Kí Ni Ìsinmi Ọlọ́run?
“Ìsinmi ti sábáàtì kan ṣì kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.”—HEB. 4:9.
1, 2. Kí la lè rí kọ́ nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:3, àwọn ìbéèrè wo la sì máa dáhùn?
NÍNÚ Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run fi ọjọ́ mẹ́fà dá ayé kí èèyàn lè máa gbé inú rẹ̀. Èyí kì í ṣe ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún o; ọjọ́ kọ̀ọ̀kan gùn ju bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ìparí ọjọ́ ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan, Bíbélì sọ pé: “Alẹ́ sì wá wà, òwúrọ̀ sì wá wà.” (Jẹ́n. 1:5, 8, 13, 19, 23, 31) Àmọ́, nígbà tó di ọjọ́ keje, Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti bù kún ọjọ́ keje, ó sì ṣe é ní ọlọ́wọ̀, nítorí pé inú rẹ̀ ni ó ti ń sinmi kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí Ọlọ́run ti dá.”—Jẹ́n. 2:3.
2 Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé gbólóhùn tó sọ nǹkan téèyàn ń ṣe lọ́wọ́ tí kò sì tíì parí rẹ̀ ni Bíbélì lò? Ó sọ pé, Ọlọ́run “ti ń sinmi.” Èyí tó túmọ̀ sí pé nígbà tí Mósè kọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì ní ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ọjọ́ keje tí Bíbélì pè ní “ọjọ́” ìsìnmí Ọlọ́run ṣì ń bá a nìṣó. Títí di báyìí ńkọ́, ṣé ìsinmi Ọlọ́run ṣì ń bá a nìṣó? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ a lè wọnú ìsinmi rẹ̀? Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
Ṣé Jèhófà Ṣì “Ń Sinmi”?
3. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 5:16, 17 ṣe fi hàn pé ọjọ́ keje tí Ọlọ́run fi sinmi ṣì ń bá a nìṣó ní ọ̀rúndún kìíní?
3 Ìdí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà tá a fi lè sọ pé ọjọ́ keje tí Ọlọ́run fi ń sinmi ṣì ń bá a nìṣó ní ọ̀rúndún kìíní. Kọ́kọ́ ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwọn alátakò tó bínú sí i torí pé ó wo ẹnì kan sàn lọ́jọ́ Sábáàtì, tí wọ́n sì kà á sí i lọ́rùn pé iṣẹ́ ló ń ṣe dípò kó máa sinmi. Olúwa sọ fún wọn pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” (Jòh. 5:16, 17) Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Wọ́n ń fi ẹ̀sùn kan Jésù pé ó ń ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ Sábáàtì. Jésù sì dá wọn lóhùn pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” Lédè mìíràn, ohun tí Jésù ń sọ fún àwọn tó ń fẹ̀sùn kàn án ni pé: ‘Irú iṣẹ́ kan náà ni èmi àti Baba mi ń ṣe. Níwọ̀n bí Baba mi sì ti ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́ jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún tó jẹ́ Sábáàtì rẹ̀, kò sí ohun tó burú níbẹ̀ bí èmi náà bá ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́, àní lọ́jọ́ Sábáàtì pàápàá.’ Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé, Sábáàtì ńlá Ọlọ́run, ìyẹn ọjọ́ keje tó fi ń sinmi kúrò nínú ṣíṣẹ̀dá àwọn nǹkan sórí ilẹ̀ ayé, kò tíì parí nígbà tí òun wà láyé.a
4. Kí ni Pọ́ọ̀lù tún sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé ọjọ́ keje ṣì ń bá a nìṣó nígbà tó wà láyé?
4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìdí kejì tó fi hàn pé ọjọ́ keje tí Ọlọ́run fi sinmi ṣì ń bá a nìṣó. Ó lo ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:2 nígbà tó ń ṣàlàyé nípa ìsinmi Ọlọ́run. Ó sọ lábẹ́ ìmísí pé: “Àwa tí a ti lo ìgbàgbọ́ wọnú ìsinmi náà ní tòótọ́.” (Héb. 4:3, 4, 6, 9) Èyí fi hàn pé ọjọ́ keje yẹn ṣì ń bá a nìṣó nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà láyé. Ìgbà wo ni ọjọ́ ìsinmi yẹn máa dópin?
