Àwọn Mẹ́ta Tó Wá Òtítọ́ Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Kẹrìndínlógún—Kí Ni Wọ́n Rí?
“KÍ ni òtítọ́?” Ìbéèrè yìí ni Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà Róòmù tó ń ṣàkóso ní Jùdíà béèrè lọ́wọ́ Jésù nígbà tó ń jẹ́jọ́ níwájú rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Jòhánù 18:38) Kì í ṣe pé Pílátù fẹ́ mọ òtítọ́ ló fi béèrè ọ̀rọ̀ yìí lọ́wọ́ Jésù, ó kàn ń ṣiyè méjì ni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Pílátù gbà ni pé ohun tẹ́nì kan bá yàn tàbí tí wọ́n kọ́ ọ láti gbà gbọ́ ni ohun tó bọ́gbọ́n mu. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lára ọ̀pọ̀ lónìí náà nìyẹn, lójú wọn kò sọ́nà tá a fi lè mọ ohun tó jóòtọ́ ní pàtó.
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nílẹ̀ Yúróòpù kò mọ ohun tó yẹ kí wọ́n gbà pé ó jẹ́ òtítọ́. Láti kékeré ni wọ́n ti fi kọ́ wọn pé póòpù ló láṣẹ jù àti pé gbogbo ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ló tọ̀nà. Nígbá náà lọ́hùn-ún, àwọn èèyàn ti ń gbọ́ ónírúurú ẹ̀kọ́ tuntun látọ̀dọ̀ àwọn Alátùn-unṣe Ìsìn, ìyẹn àwọn tó tako ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, àwọn ẹ̀kọ́ yìí sì ń jà ràn-ìn ní ilẹ̀ Yúróòpù. Èwo ni wọ́n máa gbà gbọ́ báyìí? Báwo sì ni wọ́n ṣe máa mọ èyí tó jóòtọ́?
Ní àkókò yìí, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í wá òtítọ́. Lára wọn ni àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan tó pinnu láti mọ ohun tó jẹ́ òótọ́.a Báwo ni wọ́n ṣe máa mọ ìyàtọ̀ láàárín òtítọ́ àti èké? Kí sì ni wọ́n rí? Ẹ jẹ́ ká gbé wọn yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.
“Ẹ JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN . . . JỌBA NÍNÚ Ẹ̀KỌ́ ÌSÌN”
Ẹni àkọ́kọ́ nínú wọn ni ọ̀dọ́kùnrin kan tó fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn, orúkọ rẹ̀ ni Wolfgang Capito. Ó gboyè jáde gẹ́gẹ́ bí dókítà àti amòfin, ó sì tún lọ kẹ́kọ̀ọ́ ìsìn. Ní ọdún 1512, ọ̀gbẹ́ni Capito di àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, lẹ́yìn ìgbà náà ló tún sìn lọ́dọ̀ bíṣọ́ọ̀bù àgbà ní ìlú Mainz.
Nígbà kan, òun náà lòdì sí àwọn ẹgbẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn tó ń wàásù ohun tó yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Àmọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fara mọ́ èrò àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn náà. Kí ló wá ṣe? Òpìtàn kan tó ń jẹ́ James M. Kittelson sọ́ ohun to ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n béèrè ohun tí Capito rò nípa àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì, Capito gbà pé “ìwé kan ṣoṣo tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeé gbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n lè fi mọ̀ bóyá àwọn ẹ̀kọ́ wa jẹ́ òótọ́ ni Bíbélì.” Ohun tí ọ̀gbẹ́ni Capito wá fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé ẹ̀kọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi ń kọ́ni pé búrẹ́dì àti wáìnì máa ń para dà di ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi nígbà oúnjẹ alẹ́ Olúwa kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Ó tún sọ pé jíjúbà àwọn ẹni mímọ́ kò tọ̀nà. (Wo àpótí náà ‘Wòó Bóyá Bẹ́ẹ̀ Ni Nǹkan Wọ̀nyí Rí.’) Lọ́dùn 1523, ọ̀gbẹ́ni Capito fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún bíṣọ́ọ̀bù àgbà, ó sì kó lọ sí ìlú táwọn alátùn-únṣe ìsìn pọ̀ sí nígbà náà.
