Jèhófà Ń fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Wa Ká Lè Rí Ìgbàlà
“Agbára Ọlọ́run ń fi ìṣọ́ ṣọ́ [yín] nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ fún ìgbàlà kan tí a múra tán láti ṣí payá ní sáà àkókò ìkẹyìn.”—1 PÉT. 1:4, 5.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
Báwo ni Jèhófà ṣe fà wá wá sínú ìjọsìn tòótọ́?
Báwo la ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà máa fi ìbáwí rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà?
Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa ní ìṣírí?
1, 2. (a) Kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa ìwà títọ́ wa mọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe mọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa dáradára tó?
“ẸNI tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mát. 24:13) Jésù lo ọ̀rọ̀ yìí kó lè jẹ́ kó ṣe kedere sí wa pé tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run pa wá mọ́ nígbà tó bá mú ìdájọ́ wá sórí ayé Sátánì, a gbọ́dọ̀ pa ìwà títọ́ wa mọ́ títí dé òpin. Àmọ́ èyí kò túmọ̀ sí pé Jèhófà retí pé ká fi ọgbọ́n wa àti okun wa fara dà á. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” (1 Kọ́r. 10:13) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí?
2 Kí Jèhófà lè rí i dájú pé a kò rí ìdánwò tó kọjá ohun tí a lè mú mọ́ra, ó gbọ́dọ̀ mọ gbogbo nǹkan nípa wa, tó fi mọ́ àwọn ìṣòro tá à ń dojú kọ, irú ẹni tá a jẹ́ àti bá a ṣe lè mú nǹkan mọ́ra tó. Ṣé òótọ́ ni pé gbogbo ohun tá a sọ yìí ni Ọlọ́run mọ̀ nípa wa? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà mọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa dunjú. Ó mọ gbogbo ohun tí à ń ṣe lójoojúmọ́. Kódà, ó lè fi òye mọ èrò inú wa àti ìpètepèrò ọkàn-àyà wa.—Ka Sáàmù 139:1-6.
3, 4. (a) Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì ṣe fi hàn pé Jèhófà mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa? (b) Iṣẹ́ àgbàyanu wo ni Jèhófà ń gbé ṣe lóde òní?
3 Ǹjẹ́ ó ti pọ̀ jù fún wa láti gbà gbọ́ pé ọ̀rọ̀ àwa èèyàn lásán jẹ Ọlọ́run lógún tó bẹ́ẹ̀? Onísáàmù náà Dáfídì ronú lórí irú ìbéèrè yìí, ó sọ fún Jèhófà pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?” (Sm. 8:3, 4) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì fúnra rẹ̀ ló mú kó béèrè ìbéèrè yìí. Òun ló kéré jù lọ lára àwọn ọmọkùnrin Jésè, Jèhófà sì kà á sí “ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà [òun] lọ́rùn” ó sì mú un “kúrò ní títọ agbo ẹran lẹ́yìn, kí o lè di aṣáájú” lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (1 Sám. 13:14; 2 Sám. 7:8) Ronú nípa bí ọ̀rọ̀ náà á ṣe rí lára Dáfídì nígbà tó mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé ti gbọ́ àṣàrò tí òun ṣe ní ìdákọ́ńkọ́, tó sì tún mọ èrò ọkàn ọmọdékùnrin tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn bíi tòun!
4 Ohun àgbàyanu ló jẹ́ tá a bá ronú nípa bí ọ̀rọ̀ àwa èèyàn ṣe jẹ Jèhófà lógún lóde òní. Ó ń kó “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” jọ sínú ìjọsìn tòótọ́, ó sì ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa pa ìwà títọ́ wọn mọ́. (Hág. 2:7) Ká lè túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa ìwà títọ́ wa mọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń fa àwọn èèyàn wá sínú ìjọsìn tòótọ́.
ỌLỌ́RUN LÓ FÀ WÁ
5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ Ọmọ rẹ̀? Ṣàpèjúwe.
