùwà tó bójú mu nígbà tí nǹkan bá nira máa ń so èso rere. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Japan, onílé kan àti àlejò rẹ̀ fi arákùnrin kan ṣe yẹ̀yẹ́. Arákùnrin náà rọra jáde wọ́ọ́rọ́wọ́. Bó ṣe ń bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yẹn, ó kíyè sí i pé àlejò yẹn ń wo òun láti tòsí ibi tóun wà. Nígbà tí arákùnrin náà lọ bá ọkùnrin àlejò yẹn, ọkùnrin náà ní: “Má ṣe bínú ohun tá a ṣe lẹ́ẹ̀kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tá a sọ sí ọ kò dáa, mo kíyè sí i pé ṣe lò ń rẹ́rìn-ín. Kí lèmi náà lè ṣe tí màá fi jọ ẹ́?” Torí pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọkùnrin yẹn, màmá rẹ̀ sí kú, kò gbà pé ohunkóhun tún lè mú kóun láyọ̀ mọ́ láyé yìí. Arákùnrin yẹn fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́, ó sì gbà. Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀.
Ọ̀nà Tó Dáa Jù Láti Dẹni Tó Ní Ìwà Tó Bójú Mu
14, 15. Báwo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì ṣe tọ́ ọmọ wọn?
14 Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run rí i dájú pé àwọn kọ́ àwọn ọmọ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ ilé. Wo bí Ábúráhámù àti Ísákì ọmọ rẹ̀ ṣe bá ara wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 22:7. Ẹ̀kọ́ rere táwọn òbí Jósẹ́fù kọ́ ọ hàn nínú ìwà rẹ̀. Nígbà tí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, ìwà tó bójú mu ló ń hù sáwọn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n pàápàá. (Jẹ́n. 40:8, 14) Ọ̀nà tó gbà bá Fáráò sọ̀rọ̀ fi hàn pé ó ti kọ́ bó ṣe yẹ kéèyàn máa bá ẹni tó wà nípò gíga sọ̀rọ̀.—Jẹ́n. 41:16, 33, 34.
15 Àṣẹ kan wà nínú Òfin Mẹ́wàá tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àṣẹ náà ni pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ kí àwọn ọjọ́ rẹ bàa lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ.” (Ẹ́kís. 20:12) Ọ̀nà kan táwọn ọmọ lè gbà bọlá fún àwọn òbí wọn ni pé kí wọ́n máa hùwà tó bójú mu nínú ilé. Ọmọbìnrin Jẹ́fútà fi ọ̀wọ̀ hàn fún bàbá rẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nípa fífaramọ́ ẹ̀jẹ́ tí bàbá rẹ̀ jẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún ọmọbìnrin náà rárá.—Oníd. 11:35-40.
16-18. (a) Ọ̀nà wo la lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́ ilé? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́ ilé?
16 Kíkọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́ ilé kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó yẹ ká fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú. Káwọn ọmọ wa bàa lè mọ̀wàá hù tí wọ́n bá dàgbà, ó yẹ ká kọ́ wọn bó ṣe yẹ kí wọ́n kí àlejò, bó ṣe yẹ kí wọ́n sọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ń dáhùn lórí tẹlifóònù àti tí wọ́n bá ń bá àwọn èèyàn jẹun. A ní láti jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa bá ẹni tó fẹ́ wọlé ṣílẹ̀kùn, kí wọ́n ṣèrànwọ́ fáwọn àgbàlagbà àtàwọn tó ń ṣàìsàn àti pé tẹ́nì kan bá gbẹ́rù tó wúwo, kí wọ́n ràn án lẹ́rù. Ó yẹ kí wọ́n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti máa lo àwọn èdè bí, “ẹ jọ̀wọ́,” “ẹ ṣeun,” “kò tọ́pẹ́,” “kí lẹ fẹ́ kí n bá yín ṣe?” àti “ẹ máà bínú.”
17 Kíkọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ ilé kì í ṣe ohun tó yẹ kó nira. Ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà ṣe é ni pé ká fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n kan tó ń jẹ́ Kurt sọ bí òun pẹ̀lú bùrọ̀dá òun méjì àti àbúrò òun ọkùnrin ṣe kọ́ béèyàn ṣe ń hùwà tó bójú mu, ó ní: “A máa ń rí bí dádì àti mọ́mì wa ṣe máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti bí wọ́n ṣe ń fi sùúrù àti ìgbatẹnirò bá àwọn èèyàn lò. Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, dádì mi máa ń mú mi lọ kí àwọn ará tó jẹ́ àgbàlagbà ṣáájú ìpàdé àti lẹ́yìn ìpàdé. Mo máa ń rí bí wọ́n ṣe ń kí wọn àti bí wọ́n ṣe máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn.” Kurt tún fi kún un pé: “Nígbà tó yá mo wá fìwà jọ wọ́n. Ó ti wá mọ́ mi lára láti máa fi ọ̀wọ̀ bá àwọn èèyàn lò. Kì í ṣe ọ̀ràn tipátipá, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń wù mí láti ṣe.”
