Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Nífẹ̀ẹ́ Òdodo
“Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo.”—SM. 45:7.
1. Kí ló máa mú ká lè máa tọ “àwọn òpó ọ̀nà òdodo”?
JÈHÓFÀ ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú káwọn èèyàn rẹ̀ máa tọ “àwọn òpó ọ̀nà òdodo.” (Sm. 23:3) Àmọ́, torí pé a jẹ́ aláìpé, a máa ń fẹ́ yà kúrò ní ipa ọ̀nà yẹn. Ó máa gba ìsapá gidigidi kí ẹni tó bá yà kúrò ní ipa ọ̀nà náà tó tún lè máa ṣe ohun tó tọ́. Torí náà, kí ló lè mú ká kẹ́sẹ járí? Bíi ti Jésù, a gbọ́dọ̀ fẹ́ láti máa ṣe ohun tó tọ́.—Ka Sáàmù 45:7.
2. Kí ni “àwọn òpó ọ̀nà òdodo”?
2 Kí ni “àwọn òpó ọ̀nà òdodo”? Àwọn òpó ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ yìí jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tó dá lórí àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. Nínú èdè Hébérù àti Gíríìkì, “òdodo” túmọ̀ sí rírọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ìlànà ìwà rere. Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ “ibi gbígbé òdodo,” àwọn tó ń sìn ín máa ń fẹ́ kó pinnu ipa ọ̀nà ìwà rere tó yẹ kí wọ́n máa tọ̀.—Jer. 50:7.
3. Báwo la ṣe lè mọ púpọ̀ sí i nípa òdodo Ọlọ́run?
3 Ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè máa gbà wu Ọlọ́run ní kíkún ni pé ká máa fi gbogbo ọkàn wa sapá, ká lè máa ṣe àwọn ohun tó bá ìlànà òdodo rẹ̀ mu. (Diu. 32:4) Ìyẹn sì bẹ̀rẹ̀ látorí kíkẹ́kọ̀ọ́ débi tá a bá lè kọ́ ọ dé nípa Jèhófà Ọlọ́run látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bá a bá ṣe ń mọ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀, tá a sì ń sún mọ́ ọn lójoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ náà la óò túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ òdodo rẹ̀. (Ják. 4:8) A sì tún gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí máa tọ́ wa sọ́nà nígbà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì tó kan ìgbésí ayé wa.
Wá Òdodo Ọlọ́run
4. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ wá òdodo Ọlọ́run?
4 Ka Mátíù 6:33. Bá a bá fẹ́ wá òdodo Ọlọ́run a gbọ́dọ̀ ṣe ju ká máa lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ. Kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa, ìwà tá à ń hù lójoojúmọ́ gbọ́dọ̀ bá àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ mu. Kí ló yẹ kí gbogbo àwọn tó ń wá òdodo Jèhófà ṣe? Wọ́n gbọ́dọ̀ “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”—Éfé. 4:24.
5. Kí ló máa mú ká lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì?
5 Bá a ti ń sapá láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run, nígbà míì a lè rẹ̀wẹ̀sì nítorí àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó tiwa. Kí ló lè mú ká borí ìrẹ̀wẹ̀sì tí ń tánni lókun, táá jẹ́ ká lè nífẹ̀ẹ́ òdodo ká sì máa fi ṣèwà hù? (Òwe 24:10) A gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé “pẹ̀lú ọkàn-àyà tòótọ́ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ti ìgbàgbọ́.” (Héb. 10:19-22) Yálà a jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró tàbí à ń retí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé, à ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi àti iṣẹ́ tó ń gbé ṣe gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà ńlá wa. (Róòmù 5:8; Héb. 4:14-16) Ẹ̀dà àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn wa yìí ṣàpèjúwe bí ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi ṣèrúbọ ṣe gbéṣẹ́ tó. (1 Jòh. 1:6, 7) Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Òtítọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé [nígbà] tá a bá fi gíláàsì pupa wo ohun kan tó ní àwọ̀ pupa rírẹ̀ dòdò níbi tí ìmọ́lẹ̀ wà, ó máa dà bíi pé àwọ̀ funfun ni ohun náà ní; torí náà, bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa bá tiẹ̀ pupa bí àwọ̀ rírẹ̀ dòdò, nígbà tí Ọlọ́run bá tipasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Kristi wò wọ́n, ńṣe ni wọ́n máa funfun.” (July 1879, ojú ìwé 6 [Gẹ̀ẹ́sì]) Ohun àgbàyanu mà ló jẹ́ o pé Jèhófà ti fi ẹbọ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rà wá pa dà!—Aís. 1:18.
