Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà—Yóò Ràn ẹ́ Lọ́wọ́
Gẹ́gẹ́ bí Edmund Schmidt ṣe sọ ọ́
Mo rántí àmọ̀ràn òkè yìí nígbà tí mo fẹ́ fara hàn níwájú ilé ẹjọ́ ní New York ní October 1943. Nígbà tí mo di ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, nítorí pé mo jẹ́ Kristẹni, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́rin tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ìdí ni pé mo kọ̀ láti bá wọn lọ́wọ́ sí ogun. Bíi ti àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ìjímìjí, mo ti pinnu láti “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Àmọ́ kí n tó sọ̀rọ̀ nípa ìyẹn, ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí mo ṣe dẹni tó nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run.
W Ọ́N bí mi ní April 23, ọdún 1922, nílùú Cleveland, ní ìpínlẹ̀ Ohio lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, inú yàrá tó wà nínú ilé alágbèékà lórí ilé iṣẹ́ búrẹ́dì bàbá mi ni wọ́n bí mi sí. Oṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà, bàbá mi lọ sí àpéjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (bá a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn) nílùú Cedar Point, nítòsí Sandusky, nǹkan bí ọgọ́jọ kìlómítà ni sí ilé wa.
Wọ́n rọ àwọn tó wá sí àpéjọ náà pé, “ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba [Ọlọ́run] àti Ìjọba rẹ̀.” Lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e, bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. O sì ń bá iṣẹ́ náà nìṣó fún ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] títí tó fi kú ní July 4, 1988. Màmá mi náà, jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí tó fi kú ní ọdún 1981.
Mo Dara Pọ̀ Mọ́ Àwọn Òbí Mi Nínú Ìjọsìn
Ìjọ tó ń sọ èdè Polish ní Cleveland ni ìdílé wa ń lọ. Ní àwọn ọ̀sán Saturday, àwọn àgbàlagbà àti ọ̀pọ̀ lára àwa ọmọ jọ máa ń lọ wàásù ìhìn rere láti ilé dé ilé. Ní àwọn ọjọ́ Sunday, àwọn òbí wa máa ń gbádùn àsọyé Bíbélì ní gbọ̀ngàn tá a ti ń ṣe ìpàdé. Ní àkókò kan náà, ẹnì kan tó lóye Bíbélì máa ń fi ìwé tó ń jẹ́ Duru Ọlọruna kọ́ àwa èwe tá a jẹ́ ọgbọ̀n lẹ́kọ̀ọ́. Kò pẹ́ tí èmi náà fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń yọrí sí rere.
Ní July 1931, ìdílé wa títí kan àbúrò mi Frank, lọ sí àpéjọ míì tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ní Columbus, èyí sì fi nǹkan bí ọgọ́jọ [160] kìlómítà jìn lápá gúúsù. Ìgbà yẹn ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí tó wá látinú Bíbélì. (Aísáyà 43:10-12) Ní àkókò yẹn, mo lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, mò ń pe àwọn èèyàn láti wá gbọ́ àsọyé tí Arákùnrin J. F. Rutherford, tó ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn fẹ́ sọ. Ó ti lé ní ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] báyìí tí èmi àtàwọn èèyàn Jèhófà Ọlọ́run jọ ń sìn ín.
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Mi Méso Wá Láìka Wàhálà Sí
Kárí ayé ni Ìlọsílẹ̀ Gígadabú nínú Ọrọ̀ Ajé ti ọdún 1933 nípa lórí àwọn èèyàn. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún òṣìṣẹ́ tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ìlú le, kò sí owó ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ ìjọba fún àgbàlagbà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí owó ìrànwọ́ fún àwọn tálákà. Síbẹ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin ran ara wọn lọ́wọ́. Ní àwọn ọjọ́ Sunday, ìdílé wa máa ń mú búrẹ́dì àtàwọn ìpápánu láti ilé iṣẹ́ búrẹ́dì wa wá sí ìpàdé láti fún àwọn èèyàn. Lẹ́yìn tí bàbá mi bá ti san owó tá a ná lóṣù kan, ó máa ń fi gbogbo owó tó bá ṣẹ́ kù lọ́wọ́ rẹ̀ ránṣẹ́ sí orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York. Ó mọ̀ pé wọ́n máa lo owó yẹn láti fi tẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn, ilé iṣẹ́ rédíò kó ipa pàtàkì nínú iṣẹ́ ìwàásù wa. Ilé iṣẹ́ rédíò tó lé ní irínwó [400] ló máa ń bá wa gbé àwọn àsọyé tá a sọ ní àwọn àpéjọ wa sáfẹ́fẹ́. Láwọn ọdún 1930 sí 1939, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe àwọn ẹ̀rọ giramafóònù àtàwọn àwo nílé iṣẹ́ wa ní Brooklyn. A máa ń lo ẹ̀rọ giramafóònù wọ̀nyẹn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láti gbé àsọyé Bíbélì jáde gbọ́ fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì máa ń ṣàkọsílẹ̀ iye ìgbà tí wọ́n gbọ́ ọ àti iye èèyàn tó gbọ́ ọ.