5. Kí ni Jèhófà fẹ́ lo ọjọ́ keje fún, ìgbà wo sì ni ilẹ̀ ayé máa rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí?
5 Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ṣe pàtàkì ká rántí ohun tí Jèhófà fẹ́ lo ọjọ́ keje fún. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 2:3 ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti bù kún ọjọ́ keje, ó sì ṣe é ní ọlọ́wọ̀.” Ọlọ́run ‘ṣe ọjọ́ yẹn ní ọlọ́wọ̀,’ èyí tó túmọ̀ sí pé Jèhófà ya ọjọ́ náà sí mímọ́ tàbí pé ó yà á sọ́tọ̀ kó bàa lè lò ó láti ṣe àṣeparí ohun tó fẹ́ kí ilẹ̀ ayé jẹ́. Kí ni Ọlọ́run fẹ́ kí ilẹ̀ ayé jẹ́? Ó fẹ́ kó jẹ́ ibi tí àwọn ọkùnrin àti obìnrin onígbọràn á máa gbé tí wọ́n á máa bójú tó, tí wọ́n á sì máa tọ́jú gbogbo ohun alààyè tó wà níbẹ̀. (Jẹ́n. 1:28) Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi tó jẹ́ “Olúwa sábáàtì” fi “ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí.” (Mát. 12:8) Ọjọ́ ìsinmi Ọlọ́run á máa bá a nìṣó títí dìgbà tí ilẹ̀ ayé a fi rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi.
Ẹ Má Ṣe “Ṣubú Sínú Àpẹẹrẹ Ọ̀nà Àìgbọràn Kan Náà”
6. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa, kí la sì lè rí kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ náà?
6 Ọlọ́run ṣàlàyé ohun tó fẹ́ fún Ádámù àti Éfà lọ́nà tó ṣe kedere, àmọ́ wọn kò fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, Ádámù àti Éfà ni ẹ̀dá èèyàn tó kọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn mìíràn pẹ̀lú sì ti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Kódà, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, tó jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá, ṣàìgbọràn léraléra. Torí náà, Pọ́ọ̀lù rí i pé ó pọn dandan kí òun kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní pé àwọn kan lára wọn lè di aláìgbọràn bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti wọnú ìsinmi yẹn, kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣubú sínú àpẹẹrẹ ọ̀nà àìgbọràn kan náà.” (Héb. 4:11) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn aláìgbọràn kò lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run. Kí nìyẹn túmọ̀ sí fún wa? Ṣé ohun tó túmọ̀ sí ni pé lọ́nà èyíkéyìí, tá a bá ṣe ohun tó lòdì sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ láti ṣe a kò ní wọnú ìsinmi rẹ̀? Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ìdáhùn ìbéèrè yìí, a sì máa sọ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ búburú táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi lélẹ̀ àti ohun tó kọ́ wa nípa bá a ṣe lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run.
“Dájúdájú, Wọn Kì Yóò Wọnú Ìsinmi Mi”
7. Kí nìdí tí Jèhófà fi dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì, kí ló sì yẹ kí wọ́n ṣe?
7 Ní ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà sọ ohun tó ní lọ́kàn nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ìránṣẹ́ rẹ̀, Mósè. Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, kí n sì mú wọn gòkè wá láti ilẹ̀ yẹn [Íjíbítì] sí ilẹ̀ kan tí ó dára tí ó sì ní àyè gbígbòòrò, sí ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹ́kís. 3:8) Ìdí tí Ọlọ́run fi dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè “kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì” ni pé ó fẹ́ láti sọ wọ́n di èèyàn rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù tó jẹ́ baba ńlá wọn. (Jẹ́n. 22:17) Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àwọn òfin tó máa jẹ́ kí wọ́n lè gbádùn àjọṣe tó tuni lára pẹ̀lú rẹ̀. (Aísá. 48:17, 18) Ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi [bó ṣe wà nínú àkójọ Òfin] mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, nítorí pé, gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi.” (Ẹ́kís. 19:5, 6) Torí náà, ohun tó lè mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ni pé kí wọ́n máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.
8. Báwo ni nǹkan ì bá ṣe rí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ká ní wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run?
