Ṣé Dandan Ni Kéèyàn Máa San Owó Orí?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ni kò nífẹ̀ẹ́ sí sísan owó orí. Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé, ńṣe làwọn ń fi owó orí táwọn ń san ṣòfò, nítorí pé wọn kì í lo owó náà lọ́nà tó dáa, ńṣe ni wọ́n ń ná an síbi tí kò tọ́ tàbí kí wọ́n kó owó náà jẹ. Àwọn kan kì í san owó orí nítorí pé ohun tí kò tọ́ ni àwọn tó ń gbà á ń fi ṣe. Àwọn tó ń gbé ìlú kan ní Àárín Ìlà Oòrùn ayé ṣàlàyé ìdí tí wọn kò fi sán owó orí, wọ́n ní: “A kò ní máa san owó ọta ìbọn tó ń pa àwọn ọmọ wa.”
Irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ kì í ṣe tuntun. Olóògbé Mohandas K. Gandhi tó jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn Híńdù sọ ìdí tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò fi gbà á láyè láti sanwó orí, ó ní: “Ọkùnrin tàbí obìnrin tó bá ń ti Ìjọba ológun lẹ́yìn, bóyá ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà, ti dẹ́ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ ló jẹ́ tí ọmọdé tàbí àgbà bá dá sí àbójútó irú Ìjọba náà nípa sísan owó orí.”
Bákan náà, onímọ̀ ọgbọ́n orí ọgọ́rùn-un ọdún kọkàndínlógún tó ń jẹ́ Henry David Thoreau sọ ìdí tí òun kò fi ń san owó orí tí wọ́n fi ń ti ogun lẹ́yìn. Ó béèrè pé: “Ṣé ó yẹ kí àwọn ará ìlú gba àwọn aṣòfin láyè láti ṣèpinnu tó yẹ kí àwọn ará ìlú ṣe nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn? Kí wá nìdí tí gbogbo èèyàn fi ní ẹ̀rí ọkàn?”
Ọ̀rọ̀ yìí kan àwọn Kristẹni, nítorí Bíbélì sọ kedere pé, ó yẹ kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ nínú ohun gbogbo. (2 Tímótì 1:3) Bákan náà, Bíbélì tún sọ pé àwọn aláṣẹ Ìjọba lẹ́tọ̀ọ́ láti gba owó orí. Ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga [ìjọba èèyàn], nítorí kò sí ọlá àṣẹ kankan bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, ìdí tí ń múni lọ́ranyàn wà fún yín láti wà lábẹ́ àṣẹ, kì í ṣe ní tìtorí ìrunú yẹn nìkan, ṣùgbọ́n ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn yín pẹ̀lú. Nítorí ìdí nìyẹn tí ẹ fi ń san owó orí pẹ̀lú; nítorí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run sí gbogbo ènìyàn ní sísìn nígbà gbogbo fún ète yìí gan-an. Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí.”—Róòmù 13:1, 5-7.
Nítorí ìdí yìí, àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní la mọ̀ sí àwọn tó ń sanwó orí déédéé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye tó pọ̀ lára owó náà ni ìjọba fi ń ti iṣẹ́ ogun lẹ́yìn. Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní máa ń san owó orí wọn déédéé.a Kí nìdí táwọn Kristẹni fi ń sanwó orí nígbà tí wọ́n mọ̀ pé ìjọba á fi owó náà ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn? Ṣé ó yẹ kí Kristẹni kan pa ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tì nígbà tó bá fẹ́ san owó orí?
Bí Ọ̀ràn Owó Orí Ṣe Kan Ẹ̀rí Ọkàn
Ara owó orí táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ń san ló ń bá iṣẹ́ ológun lọ. Ọ̀ràn yìí sì kan ẹ̀rí ọkàn, ìyẹn ló mú kí Gandhi àti Thoreau kọ̀ láti san owó orí nígbà tó yá.
Kíyè sí i pé kì í ṣe nítorí pé kí àwọn Kristẹni má bàa jìyà nìkan ni wọ́n fi ṣègbọràn sí àṣẹ tó wà ní Róòmù orí 13, àmọ́ ó tún jẹ́ ní tìtorí “ẹ̀rí-ọkàn [wọn].” (Róòmù 13:5) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀rí ọkàn Kristẹni kan ní láti tọ́ ọ sọ́nà pé, ó yẹ kó san owó orí, wọn ì bá tiẹ̀ fi owó náà ṣe ohun tí Kristẹni náà kò fẹ́. Tá a bá fẹ́ lóye àwọn nǹkan tó jọ pé ó ta kora yìí, a gbọ́dọ̀ mọ òtítọ́ pàtàkì kan nípa ẹ̀rí ọkàn wa, ìyẹn ohùn inú wa lọ́hùn-ún tó ń jẹ́ ká mọ̀ bóyá ohun tí a ṣe tọ́ tàbí kò tọ́.
