Ẹ Ní Ìdí fún Ayọ̀ Yíyọ̀
GBOGBO nǹkan tí Ọlọ́run dá ló wà létòlétò. Ì báà jẹ́ àwọn sẹ́ẹ̀lì tín-íntìn-tín ni o tàbí àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ńláńlá tí wọ́n wà ní onírúurú. Kò sì yẹ kí èyí yani lẹ́nu, torí pé Ẹlẹ́dàá ‘kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu.’ (1 Kọ́r. 14:33) Ohun míì tó tún kàmàmà ni ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ṣètò pé ká máa jọ́sìn òun. Ronú lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe. Ó mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀dá olóye tó dá para pọ̀ wà nínú ètò kan ṣoṣo tó ní apá ti òkè ọ̀run àti ti ilẹ̀ ayé, ó fún wọn lómìnira láti yan ohun tí wọ́n fẹ́, gbogbo wọn sì ń sìn ín ní ìṣọ̀kan. Ìyẹn mà ga lọ́lá o!
Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Jerúsálẹ́mù ló dúró fún apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run, ibẹ̀ ni tẹ́ńpìlì Jèhófà wà, ibẹ̀ náà sì ni ọba tí Ọlọ́run fòróró yàn ń gbé. Ọmọ Ísírẹ́lì kan tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí ìlú Bábílónì sọ èrò rẹ̀ nípa ìlú mímọ́ yìí pé: “Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu mi, bí èmi kì yóò bá rántí rẹ, bí èmi kì yóò bá mú kí Jerúsálẹ́mù gòkè ré kọjá olórí ìdí tí mo ní fún ayọ̀ yíyọ̀.”—Sm. 137:6.
Ṣé ojú tí ìwọ náà fi ń wo ètò Ọlọ́run lónìí nìyẹn? Ǹjẹ́ ó máa ń mú kó o láyọ̀ ju ohunkóhun mìíràn lọ? Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ mọ ìtàn apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run àti ipá tó ń kó? Ǹjẹ́ wọ́n mọrírì rẹ̀ pé àwọn wà lára ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (1 Pét. 2:17) O ò ṣe fi àwọn àbá tá a fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í mẹ́nu kàn yìí sílò nínú Ìjọsìn Ìdílé yín kí ìmọrírì tí ìdílé rẹ ní fún ètò Jèhófà lè pọ̀ sí i?
Ròyìn “Àwọn Ọjọ́ Ìgbà Pípẹ́ Sẹ́yìn”
Lọ́dọọdún, gbogbo ìdílé ní Ísírẹ́lì máa ń pé jọ pọ̀ láti ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Nígbà ìfilọ́lẹ̀ àjọyọ̀ náà, Mósè fún àwọn èèyàn náà ní ìtọ́ni pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ọmọ rẹ bá wádìí lọ́wọ́ rẹ nígbà tí ó bá yá, pé, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ nígbà náà, kí ìwọ sọ́ fún un pé, ‘Nípa okun ọwọ́ ni Jèhófà fi mú wa jáde kúrò ní Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.’” (Ẹ́kís. 13:14) Jèhófà kò fẹ́ káwọn èèyàn gbàgbé ìtàn nípa bó ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò. Ó sì dájú pé ọ̀pọ̀ lára àwọn olórí ìdílé ní Ísírẹ́lì tẹ̀ lé àṣẹ tí Mósè pa fún wọn. Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ti kọjá, ọmọ Ísírẹ́lì kan gbàdúrà pé: “Ọlọ́run, etí wa ni a fi gbọ́, àwọn baba ńlá wa alára ti ròyìn fún wa lẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò rẹ ní ọjọ́ wọn, ní àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.”—Sm. 44:1.
Bákan náà, lónìí, ọ̀dọ́ kan lè rí ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ọgọ́rùn-ún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ìtàn “àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.” Báwo lo ṣe lè mú kí àwọn ọmọ rẹ lóye àwọn ìtàn yìí? Àwọn òbí kan máa ń lo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook, àwọn ìtàn ìgbésí ayé tó ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn wa, àtàwọn ìtàn míì nípa àwọn èèyàn Ọlọ́run, tó fi mọ́ àwo DVD wa tuntun tó sọ ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní. Àwọn ìdílé sì tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà àdánwò nípa wíwo àwọn fídíò tó sọ nípa bí wọ́n ṣe ṣenúnibíni sí àwọn ará wa lábẹ́ ìjọba Soviet Union àti lábẹ́ ìjọba Násì ti orílẹ̀-èdè Jámánì. Ẹ máa lo irú àwọn nǹkan báwọ̀nyí nínú Ìjọsìn Ìdílé yín. Ìyẹn máa fún ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ yín lókun bó bá ṣẹlẹ̀ pé ohunkóhun fẹ́ dán ìwà títọ́ wọn wò.