8 Ká ní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ìgbésí ayé wọn ì bá mà dùn gan-an ni o! Jèhófà ì bá ti rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí àwọn pápá wọn, ọgbà àjàrà wọn, agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn. Á sì tún máa gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. (Ka 1 Àwọn Ọba 10:23-27.) Nígbà tí Mèsáyà dé, ì bá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan tó wà lómìnira tí nǹkan ń lọ dáadáa fún, tí kò sí lábẹ́ ìṣàkóso rírorò ti Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ì bá ti jẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká, ìyẹn á sì jẹ́ ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé àwọn tó ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run tòótọ́ máa ń rí ìbùkún gbà nípa tara àti nípa tẹ̀mí.
9, 10. (a) Kí nìdí tí kò fi tọ̀nà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fẹ́ láti pa dà lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì? (b) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá pa dà lọ sí Íjíbítì, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ìjọsìn wọn?
9 Àǹfààní tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní kò kéré. Wọ́n ní àǹfààní láti jẹ́ orílẹ̀-èdè tí Jèhófà ì bá lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé ṣẹ. Èyí máa mú kí àwọn, àti lẹ́yìn náà, gbogbo olùgbé ayé rí ìbùkún Ọlọ́run gbà! (Jẹ́n. 22:18) Àmọ́, ìran ọlọ̀tẹ̀ yẹn lápapọ̀ kò mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti jẹ́ orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run ń ṣàkóso kí wọ́n sì jẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Kódà, wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ pa dà sí Íjíbítì! (Ka Númérì 14:2-4.) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá pa dà sí Íjíbítì, báwo ni wọ́n á ṣe lè mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, kí wọ́n sì jẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn? Bí wọ́n bá pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà wọ̀nyẹn, kò sí bí wọ́n ṣe lè mú ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún wọn ṣẹ. Kódà, wọn kò ní lè máa pa Òfin Mósè mọ́, wọn kò sì ní lè jàǹfààní látinú ìṣètò Jèhófà láti mú kí wọ́n rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà. Ó dájú pé wọn kò ronú nípa Ọlọ́run, wọn kò sì ro àròjinlẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú. Ìyẹn ló mú kí Jèhófà sọ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà pé: “Ọ̀ràn ìran yìí sú mi, mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọ́n ń ṣáko lọ nínú ọkàn-àyà wọn, àwọn fúnra wọn kò sì mọ àwọn ọ̀nà mi.’ Nítorí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé, ‘Dájúdájú, wọn kì yóò wọnú ìsinmi mi.’”—Héb. 3:10, 11; Sm. 95:10, 11.
10 Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ya aláìgbọràn yìí ṣe fẹ́ láti pa dà sí Íjíbítì fi hàn pé wọn kò mọyì ìbùkún tẹ̀mí tí wọ́n ti rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ebi ewébẹ̀ líìkì, àlùbọ́sà àti aáyù tí wọ́n ń rí jẹ ní ilẹ̀ Íjíbítì ló ń pa wọ́n. (Núm. 11:5) Ńṣe lọ̀rọ̀ àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà dà bíi ti Ísọ̀ tó jẹ́ aláìmoore. Wọ́n múra tán láti pàdánù ogún wọn ṣíṣeyebíye nípa tẹ̀mí nítorí oúnjẹ aládùn.—Jẹ́n. 25:30-32; Héb. 12:16.
11. Ǹjẹ́ ìwà àìṣòótọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè yí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe pa dà?
11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ya aláìṣòótọ́, Jèhófà ń fi sùúrù “bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́” kó lè tipasẹ̀ ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn wọn ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Àwọn tó jẹ́ ara ìran tuntun yẹn ṣègbọràn sí Ọlọ́run ju àwọn baba wọn lọ. Nígbà tí Jèhófà pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun ilẹ̀ náà. Ìwé Jóṣúà 24:31 sọ nípa wọn pé: “Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ láti sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ ayé àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n wà láàyè lẹ́yìn Jóṣúà, tí wọ́n sì ti mọ gbogbo iṣẹ́ Jèhófà tí ó ṣe fún Ísírẹ́lì.”
