Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́ Ti Fún Mi Lókun
Gẹ́gẹ́ bí Marceau Leroy ṣe sọ ọ́
“NÍ ÌBẸ̀RẸ̀PẸ̀PẸ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Èmi nìkan ni mo wà nínú yàrá mi nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka gbólóhùn yìí. Kí nìdí tí mo fi kà á ní ìkọ̀kọ̀? Ìdí ni pé aláìgbọlọ́rungbọ́ paraku ni bàbá mi, ó sì dá mi lójú pé inú rẹ̀ kò ní dùn sí i tó bá rí ìwé tó wà lọ́wọ́ mi, ìyẹn Bíbélì.
Torí pé mi ò ka Bíbélì rí, àwọn ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì yẹn wọ̀ mí lákínyẹmí ara. Mo ronú pé, ‘Bí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ìṣọ̀kan sábà máa ń yà mí lẹ́nu, àmọ́ mo ti wá rí ohun tó fà á báyìí!’ Bíbélì kíkà náà gbà mí lọ́kàn débi pé mo kà á láti aago mẹ́jọ alẹ́ títí di aago mẹ́rin òru. Bí kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ ṣe di ohun tó mọ́ mi lára nìyẹn o. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí kíka Bíbélì ṣe ń fún mi lókun nínú ìgbésí ayé mi.
“Àfi Kó O Máa Kà Á Lójoojúmọ́”
Ọdún 1926 ni wọ́n bí mi, ní Vermelles, ìyẹn abúlé tí wọ́n ti ń wa èédú ní àríwá orílẹ̀-èdè Faransé. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́, èédú ṣe pàtàkì gan-an fún ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè náà. Torí pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń wa èédú, wọn kò mú mi wọ iṣẹ́ ológun. Síbẹ̀, torí pé mo fẹ́ mú kí ìgbésí ayé mi sunwọ̀n sí i, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ nípa rédíò àti iná mànàmáná, èyí tó jẹ́ kí ọ̀nà táwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá gbà ń ṣiṣẹ́ ní ìṣọ̀kan túbọ̀ wọ̀ mí lọ́kàn. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] ni mí nígbà tí ọmọ kíláàsì mi kan fún mi ní Bíbélì tí mo kọ́kọ́ ní. Ó sọ pé: “Ó yẹ kó o ka ìwé yìí.” Nígbà tí mo kà á tán, ó dá mi lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, ó sì jẹ́ ìwé tó ṣí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn payá fún aráyé.
Mo rò pé ó máa wu àwọn aládùúgbò mi pẹ̀lú láti ka Bíbélì torí náà mo gba ẹ̀dà mẹ́jọ. Ó yà mí lẹ́nu pé ńṣe ni wọ́n fi mí ṣẹ̀sín tí wọ́n sì ta kò mí. Àwọn ìbátan mi tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kìlọ̀ fún mi pé, “Ohun tó bá ti mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé yìí, àfi kó o máa kà á lójoojúmọ́!” Mo sì kà á lóòótọ́, àmọ́ mi ò kábàámọ̀ rí pé mo ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ti wa di ohun tó mọ́ mi lára.
Nígbà tí àwọn aládùúgbò mi kan kíyè sí i pé mo nífẹ̀ẹ́ láti máa ka Bíbélì, wọ́n fún mi ní àwọn ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lọ́wọ́ wọn. Ìwé kékeré bí One World, One Governmenta (àwòrán ti èdè Faransé la fi hàn lójú ìwé yìí) ṣàlàyé ìdí tí Bíbélì fi sọ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló máa yanjú ìṣòro aráyé. (Mát. 6:10) Èyí túbọ̀ mú kí n pinnu pé mi ò ní yéé sọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fáwọn ẹlòmíì.