Bẹ́ ẹ bá wulẹ̀ ń ṣàlàyé àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn wọ̀nyí fáwọn ọmọ yín, ó lè tètè sú wọn. Torí náà, ẹ jẹ́ kí wọ́n máa lóhùn sí i. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé kí ọmọ rẹ ọkùnrin yan orílẹ̀-èdè kan tó bá wù ú, kó ṣe ìwádìí ìtàn nípa àwọn èèyàn Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè náà, kó sì sọ àbájáde ìwádìí rẹ̀ fún ìdílé. Bí àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ń fòótọ́ sin Ọlọ́run látọjọ́ tó ti pẹ́ bá wà nínú ìjọ yín, ẹ lè ní kí wọ́n dara pọ mọ́ yín nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé. Bóyá ọmọ yín obìnrin lè fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò, kí wọ́n lè sọ àwọn nǹkan tójú wọ́n ti rí sẹ́yìn. Tàbí kẹ̀, ẹ lè sọ pé kí ọmọ yín ya àwòrán àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó ti wáyé láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run, irú bíi kíkọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì, àpéjọ àgbáyé táwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe tàbí bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò agbóhùnjáde lóde ẹ̀rí láwọn ìgbà kan.
Mọ Bí ‘Olúkúlùkù Ṣe Ń Ṣiṣẹ́ Rẹ̀’
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìjọ Kristẹni wé “gbogbo ẹ̀yà ara [tí ó] wà ní ìṣọ̀kan, tí gbogbo oríkě-ríkě ara wa wà ní ipò wọn, pẹlu iṣan tí ó mú wọn dúró, tí gbogbo wọn sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àyè olukuluku wọn, tí gbogbo ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan fi ń dàgbà, tí ó ń mú kí gbogbo ara rẹ̀ dàgbà nínu ìfẹ́.” (Éfé. 4:16, Ìròhìn Ayọ̀) Bá a bá kọ́ nípa bí ara ẹ̀dá èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́, ó máa mú kí ìmọrírì àti ọ̀wọ̀ tá a ní fún Ẹlẹ́dàá wa pọ̀ sí i. Bákan náà, tá a bá ṣàyẹ̀wò bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé, ẹnu máa yà wá láti rí “ọ̀pọ̀ oríṣiríṣi ọgbọ́n Ọlọ́run.”—Éfé. 3:10.
Jèhófà ṣàlàyé bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ètò rẹ̀, tó fi mọ́ apá tó jẹ́ tòkè ọ̀run lára rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù Kristi ló kọ́kọ́ fún ní ìṣípayá, lẹ́yìn náà ni Jésù “rán áńgẹ́lì rẹ̀ jáde, ó sì gbé e kalẹ̀ nípa àwọn àmì nípasẹ̀ rẹ̀ fún ẹrú rẹ̀ Jòhánù, ẹni tí ó jẹ́rìí.” (Ìṣí. 1:1, 2) Bí Ọlọ́run bá fún wa ní ìṣípayá bí nǹkan ṣe ń lọ nínú apá ti òkè ọ̀run lára ètò rẹ̀, ṣé kò wá ní fẹ́ ká lóye bí ‘olúkúlùkù ṣe ń ṣiṣẹ́’ nínú apá tó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé?
Bí àpẹẹrẹ, bí alábòójútó àyíká bá máa tó bẹ ìjọ yín wò, ẹ ò ṣe jíròrò ojúṣe àti àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ní gẹ́gẹ́ bí ìdílé? Báwo ni wọ́n ṣe ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́? Lára ìbéèrè míì tá a lè gbé yẹ̀ wò ni pé: Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa? Ibo ni ètò Ọlọ́run ti ń rí owó tí wọ́n ń ná? Báwo la ṣe ṣètò Ìgbìmọ̀ Olùdarí, báwo ni ìgbìmọ̀ náà sì ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí?
Bá a bá lóye bí Jèhófà ṣe ṣètò àwọn èèyàn rẹ̀, ó kéré tán ó máa ṣe wá láǹfààní lọ́nà mẹ́ta: A máa ní ìmọrírì tó pọ̀ sí i fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára nítorí tiwa. (1 Tẹs. 5:12, 13) Ó máa mú ká fẹ́ láti kọ́wọ́ ti gbogbo ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà. (Ìṣe 16:4, 5) Ní àkótán, bá a bá ṣe ń rí ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí àwọn tó ń mú ipò iwájú fi ń ṣe àwọn ìpinnu àti ìdí tí wọ́n fi ń ṣètò àwọn nǹkan lọ́nà tí wọ́n ń gbà ṣe é, a óò túbọ̀ máa fọkàn tán wọn.—Héb. 13:7.