12. Báwo la ṣe mọ̀ pé ó ṣeé ṣe láti wọnú ìsinmi Ọlọ́run lónìí?
12 Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìran tó jẹ́ onígbọràn yìí kú tán, ìran mìíràn sì dìde lẹ́yìn wọn tí “kò mọ Jèhófà tàbí iṣẹ́ tí ó ti ṣe fún Ísírẹ́lì.” Nípa bẹ́ẹ̀, “àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣubú sínú ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, wọ́n sì ń sin àwọn Báálì.” (Oníd. 2:10, 11) Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọn kò gbádùn àlàáfíà tó wà pẹ́ títí pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí èyí, Ilẹ̀ Ìlérí náà kò já sí “ibi ìsinmi” fún wọn ní ti gidi. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò tó yàtọ̀ síyẹn, ó sọ pé: “Bí Jóṣúà bá ti mú [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] lọ sí ibi ìsinmi kan, Ọlọ́run lẹ́yìn náà kì bá ti sọ̀rọ̀ ọjọ́ mìíràn. Nítorí náà, ìsinmi ti sábáàtì kan ṣì kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.” (Héb. 4:8, 9) Àwọn Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù pè ní “àwọn ènìyàn Ọlọ́run.” Ṣé ohun tí ìyẹn wá túmọ̀ sí ni pé àwọn Kristẹni lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run? Ó dájú pé ohun tó ń sọ nìyẹn, yálà irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ Júù tàbí wọn kì í ṣe Júù!
Àwọn Kan Kò Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run
13, 14. (a) Nígbà ayé Mósè, kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run? (b) Ní ọ̀rúndún kìíní, ǹjẹ́ ó pọn dandan pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa Òfin Mósè mọ́ kí wọ́n tó lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run?
13 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé àwọn Hébérù kan tó jẹ́ Kristẹni kò fara mọ́ ọ̀nà tí ìfẹ́ Ọlọ́run gbà ń ní ìmúṣẹ, ó kọ̀wé sí wọn. (Ka Hébérù 4:1.) Kí ni wọ́n ṣe tó fi hàn pé wọn kò fara mọ́ ọn? Wọ́n ṣì ń pa díẹ̀ lára àwọn Òfin Mósè mọ́. Òótọ́ ni pé fún nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún, ọ̀nà tí ọmọ Ísírẹ́lì èyíkéyìí fi lè ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu ni pé kó máa pa Òfin Mósè mọ́. Àmọ́, lẹ́yìn ikú Jésù, kò sí ìdí fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Àwọn Kristẹni kan kò gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, torí náà wọ́n ń bá a nìṣó láti máa pa àwọn kan lára Òfin Mósè mọ́.b
14 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé fún àwọn Kristẹni tí wọ́n ṣì ń pa Òfin Mósè mọ́ pé Jésù tó jẹ́ àlùfáà àgbà sàn ju àlùfáà àgbà èyíkéyìí tó jẹ́ aláìpé lọ. Ó jẹ́ kó yé wọn pé májẹ̀mú tuntun sàn ju májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì dá lọ. Ó sì tún fi yé wọn pé tẹ́ńpìlì ńlá ti Jèhófà sàn ju tẹ́ńpìlì tí a fi ọwọ́ ṣe lọ. (Héb. 7:26-28; 8:7-10; 9:11, 12) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí Òfin Mósè ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pa mọ́ ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó ṣàlàyé bí àwọn Kristẹni ṣe lè wọnú ọjọ́ ìsinmi Jèhófà. Ó sọ pé: “Ìsinmi ti sábáàtì kan ṣì kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Nítorí ẹni tí ó ti wọnú ìsinmi Ọlọ́run, òun pẹ̀lú ti sinmi kúrò nínú àwọn iṣẹ́ tirẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe kúrò nínú tirẹ̀.” (Héb. 4:8-10) Àwọn Hébérù tó di Kristẹni wọ̀nyẹn kò tún gbọ́dọ̀ máa ronú pé àwọn lè rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí Òfin Mósè pa láṣẹ. Ìdí ni pé láti ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi ló ń rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run.
15. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onígbọràn tá a bá máa wọnú ìsinmi Ọlọ́run?