Ọ̀kan lára àwọn tó kọ́kọ́ gba Bíbélì lọ́wọ́ mi ni Noël, ọ̀rẹ́ mi kan tá a jọ gbé ibì kan náà dàgbà. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni Noël torí náà ó ṣètò pé ká lọ bá ọkùnrin kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti di àlùfáà. Ẹ̀rù bà mí, àmọ́ mo mọ̀ látinú ohun tí mo ti kà nínú ìwé Sáàmù 115:4-8 àti Mátíù 23:9, 10 pé Ọlọ́run kò fàyè gba lílo ère nínú ìjọsìn àti fífi orúkọ oyè pe àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì. Èyí ló jẹ́ kí n lè fìgboyà gbèjà ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà gbọ́. Ìwàásù yẹn mú kí Noël gba òtítọ́, adúróṣinṣin sì ni títí dòní.
Mo tún lọ kí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin. Ọkọ rẹ̀ ní àwọn ìwé tó dá lórí ìbẹ́mìílò, àwọn ẹ̀mí èṣù sì ń yọ ọ́ lẹ́nu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọ́kọ́ dà bíi pé mi ò lágbára, àwọn ẹsẹ Bíbélì bíi Hébérù 1:14 mú kó dá mi lójú pé àwọn áńgẹ́lì Jèhófà ń tì mí lẹ́yìn. Nígbà tí ọkọ ẹ̀gbọ́n mi fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò tó sì kó gbogbo nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ awo dà nù, àwọn ẹ̀mí èṣù kò dà á láàmú mọ́. Òun àti ẹ̀gbọ́n mi di Ẹlẹ́rìí tó ń fìtara wàásù.
Ní ọdún 1947 Arthur Emiot, ará Amẹ́ríkà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, wá sí ilé mi. Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi sọ fún un pé kó sọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń pàdé fún mi. Ó sọ fún mi pé àwùjọ kan wà ní ìlú Liévin, tó fi nǹkan bíi kìlómítà mẹ́wàá jìnnà síbi tí mò ń gbé. Ó ṣòro nígbà yẹn láti rí kẹ̀kẹ́ gùn, torí náà fún oṣù mélòó kan ńṣe ni mò ń fẹsẹ̀ rìn lọ sí ìpàdé tí màá sì tún fẹsẹ̀ rìn pa dà sílé. Ìjọba ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé fún ọdún mẹ́jọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn kò ju ẹgbẹ̀rún méjì ó lé okòó dín nírínwó [2,380], àwọn tó ti orílẹ̀-èdè Poland wá ló sì pọ̀ jù nínú wọn. Àmọ́ ní September 1, ọdún 1947, wọ́n fàyè gba iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin lẹ́ẹ̀kan sí i lórílẹ̀-èdè Faransé. A ṣí ẹ̀ka ọ́fíìsì kan sí ìlú Paris ní Villa Guibert. Torí pé kò sí aṣáájú-ọ̀nà kankan ní orílẹ̀-èdè Faransé, Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ń jẹ́ Informant nígbà yẹn, polongo pé a nílò àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé táá máa ròyìn àádọ́jọ [150] wákàtí lóṣù. (Ní ọdún 1949 wọ́n dín in kù sí ọgọ́rùn-ún wákàtí.) Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù 17:17, mo rí i pé “òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run],” èyí mú kí n ṣe ìrìbọmi ní ọdún 1948, mo sì di aṣáájú-ọ̀nà ní December ọdún 1949.
