Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Fi Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà Sí Ipò Àkọ́kọ́?
“Ẹnu mi yóò máa ròyìn òdodo rẹ lẹ́sẹẹsẹ, ìgbàlà rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” —SM. 71:15.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
Kí ló mú kí Nóà, Mósè, Jeremáyà àti Pọ́ọ̀lù fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn?
Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pinnu ọ̀nà tó o máa gbà gbé ìgbésí ayé rẹ?
Kí nìdí tó o fi pinnu láti fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́?
1, 2. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé kí ẹnì kan ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà? (b) Báwo la ṣe máa jàǹfààní tá a bá ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Nóà, Mósè, Jeremáyà àti Pọ́ọ̀lù, yàn láti ṣe?
ÌGBÉSẸ̀ tó gba àròjinlẹ̀ lo gbé nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́, tó o ṣèrìbọmi, tó o sì di ọmọlẹ́yìn Jésù. Ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ lo ṣe nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ńṣe ló dà bí ìgbà tó o sọ pé: ‘Jèhófà, mo fẹ́ kó o di Ọ̀gá mi, kó o sì máa tọ́ mi sọ́nà nínú gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe ní ìgbésí ayé mi. Ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́. Mo fẹ́ kó jẹ́ ìwọ ni wàá máa pinnu bí màá ṣe máa lo àkókò mi, ohun tí mo máa fi sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé mi àti bí mo ṣe máa lo ohun ìní mi àtàwọn ẹ̀bùn àbínibí mi.’
2 Tó o bá jẹ́ Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, èyí ni olórí ohun tó o ṣèlérí fún Jèhófà pé wàá ṣe. A gbóríyìn fún ẹ nítorí ìpinnu tó o ṣe yìí; ìpinnu tó dára tó sì mọ́gbọ́n dání ni. Ní báyìí tó o ti mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá rẹ, báwo nìyẹn ṣe kan ọ̀nà tí ò ń gbà lo àkókò rẹ? Àpẹẹrẹ Nóà, Mósè, Jeremáyà àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìbéèrè yẹn yẹ̀ wò. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló fi tọkàntọkàn sin Jèhófà. Ọ̀rọ̀ tiwa náà kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí tiwọn. Àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe nípa ohun tí wọ́n máa fi sí ipò àkọ́kọ́ lè mú kí àwa náà ṣàyẹ̀wò ọ̀nà tí à ń gbà lo àkókò wa.—Mát. 28:19, 20; 2 Tím. 3:1.
ṢÁÁJÚ ÌKÚN OMI
3. Báwo ni àkókò wa yìí ṣe jọ ti ọjọ́ Nóà?
3 Jésù sọ bí ọjọ́ Nóà àti àkókò wa ṣe jọra. Ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí. Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” (Mát. 24:37-39) Ọ̀pọ̀ lónìí ló ń gbé ìgbésí ayé wọn láìka bí àkókò wa ṣe jẹ́ kánjúkánjú sí. Wọn kò fiyè sí ìkìlọ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń kéde rẹ̀. Bíi ti ìgbà ayé Nóà, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò gbà pé Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ aráyé. (2 Pét. 3:3-7) Síbẹ̀, báwo ni Nóà ṣe lo àkókò rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó yí i ká kò fetí sí ìkìlọ̀ rẹ̀?
4. Báwo ni Nóà ṣe lo àkókò rẹ̀ lẹ́yìn tí Jèhófà ti gbéṣẹ́ lé e lọ́wọ́, kí sì nìdí?
4 Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti sọ ohun tó ní lọ́kàn fún Nóà, tó sì ti gbé iṣẹ́ lé e lọ́wọ́, ó kan ọkọ̀ áàkì kó lè gba ẹ̀mí àwọn èèyàn àti ti ẹranko là. (Jẹ́n. 6:13, 14, 22) Nóà tún kéde fáwọn èèyàn pé ìdájọ́ Jèhófà ń bọ̀. Àpọ́sítélì Pétérù pè é ní “oníwàásù òdodo,” èyí tó fi hàn pé Nóà sapá láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bí ipò tí wọ́n wà ṣe léwu tó. (Ka 2 Pétérù 2:5.) Ǹjẹ́ o ronú pé ó máa bọ́gbọ́n mu fún Nóà àti ìdílé rẹ̀ láti dá okòwò kan sílẹ̀, kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe yọrí ọlá ju àwọn alájọgbáyé wọn, tàbí kí wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ? Ó dájú pé ìyẹn kò mọ́gbọ́n dání! Níwọ̀n bí wọ́n ti mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, wọ́n yẹra fún irú àwọn nǹkan tó lè fa ìpínyà ọkàn bẹ́ẹ̀.