Máa Yẹ Ìhámọ́ra Tẹ̀mí Rẹ Wò
6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa yẹ ìhámọ́ra tẹ̀mí wa wò?
6 Kò sí ìgbà kan tó yẹ ká bọ́ “àwo ìgbàyà ti òdodo” sílẹ̀ torí pé ó jẹ́ apá pàtàkì lára ìhámọ́ra tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Éfé. 6:11, 14) Yálà a ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà ni o tàbí a ti ń sìn láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó ṣe pàtàkì pé ká máa yẹ ìhámọ́ra tẹ̀mí wa wò lójoojúmọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ti lé Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run wá sí sàkáání ilẹ̀ ayé. (Ìṣí. 12:7-12) Inú ń bí Sátánì ó sì mọ̀ pé àkókò kúkúrú ni òun ní. Torí náà, ńṣe ló túbọ̀ ń gbógun ti àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ǹjẹ́ a mọrírì bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká má ṣe bọ́ “àwo ìgbàyà ti òdodo” sílẹ̀ nígbà kankan?
7. Kí ló yẹ ká máa ṣe bá a bá mọrírì bá a ṣe nílò “àwo ìgbàyà ti òdodo” tó?
7 Bí àwo ìgbàyà ṣe máa ń dàábò bo ọkàn wa, bẹ́ẹ̀ ni òdodo ṣe máa ń dàábò bo ọkàn-àyà wa. Torí pé a jẹ́ aláìpé, ọkàn-àyà wa máa ń ṣe àdàkàdekè, ó sì máa ń gbékútà. (Jer. 17:9) Níwọ̀n bí ọkàn-àyà wa ti máa ń fẹ́ láti ṣe ohun tó burú, ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́ ọ, ká sì jẹ́ kó máa darí wa síbi tó tọ́. (Jẹ́n. 8:21) Bá a bá mọrírì bá a ṣe nílò “àwo ìgbàyà ti òdodo” tó, a kò ní bọ́ ọ sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ ká lè lọ́wọ́ nínú àwọn eré ìnàjú tó dá lórí ohun tí Ọlọ́run kórìíra; a kò sì ní máa ronú nípa híhùwà àìtọ́. A kò ní máa fi ọ̀pọ̀ àkókò tó ṣeyebíye ṣòfò nídìí tẹlifíṣọ̀n. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó máa sapá láti ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí. Bí ríronú lórí àwọn nǹkan tó lòdì sí ìlànà òdodo Ọlọ́run bá tiẹ̀ mú ká kọsẹ̀ fúngbà díẹ̀, Jèhófà ṣì máa ràn wá lọ́wọ́ láti pa dà bọ̀ sípò.—Ka Òwe 24:16.
8. Kí nìdí tá a fi nílò “apata ńlá ti ìgbàgbọ́”?
8 Òmíràn lára ìhámọ́ra tẹ̀mí wa ni “apata ńlá ti ìgbàgbọ́.” Ó máa ń mú ká lè “paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà.” (Éfé. 6:16) Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ àtọkànwá fún Jèhófà sì máa ń jẹ́ ká fi òdodo ṣèwà hù ká má bàa kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Bá a ṣe ń kọ́ láti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà la ó ṣe túbọ̀ máa mọyì òdodo rẹ̀ tó. Àmọ́ ẹ̀rí ọkàn wa ńkọ́? Báwo ló ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ bá a ti ń sapá láti nífẹ̀ẹ́ òdodo?
Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere
9. Báwo la ṣe ń jàǹfààní látinú níní ẹ̀rí ọkàn rere?
9 Nígbà tá a ṣe ìrìbọmi, a bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní “ẹ̀rí-ọkàn rere.” (1 Pét. 3:21) Torí pé a lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà, ẹ̀jẹ̀ Jésù bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀ a sì tipa bẹ́ẹ̀ wà ní ipò mímọ́ lójú Ọlọ́run. Àmọ́, kí ìgbàlà wa bàa lè dájú, a gbọ́dọ̀ ní ẹ̀rí ọkàn rere. Bí ẹ̀rí ọkàn wa bá dá wa lẹ́bi tàbí tó kìlọ̀ fún wa nígbà míì, ó yẹ ká kún fún ọpẹ́ pé ó ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Bí ẹ̀rí ọkàn wa bá ń ta wá lólobó lọ́nà yìí, ìyẹn á fi hàn pé ó ṣì ń ṣiṣẹ́ lọ́nà táá mú ká lè máa rìn ní àwọn ọ̀nà òdodo Jèhófà. (1 Tím. 4:2) Àmọ́ ohun míì tún wà tí ẹ̀rí ọkàn lè ṣe fún àwọn tó fẹ́ láti máa nífẹ̀ẹ́ òdodo.
10, 11. (a) Sọ ìrírí kan tó sọ ìdí tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn sí ẹ̀rí ọkàn wa tá a fi Bíbélì kọ́. (b) Kí nìdí tí ìfẹ́ fún òdodo fi lè mú ká máa láyọ̀?
10 Tá a bá ṣe ohun tí kò dára, ẹ̀rí ọkàn wa lè dá wa lẹ́bi tàbí kó máa dà wá láàmú. Nígbà tí ọ̀dọ́ kan yà kúrò ní “àwọn òpó ọ̀nà òdodo,” wíwo àwòrán oníhòòhò di bárakú fún un ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í mugbó. Ọkàn rẹ̀ máa ń dá a lẹ́bi tó bá lọ sí àwọn ìpàdé ó sì máa ń dà bí alágàbàgebè tó bá wà lóde ẹ̀rí, torí náà ó dẹ́kun láti máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni yìí. Ó sọ pé: “Àmọ́, mi ò mọ̀ pé ẹ̀rí ọkàn mi máa dá mi lẹ́bi gbogbo ìwà tí mò ń hù yìí. Ó sì tó ọdún mẹ́rin tí mo fi hùwà òmùgọ̀ náà.” Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ó yẹ kí òun pa dà sínú òtítọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ronú pé Jèhófà kò ní tẹ́tí sí àdúrà òun, síbẹ̀ ó gbàdúrà ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì. Ní èyí tí kò tó ìṣẹ́jú mẹ́wàá lẹ́yìn náà, ìyá rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ wò, ó sì fún un ní ìṣírí pé kó máa lọ sí àwọn ìpàdé. Ó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba ó sì ní kí alàgbà kan máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó gba ẹ̀mí òun là.
11 Ǹjẹ́ a kò rí i báyìí pé àǹfààní púpọ̀ wà nínú kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́? Bá a ṣe ń kọ́ láti máa nífẹ̀ẹ́ òdodo tá a sì ń fi ṣèwà hù síwájú àti síwájú sí i, bẹ́ẹ̀ la ó máa rí ayọ̀ tó pọ̀ sí i nínú ṣíṣe ohun tó dùn mọ́ Baba wa ọ̀run. Èyí tó tún wá pabanbarì jù lọ ni pé, ọjọ́ ń bọ̀ tí ẹ̀rí ọkàn gbogbo ẹ̀dá á máa mú kí wọ́n láyọ̀; gbogbo wọn á sì máa ṣe àgbéyọ àwọn ànímọ́ tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ àwòrán Ọlọ́run lọ́nà pípé. Torí náà, ẹ jẹ́ ká mú kí ìfẹ́ fún òdodo fìdí múlẹ̀ ṣinṣin nínú ọkàn wa ká sì máa múnú Jèhófà dùn.—Òwe 23:15, 16.
12, 13. Báwo la ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa?