5 Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòh. 6:44) Ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé a nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ká tó lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fa àwọn ẹni bí àgùntàn wá sọ́dọ̀ Ọmọ rẹ̀? Ó máa ń lo iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò míṣọ́nnárì wà ní ìlú Fílípì, wọ́n pàdé obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere fún un. Àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí náà sọ pé: “Jèhófà sì ṣí ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti fiyè sí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.” Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run fún Lìdíà ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó lè lóye ọ̀rọ̀ náà, ohun tí èyí sì yọrí sí ni pé òun àti ìdílé rẹ̀ ṣe ìrìbọmi.—Ìṣe 16:13-15.
6. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fa gbogbo wa wá sínú ìjọsìn tòótọ́?
6 Ǹjẹ́ Lìdíà nìkan ni irú èyí ṣẹlẹ̀ sí? Rárá o. Tó o bá jẹ́ Kristẹni tó ti ṣe ìyàsímímọ́, Ọlọ́run ló fa ìwọ náà wá sínú ìjọsìn tòótọ́. Bí Baba wa ọ̀run ṣe rí ohun iyebíye lọ́kàn Lìdíà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí ohun rere lọ́kàn ìwọ náà. Nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sí ìhìn rere, Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye rẹ̀ nípa fífún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́. (1 Kọ́r. 2:11, 12) Nígbà tó o sapá láti fi ohun tí o kọ́ sílò, ó bù kún ìsapá rẹ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Inú rẹ̀ sì dùn nígbà tó o ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún un. Kódà, látìgbà tó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ní ojú ọ̀nà tó lọ sí ìyè ni Jèhófà ti ń wà pẹ̀lú rẹ nínú ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí ò ń gbé.
7. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa jẹ́ olóòótọ́?
7 Lẹ́yìn tí Jèhófà ti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa rìn pẹ̀lú rẹ̀, kò ní fi wá sílẹ̀ pé ká máa fúnra wa pinnu bí a ṣe máa dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí òun. Ó mọ̀ pé a kò dá wá sínú òtítọ́, torí náà kò lè ṣeé ṣe fún wa láti dá dúró sínú òtítọ́. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, ó sọ pé: “Agbára Ọlọ́run ń fi ìṣọ́ ṣọ́ [yín] nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ fún ìgbàlà kan tí a múra tán láti ṣí payá ní sáà àkókò ìkẹyìn.” (1 Pét. 1:4, 5) Gbogbo Kristẹni ni ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ yẹn kàn, ó sì yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lóde òní nífẹ̀ẹ́ sí i. Kí nìdí? Torí pé gbogbo wa la nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ká lè máa jẹ́ olóòótọ́ sí i.
ỌLỌ́RUN DÁ A DÚRÓ KÓ MÁ BÀA ṢI ẸSẸ̀ GBÉ
8. Kí nìdí tí a fi gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra ká má bàa ṣi ẹsẹ̀ gbé?
8 Kòókòó-jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé àti àìpé tiwa fúnra wa lè mú ká má ka àwọn nǹkan tẹ̀mí sí pàtàkì mọ́, ìyẹn sì lè mú ká ṣi ẹsẹ̀ gbé kí àwa fúnra wa tó mọ̀. (Ka Gálátíà 6:1.) A rí àpẹẹrẹ èyí nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé nínú ìgbésí ayé Dáfídì.
9, 10. Báwo ni Jèhófà ṣe dá Dáfídì dúró kó má bàa ṣi ẹsẹ̀ gbé, kí ni Jèhófà sì ń ṣe fún àwa náà lónìí?
9 Nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba ń wá bó ṣe máa gba ẹ̀mí Dáfídì, Dáfídì kó ara rẹ̀ ní ìjánu nípa ṣíṣàì gbẹ̀san lára ọba tó jẹ́ òjòwú yìí, ohun tó ṣe yìí sì wúni lórí gan-an. (1 Sám. 24:2-7) Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí àìpé fi fẹ́ mú kí Dáfídì ṣi ẹsẹ̀ gbé. Ó nílò oúnjẹ àti omi fún àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bẹ Nábálì, tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé kó ran òun lọ́wọ́. Nígbà tí Nábálì kan Dáfídì lábùkù, inú bí Dáfídì gan-an, ó sì gbéra kó lè lọ gbẹ̀san lára agbo ilé Nábálì, ó ti gbàgbé pé òun máa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí òun bá pa àwọn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ Ábígẹ́lì, ìyàwó Nábálì tó dá sí ọ̀rọ̀ náà kó tó pẹ́ jù, Dáfídì ì bá ṣe àṣìṣe tó burú jáì. Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà ló yọ òun, ó sì sọ fún obìnrin náà pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi! Ìbùkún sì ni fún ìlóyenínú rẹ, ìbùkún sì ni fún ìwọ tí o ti dá mi dúró lónìí yìí kí n má bàa wọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, kí n sì mú kí ọwọ́ ara mi wá ṣe ìgbàlà mi.”—1 Sám. 25:9-13, 21, 22, 32, 33.
