ǸJẸ́ O MỌ̀?
Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, kí ló túmọ̀ sí?
ÌWÉ Mímọ́ sọ fún wa nípa àwọn mélòó kan tí wọ́n fa aṣọ ara wọn ya. Ìyẹn lè ṣàjèjì sí àwọn tó bá ń ka Bíbélì lóde òní, àmọ́ lójú àwọn Júù ńṣe lẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ń fi bí àìnírètí, ẹ̀dùn ọkàn, ìrẹ̀sílẹ̀, ìkannú, tàbí ìbànújẹ́ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó hàn.
Bí àpẹẹrẹ, Rúbẹ́nì “gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya” nígbà tó rí i pé gbogbo ìsapá òun láti gba Jósẹ́fù arákùnrin rẹ̀ sílẹ̀ já sí pàbó, torí pé wọ́n ti ta Jósẹ́fù sóko ẹrú. Jékọ́bù tó jẹ́ bàbá wọn náà “gbọn aṣọ àlàbora rẹ̀ ya” nígbà tó rò pé ẹranko ẹhànnà kan ti ní láti pa Jósẹ́fù jẹ. (Jẹ́n. 37:18-35) Jóòbù ‘gbọn aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ ya’ nígbà tí wọ́n sọ fún un pé gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú. (Jóòbù 1:18-20) Ońṣẹ́ kan tí ‘ẹ̀wù rẹ̀ wà ní gbígbọ̀nya’ ló tọ Élì, Àlùfáà Àgbà wá kó lè sọ fún un pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú ogun, wọ́n ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì àti pé wọ́n ti gba àpótí májẹ̀mú. (1 Sám. 4:12-17) Nígbà tí wọ́n ka àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Òfin fún Jòsáyà, tó sì gbọ́ nípa ọ̀pọ̀ àṣìṣe táwọn èèyàn rẹ̀ ti ṣe “ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya.”—2 Ọba 22:8-13.
Nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ Jésù, Káyáfà tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà “fa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ ya,” lẹ́yìn tó gbọ́ ohun tí ó kà sí ọ̀rọ̀ òdì. (Mát. 26:59-66) Òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rábì kan sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ tí wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run wà lábẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti fa ẹ̀wù ara rẹ̀ ya. Àmọ́ èrò míì tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn rábì lẹ́yìn tí wọ́n pa tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù run ni pé “lóde ìwòyí, kò sídìí fún ẹni tó bá gbọ́ tí wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Orúkọ Ọlọ́run láti fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀wù onítọ̀hún á di àkísà.”
Àmọ́ ṣá o, àṣà kéèyàn máa fa ẹ̀wù ara rẹ̀ ya kò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run, àyàfi tó bá jẹ́ pé kò sí ẹ̀tàn nínú irú ẹ̀dùn ọkàn bẹ́ẹ̀. Ìyẹn ló mú kí Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘fa ọkàn wọn ya, kì í sì í ṣe ẹ̀wù wọn; kí wọ́n sì padà wá sọ́dọ̀ òun.’—Jóẹ́lì 2:13.