Mo Pa Dà sí Ìlú Dunkerque Láti Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
Mi ò pẹ́ púpọ̀ ní ìlú Agen tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Faransé níbi tí mo ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn mi. Torí pé mi ò ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wa èédú mọ́, ìjọba lómìnira láti mú mi wọ iṣẹ́ ológun. Níwọ̀n bí mo sì ti kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, ìjọba sọ mí sẹ́wọ̀n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò gbà kí n ní Bíbélì lọ́wọ́, mo rí ojú ìwé mélòó kan gbà lára ìwé Sáàmù. Kíka àwọn ìwé náà fún mi ní ìṣírí. Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ìpinnu pàtàkì kan wà tí mo ní láti ṣe. Ìpinnu náà ni pé, Ṣé kí n dá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún dúró, kí n bàa lè ní ìdílé tèmi? Ohun tí mo kà nínú Bíbélì ló tún ràn mí lọ́wọ́ láti pinnu ohun tí màá ṣe. Mo ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Fílípì 4:11-13 pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” Mo pinnu láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nìṣó. Lọ́dún 1950, wọ́n ní kí n lọ máa sìn ní ibòmíràn, ìyẹn ní ìlú Dunkerque tí mo ti wàásù nígbà kan rí.
Nígbà tí mo débẹ̀, mi ò ní ohunkóhun. Ogun Àgbáyé Kejì ti ba gbogbo ìlú náà jẹ́, ó sì ṣòro láti rí ibùgbé. Mo pinnu láti lọ kí ìdílé kan tí mo máa ń lọ wàásù fún nígbà yẹn. Ìyàwó ni mo bá nílé, inú rẹ̀ sì dùn gan-an. Ó sọ pé: “Ọ̀gbẹ́ni Leroy wọ́n ti dá a yín sílẹ̀! Ọkọ mi sọ pé bí ọ̀pọ̀ ọkùnrin bá rí bíi tiyín, kò ní sí ogun rárá.” Wọ́n ní ilé kan tí wọ́n máa ń fi háyà, torí náà wọ́n ní kí n máa gbé ibẹ̀ títí di àkókò tí àwọn arìnrìn àjò sábà máa ń wá gba ibẹ̀. Ní ọjọ́ yẹn kan náà, ẹ̀gbọ́n Arthur Emiot ọkùnrin, tó ń jẹ́ Evans fi iṣẹ́ kan lọ̀ mí.b Ó ń ṣe ògbufọ̀ ní èbúté ọkọ̀ ojú omi, ó sì ń wá ọlọ́dẹ táá máa ṣọ́ ọkọ̀ ojú omi kan. Ó mú mi lọ bá ọ̀kan lára àwọn ọ̀gákọ̀ ọkọ̀ ojú omi náà. Àmọ́, torí pé nígbà tí mo jáde lẹ́wọ̀n, ńṣe ni mo rù gan-an, Evans ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi. Ọ̀gákọ̀ náà sì sọ pé kí n lọ mú oúnjẹ tí mo bá fẹ́ nínú fìríìjì. Ní ọjọ́ kan ṣoṣo yẹn, mo rí ibùgbé, iṣẹ́ àti oúnjẹ! Èyí mú kí n túbọ̀ ní ìgbọ́kànlé nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:25-33.
Nígbà tí àwọn arìnrìn-àjò dé, èmi àti Simon Apolinarski, tá a jọ ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà wá ibùgbé mìíràn, àmọ́ a pinnu pé a ò ní fi ìpínlẹ̀ ìwàásù wa sílẹ̀. Wọ́n ní ká wá máa gbé níbi tí wọ́n ń fi àwọn ẹṣin wọ̀ sí, a máa ń kó koríko tó wà níbẹ̀ jọ a ó sì sùn lé e lórí. A máa ń wàásù láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. A wàásù fún ẹni tó ni ibi tí wọ́n ń fi àwọn ẹṣin wọ̀ sí náà, ó sì di ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ èèyàn tó gba òtítọ́ ní ìlú náà. Kò pẹ́ tí àpilẹ̀kọ kan fi jáde nínú ìwé ìròyìn ìlú Dunkerque tó ń kìlọ̀ fún àwọn tó ń gbé ìlú yẹn pé “àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ya wọ àgbègbè náà, wọ́n sì ń tan ẹ̀kọ́ wọn kálẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, èmi, Simon àti àwọn akéde mélòó kan ni kìkì Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú yẹn! Bí ìṣòro bá dojú kọ wá, ṣíṣàṣàrò lórí ìrètí táwa Kristẹni ní àti ríronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà tọ́jú wa ló máa ń fún wa níṣìírí. Nǹkan bí ọgbọ̀n [30] akéde ló ń ròyìn déédéé ní ìlú Dunkerque nígbà tí ìpínlẹ̀ ìwàásù mi yí pa dà ní ọdún 1952.