ỌMỌ ỌBA ILẸ̀ ÍJÍBÍTÌ KAN YAN OHUN TÓ FẸ́
5, 6. (a) Kí ló ṣeé ṣe kí ẹ̀kọ́ tí Mósè kọ́ múra rẹ̀ sílẹ̀ láti dì? (b) Kí nìdí tí Mósè fi kọ àwọn àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún un nílẹ̀ Íjíbítì?
5 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Mósè. Ọmọbìnrin Fáráò ló gbà á ṣọmọ, torí náà ààfin ọba Íjíbítì ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọba. Nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, wọ́n kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ “nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì.” (Ìṣe 7:22; Ẹ́kís. 2:9, 10) Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀kọ́ tó gbà yìí múra rẹ̀ sílẹ̀ láti di ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ láàfin Fáráò. Ipò ọlá ni ì bá wà nínú ìjọba tó lágbára jù lọ nígbà ayé rẹ̀, ì bá sì ní àwọn nǹkan amáyédẹrùn pẹ̀lú àwọn àǹfààní àti ìgbádùn tó máa ń bá irú ipò ọlá bẹ́ẹ̀ rìn. Àmọ́, ṣé gbígbádùn àwọn nǹkan yẹn ló jẹ Mósè lógún?
6 Nítorí ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Mósè ti gbà lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ gangan ní kùtùkùtù ìgbésí ayé rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó mọ ohun tí Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù tí wọ́n jẹ́ baba ńlá rẹ̀. Mósè ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí wọ̀nyẹn. Ó ṣeé ṣe kó ti ronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ àti bó ṣe máa pa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́. Torí náà, nígbà tí àkókò tó fún un láti yàn bóyá kó jẹ́ ọmọ ọba Íjíbítì tàbí ẹrú tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, kí ló yàn láti ṣe? Mósè yàn “pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” (Ka Hébérù 11:24-26.) Lẹ́yìn náà, ó tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà nípa bó ṣe yẹ kó lo ìgbésí ayé rẹ̀. (Ẹ́kís. 3:2, 6-10) Kí nìdí tí Mósè fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́. Ó parí èrò sí pé tí òun bá dúró sí Íjíbítì, ọwọ́ òun kò ní tẹ àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe. Kódà, kò pẹ́ tí Ọlọ́run fi fi ìyọnu mẹ́wàá kọlu orílẹ̀-èdè yẹn. Ǹjẹ́ o rí ẹ̀kọ́ tí àwa tá a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà lónìí lè rí kọ́ nínú èyí? Dípò tí a ó fi máa lépa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tàbí ìgbádùn nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ńṣe ló yẹ ká kó gbogbo àníyàn wa lé Jèhófà àti iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.
JEREMÁYÀ MỌ OHUN TÓ Ń BỌ̀ WÁ ṢẸLẸ̀
7. Báwo ni ipò tí Jeremáyà wà ṣe jọ tiwa?
7 Ọkùnrin míì tó fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ ni wòlíì Jeremáyà. Jèhófà gbé iṣẹ́ lé Jeremáyà wòlíì rẹ̀ lọ́wọ́ pé kó kéde ìdájọ́ Ọlọ́run tó ń bọ̀ sórí àwọn èèyàn ìlú Jerúsálẹ́mù àti Júdà tí wọ́n ti di apẹ̀yìndà. Lọ́rọ̀ kan, “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” ni Jeremáyà gbé ayé. (Jer. 23:19, 20) Ó mọ̀ dáadáa pé ètò àwọn nǹkan nígbà ayé rẹ̀ kò ní máa bá a lọ bó ṣe wà nígbà yẹn.
8, 9. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí Bárúkù yí ìrònú rẹ̀ pa dà? (b) Kí ló yẹ ká ní lọ́kàn tá a bá ń wéwèé ohun tá a máa ṣe?