Lọ́dún 1933, ọ̀gbẹ́ni Adolf Hitler àti ẹgbẹ́ òṣèlú Násì dé ipò agbára lórílẹ̀-èdè Jámánì. Wọ́n ṣe inúnibíni tó rorò sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí pé a kò lọ́wọ́ sí òṣèlú. (Jòhánù 15:19; 17:14) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Jámánì ni wọ́n rán lọ sí ẹ̀wọ̀n tàbí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú òṣèlú tàbí láti kókìkí Hitler. Wọ́n pa ọ̀pọ̀ lára wọn, wọ́n sì fi àwọn kan ṣe iṣẹ́ títí wọ́n fi kú. Ọ̀pọ̀ ló kú kété lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀ nítorí ìwà òǹrorò tí wọ́n ti hù sí wọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ ohun tójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí nílẹ̀ ibòmíì, títí kan orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
A lọ sí àpéjọ kan nílùú Detroit, ní ìpínlẹ̀ Michigan lọ́dún 1940. Ní July 28, mo ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Ní oṣù tó ṣáájú àpéjọ náà, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ṣòfin pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ẹnì kan dá tí kò bá kí àsíá, ńṣe ni wọ́n sì máa lé ẹni náà kúrò nílé ẹ̀kọ́. Kí ni àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe sí ọ̀ràn náà? Ọ̀pọ̀ lára wọn dá ilé ẹ̀kọ́ tiwọn sílẹ̀ kí wọ́n bàa lè kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀kọ́ ìwé. Wọ́n ń pe àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà ní Kingdom Schools.
Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ní September 1939 ní Yúróòpù, ìfẹ́ fún orílẹ̀-èdè ẹni sì gbòde kan ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà nígbà ogun náà. Tàgbàtèwe tí wọn kò lóye wa ń fòòró ẹ̀mí wa, wọ́n sì ń lù wá. Ìròyìn fi hàn pé ó ju ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún [2,500] ìgbà táwọn èèyànkéèyàn hùwà ipá sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1940 sí 1944. Inúnibíni náà le sí i nígbà tí àwọn ará Japan kọ lu erékùṣù Pearl Harbor ní December 7, 1941. Ní àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn ni orúkọ àwọn òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi àkókò púpọ̀ wàásù. Mo tọ́jú owó pa mọ́ láti fi ra ilé àgbérìn tó ga tó mítà méje, àwa mélòó kan sì wá sí Louisiana láti ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀.
Inúnibíni ní Gúúsù Amẹ́ríkà
A gba àṣẹ lọ́dọ̀ àwọn tó ń gbé ládùúgbò láti gbé ilé àgbérìn wa sí oko igi èso kan tó wà nítòsí ìlú Jeanerette. Ní ọjọ́ Saturday a pinnu láti wàásù ní ojú pópó, àmọ́ ọ̀gá ọlọ́pàá pe àwọn ọlọ́pàá tó ń bá a ṣiṣẹ́, wọ́n sì mú wa bí ẹlẹ́wọ̀n lọ sí gbọ̀ngàn ìlú. Àwọn èèyànkéèyàn tí wọ́n tó nǹkan bí igba [200] kóra jọ síta gbọ̀ngàn náà, àwọn ọlọ́pàá sì ní ká máa lọ láìsí ààbò kankan. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa pé àwọn èèyànkéèyàn náà kúrò lọ́nà, wọ́n sì jẹ́ ká kọjá. Lọ́jọ́ kejì, a lọ sí ìlú Baton Rouge, ìlú ńlá tó wà nítòsí, láti lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí.