12 Kí la lè ṣe ká bàa lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa? Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde wa tá a gbé karí Bíbélì, ó ṣe pàtàkì ká rántí pé “ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.” (Òwe 15:28) Ronú nípa bí èyí ti ṣàǹfààní tó nígbà tá a bá dojú kọ àwọn ìbéèrè nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Bó bá ṣe kedere pé iṣẹ́ kan kò bá àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ mu, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa máa tètè tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà fún wa. Àmọ́, bí kò bá dá wa lójú bóyá irú iṣẹ́ kan bá Ìwé Mímọ́ mu, ó yẹ ká ṣàwárí àwọn ìlànà Bíbélì ká sì gbé wọn yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà.a Èyí tún kan àwọn ìlànà tó wé mọ́ bá ò ṣe ní ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn àwọn míì. (1 Kọ́r. 10:31-33) Ìlànà tó tún wá ṣe pàtàkì jù lọ ni èyí tó kan àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Bá a bá gbà pé Jèhófà wà, ó yẹ ká máa bi ara wa pé, ‘Bí mo bá gba irú iṣẹ́ yìí, ṣé ó máa dun Jèhófà, táá sì mú kí inú rẹ̀ bà jẹ́?’—Sm. 78:40, 41.
13 Tá a bá ń múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tàbí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ sílẹ̀, ó yẹ ká máa fi sọ́kàn pé ó ṣe pàtàkì láti máa ṣàṣàrò lórí àwọn ìsọfúnni tó wà níbẹ̀. Ṣé a máa ń yára fa ìlà sábẹ́ ìdáhùn sí ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà tí a sì máa yára kọjá lọ sí ìpínrọ̀ tó kàn? Agbára káká ni kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí fi lè jẹ́ kéèyàn ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún òdodo tàbí kéèyàn ní ẹ̀rí ọkàn tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Ká tó lè nífẹ̀ẹ́ òdodo, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa ká sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bá a bá fẹ́ kọ́ láti fi gbogbo ọkàn-àyà wa nífẹ̀ẹ́ òdodo, a gbọ́dọ̀ sapá gidigidi!
Ebi àti Òùngbẹ fún Òdodo
14. Kí ni Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi fẹ́ ká ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa?
14 Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi fẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa. Kí ló lè pa kún ayọ̀ wa? Ìfẹ́ fún òdodo ni! Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo, níwọ̀n bí a ó ti bọ́ wọn yó.” (Mát. 5:6) Báwo ni gbólóhùn yìí ti ṣe pàtàkì tó fáwọn tó fẹ́ láti nífẹ̀ẹ́ òdodo?
15, 16. Báwo ni àwọn tí ebi ń pa tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo ṣe lè rí ìtẹ́lọ́rùn?
15 Ẹni búburú náà ló ń ṣàkóso ayé tá à ń gbé yìí. (1 Jòh. 5:19) Bí a bá ń ka ìwé ìròyìn ní orílẹ̀-èdè èyíkéyìí, a máa rí àwọn ìròyìn nípa bí ìwà ìkà àti ìwà ipá ṣe ń pọ̀ sí i lọ́nà tí a kò rí irú rẹ̀ rí. Ìwà tó burú jáì tí àwọn èèyàn ń hù sí ọmọnìkejì wọn máa ń da àwọn olódodo láàmú torí pé irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ kò ṣeé ronú kàn. (Oníw. 8:9) Níwọ̀n bá a ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a mọ̀ pé òun nìkan ṣoṣo ló lè bọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo yó, kó sì pòùngbẹ wọn nípa tẹ̀mí. Ọlọ́run máa tó mú àwọn tí kò ṣèfẹ́ rẹ̀ kúrò, àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà àtàwọn ìwà ibi wọn kò sì ní fa ìrora ọkàn fún àwọn olùfẹ́ òdodo mọ́. (2 Pét. 2:7, 8) Ẹ wo bí ìyẹn ṣe máa tù wá lára tó!