18 Táwọn òbí bá ń kọ́ ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ilé, kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde rẹ̀? Àwọn ọmọ náà yóò lè ní ọ̀rẹ́, wọ́n á sì lè máa bá àwọn èèyàn gbé láìjà láìta. Wọ́n á tún ti kọ́ bí wọ́n á ṣe máa bá ọ̀gá àtàwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọmọ tó bá mọ̀wàáhù, tó lẹ́kọ̀ọ́ ilé, tó sì jẹ́ olóòótọ́ máa ń mú káwọn òbí wọn láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.—Ka Òwe 23:24, 25.
Ìwà Tó Bójú Mu Ń Jẹ́ Ká Dá Yàtọ̀
19, 20. Kí nìdí tó fi yẹ ká pinnu láti máa fara wé Ọlọ́run wa olóore ọ̀fẹ́ àti Ọmọ rẹ̀?
19 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfé. 5:1) Ohun tó túmọ̀ sí láti fara wé Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ ni pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, irú èyí tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní di alágàbàgebè tó ń fi ìwà ọmọ ọmọlúwàbí ṣe ojú ayé, torí kó lè rí ojúure àwọn aláṣẹ tàbí torí ohun tó máa jẹ tó ń wá.—Júúdà 16.
20 Láwọn ọjọ́ tó kẹ́yìn ìṣàkóso burúkú ti Sátánì yìí, Sátánì fẹ́ rí i pé àwọn èèyàn ò tẹ̀ lé ìlànà tí Jèhófà fi lélẹ̀ nípa bíbọ̀wọ̀ fúnni mọ́. Àmọ́ kò ní ṣeé ṣe fún Èṣù láé láti ba ìwà rere àwa Kristẹni tòótọ́ jẹ́. Ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù wa pinnu láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run wa olóore ọ̀fẹ́ àti ti Ọmọ rẹ̀. Èyí ni yóò máa mú kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà wa yàtọ̀ sí tàwọn tó ti ya oníwàkiwà. A ó sì máa mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa tó fi àpẹẹrẹ bó ṣe yẹ ká máa hùwà hàn wá, a ó sì tún máa fa àwọn olóòótọ́ èèyàn wá sínú ìjọsìn tòótọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láwọn ibì kan, ìwà àrífín ló jẹ́ fún èèyàn láti máa la orúkọ mọ́ ẹni tó jù ú lọ lórí, àyàfi tó bá jẹ́ pé onítọ̀hún ló ní kó máa pe òun lórúkọ. Láwọn irú ibi bẹ́ẹ̀, kò yẹ káwa Kristẹni máa pe ẹni tó bá jù wá lọ lórúkọ.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí la rí kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà tó bójú mu?
• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé fífi ọ̀yàyà kí àwọn èèyàn máa ń sọ ohun tó dáa nípa àwa Kristẹni?
• Báwo ni fífi ọ̀wọ̀ hàn ṣe lè mú kí iṣẹ́ ìwàásù wa so èso rere?
• Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ilé?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Fi Ẹ̀rín Músẹ́ Bẹ̀rẹ̀
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń lọ́ra láti bá ẹni tí wọn ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀. Àmọ́ tórí ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá gidigidi láti kọ́ béèyàn ṣe ń bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀, torí pé a fẹ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ béèyàn ṣe ń bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀?
Ìlànà kan tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn wà nínú Fílípì 2:4, tó sọ pé: “Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” Ro ọ̀rọ̀ yẹn wò lọ́nà yìí: Tí o kò bá tíì rí ẹnì kan rí, àjèjì ló máa kà ọ́ sí. Báwo wá lo ṣe lè mú kí ọkàn onítọ̀hún balẹ̀? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa rírẹ́rìn-ín músẹ́ kó o sì kí i tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Àmọ́ kò tán síbẹ̀.
Tó o bá ń gbìyànjú láti bá ẹnì kan sọ̀rọ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹni náà ń ro nǹkan kan tẹ́lẹ̀ kó o tó já lu ohun tó ń rò lọ́kàn. Tó o bá ń gbìyànjú láti jẹ́ kẹ́ ẹ jọ jíròrò ohun tó wà lọ́kàn rẹ láìwo ti ohun tó wà lọ́kàn onítọ̀hún, ó lè ṣàìdá ọ lóhùn dáadáa. Torí náà, tó bá ṣeé ṣe fún ọ láti fòye mọ ohun tó ti ń rò tẹ́lẹ̀, o ò ṣe kúkú fìyẹn bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò rẹ pẹ̀lú rẹ̀. Ohun tí Jésù ṣe gan-an nìyẹn nígbà tó rí obìnrin kan létí kànga kan ní Samáríà. (Jòh. 4:7-26) Bí obìnrin náà ṣe máa rí omi ló ń rò lọ́kàn. Jésù sì jẹ́ kí ìjíròrò òun dá lórí omi tí obìnrin yẹn ń ronú nípa rẹ̀, kò sì pẹ́ tó fi yí ìjíròrò náà pa dà sí ìjíròrò tẹ̀mí tó lárinrin.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Híhùwà ọ̀rẹ́ sáwọn èèyàn lè mú ká láǹfààní àtijẹ́rìí fún wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Gbogbo ìgbà ló tọ́ ká máa hùwà tó bójú mu