Mo Gbára Dì fún Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Mìíràn
Lẹ́yìn tí mo ti gbé fún ìgbà díẹ̀ ní ìlú Amiens, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì ní kí n lọ wàásù ní ìlú Boulogne-Billancourt, tó wà ní ìgbèríko Paris. Mo ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀, nígbà tó yá àwọn kan nínú wọn gba iṣẹ́ alákòókò kíkún, àwọn kan sì di míṣọ́nnárì. Ọ̀dọ́kùnrin kan, Guy Mabilat, gba òtítọ́ ó sì tẹ̀ síwájú débi pé ó sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká àti lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè. Nígbà tó yá, ó ṣe àbójútó iṣẹ́ kíkọ́ ilé ìtẹ̀wé tó wà ní Bẹ́tẹ́lì lónìí ní ìlú Louviers, tó jìnnà díẹ̀ sí ìlú Paris. Bí mo ṣe ń jíròrò Bíbélì déédéé lóde ẹ̀rí túbọ̀ tẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ mi lọ́kàn, ó ti mú kí n láyọ̀ gan-an kí n sì mú bí mo ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i.
Lẹ́yìn náà lọ́dún 1953, láìròtẹ́lẹ̀ wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, mo sìn ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Alsace-Lorraine, tó jẹ́ pé láàárín ọdún 1871 sí 1945, ìgbà méjì ni orílẹ̀-èdè Jámánì gbà á. Torí náà, mo ní láti kọ́ èdè Jámánì. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àyíká, kò fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, tẹlifíṣọ̀n, tàbí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ní ẹkùn ìpínlẹ̀ yẹn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí rédíò tàbí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà. Síbẹ̀, ìyẹn kò ní kí inú mi máa bà jẹ́ tàbí kí n máa ṣẹ́ ara mi níṣẹ̀ẹ́. Ká sòótọ́, mo láyọ̀ gan-an nígbà yẹn. Ní tèmi, àìsí àwọn nǹkan tó lè pín ọkàn ẹni níyà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bó ṣe rí lónìí mú kó rọrùn fún mi láti jẹ́ kí ‘ojú mi mú ọ̀nà kan.’—Mát. 6:19-22.
Àpéjọ “Ijọba Alayọ Iṣẹgun” tá a ṣe ní ìlú Paris ní ọdún 1955 jẹ́ mánigbàgbé fún mi. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé ẹni tí mo máa fẹ́, ìyẹn Irène Kolanski tó fi ọdún kan jù mí lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Poland ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí onítara fún ọ̀pọ̀ ọdún. Adolf Weber bẹ̀ wọ́n wò nígbà tí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè Faransé. Adolf ti fìgbà kan rí ṣe iṣẹ́ olùtọ́jú ọgbà fún Arákùnrin Russell, ó sì wá sí ilẹ̀ Yúróòpù láti wàásù ìhìn rere. Mo fẹ́ Irène lọ́dún 1956, ó sì dara pọ̀ mọ́ mi lẹ́nu iṣẹ́ àyíká. Ó ti jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún mi láti àwọn ọdún yìí wá!
Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, ohun kan tún ṣẹlẹ̀ tó yà mí lẹ́nu, a yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè. Síbẹ̀, nítorí pé àwọn arákùnrin tó lè ṣiṣẹ́ àyíká kò pọ̀ tó, mo ṣì ń bẹ àwọn ìjọ kan wò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Ọwọ́ mi dí gan-an nígbà yẹn! Ní àfikún sí lílo ọgọ́rùn-ún [100] wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣù, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ mo ní láti sọ àwọn àsọyé, kí n bẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ mẹ́ta wò, kí n yẹ àwọn àkọsílẹ̀ ìjọ wò, kí n sì tún kọ ìròyìn ránṣẹ́ sí ọ́fíìsì. Báwo ni màá ṣe ra àkókò pa dà kí n lè máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ohun kan ṣoṣo tí mo rí i pé mo lè ṣe ni pé kí n gé àwọn ojú ìwé mélòó kan lára Bíbélì ògbólógbòó kan kí n sì máa mú wọn kiri. Ìgbàkigbà tí mo bá ń dúró de ẹnì kan, màá yọ àwọn ojú ìwé Bíbélì náà jáde màá sì kà á. Àwọn àkókò ṣókí tí ń tuni lára nípa tẹ̀mí wọ̀nyẹn ló mú kí n lè máa bá a lọ lẹ́nu iṣẹ́ tá a yàn fún mi.
Ní ọdún 1967, wọ́n pe èmi àti Irène láti wá máa sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ìlú Boulogne-Billancourt. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, ó sì ti lé ní ogójì [40] ọdún báyìí tí mo ti ń gbádùn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn. Apá kan tó máa ń dùn mọ́ mi lára iṣẹ́ mi ní fífèsì sí àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi béèrè àwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì. Inú mi máa ń dùn gan-an láti walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti láti ‘gbèjà ìhìn rere!’ (Fílí. 1:7) Ó tún jẹ́ ayọ̀ mi láti máa bójú tó ìjíròrò Bíbélì nígbà ìjọsìn òwúrọ̀ tá a máa ń ṣe ká tó jẹ oúnjẹ àárọ̀. Ní ọdún 1976, wọ́n yàn mí láti di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní orílẹ̀-èdè Faransé.
Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àwọn àkókò tí nǹkan ṣòro fún mi, àkókò tó nira jù lọ fún mi ni ìsinsìnyí tí ọjọ́ ogbó ti dé, tí àìlera sì dín ohun tí èmi àti Irène lè ṣe kù. Síbẹ̀, kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀ àti jíjíròrò rẹ̀ ń sọ ìrètí tá a ní dọ̀tun. A máa ń gbádùn wíwọkọ̀ lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wa láti lọ sọ ìrètí tá a ní yìí fáwọn ẹlòmíì. Àpapọ̀ ìrírí táwa méjèèjì ti ní fún ohun tó lé ní ọgọ́fà [120] ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ń mú ká fi tọkàntọkàn dámọ̀ràn ọ̀nà ìgbésí ayé yìí kan náà fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ láti ní ìgbésí ayé tó gbádùn mọ́ni, tó kún fún ayọ̀, tó sì ṣàǹfààní. Nígbà tí Dáfídì Ọba kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Sáàmù 37:25, òun náà ti “darúgbó,” bíi tirẹ̀ èmi náà, “kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá.”
Ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, Jèhófà ti fún mi lókun nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ní nǹkan tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn àwọn ìbátan mi ti sọ fún mi tẹ́lẹ̀ pé kíka Bíbélì máa di ohun tí màá máa ṣe lójoojúmọ́. Ọ̀rọ̀ wọ́n tọ̀nà. Ó ti mọ́ mi lára láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, mi ò sì kábàámọ̀ rẹ̀ rí!
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ṣe é ní ọdún 1944, àmọ́ a kò tẹ̀ ẹ́ mọ́.
b Bó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa Evans Emiot wo Ilé Ìṣọ́, January 1, 1999, ojú ìwé 22 àti 23.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Èmi àti Simon rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Irú Bíbélì tí mo kọ́kọ́ rí gbà rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìgbà tí mò ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ọjọ́ tá a ṣègbéyàwó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń gbádùn mọ́ èmi àti Irène