Ilé rẹ̀ tó wà ní Strasbourg wá di ibi tí àwọn míì tí kò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ti ń pàdé láti jíròrò àwọn ọ̀ràn tó bá jẹ́ mọ́ ẹ̀sìn àti àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára wọn ṣì ń gbé ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan lárugẹ, síbẹ̀ nígbà tí ìwé The Radical Reformation sọ nípa àwọn ìwé tí Capito kọ, ó ní “kò sọ ohun tó gbà gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan” torí pé ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tó ń jẹ́ Michael Servetus ti fi Bíbélì ṣàlàyé bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ṣe tako Ìwé Mímọ́.b
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, wọ́n máa ń fi ìyà burúkú jẹ ẹni tí kò bá gba ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan, torí ẹ̀ ni Capito kò fi sọ ohun tó gbà gbọ́ ní gbangba. Síbẹ́, àwọn ìwé tó kọ fi hàn pé kó tó pàdé ọ̀gbẹ́ni Servetus ni kò ti fi taratara gba ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan gbọ́. Àlùfáà ìjọ Kátólíìkì kan sọ nípa Capito àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Wọ́n máa ń pàdé ní ìkọ̀kọ̀ láti jíròrò àwọn nǹkan àdììtú tó wà nínú ẹ̀sìn àti ní pàtàkì ọ̀ràn Mẹ́talọ́kan tí ṣọ́ọ̀ṣì kà sí Mímọ́ jù lọ.” Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kan lẹ́yìn ìgbà náà, ọ̀gbẹ́ni Capito ni orúkọ rẹ̀ kọ́kọ́ fara han lára àwọn òǹkọ̀wé tó gbajúmọ̀ tó ta ko ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan.
Capito gbà gbọ́ pé Bíbélì ni orísun òtítọ́. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti òfin Jésù jọba nínú ẹ̀kọ́ ìsìn.” Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Kittelson ṣe sọ, Capito gbà pé “àìka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ló fà á tí ẹnu àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ò fi kò.”
Irú ìtara yìí ní ọ̀dọ́kùnrin kan tó gbé lọ́dọ̀ Capito lọ́dún 1526 ní. Orúkọ rẹ̀ ni Martin Cellarius (táwọn míì mọ̀ sí Martin Borrhaus), ó sì wu òun náà láti ní ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.
“ÌMỌ̀ ỌLỌ́RUN TÒÓTỌ́”
Wọ́n bí ọ̀gbẹ́ni Cellarius ní ọdún 1499, ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ìsìn, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ọgbọ́n orí, lẹ́yìn náà ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní ìlú Wittenberg lórílẹ̀-èdè Jámánì. Ìlú Wittenberg tó ń gbé yìí ni Àtúnṣe Ìsìn ti bẹ̀rẹ̀, bí òun náà ṣe di ojúlùmọ̀ Martin Luther àtàwọn míì tó fẹ́ ṣàtúnṣe sí àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì nìyẹn. Báwo ni ọ̀gbẹ́ni Cellarius ṣe máa mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọgbọ́n orí èèyàn àti ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì?
Ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Teaching the Reformation sọ pé ọ̀gbẹ́ni Cellarius gbà pé téèyàn bá fẹ́ lóye Bíbélì dáadáa, “ó gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, kó máa fi àwọn ẹsẹ Bíbélì wéra lọ́kan-ò-jọ̀kan, kó máa gbàdúrà, kó sì máa tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.” Kí ni ohun tó rí nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Ní oṣù July ọdún 1527, ọ̀gbẹ́ni Cellarius ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìwádìí tó ṣe sínú ìwé tó pè ní On the Works of God. Ó sọ pé ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì fi kọ́ni pé búrẹ́dì àti wáìnì máa ń di ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù nígbà oúnjẹ alẹ́ olúwa kò rí bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Robin Barnes ṣe sọ, ìwé tí Cellarius kọ tún “ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì níbi tó ti sọ pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí ìyọnu àjálù àti ìyà máa dé bá gbogbo ayé lápapọ̀, lẹ́yìn náà, àtúnṣe á bá gbogbo àgbáyé.”—2 Pétérù 3:10-13.
Apá kan tó gba àfiyèsí lára iṣẹ́ rẹ̀ ni ohun tó sọ nípa ẹni tí Jésù Kristi jẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ta ko ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ní tààràtà, síbẹ̀ ọ̀gbẹ́ni Cellarius sọ pé ìyàtọ̀ wà láàárín “Baba wa Ọ̀run” àti “Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀,” ó wá kọ̀wé pé, Jésù jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́run àti àwọn ọmọ Ọlọ́run olódùmarè.—Jòhánù 10:34, 35.
Nínú ìwé kan tí Robert Wallace kọ lọ́dún 1850, èyí tó pè ní Antitrinitarian Biography, ó sọ pé àwọn ìwé tí Cellarius kọ yàtọ̀ sí àwọn èyí tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún tó jẹ́ pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ni wọ́n gbé lárugẹ.c Èyí ló mú kí àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀gbẹ́ni Cellarius kò gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́. Kódà, wọ́n pè é ní ọ̀kan lára àwọn tí Ọlọ́run lò láti “fi ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ àti ti Kristi kọ́ àwọn èèyàn.”
Ó RÈTÍ PÉ ṢỌ́Ọ̀ṢÌ MÁA PA DÀ BỌ̀ SÍPÒ
Ní nǹkan bí ọdún 1527, ìlú Wittenberg ni ọ̀gbẹ́ni kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsìn tó ń jẹ́ Johannes Campanus ń gbé, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀mọ̀wé tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ tì sẹ́yìn nígbà yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn alátùn-únṣe ìsìn ló ń gbé, ẹ̀kọ́ tí Martin Luther ń kọ́ àwọn èèyàn kò tẹ́ ẹ lọ́rùn rárá. Kí nìdí?
Ọ̀gbẹ́ni Campanus kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tó sọ pé búrẹ́dì àti wáìnì máa ń para dà di ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù nígbà oúnjẹ alẹ́ Olúwa tàbí pé ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù ló wà nínú búrẹ́dì àti wáìnì náà.d Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé náà André Séguenny ṣe sọ, ọ̀gbẹ́ni Campanus gbà gbọ́ pé “Búrẹ́dì ni búrẹ́dì n jẹ́, àmọ́ tó bá di ìgbà oùnjẹ alẹ́ Olúwa, ńṣe ni Búrẹ́dù náà ń ṣàpẹẹrẹ ẹran ara Kristi.” Ní ìpàdé kan tí wọ́n ṣe ní Marburg lọ́dún 1529 níbi tí wọ́n ti jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ náà, wọn ò gba ọ̀gbẹ́ni Campanus láyè láti sọ ohun tó ti kọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Látìgbà yẹn làwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Wittenberg kò ti gba tiẹ̀ mọ́.
Ohun tó tiẹ̀ bí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú jù lọ ni ohun tó sọ nípa Baba, Ọmọ àti ẹmi mímọ́. Nínú ìwé Restitution tó kọ lọ́dún 1532, ọ̀gbẹ́ni Campanus sọ pé ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù àti Baba rẹ̀. Ó ṣàlàyé pé Baba àti Ọmọ “jẹ́ ọ̀kan” bí ìgbà tí a bá sọ pé ọkọ àti ìyàwó jẹ́ “ara kan,” síbẹ̀ ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà ní ìṣọ̀kan ni wọ́n. (Jòhánù 10:30; Mátíù 19:5) Ọ̀gbẹ́ni Campanus ṣàkíyèsí pé Ìwé Mímọ́ lo àpèjúwe kan-náà láti fi hàn pé Baba ní ọlá àṣẹ lórí Ọmọ nígbà tó sọ pé: “Orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 11:3.
