Ǹjẹ́ O Mọyì Bí Jèhófà Ṣe Ń Fìfẹ́ Ṣọ́ Wa?
“Ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.”—ÒWE 15:3.
1, 2. Báwo ni bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ ṣọ́ wa ṣe yàtọ̀ sí ti kámẹ́rà tí wọ́n fi ń ṣọ́ni lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀?
NÍ Ọ̀PỌ̀ orílẹ̀-èdè, ọ̀pọ̀ ibi ni ìjọba gbé kámẹ́rà tí wọ́n fi ń ṣọ́ àwọn ọkọ̀ tó ń lọ tó ń bọ̀ sí kó lè máa yàwòrán bí jàǹbá ọkọ̀ ṣe ṣẹlẹ̀. Bí ọkọ̀ kan bá kọ lu òmíràn, tí dẹ́rẹ́bà ọkọ̀ náà sì sá lọ, àwòrán inú kámẹ́rà yìí làwọn aláṣẹ á fi wá ọkọ̀ náà kàn, wọ́n á sì fàṣẹ ọba mú dẹ́rẹ́bà tó sá lọ náà. Pẹ̀lú bí kámẹ́rà ṣe wà káàkiri yìí, ńṣe ló túbọ̀ ń ṣòro fáwọn èèyàn láti bọ́ lọ́wọ́ ìyà tó tọ́ sí wọn.
2 Àmọ́, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ kí àwọn kámẹ́rà tó wà káàkiri ibi gbogbo yìí rán wa létí ohunkóhun nípa Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́? Bíbélì sọ pé ojú rẹ̀ “ń bẹ ní ibi gbogbo.” (Òwe 15:3) Àmọ́, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ńṣe ni Jèhófà ń ṣọ́ wa lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀? Ṣé torí ohun tí Ọlọ́run fi ń ṣọ́ wa ni kó lè mọ̀ bóyá à ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ kó sì fi ìyà tó tọ́ jẹ wá tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀? (Jer. 16:17; Héb. 4:13) Rárá o! Ohun tó mú kí Jèhófà máa kíyè sí wa gan-an ni pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, ọ̀rọ̀ wa sì jẹ ẹ́ lógún.—1 Pét. 3:12.
3. Sọ márùn-ún lára ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń fìfẹ́ bójú tó wa, tá a máa jíròrò báyìí.
3 Kí ló máa mú ká mọyì rẹ̀ pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ló mú kó máa ṣọ́ wa? Ẹ jẹ́ ká jíròrò bó ṣe ń fi hàn pé òun ń fìfẹ́ ṣọ́ wa. (1) Ó máa ń kìlọ̀ fún wa tá a bá ń ro èròkerò. (2) Ó máa ń tọ́ wa sọ́nà tá a bá gbé ìgbésẹ̀ tí kò tọ́. (3) Ó máa ń darí wa nípasẹ̀ àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (4) Ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ tí onírúurú àdánwò bá ń dé bá wa. (5) Ó máa ń san èrè fún wá tó bá kíyè sí ẹ̀mí rere tá a ní.
ỌLỌ́RUN TÓ Ń ṢỌ́ WA MÁA Ń KÌLỌ̀ FÚN WA
4. Kí ni Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó ń kìlọ̀ fún Kéènì pé ẹ̀ṣẹ̀ “lúgọ sí ẹnu ọ̀nà”?
4 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká jíròrò bí Ọlọ́run ṣe máa ń kìlọ̀ fún wa tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í ro èròkerò. (1 Kíró. 28:9) Ká lè mọyì apá yìí lára bí Ọlọ́run ṣe ń fìfẹ́ ṣọ́ wa, ẹ jẹ́ ká jíròrò ọwọ́ tó fi mú Kéènì. Ẹ rántí pé ‘ìbínú Kéènì gbóná’ nígbà tí kò rí ojú rere Jèhófà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 4:3-7.) Jèhófà rọ Kéènì pé kó “yíjú sí ṣíṣe rere.” Jèhófà wá kìlọ̀ fún un pé, bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ “lúgọ sí ẹnu ọ̀nà.” Ọlọ́run wá bi í pé: ‘Ìwọ yóò ha kápá rẹ̀ bí?’ Ó fẹ́ kí Kéènì fetí sí ìkìlọ̀ kó lè pa dà rí “ojú rere.” Ojúure Ọlọ́run ló lè mú kí ara èèyàn yá gágá, èyí á sì mú kéèyàn máa gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.
5. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń kìlọ̀ fún wa nípa àwọn èròkerò tá a bá ní?
5 Báwo ló ṣe ń kìlọ̀ fún wa lóde òní? Ojú Jèhófà máa ń rí ọkàn wa; ó mọ èrò wa àti ẹ̀mí tá a fi ń ṣe nǹkan, torí náà a ò lè fi ohunkóhun pa mọ́ fún un. Ó wu Baba wa onífẹ̀ẹ́ pé ká máa tọ ọ̀nà òdodo; síbẹ̀, kì í fipá mú wa pé ká kúrò lójú ọ̀nà tá a bá ń tọ̀. Tá a bá ń forí lé ibi tí kò tọ́, ó máa ń kìlọ̀ fún wa nípasẹ̀ Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lọ́nà wo? Bá a ṣe ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, a sábà máa ń rí àwọn gbólóhùn tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìfẹ́ láti hùwà tí kò tọ́ àti èròkerò. Láfikún, àwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ń pèsè lè mú ká túbọ̀ lóye ìṣòro kan tá a ti ń sapá láti borí tipẹ́tipẹ́, wọ́n sì lè jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè borí rẹ̀. A sì tún máa ń rí ìmọ̀ràn tó bọ́ sákòókò gbà láwọn ìpàdé ìjọ tá a máa ń ṣe.
6, 7. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn ìtẹ̀jáde tí ètò Ọlọ́run ń pèsè fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ? (b) Báwo lo ṣe lè jàǹfààní látinú bí Jèhófà ṣe dìídì nífẹ̀ẹ́ rẹ?
6 Irú àwọn ìkìlọ̀ tá à ń rí gbà yìí fi hàn lóòótọ́ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló mú kó máa ṣọ́ wa. Kò sí àní-àní pé ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, tìtorí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni ètò Ọlọ́run fi ń pèsè àwọn ìtẹ̀jáde, gbogbo ìjọ ni àwọn ìmọ̀ràn tá à ń gbà nípàdé sì wà fún. Síbẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń kìlọ̀ fún wa yìí, ńṣe ló ń darí rẹ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó o lè ṣàtúnṣe èrò rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè sọ pé àwọn nǹkan yìí fi hàn pé Jèhófà dìídì nífẹ̀ẹ́ rẹ.
7 Kí àwọn ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run ń fún wa tó lè ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún. Lẹ́yìn náà ká fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò, ká sapá gidigidi láti mú èrò èyíkéyìí tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu kúrò lọ́kàn wa. (Ka Aísáyà 55:6, 7.) Tá a bá fetí sí ìkìlọ̀ tó fún wa, a ò ní ti ìka àbámọ̀ bọnu. Àmọ́, tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé a ti hùwà tí kò tọ́ ńkọ́? Ìrànlọ́wọ́ wo ni Baba wa onífẹ̀ẹ́ máa ṣe fún wa?
BABA WA ONÍFẸ̀Ẹ́ MÁA Ń TỌ́ WA SỌ́NÀ
8, 9. Báwo ni ìmọ̀ràn tí Jèhófà ń fún wa nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe fi bí ìfẹ́ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó hàn? Sọ àpẹẹrẹ kan.