15 Kí ló fà á tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gbáyé ní ọjọ́ Mósè kò fi wọ Ilẹ̀ Ìlérí? Ìdí ni pé wọ́n jẹ́ aláìgbọràn. Kí ló fà á tí àwọn Kristẹni kan ní ìgbà ayé Pọ́ọ̀lù kò fi wọnú ìsinmi Ọlọ́run? Àìgbọràn náà ló fà á. Wọn kò gbà pé ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́ kí àwọn èèyàn máa gbà jọ́sìn òun ti yí pa dà àti pé kò fẹ́ káwọn èèyàn máa tẹ̀ lé Òfin Mósè mọ́.
Bá A Ṣe Lè Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run Lónìí
16, 17. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti wọnú ìsinmi Ọlọ́run lónìí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
16 Kò wọ́pọ̀ káwọn Kristẹni lónìí sọ pé ó di dandan káwọn pa Òfin Mósè mọ́ káwọn bàa lè rí ìgbàlà. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ sí àwọn ará Éfésù ṣe kedere. Ó sọ pé: “Nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí, a ti gbà yín là nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; èyí kì í sì í ṣe ní tìtorí tiyín, ẹ̀bùn Ọlọ́run ni. Bẹ́ẹ̀ kọ́, kì í ṣe ní tìtorí àwọn iṣẹ́, kí ènìyàn kankan má bàa ní ìdí fun ṣíṣògo.” (Éfé. 2:8, 9) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo wá ni àwọn Kristẹni ṣe lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run? Jèhófà ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi rẹ̀ kó bàa lè lò ó láti ṣe àṣeparí ohun tó fẹ́ kí ilẹ̀ ayé jẹ́. A lè wọnú ìsinmi Jèhófà tàbí, ká dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ìsinmi rẹ̀, tá a bá jẹ́ onígbọràn tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ fún wa nípa ọ̀nà tí ìfẹ́ rẹ̀ ń gbà ní ìmúṣẹ.
17 Àmọ́ bí a kò bá fi ojú pàtàkì wo ìmọ̀ràn Bíbélì tá à ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye, tá a sì yàn láti máa ṣe ohun tó wù wá, a jẹ́ pé ńṣe là ń ṣe ohun tó lòdì sí ọ̀nà tí ìfẹ́ Ọlọ́run ń gbà ní ìmúṣẹ. Èyí sì lè ba àjọṣe rere tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ipò díẹ̀ kan tó wọ́pọ̀ èyí tó lè dán ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run wò, a sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìpinnu wa yálà láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run tàbí láti máa ṣe ohun tó wù wá ṣe lè fi hàn bóyá òótọ́ la ti wọnú ìsinmi Ọlọ́run.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì ní ọjọ́ Sábáàtì síbẹ̀ ‘wọ́n ń bá a lọ láìjẹ̀bi.’ Ọlọ́run ti yan Jésù ṣe àlùfáà àgbà nínú tẹ́ńpìlì ńlá nípa tẹ̀mí. Torí náà, òun pẹ̀lú lè ṣe iṣẹ́ tẹ̀mí tí Ọlọ́run yàn fún un ní ọjọ́ Sábáàtì láìbẹ̀rù pé òun máa rú òfin Sábáàtì.—Mát. 12:5, 6.
b A kò lè sọ bóyá Júù èyíkéyìí tó di Kristẹni rú ẹbọ ní Ọjọ́ Ètùtù, lẹ́yìn ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Bí a bá rí ẹni tó rú irú ẹbọ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé kò fi ọ̀wọ̀ hàn fún ẹbọ Jésù nìyẹn. Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan tó di Kristẹni ṣì ń tẹ̀ lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kan tó jẹ́ apá kan Òfin Mósè.—Gál. 4:9-11.
Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé Lórí
• Nítorí kí ni Ọlọ́run ṣe ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún ìsinmi?
• Báwo la ṣe mọ̀ pé ọjọ́ keje ṣì ń bá a nìṣó títí di báyìí?
• Kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gbáyé ní ọjọ́ Mósè àtàwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní kò fi wọnú ìsinmi Ọlọ́run?
• Báwo la ṣe lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run lónìí?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
A lè wọnú ìsinmi Jèhófà lónìí tá a bá jẹ́ onígbọràn tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ fún wa nípa ọ̀nà tí ìfẹ́ rẹ̀ ń gbà ní ìmúṣẹ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Kí ló ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣe bí wọ́n bá fẹ́ wọnú ìsinmi Ọlọ́run?