Ẹ Jẹ́ Ká Gbọ́ Ìdáhùn Jésù
Ọ̀pọ̀ èèyàn tí kì í fi ẹ̀sìn ṣeré gbà pé ó yẹ kí àwọn onísìn máa lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ìṣèlú. Wọ́n gbà gbọ́ pé ipa kékeré kọ́ ni àwọn onísìn máa kó tó bá di pé kí wọ́n yanjú ìṣòro aráyé. Àmọ́, àwọn míì táwọn náà ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run gbà pé kò yẹ kéèyàn da ọ̀ràn ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ ìṣèlú. Kí ni èrò tìẹ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ṣé ó yẹ kí ìsìn máa lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ìṣèlú? Ṣé ó yẹ kí àwọn èèyàn da nǹkan méjì tó máa ń nípa lórí aráyé lọ́nà tó lágbára tó bẹ́ẹ̀ pa pọ̀?
JÉSÙ KRISTI ni àwọn èèyàn sọ pé ó “gbayì jù lọ látìgbà tí aráyé ti ń ṣe ẹ̀sìn.” Torí náà, ẹ wo bó ṣe máa rí ká ní a lè béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, Ǹjẹ́ ó yẹ kí ìsìn máa dá sí ọ̀ràn ìṣèlú? Kí ló máa sọ? Nígbà tó wà láyé, ó dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè, èyí táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láwọn ìlànà tó máa jẹ́ kí wọ́n fòye mọ ipa tó yẹ kí wọ́n kó ní ibi tí wọ́n bá ń gbé. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó mélòó kan yẹ̀ wò nínú ìwàásù táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa yẹn.
Wọ́n Ní Ipa Rere Lórí Ìgbé Ayé Àwọn Èèyàn
Jésù sọ bó ṣe yẹ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ṣe sí àwọn èèyàn. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ilẹ̀ ayé; ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá pàdánù okun rẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú adùn-iyọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ sípò? Kò ṣeé lò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe kí a dà á sóde, kí àwọn ènìyàn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. . . . Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:13-16) Kí nìdí tí Jésù fi fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wé iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀?
Ọ̀rọ̀ Jésù fi hàn pé kì í ṣe àárín àwùjọ kéréje kan ni wọ́n ti máa dà bí iyọ̀, bí kò ṣe láàárín gbogbo aráyé. Kì í ṣe ìwọ̀nba èèyàn ni wọ́n á máa tàn ìmọ́lẹ̀ fún, bí kò ṣe fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ ríran kedere. Àwọn àfiwé ọ̀rọ̀ tí Jésù lò yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé kò fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀ láìbá àwọn èèyàn tó kù da nǹkan pọ̀. Kí nìdí tí kò fi fẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?
Kíyè sí àwọn kókó yìí: Tí a kò bá fi iyọ̀ pa àwọn oúnjẹ kan àtàwọn nǹkan míì, èyí lè mú kí wọ́n bà jẹ́. Iná fìtílà kò lè lé òkùnkùn inú yàrá kan lọ bí wọn kò bá tan iná fìtílà náà sí ibẹ̀. Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé kò sígbà kan tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ máa gbé ní àwọn apá ibi àdádó kan lórí ilẹ̀ ayé, èyí tí wọ́n á pè ní àdúgbò àwọn onígbàgbọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa gbé nínú ọgbà ilé ìsìn níbi tó jẹ́ pé wọn kò ní ní ohunkóhun láti ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn inú ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, bó ṣe ṣe pàtàkì pé kí iyọ̀ wà nínú oúnjẹ, kí iná sì wà nínú ilé láti lé òkùnkùn lọ, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ sún mọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè ní ipa rere lórí ìgbé ayé wọn.
“Wọn Kì í Ṣe Apá Kan Ayé”
Àmọ́, ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa bá àwọn èèyàn ṣe nǹkan pa pọ̀ gbé ìbéèrè pàtàkì kan dìde pé: Ṣé ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa lọ́wọ́ nínú ìṣèlú? Kí nìdí tá a fi béèrè bẹ́ẹ̀? Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ó gbàdúrà nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:15, 16) Torí náà, báwo ni àwọn Kristẹni á ṣe máa bá àwọn èèyàn ṣe nǹkan pa pọ̀ nílùú tí wọ́n ń gbé, síbẹ̀ kí wọ́n má sì jẹ́ apá kan ayé? Ká lè rí ìdáhùn sí ọ̀rọ̀ yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè mẹ́ta míì yẹ̀ wò:
• Ojú wo ni Jésù fi wo ọ̀rọ̀ ìṣèlú?
• Kí ló yẹ kí àwọn Kristẹni ṣe lónìí?
• Báwo ni ẹ̀kọ́ tí àwọn Kristẹni fi ń kọ́ni ṣe ń ṣe àwọn ará ìlú láǹfààní?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé òun kò fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun dá ara wọn yà sọ́tọ̀ láìbá àwọn èèyàn tó kù da nǹkan pọ̀