Kí ni Campanus wá sọ nípa ẹ̀mí mímọ́? Ó fi Bíbélì ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn pé: “Kò sí ibì kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kẹta . . . Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run jẹ́ ipa ìṣiṣẹ́ rẹ̀ ní ti pé òun ni Ọlọ́run máa ń lò láti fi ṣe àwọn nǹkan.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:2.
Luther pe Campanus ní asọ̀rọ̀ òdì àti ọ̀tá Ọmọ Ọlọ́run. Ọ̀kan lára àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tiẹ̀ sọ pé kí wọ́n yẹgi fún un. Síbẹ̀, kò jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun. Ìwé náà, The Radical Reformation sọ pé “Ó dá Campanus lójú pé wọn kò lóye ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni tí àwọn àpọ́sítélì náà sì gbà gbọ́ ìyẹn ni pé, Ọlọ́run kì í ṣe apá kan Ọlọrun ẹlẹ́ni mẹ́ta, èyí ló fàá tí ṣọ́ọ̀ṣì fi kùnà.”
Kò wá sí ọ̀gbẹ́ni Campanus lọ́kàn rí láti dá àwùjọ ẹ̀sìn kan sílẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìsapá láti wá òtítọ́, ó sọ pé kò sí òtítọ́ “láàárín onírúurú ẹ̀ya ẹ̀sìn àti àwọn tó ń tako ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì.” Ohun tó rò ni pé kí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì máa tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Kristẹni tòótọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì. Níkẹyìn àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gbá ọ̀gbẹ́ni Campanus mú, wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n fún ohun tó lé ní ogún [20] ọdún. Àwọn òpìtàn gbà pé ó kú ní nǹkan bí ọdún 1575.
“Ẹ MÁA WÁDÌÍ OHUN GBOGBO DÁJÚ”
Ohun tó ran Capito, Cellarius, Campanus àti àwọn míì lọ́wọ́ láti mọ ìyàtọ̀ láàárìn òtítọ́ àti èké ni pé wọ́n fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo èrò wọn ló bá Bíbélì mu, síbẹ̀ àwọn ọkùnrin tó ń wá òtítọ́ yìí fi ìrẹ̀lẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí wọ́n ṣàwárí.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá gba àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.” (1 Tẹsalóníkà 5:21) Kó o lè túbọ̀ lóye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì dáadáa, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ìwé kan tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ìwé náà ní àkòrí tó bá a mu wẹ́kú, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
a Wo Ilé Ìṣọ́ January 15, 2012 ojú ìwé 7 sí 8, ìpinrọ̀ 14 sí 17. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
b Wo àpilẹ̀kọ́ náà, “Michael Servetus—A Solitary Quest for the Truth,” tó wà nínú Jí! May 2006 lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
c Ìwé yìí sọ nípa ọ̀rọ̀ tí ọ̀gbẹ́ni Cellarius lò, ìyẹn “ọlọ́run” nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jésú, ó sọ pé: “Lẹ́tà kékeré ni ó fi bẹ̀rẹ̀, ìyẹn deus, kì í ṣe lẹ́tà ńlá. Lẹ́tà ńlá ló máa ń fi bẹ̀rẹ̀ Deus nígbàkúùgbà tó bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run Olódùmarè.”
d Ọ̀gbẹ́ni Luther ló pilẹ̀ ẹ̀kọ́ náà pé ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù “ló wà nínú” búrẹ́dì àti wáìnì nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.