8 A sábà máa ń rí i ní ti gidi pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa nígbà tí ẹnì kan bá tọ́ wa sọ́nà. (Ka Hébérù 12:5, 6.) Ká sòótọ́, inú wa kì í sábà dùn tí wọ́n bá gbà wá nímọ̀ràn tàbí tí wọ́n bá bá wa wí. (Héb. 12:11) Síbẹ̀, ronú nípa ohun tí ẹni tó ń gbà wá nímọ̀ràn máa gbé yẹ̀ wò. Ó ti ní láti kíyè sí bí ohun tá à ń ṣe ṣe lè nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, ó ti ní láti gba bí ọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára wa rò, ó sì gbọ́dọ̀ ṣe tán láti wá àkókò kó sì sapá láti wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táá fi tọ́ wa sọ́nà ká lè máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Kí ni ká wá sọ nípa Jèhófà tó jẹ́ Orísun ìmọ̀ràn yẹn? Ó dájú pé ọ̀rọ̀ wa jẹ òun náà lógún.
9 Ẹ jẹ́ ká wo bí ìmọ̀ràn tí ará kan fún wa ṣe lè fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún. Kí arákùnrin kan tó rí òtítọ́, ó ti máa ń wo àwòrán oníhòòhò lémọlemọ́, àmọ́ ó jáwọ́ nínú ìwà náà. Síbẹ̀, èròkerò yẹn ṣì máa ń wá sí i lọ́kàn, bí ìgbà tí àjókù igi bá ń rú èéfín. Nígbà tó ra fóònù alágbèéká tuntun, ló bá tún pa dà sí ìwà rẹ̀ àtijọ́. (Ják. 1:14, 15) Ó máa ń lo fóònù rẹ̀ láti lọ sórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ti lè rí àwòrán oníhòòhò. Lọ́jọ́ kan, nígbà tó ń lo fóònù rẹ̀ láti wàásù fẹ́nì kan, ó yá alàgbà kan ní fóònù rẹ̀ kí onítọ̀hún lè wo àwọn àdírẹ́sì kan. Bí alàgbà náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lo fóònù yẹn, àwọn ìkànnì tí kò bójú mu yọjú. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló mú kí wọ́n ṣèrànwọ́ fún arákùnrin wa tí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ti ń bà jẹ́ lọ yìí. Wọ́n fún un ní ìmọ̀ràn tó bọ́ sákòókò, ó jàǹfààní látinú ìtọ́sọ́nà tí wọ́n fún un, ó sì wá borí ìwà tí kò tọ́ náà. A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ tó máa ń rí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá à ń dá níkọ̀kọ̀, tó sì ń tọ́ wa sọ́nà kó tó di pé a gun igi ré kọjá ewé!
A MÁA JÀǸFÀÀNÍ TÁ A BÁ Ń FI ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ SÍLÒ
10, 11. (a) Báwo lo ṣe lè wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run? (b) Báwo ni ìdílé kan ṣe rí i pé ó bọ́gbọ́n mu bí àwọn ṣe gbà kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà?
10 Onísáàmù náà kọrin sí Jèhófà pé: “Ìmọ̀ràn rẹ ni ìwọ yóò fi ṣamọ̀nà mi.” (Sm. 73:24) Nígbàkigbà tá a bá nílò ìtọ́sọ́nà, a lè “ṣàkíyèsí” Jèhófà nípa wíwo inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ká lè mọ èrò rẹ̀ nípa ohun tá a fẹ́ ṣe. Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ó máa ṣe wá láǹfààní nípa tẹ̀mí. Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún máa ràn wá lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ohun tá a nílò nípa tara.—Òwe 3:6.