Gbogbo wa la ní ohùn inú lọ́hùn-ún tí Thoreau sọ, àmọ́ kò fí bẹ́ẹ̀ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Kí á bàa lè wu Ọlọ́run, ẹ̀rí ọkàn wa gbọ́dọ̀ bá àwọn ìlànà ìwà rere tó gbé kálẹ̀ mu. Ìgbà gbogbo ló yẹ kí á máa tọ́ èrò wa sọ́nà kó lè bá ti Ọlọ́run mu nítorí pé èrò rẹ̀ ga ju tiwa lọ fíìfíì. (Sáàmù 19:7) Nítorí náà, ó yẹ ká sapá láti lóye ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìjọba táwọn èèyàn gbé kalẹ̀. Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wò wọ́n?
A kíyè sí i pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe ìjọba táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ ní “ìránṣẹ́ Ọlọ́run sí gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 13:6) Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé wọ́n ń mú kí nǹkan wà létòlétò ní ìlú, wọ́n sì ń ṣe àwọn nǹkan tó wúlò fún àwọn èèyàn. Àwọn ìjọba tó jẹ́ oníwà ìbàjẹ́ pàápàá máa ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa kó lẹ́tà lọ síbi tó yẹ, wọ́n máa ń ṣètò ẹ̀kọ́ ìwé, iṣẹ́ panápaná àti àwọn agbófinró. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ń rí kùdìẹ̀-kudiẹ tí àwọn aláṣẹ yìí ní, ó fàyè gbà wọ́n pé kí wọ́n máa wà fún àkókò kan, ó sì pàṣẹ pé kí á máa san owó orí, nítorí ọ̀wọ̀ tí a ní fún ìṣètò òun, ìyẹn bó ṣe gba àwọn ìjọba yìí láyè láti máa ṣàkóso aráyé.
Àmọ́ ṣá o, ìgbà díẹ̀ ni Ọlọ́run fi máa gba ìjọba èèyàn láyè. Ìfẹ́ rẹ̀ ni láti fi Ìjọba rẹ̀ ọ̀run rọ́pò wọn kí ó sì ṣe àtúnṣe sí gbogbo ìpalára tí ìṣàkóso èèyàn ti ṣe fún aráyé láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún wá. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Àmọ́ kí Ìjọba yẹn tó dé, Ọlọ́run kò fẹ́ kí àwọn Kristẹni máa ṣàìgbọràn sí àṣẹ ìjọba, bóyá nípa ṣíṣàì san owó orí tàbí láwọn ọ̀nà míì.
Bíi ti Gandhi, tó o bá ṣì ń lérò pé bí wọ́n ṣe ń fi owó orí tó ò ń san ti ogun lẹ́yìn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńkọ́? Bí a bá fẹ́ rí ohun tó wà ní àgbègbè kan dáadáa ńṣe la máa gun orí òkè tó ga, bákan náà ni a lè mú èrò wa bá ti Ọlọ́run mu nípa ríronú lórí bí èrò rẹ̀ ṣe ga ju tiwa lọ fíìfíì. Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ pé: “Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.”—Aísáyà 55:8, 9.
Ǹjẹ́ Àṣẹ Wọn Ní Ààlà?
Ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa sísan owó orí kò túmọ̀ sí pé àṣẹ àwọn ìjọba lórí àwọn èèyàn kò ní ààlà. Jésù kọ́ni pé àṣẹ tí ó ní ààlà ni Ọlọ́run yọ̀ǹda fún àwọn ìjọba wọ̀nyí. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jésù bóyá ó tọ́ lójú Ọlọ́run láti máa san owó orí fún ìjọba Róòmù tó ń ṣàkóso nígbà yẹn, Jésù sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Máàkù 12:13-17.
“Késárì” ni ìjọba, àwọn ló máa ń tẹ owó, àwọn ló sì máa sọ ibi tí agbára rẹ̀ mọ. Nítorí náà, lójú Ọlọ́run, wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé kí á san owó orí láti fi dí àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ṣe. Síbẹ̀, Jésù fi hàn pé, ìgbésí ayé wa àti ìjọsìn wa tó jẹ́ “ohun ti Ọlọ́run,” ni a kò gbọ́dọ̀ fi fún àjọ táwọn èèyàn dá sílẹ̀. Nígbà tí òfin èèyàn bá forí gbárí pẹ̀lú ti Ọlọ́run, àwọn Kristẹni “gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.