16 Níwọ̀n bá a ti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà àti ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, a mọ̀ pé gbogbo àwọn tí ebi ń pa tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo ni ‘a ó bọ́ yó.’ Wọn yóò rí ìtẹ́lọ́rùn kíkún nípasẹ̀ àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí Ọlọ́run ń ṣètò rẹ̀, nínú èyí tí ‘òdodo yóò máa gbé,’ (2 Pét. 3:13) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká sọ̀rètí nù tàbí kó yà wá lẹ́nu pé ìnilára àti ìwà ipá ti mú kí òdodo kásẹ̀ nílẹ̀ nínú ayé Sátánì yìí. (Oníw. 5:8) Jèhófà, Ẹni Gíga Jù Lọ, mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì máa tó gba àwọn olùfẹ́ òdodo sílẹ̀.
Àǹfààní Tó Wà Nínú Nínífẹ̀ẹ́ Òdodo
17. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó ń wá látinú nínífẹ̀ẹ́ òdodo?
17 Ìwé Sáàmù 146:8 sọ àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tó wà nínú títọ ipa ọ̀nà òdodo. Onísáàmù náà sọ pé: “Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn olódodo.” Ìyẹn mà ga o! Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa torí pé a nífẹ̀ẹ́ òdodo! Torí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa yìí, ó dá wa lójú pé ó máa pèsè ohun tá a nílò fún wa bá a ṣe ń fi àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa. (Ka Sáàmù 37:25; Òwe 10:3.) Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo ayé yìí pátá á di ohun ìní àwọn olùfẹ́ òdodo. (Òwe 13:22) Èrè tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn Ọlọ́run máa rí gbà torí pé wọ́n ti fi òdodo ṣèwà hù ni ayọ̀ ńláǹlà àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè ẹlẹ́wà lórí ilẹ̀ ayé. Kódà, ní báyìí, Jèhófà ń mú kí àwọn tó fẹ́ràn òdodo Ọlọ́run ní ìbàlẹ̀ ọkàn, èyí sì túbọ̀ ń mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan nínú ìdílé tàbí nínú ìjọ.—Fílí. 4:6, 7.
18. Àwọn nǹkan rere wo ló yẹ ká máa ṣe bá a ti ń dúró de ọjọ́ Jèhófà?
18 Bá a ṣe ń dúró de dídé ọjọ́ ńlá Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti wá òdodo rẹ̀. (Sef. 2:2, 3) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀. Ìyẹn kan rírí sí i pé a kò fìgbà kan bọ́ “àwo ìgbàyà ti òdodo” wa sílẹ̀, kó lè máa dáàbò bo ọkàn-àyà wa. Ó tún yẹ ká ní ẹ̀rí ọkàn rere, tí yóò mú ká láyọ̀, tí yóò sì máa mú ọkàn Ọlọ́run wa yọ̀.—Òwe 27:11.
19. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 “Ojú [Jèhófà] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíró. 16:9) Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣe tù wá nínú tó bá a ti ń ṣe ohun tó dára, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò àwọn nǹkan túbọ̀ ń di èyí tí kò fara rọ, tí ìwà ipá àti ìwà ibi sì ń pọ̀ sí i nínú ayé ìjàngbọ̀n yìí! Dájúdájú, ọ̀nà òdodo tá à ń tọ̀ lè máa rú aráyé tó ti sọ ara rẹ̀ di àjèjì sí Ọlọ́run lójú. Àmọ́, à ń rí àǹfààní tó pọ̀ nínú rírọ̀ mọ́ òdodo Jèhófà. (Aísá. 48:17; 1 Pét. 4:4) Torí náà, pẹ̀lú ọkàn-àyà pípé, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa rí ìgbádùn nínú nínífẹ̀ẹ́ òdodo àti fífi òdodo ṣèwà hù pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa. Àmọ́ ṣá o, níní ọkàn-àyà pípé tún kan kéèyàn kórìíra ìwà-àìlófin. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ ká mọ ohun tí èyí túmọ̀ sí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, wo Ilé Ìṣọ́ April 15, 1999, ojú ìwé 28 sí 30.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọrírì ìràpadà ká bàa lè nífẹ̀ẹ́ òdodo?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká gbé “àwo ìgbàyà ti òdodo” wọ̀?
• Báwo la ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ẹ̀rí ọkàn tá a kọ́ á jẹ́ ká rí ojútùú sáwọn ìbéèrè nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́