11 A lè rí àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe tọ́ àwọn kan sọ́nà nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin àgbẹ̀ kan tó gba oko dá. Àgbègbè olókè tó wà ní erékùṣù Masbate lórílẹ̀-èdè Philippines ló ń gbé. Aṣáájú-ọ̀nà lòun àti ìyàwó rẹ̀, wọ́n sì ní àwọn ọmọ tó pọ̀ díẹ̀. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wọn lọ́jọ́ kan nígbà tí olóko sọ fún wọn pé òun fẹ́ lo ilẹ̀ òun. Kí ló mú kó sọ bẹ́ẹ̀? Àwọn kan ló fẹ̀sùn èké kan ìdílé náà pé wọ́n hùwà àìṣòótọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé arákùnrin náà ń ronú nípa ibi tí òun àti ìdílé rẹ̀ á máa gbé, ó sọ pé: “Jèhófà máa pèsè. Láìka ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀ sí, ìgbà gbogbo ló máa ń bójú tó wa.” Ó bójú mu bí arákùnrin náà ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ìdí ni pé ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ìdílé náà gbọ́ pé kí àwọn ṣì máa lo ilẹ̀ náà nìṣó, èyí sì mú inú wọn dùn gan-an. Kí ló fà á tí ọ̀rọ̀ fi yí pa dà? Ẹni tó ni ilẹ̀ náà kíyè sí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fẹ̀sùn èké kan ìdílé Ẹlẹ́rìí náà, wọ́ọ́rọ́wọ́ ni wọ́n ń lọ láìjà láìta. Ó kíyè sí i pé ìlànà Bíbélì tí wọ́n ń tẹ̀ lé ló ràn wọ́n lọ́wọ́. Ohun tó wú olóko náà lórí nìyẹn tó fi ní kí wọ́n máa ro ilẹ̀ náà lọ, tó sì tún fún wọn ní ilẹ̀ míì ní àfikún sí i. (Ka 1 Pétérù 2:12.) Láìsí àní-àní, Jèhófà ń tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ká lè kojú àwọn ìṣòro tá a ní.
Ọ̀RẸ́ TÓ Ń DÚRÓ TINI LỌ́JỌ́ ÌṢÒRO
12, 13. Àwọn ipò wo ló lè mú kí àwọn kan máa ronú pé bóyá ni Ọlọ́run ń kíyè sí i pé àwọn ń jìyà?
12 Àmọ́, láwọn ìgbà míì, ipò tó ń pọ́nni lójú lè ṣàìlọ bọ̀rọ̀. Ó lè jẹ́ àìsàn líle koko ló ń bá wa fínra tàbí kí àwọn ìbátan wa tímọ́tímọ́ máa ta kò wá ṣáá, wọ́n sì lè máa ṣe inúnibíni sí wa lemọ́lemọ́. Àwọn gbúngbùngbún tó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láàárín àwa àtàwọn míì nínú ìjọ, tó sì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa ńkọ́?
13 Bí àpẹẹrẹ, ó lè dùn ẹ́ tí arákùnrin kan bá sọ ọ̀rọ̀ tó o gbà pé kò tọ́ sí ẹ. O lè torí ìyẹn sọ pé, ‘Kò yẹ kírú èyí máa ṣẹlẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run!’ Síbẹ̀, ètò Ọlọ́run lè máa fún arákùnrin tó sọ̀rọ̀ yẹn ní onírúurú ojúṣe nínú ìjọ, ó sì ṣeé ṣe kí àwọn míì máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere. O wá lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Ṣé Jèhófà ò rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni? Ṣé á kàn máa wò ó níran ni?’—Sm. 13:1, 2; Háb. 1:2, 3.
14. Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí Ọlọ́run kì í fi í sábà dá sí ìṣòro tá a bá ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì?
14 Jèhófà lè nídìí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí kò fi bá wa dá sí i. Bí àpẹẹrẹ, o lè ronú pé ẹni tẹ́ ẹ jọ ní aáwọ̀ ló ni ẹ̀bi tó pọ̀ jù lọ, tó sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run. Lójú Ọlọ́run, ó lè jẹ́ pé ìwọ gan-an lo lẹ̀bi tó pọ̀ jù, tó ò sì mọ̀. Ọ̀rọ̀ tó o gbà sí ìbínú lè wá jẹ́ ìmọ̀ràn tó o nílò gan-an, tó yẹ kó o fara balẹ̀ ronú lé lórí. Arákùnrin Karl Klein, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí kó tó kú, sọ nínú ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ pé ìgbà kan wà tí Arákùnrin J. F. Rutherford bá òun wí láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Arákùnrin Rutherford kí Arákùnrin Klein tọ̀yàyàtọ̀yàyà pé, “Pẹ̀lẹ́ o Karl!” Àmọ́, imú ni Arákùnrin Klein fi dá a lóhùn, torí pé inú ṣì ń bí i torí ìbáwí tó fún un. Nígbà tí Arákùnrin Rutherford rí i pé inú ṣì ń bí Arákùnrin Klein torí ọ̀rọ̀ tóun bá a sọ, ó kìlọ̀ fún un pé tí kò bá ṣọ́ra, ó máa kó sọ́wọ́ Èṣù. Arákùnrin Klein wá sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé tá a bá di arákùnrin wa sínú, pàápàá jù lọ torí pé ó bá wa sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ojúṣe rẹ̀, ńṣe là ń ti ara wa sẹ́nu pàkúté Èṣù.a
15. Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn táá jẹ́ kó o máa mú sùúrù nígbà tó o bá ń retí pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro kan?