8 Kí ni àwọn ohun tí Jeremáyà gbà gbọ́ mú kó kọ̀ láti ṣe? Kò wá bó ṣe máa sọ ara rẹ̀ di ẹni ńlá nínú ètò tó ti fẹ́ pa run yẹn. Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀? Àmọ́ ṣá o, fún àwọn àkókò kan Bárúkù tó jẹ́ akọ̀wé Jeremáyà kò lóye ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere. Torí náà, Ọlọ́run mí sí Jeremáyà láti sọ fún akọ̀wé rẹ̀ pé: “Wò ó! Ohun ti mo kọ́ ni èmi yóò ya lulẹ̀, ohun tí mo sì gbìn ni èmi yóò fà tu, àní gbogbo ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ní tìrẹ, ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́. Nítorí kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí gbogbo ẹran ara, . . . èmi yóò sì fi ọkàn rẹ fún ọ bí ohun ìfiṣèjẹ ní gbogbo ibi tí ìwọ bá lọ.”—Jer. 45:4, 5.
9 A kò mọ “àwọn ohun ńláńlá” tí Bárúkù ń wá fún ara rẹ̀.a Ohun tá a mọ̀ ni pé, àwọn ohun tí kò ní láárí ni, àwọn nǹkan tó máa pa run nígbà tí àwọn ará Bábílónì bá ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ǹjẹ́ o rí ẹ̀kọ́ tí ìyẹn fi kọ́ wa? Tá a bá fẹ́ ní àwọn ohun tó pọn dandan, a gbọ́dọ̀ ní àwọn ìwéwèé kan fún ọjọ́ ọ̀la. (Òwe 6:6-11) Àmọ́ ǹjẹ́ ó mọ́gbọ́n dání ká máa lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun wa láti máa fi lépa àwọn nǹkan tí kò ní tọ́jọ́? Òótọ́ ni pé, ètò Jèhófà kò dẹ́kun láti máa wéwèé fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, àwọn ilé tí à ń lò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn iṣẹ́ míì tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn nǹkan wọ̀nyí máa tọ́jọ́ torí pé ohun tí wọ́n wà fún ni pé kí àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú. Ó tọ́ kí gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ ní irú àfojúsùn yìí nígbà tí wọ́n bá ń wéwèé ohun tí wọ́n máa ṣe. Ǹjẹ́ ó dá ẹ lójú pé ò ń bá a nìṣó ní “wíwá ìjọba náà àti òdodo [Jèhófà] lákọ̀ọ́kọ́”?—Mát. 6:33.
‘MO KÀ WỌ́N SÍ Ọ̀PỌ̀ RẸPẸTẸ PÀǸTÍRÍ’
10, 11. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ń fi gbogbo okun rẹ̀ lépa kó tó di Kristẹni? (b) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi yí àwọn ohun tó ń lépa pa dà látòkèdélẹ̀?
10 Lákòótán, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Kó tó di Kristẹni, ọkàn rẹ̀ balẹ̀ torí pé ó ní iṣẹ́ tó dára lọ́wọ́. Ó ti kẹ́kọ̀ọ́ òfin àwọn Júù lọ́dọ̀ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ tó gbajúmọ̀ jù lọ nígbà ayé rẹ̀. Ó gba àṣẹ lọ́dọ̀ àlùfáà àgbà àwọn Júù. Ó sì ń tẹ̀ síwájú gan-an nínú ẹ̀sìn àwọn Júù, ju ọ̀pọ̀ lára àwọn ojúgbà rẹ̀ lọ. (Ìṣe 9:1, 2; 22:3; 26:10; Gál. 1:13, 14) Síbẹ̀, gbogbo èyí ló yí pa dà nígbà tí Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Jèhófà kò bù kún àwọn Júù gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan mọ́.
11 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé kò sí iṣẹ́ tí ẹnì kan yàn láti ṣe nínú ètò àwọn Júù, tó níye lórí lójú Jèhófà, torí pé orílẹ̀-èdè yẹn kò ní pẹ́ pa run. (Mát. 24:2) Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ Farisí tẹ́lẹ̀ rí yìí sọ pé àwọn ohun tí òun ti kà sí pàtàkì tẹ́lẹ̀ jẹ́ “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí” nígbà tó fi wọ́n wé òye kedere tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní nípa àwọn ètè Ọlọ́run àti àǹfààní iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Pọ́ọ̀lù pa àwọn nǹkan tó ń lépa nínú ẹ̀sìn àwọn Júù tì, ó sì fi gbogbo èyí tó kù nínú ìgbésí ayé rẹ̀ wàásù ìhìn rere.—Ka Fílípì 3:4-8, 15; Ìṣe 9:15.