Nígbà tá a pa dà dé Jeanerette, a rí ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ilẹ̀kùn ilé àgbérìn wa, ó ní: “Jọ̀wọ́ wá rí mi ní àgọ́ àwọn òṣìṣẹ́ elépo.” Ọ̀gbẹ́ni “E. M. Vaughn ló buwọ́ lu ọ̀rọ̀ tó wà lára ilẹ̀kùn náà.” A rí Ọ̀gbẹ́ni Vaughn, ó sì ní ká wá bá òun àti ìyàwó òun jẹun. Ó sọ fún wa pé òun àtàwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ òun wà lára àwọn tó kóra jọ lọ́jọ́ Saturday, ó ní ká ní àwọn èèyànkéèyàn yẹn fẹ́ fọwọ́ kàn wá lọ́jọ́ yẹn ni, òun ì bá gbèjà wa. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìṣírí tó fún wa àti ìtìlẹ́yìn rẹ̀.
Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, àwọn ọlọ́pàá tó ń gbébọn mú wa, wọ́n sì gba gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa. Wọ́n gba gbogbo kọ́kọ́rọ́ ilé àgbérìn mi, wọ́n sì fi mí sẹ́wọ̀n fún ọjọ́ mẹ́tàdínlógún nínú àhámọ́ aládàáwà, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí oúnjẹ. Ọ̀gbẹ́ni Vaughn sapá láti ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ kẹ́sẹ járí. Lákòókò tá a wà ní àhámọ́ yẹn, àwọn èèyànkéèyàn yẹn jà wá lólè, wọ́n sì sun gbogbo ohun tá a ní, títí kan ilé àgbérìn mi. Nígbà yẹn, mi ò mọ̀ pé ńṣe ni Jèhófà ń múra mi sílẹ̀ fún ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí mi.
Wọ́n Fi Mí Sẹ́wọ̀n ní Àríwá Amẹ́ríkà
Oṣù kan lẹ́yìn tí mo pa dà dé láti àríwá Amẹ́ríkà, wọ́n yan èmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí míì láti lọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Olean, ní ìpínlẹ̀ New York. Nígbà tá a wà níbẹ̀, ìjọba ní kí n forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ológun, àmọ́ wọ́n fún mi láǹfààní láti wà lára àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun. Àmọ́ lẹ́yìn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún mi, tí wọ́n rí i pé ara mi dá ṣáṣá, pé orí mi sì pé, ńṣe ni wọ́n lu ìwé mi ní òǹtẹ̀, “Àwọn Tó Máa Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Àwọn Ológun.”
Ó ṣeé ṣe fún mi láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà mi nìṣó fún nǹkan bí ọdún kan sí i. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 1943, àwọn ọlọ́pàá FBI mú mi nítorí pé mi ò jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti pé mi ò wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun. Wọ́n ní kí n lọ fara hàn ní ilé ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Syracuse ní New York lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e fún ìgbẹ́jọ́. Wọ́n ní mo jẹ̀bi, ìgbẹ́jọ́ mi yóò sì wáyé lọ́jọ́ méjì lẹ́yìn náà.
Èmi fúnra mi ni mo ṣe agbẹjọ́rò ara mi. Ní àwọn ìpàdé wa, wọ́n ti fún àwa ọ̀dọ́ ní ìtọ́ni nípa bá a ṣe máa gbèjà ẹ̀tọ́ wa nílé ẹjọ́ àti bó ṣe yẹ ká máa hùwà tó bójú mu níbẹ̀. Mo rántí ìmọ̀ràn tí mo sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Àwọn kan lára àwọn tó ń bá wa ṣẹjọ́ sọ pé àwa Ẹlẹ́rìí mọ òfin ju àwọn lọ! Síbẹ̀, ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ sọ pé mo jẹ̀bi. Nígbà tí adájọ́ béèrè pé ṣé mo ní ohun kan láti sọ, mo kàn fèsì pé, “Lónìí orílẹ̀-èdè yìí ń jẹ́jọ́ níwájú Ọlọ́run nípa bó ṣe ń ṣe sí àwọn tó ń sin Ọlọ́run.”
Wọ́n ní kí n lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin nílé ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ ní Chillicothe, ní ìpínlẹ̀ Ohio. Wọ́n fún mi níṣẹ́ níbẹ̀ láti máa ṣe akọ̀wé òṣìṣẹ́ kan tó ń bójú tó àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ kan nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan, ọkùnrin kan wá láti Washington D.C., láti ṣe ìwádìí pàtàkì ní ọ́fíìsì wa, ó sọ pé àwọn ń ṣèwádìí nípa Hayden Covington tó jẹ́ agbẹjọ́rò fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì mọ̀ ọ́n káàkiri gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn amòfin tó dára jù lọ nílẹ̀ Amẹ́ríkà.