10 Kí la lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Jèhófà lo Ábígẹ́lì láti dá Dáfídì dúró kó má bàa ṣi ẹsẹ̀ gbé. Ohun tó ń ṣe fún àwa náà lónìí nìyẹn. Àmọ́ ṣá o, a kò gbọ́dọ̀ retí pé kí Ọlọ́run rán ẹnì kan pé kó wá dá wa dúró nígbàkigbà tá a bá ti fẹ́ ṣe àṣìṣe; a kò sì gbọ́dọ̀ ronú pé a ti mọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe bí ọ̀ràn èyíkéyìí bá ṣẹlẹ̀ tàbí ohun tó máa fàyè gbà láti mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. (Oníw. 11:5) Àmọ́, a lè ní ìgbọ́kànlé pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà mọ ipò wa àti pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ó mú un dá wa lójú pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sm. 32:8) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fún wa ní ìmọ̀ràn? Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú ìmọ̀ràn rẹ̀? Báwo ló sì ṣe lè dá wa lójú pé Jèhófà ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ lóde òní? Kíyè sí bí ìwé Ìṣípayá ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn.
ÌBÁWÍ Ń DÁÀBÒ BÒ WÁ
11. Báwo ni Jèhófà ṣe mọ̀ nípa ohun tó ń lọ nínú ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀ tó?
11 Nínú ìran tó wà nínú ìwé Ìṣípayá orí 2 àti 3, Jésù Kristi tá a ti ṣe lógo wo bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú àwọn ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré. Ìran náà fi hàn pé kì í ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lápapọ̀ nìkan ni Kristi ń rí, ó tún ń kíyè sí àwọn nǹkan pàtó tó ń ṣẹlẹ̀. Ó tiẹ̀ dárúkọ àwọn kan, ó gbóríyìn fún àwọn kan lára wọn, ó sì fún àwọn míì ní ìbáwí. Kí ni èyí fi hàn? Nínú ìmúṣẹ ìran yẹn, ìjọ méje náà dúró fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà láyé lẹ́yìn ọdún 1914, ìlànà tó wà nínú ìbáwí tí Jésù fún ìjọ méjèèje náà sì kan gbogbo ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé lóde òní. Torí náà, ó tọ́ tá a bá parí èrò sí pé Jèhófà ń lo Ọmọ rẹ̀ láti darí àwọn èèyàn rẹ̀ lóde òní. Àǹfààní wo la lè rí nínú bí Jésù ṣe ń darí ìjọ?
12. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà máa darí ìṣísẹ̀ wa?
12 Ọ̀nà kan tí ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń fún wa tìfẹ́tìfẹ́ lè gbà ṣe wá láǹfààní ni pé ká máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Jèhófà ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó jíire látinú Ìwé Mímọ́ nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye. (Mát. 24:45) Kí ìtọ́sọ́nà náà lè ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ máa wá àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ká sì máa fi àwọn ohun tí à ń kọ́ sílò. Ìdákẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ‘ṣọ́ wa ká má bàa kọsẹ̀.’ (Júúdà 24) Ǹjẹ́ o ti kẹ́kọ̀ọ́ ohun kan látinú àwọn ìwé wa tó dà bíi pé torí tìrẹ gan-an ni wọ́n ṣe kọ ọ́? Gbà pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń tọ́ ẹ sọ́nà. Bí ọ̀rẹ́ kan ṣe lè fi ọwọ́ tọ́ ẹ léjìká kó sì pe àfiyèsí rẹ sí ohun kan, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe lè lo ẹ̀mí rẹ̀ láti pe àfiyèsí rẹ sí ìwà tàbí ànímọ́ kan tó o ní tó yẹ kí ìwọ tàbí ọ̀pọ̀ àwọn míì tó ní irú ìwà tàbí ànímọ́ kan náà ṣiṣẹ́ lé lórí. Tá a bá ń fiyè sí ibi tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí wa sí, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ ìṣísẹ̀ wa. (Ka Sáàmù 139:23, 24.) Torí náà, ó máa dára ká ronú nípa ọwọ́ tá a fi mú ìdákẹ́kọ̀ọ́.