15 Síbẹ̀, a lè má fi bẹ́ẹ̀ mú sùúrù tó bá dà bíi pé ìṣòro tá a ní kò lójú. Kí la lè ṣe? Jẹ́ ká sọ pé ò ń wakọ̀ lọ lójú ọ̀nà márosẹ̀, ló wá di pé sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ wà. O ò mọ bẹ́ ẹ ṣe máa pẹ́ tó lẹ́nu sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ náà. Tó o bá jẹ́ kínú bí ẹ tó o sì gbìyànjú láti wá ọ̀nà míì gbà, o lè ṣìnà kó o sì pẹ́ débi tó ò ń lọ. Àmọ́, o lè máà pẹ́ rárá ká sọ pé o ní sùúrù. Bó ṣe máa rí náà nìyẹn tó o bá rọ̀ mọ́ ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bópẹ́bóyá wàá dé ibi tó ò ń lọ.
16. Ohun mìíràn wo ló lè mú kí Jèhófà pinnu pé òun kò ní tètè dá wa nídè kúrò nínú àdánwò?
16 Jèhófà lè má tètè dá wa nídè nínú àdánwò torí pé ó fẹ́ ká gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó yẹ. (Ka 1 Pétérù 5:6-10.) Àmọ́ o, Ọlọ́run kì í dán wa wò! (Ják. 1:13) “Elénìní yín, Èṣù,” ló ń fa èyí tó pọ̀ jù nínú àdánwò. Síbẹ̀, Ọlọ́run lè lo ipò tó nira láti mú ká kọ́ bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú òun. Ó rí i pé à ń jìyà, àmọ́ “nítorí ó bìkítà fún” wa, ó máa rí sí i pé kò ju “ìgbà díẹ̀” lọ tá a fi ní láti fara dà á. Ǹjẹ́ o mọyì bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ ṣọ́ ẹ nígbà tó o wà lábẹ́ àdánwò, tó sì dá ẹ lójú pé ó máa ṣe ọ̀nà àbáyọ?—2 Kọ́r. 4:7-9.
JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ FI OJÚURE HÀN SÍ Ẹ
17. Àwọn wo ni Jèhófà ń wá kiri, kí sì nìdí?
17 Paríparí rẹ̀, ìdí tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ wà tí Ọlọ́run fi ń kíyè sí ìgbésí ayé wa. Ọlọ́run tipasẹ̀ Hánáánì aríran sọ fún Ásà Ọba pé: “Ojú [Jèhófà] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíró. 16:9) Ní ti Ásà, kò fi ọkàn pípé wá Ọlọ́run. Àmọ́ ní tìrẹ, tó o bá ń ṣe ohun tó tọ́ láìjáwọ́, ó dájú pé Jèhófà máa “fi okun rẹ̀ hàn” nítorí rẹ.
18. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn èèyàn kò mọyì rẹ, kí ló yẹ kó o máa rántí nípa Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
18 Ọlọ́run fẹ́ ká “máa wá ohun rere,” ká “nífẹ̀ẹ́ ohun rere,” ká sì “máa ṣe ohun rere” kó bàa lè “fi ojú rere hàn” sí wa. (Ámósì 5:14, 15; 1 Pét. 3:11, 12) Jèhófà máa ń kíyè sí àwọn olódodo, ó sì máa ń bù kún wọn. (Sm. 34:15) Ìwọ wo àpẹẹrẹ Ṣífúrà àti Púà tí wọ́n jẹ́ agbẹ̀bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lóko ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì, àwọn obìnrin méjì yìí bẹ̀rù Ọlọ́run ju Fáráò lọ, wọn ò ṣe ohun tí Fáráò sọ pé kí wọ́n ṣe pé kí wọ́n pa àwọn ọmọkùnrin Júù lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbẹ̀bí wọn. Ó dájú pé wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, torí náà ni ẹ̀rí ọkàn wọn ṣe sún wọn láti dá ẹ̀mí àwọn ọmọ jòjòló náà sí. Ọlọ́run wá fún Ṣífúrà àti Púà ní ìdílé tiwọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (Ẹ́kís. 1:15-17, 20, 21) Jèhófà kíyè sí iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè máa ronú pé kò sẹ́ni tó bìkítà nípa ohun rere tá à ń ṣe. Àmọ́ Jèhófà bìkítà. Ó kíyè sí gbogbo rere tá a ti ṣe, ó sì máa san wá lẹ́san rere.—Mát. 6:4, 6; 1 Tím. 5:25; Héb. 6:10.
19. Báwo ni arábìnrin kan ṣe wá mọ̀ pé Jèhófà kíyè sí rere tí òun ṣe?
19 Ní orílẹ̀-èdè Austria, arábìnrin kan wá mọ̀ pé Ọlọ́run tó jẹ́ arínúróde rí i bí òun ṣe ń ṣiṣẹ́ kárakára. Ọmọ orílẹ̀-èdè Hungary gangan ni arábìnrin náà, wọ́n fún un ní àdírẹ́sì ọmọ ìlú rẹ̀ kan tó fẹ́ kí àwa Ẹlẹ́rìí wá máa wàásù fún òun. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló wá ilé náà lọ, àmọ́ kò bá ẹnikẹ́ni nílé. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì pa dà lọ sílé náà. Láwọn ìgbà míì, ó máa ń ṣe é bíi pé ẹnì kan wà nínú ilé náà, àmọ́ onítọ̀hún kò dá a lóhùn. Ó máa ń fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, á kọ lẹ́tà, àdírẹ́sì ilé tirẹ̀, tẹlifóònù àtàwọn nǹkan míì tẹ́ni náà á lè fi kàn sí i. Lẹ́yìn ọdún kan àtààbọ̀ tó ti ń pààrà ilé náà, wọ́n jàjà ṣílẹ̀kùn! Obìnrin kan tí ara rẹ̀ yá mọ́ni jáde, ó kí arábìnrin wa, ó sì sọ fún un pé: “Ẹ wọlé. Gbogbo ìwé tẹ́ ẹ kó sílẹ̀ ni mo kà, mo sì ti ń rétí yín.” Ìtọ́jú oníkẹ́míkà, tí wọ́n sábà máa ń fún àwọn tó ní àrùn jẹjẹrẹ tí obìnrin náà ń gbà ní kò jẹ́ kó lágbára láti gbàlejò. Ká tó wí ká tó fọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó dájú pé Ọlọ́run san arábìnrin wa lẹ́san gbogbo ìsapá tó ṣe taápọntaápọn!
20. Báwo ló ṣe rí lára rẹ pé Jèhófà ń fìfẹ́ ṣọ́ ẹ?
20 Gbogbo ohun tó ò ń ṣe pátá ni Jèhófà ń rí, ó sì máa san ẹ́ lẹ́san bópẹ́bóyá. Tó bá wá sí ẹ lọ́kàn pé ojú Ọlọ́run ń wò ẹ́, má ṣe rò pé ṣe ló ń ṣọ́ ẹ bíi tàwọn kámẹ́rà tí wọ́n fi ń ṣọ́ni lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí mímọ̀ tó o mọ̀ pé Jèhófà ń ṣọ́ ẹ mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tó dìídì nífẹ̀ẹ́ rẹ, tí ọ̀rọ̀ rẹ sì jẹ lógún!
a Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Klein wà nínú Ile-Iṣọ Naa ti April 15, 1985.