ṢÀGBÉYẸ̀WÒ ÀWỌN OHUN TÓ O FI SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́
12. Kí ni Jésù gbájú mọ́ lẹ́yìn tó ṣe ìrìbọmi?
12 Nóà, Mósè, Jeremáyà, Pọ́ọ̀lù àtàwọn èèyàn míì bíi tiwọn lo èyí tó pọ̀ jù lára àkókò wọn àti okun wọn láti lépa àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ rere ni wọ́n jẹ́ fún wa. Lóòótọ́, Jésù lẹni tó tóbi jù lọ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ya ara wọn sí mímọ́ fún un. (1 Pét. 2:21) Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, ó ya èyí tó kù nínú ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere àti bíbọlá fún Jèhófà. Ibi tó yẹ kí Kristẹni kan tó gba Jèhófà ní Ọ̀gá parí èrò sí ni pé, sísin Jèhófà ló yẹ kó gba ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé òun. Ṣé ohun tó gba ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé tìrẹ náà nìyẹn? Báwo la ṣe lè fi àwọn àfojúsùn tó kan iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà àti àwọn ìgbòkègbodò tó pọn dandan nípa tara sí àyè tó yẹ olúkúlùkù wọn?—Ka Sáàmù 71:15; 145:2.
13, 14. (a) Kí la fún gbogbo àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ ní ìṣírí pé kí wọ́n ṣe? (b) Irú ìtẹ́lọ́rùn wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lè ní?
13 Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni ètò Jèhófà ti ń fún àwọn Kristẹni ní ìṣírí léraléra pé kí wọ́n ronú nípa ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kí wọ́n sì gbàdúrà nípa rẹ̀. Àmọ́, onírúurú nǹkan ni kò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti máa ya àádọ́rin [70] wákàtí sọ́tọ̀ lóṣooṣù fún iṣẹ́ ìwàásù. Kò yẹ kí wọ́n jẹ́ kí èyí bà wọ́n lọ́kàn jẹ́. (1 Tím. 5:8) Àmọ́, ìwọ ńkọ́? Ṣé lóòótọ́ ni kò ṣeé ṣe fún ẹ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà?
14 Ronú nípa ayọ̀ tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run ní lásìkò Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún yìí. Ní oṣù March, ètò àkànṣe kan mú kó ṣeé ṣe fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láti pinnu bóyá ọgbọ̀n [30] tàbí àádọ́ta [50] wákàtí làwọn máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá. (Sm. 110:3) Àwọn tó ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lé ní mílíọ̀nù kan dáadáa, ó dà bíi pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ni ará wọn yá gágá tí wọ́n sì láyọ̀. Ǹjẹ́ o lè ṣètò àwọn nǹkan lọ́nà táá mú kó o máa ní irú ayọ̀ yìí déédéé? Lópin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ìtẹ́lọ́rùn ńláǹlà tí àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ní máa ń mú kí wọ́n lè sọ pé, “Jèhófà, mo ti ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ.”
15. Kí ló yẹ kí Kristẹni kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ nígbà tó ṣì wà nílé ìwé?
15 Tó o bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣe tán ní iléèwé, o lè rí i pé o ní ìlera tó dáa, o kò sì ní ojúṣe tó pọ̀ láti bójú tó. Ǹjẹ́ o ti ronú jinlẹ̀ nípa gbígba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé? Kò sí àní-àní pé àwọn agbaninímọ̀ràn níléèwé gbà pé ohun tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní jù ni pé kó o lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, kó o sì wá iṣẹ́ gidi kan ṣe. Síbẹ̀, ètò tí kì í tọ́jọ́ táwọn èèyàn dá sílẹ̀ àti owó ni wọ́n gbọ́kàn lé. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tó o bá fi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ṣe àfojúsùn rẹ, ohun tó dára tó sì máa wà pẹ́ títí lò ń lépa yẹn. Wàá sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ pípé tí Jésù fi lélẹ̀. Irú ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání bẹ́ẹ̀ máa fún ẹ láyọ̀. Ó sì máa dáàbò bò ẹ́. Á tún fi hàn pé o ti pinnu láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ sí Jèhófà ṣẹ.—Mát. 6:19-21; 1 Tím. 6:9-12.