13. Kí nìdí tó fi mọ́gbọ́n dání pé ká ṣàyẹ̀wò ọwọ́ tá a fi mú ìkẹ́kọ̀ọ́?
13 Tá a bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí eré ìnàjú, ó máa gba àkókò tó yẹ ká fi ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ wa. Arákùnrin kan sọ ohun tó kíyè sí, ó ní: “Ó rọrùn gan-an láti lo àkókò tó yẹ kéèyàn fi dá kẹ́kọ̀ọ́ fún nǹkan míì. Eré ìnàjú ti wá wọ́pọ̀ gan-an lásìkò yìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, kì í sì í náni lówó bíi ti ìgbà kan. Ó wà lórí tẹlifíṣọ̀n, lórí kọ̀ǹpútà àti lórí fóònù. Ńṣe ló yí wa ká.” Tí a kò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò tó yẹ ká fi ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀ fún nǹkan míì títí tí a kò fi ní ráyè fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ mọ́. (Éfé. 5:15-17) Ó máa dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Báwo ni mo ṣe ń wá àyè tó láti walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ṣé ìgbà tí mo bá ní àsọyé tàbí tí mo fẹ́ múra ìpàdé sílẹ̀ nìkan ni mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́?’ Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, bóyá a tún lè máa lo àkókò tá a yà sọ́tọ̀ fún Ìjọsìn Ìdílé tàbí ìdákẹ́kọ̀ọ́ láti fi wá ọgbọ́n Ọlọ́run, èyí tí Jèhófà ń pèsè láti fi ṣọ́ wa ká lè rí ìgbàlà.—Òwe 2:1-5.
ÌṢÍRÍ Ń MẸ́SẸ̀ WA DÚRÓ
14. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé Jèhófà máa ń kíyè sí bí nǹkan ṣe rí lára wa?
14 Dáfídì dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro tó le koko nígbèésí ayé rẹ̀. (1 Sám. 30:3-6) Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ fi hàn pé Jèhófà mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ̀. (Ka Sáàmù 34:18; 56:8.) Ọlọ́run mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára tiwa náà. Tí a bá ní ‘ìròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà’ tàbí tí ohun kan ‘wó ẹ̀mí wa palẹ̀,’ ó máa ń sún mọ́ wa. Èyí tó láti tù wá nínú dé ìwọ̀n àyè kan, bó ṣe tu Dáfídì nínú, tó fi kọ ọ́ lórin pé: “Èmi yóò kún fún ìdùnnú, èmi yóò sì máa yọ̀ nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, ní ti pé ìwọ ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́; ìwọ ti mọ̀ nípa àwọn wàhálà ọkàn mi.” (Sm. 31:7) Àmọ́ kì í ṣe pé Jèhófà kàn ń kíyè sí wàhálà wa o. Ó tún máa ń gbé wa ró ní ti pé ó máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń fún wa ní ìṣírí. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó ń gbà ṣe èyí jẹ́ nípasẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ.
15. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ásáfù?
15 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ásáfù jẹ́ ká rí ọ̀kan lára àwọn àǹfààní tó wà nínú lílọ sí àwọn ìpàdé. Nígbà tí Ásáfù ń ronú nípa àìṣèdájọ́ òdodo tó wà nígbà ayé rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá ni àǹfààní wà nínú sísin Ọlọ́run. Èyí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Ásáfù. Ó ṣàpèjúwe bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀ báyìí: “Ọkàn-àyà mi di kíkorò, kíndìnrín mi sì ro mí gógó.” Torí náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jáwọ́ nínú sísin Jèhófà. Kí ló wá ran Ásáfù lọ́wọ́ tó fi pe orí ara rẹ̀ wálé? Ó sọ pé: ‘Mo wá sínú ibùjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run.’ Bó ṣe wá sí àárín àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà ló ràn án lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe ìrònú rẹ̀. Ó rí i pé àṣeyọrí àwọn ẹni burúkú kò ní tọ́jọ́, ó sì dájú pé Jèhófà máa mú àwọn ọ̀ràn tọ́. (Sm. 73:2, 13-22) Bí ọ̀rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Àníyàn ṣíṣe lórí bá a ṣe máa kojú àìsí ìdájọ́ òdodo tó kúnnú ayé Sátánì yìí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Tá a bá ń pé jọ pẹ̀lú àwọn ará wa, ó máa mú kí ara tù wá, kò sì ní jẹ́ ká pàdánù ayọ̀ tí à ń rí nínú jíjọ́sìn Jèhófà.
16. Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ Hánà?
16 Tó bá wá jẹ́ pé ohun kan ló ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ tó mú kó ṣòro fún ẹ láti máa lọ sí àwọn ìpàdé ńkọ́? Bóyá ńṣe ni àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan bọ́ lọ́wọ́ rẹ tí ìyẹn sì kó ìtìjú bá ẹ, tàbí tó o ní èdèkòyédè pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin kan. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Hánà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Ka 1 Sámúẹ́lì 1:4-8.) Rántí pé ìṣòro ìdílé tí Hánà ní pẹ̀lú Pẹ̀nínà, orogún rẹ̀ máa ń múnú bí i. Ìṣòro náà sì máa ń le sí i lọ́dọọdún, nígbà tí ìdílé náà bá lọ sí Ṣílò láti rúbọ sí Jèhófà. Ọ̀rọ̀ náà kó ìdààmú bá Hánà débi pé ó “máa ń sunkún, kò sì ní jẹun.” Síbẹ̀ kò jẹ́ kí èyí dí òun lọ́wọ́ láti máa jọ́sìn Jèhófà. Jèhófà kíyè sí ìṣòtítọ́ rẹ̀, ó sì bù kún un.—1 Sám. 1:11, 20.
17, 18. (a) Àwọn ọ̀nà wo là ń gbà fún wa ní ìṣírí láwọn ìpàdé ìjọ? (b) Báwo ni àbójútó onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ń fún wa ká bàa lè rí ìgbàlà ṣe rí lára rẹ?
17 Àwọn Kristẹni òde òní ní ìdí rere láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hánà. A gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ tó bá dọ̀rọ̀ lílọ sí ìpàdé. Bí gbogbo wa ṣe mọ̀, a máa ń rí ìṣírí tó ń ṣe wá láǹfààní gbà láwọn ìpàdé. (Héb. 10:24, 25) Bá a ṣe ń pé jọ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni máa ń tù wá nínú. Ọ̀rọ̀ kékeré kan tí wọ́n sọ nínú àsọyé tàbí nígbà tí ẹnì kan dáhùn lè wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin. Ẹnì kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lè fetí sílẹ̀ sí wa tàbí kó sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fún wa nígbà tá a bá ní ìjíròrò pẹ̀lú rẹ̀ ṣáájú tàbí lẹ́yìn ìpàdé. (Òwe 15:23; 17:17) Ara wa máa ń yá gágá bá a ṣe ń kọrin sí Jèhófà. A tún nílò ìṣírí tí à ń rí gbà ní àwọn ìpàdé nígbà tí ‘ìrònú kan bá ń gbé wa lọ́kàn sókè,’ níbẹ̀ ni Jèhófà ti máa ń gbé wa ró nípasẹ̀ ‘ìtùnú tirẹ̀,’ ó sì máa ń tì wá lẹ́yìn kí ìpinnu wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí i lè túbọ̀ lágbára.—Sm. 94:18, 19.
18 Ọkàn wa balẹ̀ torí pé Ọlọ́run ń bójú tó wa tìfẹ́tìfẹ́, ó sì ń ṣe wá bíi ti onísáàmù náà Ásáfù, tó kọrin sí Jèhófà pé: “Ìwọ ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ìmọ̀ràn rẹ ni ìwọ yóò fi ṣamọ̀nà mi.” (Sm. 73:23, 24) Inú wa mà dùn gan-an ni o, pé Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ wa ká lè rí ìgbàlà!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Jèhófà ló fa ìwọ náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ń fi ìṣọ́ ṣọ́ wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ìṣírí tí à ń rí gbà máa ń gbé wa ró