Olùṣèwádìí náà sọ pé òun fẹ́ rí fáìlì àwọn ẹlẹ́wọ̀n méjì, ìyẹn Danny Hurtado àti Edmund Schmidt. Ọ̀gá àgbà ẹ̀ka iṣẹ́ mi sọ pé, “Ó mà ṣe kòńgẹ́ o, Ọ̀gbẹ́ni Schmidt” tí ẹ̀ ń wá fáìlì rẹ̀ rèé. Olùṣèwádìí náà wá ṣe iṣẹ́ náà láṣìírí ni, àmọ́, ó yà á lẹ́nu pé a ti mọ gbogbo ọ̀ràn náà. Kò pẹ́ tí wọ́n fi yí iṣẹ́ mi pa dà, wọ́n ní kí n lọ máa ṣiṣẹ́ nílé ìgbọ́únjẹ.
Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà, Iṣẹ́ Ìsìn Bẹ́tẹ́lì àti Ìgbéyàwó
Ní September 26, 1946, wọ́n dá mi sílẹ̀ kí ọjọ́ tí mó máa fi ṣẹ̀wọ̀n tó pé, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà mi pa dà, lọ́tẹ̀ yìí ní Ìjọ Highland Park ní California. Nígbà tó yá ní September 1948, ọwọ́ mi tẹ ohun tí mo ti ń wá tipẹ́. Wọ́n pè mí pé kí n wá máa ṣe búrẹ́dì ní orílé-iṣẹ́ (Bẹ́tẹ́lì) wa ní Brooklyn, ìyẹn ibi tá a ti ń ṣe ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń lò nínú iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo fi iṣẹ́ ọ̀gá àwọn tó ń ṣe ìpápánu nílé oúnjẹ ní Glendale sílẹ̀, mo sì lọ sí Bẹ́tẹ́lì.
Ọdún méje lẹ́yìn náà lọ́dún 1955, wọ́n fẹ́ ṣe àwọn àpéjọ àgbáyé mélòó kan ní Yúróòpù. Àwọn ará ilé mi fún mi ní owó láti lọ síbẹ̀. Mo gbádùn àpéjọ tá a ṣe ní London, Paris, Rome, pàápàá èyí tá a ṣe nílùú Nuremberg, lórílẹ̀-èdè Jámánì, níbi tí èèyàn tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn àti ẹgbẹ̀rún méje [107,000] ti péjọ nínú pápá ìṣiré ńlá tí Hitler lò nígbà tó ń fi àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yangàn bó ṣe ń yẹ̀ wọ́n wò. Lára àwọn tó wà ní àpéjọ náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí tí Hitler ti pinnu pé òun máa pa run ráúráú. Inú mi dùn gan-an láti bá wọn péjọ!
Ní àpéjọ Nuremberg, mo pàdé Brigitte Gerwien, ọ̀dọ́bìnrin ará Jámánì kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, ìfẹ́ rẹ̀ sì wọ̀ mí lọ́kàn. Kò pé ọdún kan ká tó ṣègbéyàwó, a sì pa dà sí Glendale láti máa gbé nítòsí àwọn òbí mi. A bí Tom ọmọkùnrin wa àkọ́kọ́ lọ́dún 1957, a bí Don, ọmọkùnrin wa kejì lọ́dún 1958 àti ọmọbìnrin wa, Sabena, lọ́dún 1960.
Mo Gbé Ìgbé Ayé Tó Ládùn
Àwọn kan ti bi mí bóyá mo kábàámọ̀ ìkọlù látọ̀dọ̀ àwọn èèyànkéèyàn àti bí wọ́n ṣe fi mí sẹ́wọ̀n nítorí pé mò ń sin Ọlọ́run. Mi ò kábàámọ̀ rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo ní àǹfààní láti sìn ín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fi òótọ́ sìn ín. Mo retí pé ìrírí mi á fún àwọn míì ní ìṣírí láti sún mọ́ Ọlọ́run kí wọ́n má sì fi í silẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti jìyà nítorí pé wọ́n ń sìn ín. Àmọ́, ṣé kì í ṣe ohun tí wọ́n ní ká máa retí nìyẹn? Bíbélì sọ pé, “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Síbẹ̀, ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Sáàmù 34:19 ṣe jẹ́ òótọ́ tó pé: “Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo, ṣùgbọ́n Jèhófà ń dá a nídè nínú gbogbo wọn”!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́, a kò tẹ̀ ẹ́ mọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
À wàásù nílùú Louisiana ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé ọdún 1940
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Mò ń ṣe búrẹ́dì fún àwọn tó ń sìn ní orílé-iṣẹ́ wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Èmi àti ìyàwó mi rèé