Inú àwọn Kristẹni òde òní lè má dùn nítorí ọ̀nà tí àwọn ìjọba ń gbà ná lára owó orí tí wọ́n ń san, àmọ́ wọn kì í tojú bọ ọ̀ràn ìjọba tàbí mú ìjọba lọ́ràn-an-yàn láti ṣe nǹkan nípa gbígbó ìjọba lẹ́nu tàbí kí wọ́n sọ pé àwọn kò ní san owó orí. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé wọn kò nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ohun tí Ọlọ́run máa lò láti fi yanjú ìṣòro aráyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń fi sùúrù dúró de àkókò tí Ọlọ́run máa yanjú ọ̀ràn aráyé nípasẹ̀ ìṣàkóso Jésù Ọmọ rẹ̀, ẹni tó sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”—Jòhánù 18:36.
Jàǹfààní Látinú Ẹ̀kọ́ Bíbélì
O lè jàǹfààní tó pọ̀ tó o bá ń ṣe ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa sísan owó orí. O kò ní jìyà tó wà fún àwọn arúfin, o ò sì ní máa bẹ̀rù bóyá ọwọ́ àwọn aláṣẹ á tẹ̀ ọ́. (Róòmù 13:3-5) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé wàá ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lójú Ọlọ́run, bó o sì ṣe ń pa òfin ìlú mọ́, wàá tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún Ọlọ́run. O lè máà ní owó lọ́wọ́ bíi ti àwọn tí kì í san owó orí tàbí àwọn tí kì í san iye owó orí tó yẹ kí wọ́n san, àmọ́ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí Ọlọ́run pé òun á bójú tó àwọn ìránṣẹ́ òun olóòótọ́. Dáfídì tóun náà jẹ́ ara àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “ Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.”—Sáàmù 37:25.
Lékè gbogbo rẹ̀, tó o bá mọ ìdí tí Bíbélì fi pàṣẹ pé ká máa san owó orí, tó o sì ń tẹ̀ lé àṣẹ náà, ọkàn rẹ á balẹ̀.Ọlọ́run kò ní dá ẹ lẹ́bi lórí ohun tí ìjọba bá fi owó orí tí wọ́n gbà lọ́wọ́ rẹ ṣe, bí òfin kì í ṣe dá ayálégbé lẹ́bi lórí ohun tí onílé fi owó ilé tó gbà lọ́wọ́ rẹ̀ ṣe. Kí ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Stelvio tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Bíbélì, ọ̀pọ̀ ọdún ló fi wá àyípadà sí ọ̀ràn òṣèlú ní gúúsù Yúróòpù. Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí tí òun fi jáwọ́ nínú gbogbo akitiyan yẹn, ó sọ pé: “Mo ní láti gbà pé èèyàn kò lè mú ìdájọ́ òdodo, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà kárí ayé. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè mú àwùjọ èèyàn tó yàtọ̀ tó sì dára jù wá.”
Bíi ti Stelvio, tó o bá ‘san ohun ti Ọlọ́run pa dà fún Ọlọ́run’ tinútinú, ọkàn tìrẹ náà yóò balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ìwọ yóò wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìṣàkóso òdodo wá sí gbogbo ayé, wàá sì rí i nígbà tó bá mú gbogbo ìpalára àti àìṣẹ̀tọ́ ti ìṣàkóso èèyàn kúrò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa àkọsílẹ̀ tó fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń san owó orí, ka Ilé Ìṣọ́, November 1, 2002, ojú ìwé 13, ìpínrọ̀ 15 àti ti May 1, 1996, ojú ìwé 17, ìpínrọ̀ 7.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
Ó yẹ kí á máa tọ́ èrò inú wa sọ́nà kó lè bá ti Ọlọ́run mu nítorí pé èrò rẹ̀ ga ju tiwa lọ fíìfíì
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]
Bí àwọn Kristẹni ti ń ṣègbọràn nípa sísan owó orí, ìyẹn ń jẹ́ kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn rere lójú Ọlọ́run ó sì ń fi hàn pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó máa pèsè ohun tí àwọn nílò
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]
“Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run”
[Credit Line]
Gbogbo ẹ̀tọ́ jẹ́ ti British Museum