“Ẹ Bẹ Àwọn Ilé Gogoro Ibùgbé Rẹ̀ Wò”
“Ẹ rìn yí Síónì ká, kí ẹ sì lọ káàkiri nínú rẹ̀, ẹ ka àwọn ilé gogoro rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ọkàn-àyà yín ṣàníyàn nípa ohun àfiṣe-odi rẹ̀. Ẹ bẹ àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ wò, kí ẹ lè ròyìn rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ fún ìran ẹ̀yìn ọ̀la.” (Sm. 48:12, 13) Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, onísáàmù náà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n wo Jerúsálẹ́mù kínníkínní. Ǹjẹ́ o lè ronú nípa ìrírí mánigbàgbé tí àwọn ìdílé ní Ísírẹ́lì máa ń ní bí wọ́n bá rìnrìn àjò lọ sí ìlú mímọ́ náà fún àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún tí wọ́n sì rí tẹ́ńpìlì àgbàyanu tó wà níbẹ̀? Èyí ti ní láti mú kí wọ́n “ròyìn rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ fún ìran ẹ̀yìn ọ̀la.”
Ronú nípa ayaba Ṣébà, ẹni tó kọ́kọ́ ń ṣiyè méjì nípa àwọn ìròyìn tó gbọ́ nípa ìṣàkóso gíga lọ́la Sólómọ́nì àti ọgbọ́n jíjinlẹ̀ tó ní. Kí ló mú kó dá a lójú pé òótọ́ ni àwọn nǹkan tó gbọ́? Ó sọ pé: “Èmi kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọn títí mo fi wá kí ojú èmi fúnra mi lè rí i.” (2 Kíró. 9:6) Ó dájú pé ohun tá a bá fi ‘ojú tiwa’ fúnra wa rí lè nípa tó jinlẹ̀ lórí wa.
Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ‘ojú tiwọn’ fúnra wọn rí àwọn ohun àgbàyanu tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ètò Jèhófà? Bí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wà nítòsí ilé rẹ, sapá láti ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ibi tí Mandy àti Bethany gbé dàgbà fi nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] kìlómítà, ìyẹn ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ibùsọ̀, jìn sí Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè wọn. Síbẹ̀, àwọn òbí wọn ṣètò kí wọ́n lè máa rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ lemọ́lemọ́, pàápàá jù lọ nígbà táwọn ọmọ wọn obìnrin ti bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà. Wọ́n ṣàlàyé pé: “A kò kọ́kọ́ rò pé ó yẹ ká máa lọ sí Bẹ́tẹ́lì, torí a rò pé àwọn arúgbó nìkan ni ibẹ̀ wà fún. Ṣùgbọ́n a rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára fún Jèhófà tí wọ́n sì ń gbádùn iṣẹ́ wọn! A wá rí i pé ètò Jèhófà gbòòrò ré kọjá agbègbè kékeré tí à ń gbé, ńṣe ni gbogbo ìbẹ̀wò tá à ń ṣe sí Bẹ́tẹ́lì ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó sì ń mú ká túbọ̀ fẹ́ láti máa sìn ín.” Bí Mandy àti Bethany ṣe wo ètò Ọlọ́run kínníkínní yìí mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n sì rí ìkésíni gbà láti lọ ṣe iṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni ní Bẹ́tẹ́lì fún àkókò díẹ̀.
Ọ̀nà mìíràn wà tá a tún lè gbà “rí” ètò Jèhófà, èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì kò ní àǹfààní rẹ̀. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti rí àwọn fídíò àti àwo DVD gbà, èyí tó sọ onírúurú àwọn nǹkan nípa ètò Ọlọ́run, irú bíi: Jehovah’s Witnesses—Organized to Share the Good News, Our Whole Association of Brothers, To the Ends of the Earth àti United by Divine Teaching. Bí ìwọ àti ìdílé rẹ bá rí iṣẹ́ ribiribi tí àwọn òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù, àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn arákùnrin tó ń bójú tó ìṣètò àpéjọ ń gbé ṣe, wàá túbọ̀ ní ìmọrírì àtọkànwá fún ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí ayé.
Ipa pàtàkì ni olúkúlùkù ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run ń kó nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere àti ṣíṣètìlẹyìn fún àwọn Kristẹni tó wà ní àgbègbè wọn. Àmọ́ ṣá o, wá àkókò tí ìwọ àti ìdílé rẹ á fi máa rántí “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará [wa] nínú ayé.” Èyí máa ran ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ‘dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́,’ kẹ́ ẹ sì máa rántí pé ẹ ní ìdí fún ayọ̀ yíyọ̀.—1 Pét. 5:9.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Ohun Pàtàkì Tó Yẹ Ká Mọ̀ Nípa Ètò Ọlọ́run
A ní ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde tó lè ran gbogbo èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa àwọn èèyàn Ọlọ́run àti bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ètò Jèhófà. Àwọn ìbéèrè tó lè ràn yín lọ́wọ́ rèé:
☞ Báwo ni iṣẹ́ táwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ń ṣe lóde òní ṣe bẹ̀rẹ̀?—Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 222 sí 227; Ilé Ìṣọ́, November 15, 1996, ojú ìwé 10 sí 15.
☞ Kí ló jẹ́ mánigbàgbé nípa “Ọjọ́ Àwọn Ọmọdé” ní Àpéjọ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Ọdún 1941?—Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 86 àti 88; Ilé Ìṣọ́ July 15, 2001, ojú ìwé 8.
☞ Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń ṣe àwọn ìpinnu?—“Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 108 sí 114.