16, 17. Àwọn ìbéèrè wo ló jẹ yọ nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àtàwọn ìlépa míì?
16 Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ló ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè rówó gbọ́ bùkátà tó pọn dandan nínú ìdílé wọn. Síbẹ̀, àwọn míì lè máa ṣiṣẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ. (1 Tím. 6:8) Àwọn oníṣòwò ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú ká gbà pé gbogbo nǹkan tuntun tí wọ́n ṣe jáde jẹ́ kòṣeémánìí. Àmọ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò fẹ́ kí ayé Sátánì pinnu ohun tí àwọn máa fi sí ipò àkọ́kọ́ fún àwọn. (1 Jòh. 2:15-17) Ní ti àwọn tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, ọ̀nà wo ló tún dára jù tí wọ́n lè gbà lo àkókò wọn ju pé kí wọ́n tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, kí wọ́n sì fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́?
17 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara wọn sí mímọ́ lè bi ara wọn pé: Kí ni ohun tí mo kà sí pàtàkì jù nígbèésí ayé mi? Ṣé mò ń fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́? Ǹjẹ́ mo fìwà jọ Jésù nípa níní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ? Ǹjẹ́ mò ń fi ìmọ̀ràn Jésù pé ká máa tẹ̀ lé òun nígbà gbogbo sílò? Ǹjẹ́ mo lè ṣàtúnṣe àwọn nǹkan tí mo máa ń ṣe déédéé kí n lè ní àkókò tó pọ̀ sí i fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tàbí àwọn ìgbòkègbodò míì tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? Kódà bí ipò mi kò bá gbà mí láyè báyìí láti mú iṣẹ́ ìsìn mi gbòòrò sí i, ǹjẹ́ mò ń bá a nìṣó láti máa ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ?
“KÍ Ẹ LÈ FẸ́ LÁTI ṢE, KÍ Ẹ SÌ GBÉ ÌGBÉSẸ̀”
18, 19. Kí lo lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ṣe fún ẹ, kí sì nìdí tí irú àdúrà bẹ́ẹ̀ fi lè mú inú rẹ̀ dùn?
18 Ìtara tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ní máa ń fúnni láyọ̀. Síbẹ̀, bí ipò àwọn míì bá tiẹ̀ gbà wọ́n láyè láti di aṣáájú-ọ̀nà, ó lè má wù wọ́n tàbí kí wọ́n máà kúnjú ìwọ̀n. (Ẹ́kís. 4:10; Jer. 1:6) Kí ló wá yẹ kí wọ́n ṣe? Ǹjẹ́ kò yẹ kí wọ́n gbàdúrà nípa rẹ̀? Ó yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé Jèhófà “ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, nítorí ti ìdùnnú rere rẹ̀, kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.” (Fílí. 2:13) Bí kò bá wá látọkàn rẹ pé kó o fi kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ, kó sì fún ẹ lókun.—2 Pét. 3:9, 11.
19 Nóà, Mósè, Jeremáyà, Pọ́ọ̀lù àti Jésù jẹ́ olùfọkànsìn. Wọ́n lo àkókò wọn àti okun wọn láti polongo àwọn ìkìlọ̀ Jèhófà. Wọn kò jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wọn níyà. Òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti sún mọ́lé; torí náà, gbogbo àwa tá a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run gbọ́dọ̀ rí i dájú pé à ń bá a nìṣó láti máa sa gbogbo ipá wa láti máa tẹ̀ lé àwọn àpẹẹrẹ àtàtà tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (Mát. 24:42; 2 Tím. 2:15) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó máa mú inú Jèhófà dùn, yóò sì bù kún wa lọ́pọ̀ jaburata.—Ka Málákì 3:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn èèyàn kò fetí sí ìkìlọ̀ Nóà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ǹjẹ́ o ti ronú jinlẹ̀ nípa gbígba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé?