“Nífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ara Rẹ”
“[Òfin] èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’” —MÁT. 22:39.
1, 2. (a) Kí ni Jésù sọ pé ó jẹ́ àṣẹ kejì tó tóbi jù lọ nínú Òfin? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò báyìí?
FARISÍ kan fẹ́ láti dán Jésù wò, ó wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olùkọ́, èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin?” Bí a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, Jésù dá a lóhùn pé “àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní” ni pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” Jésù wá fi kún un pé: “Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’”—Mát. 22:34-39.
2 Jésù sọ pé ká fẹ́ràn aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa. Torí náà, ó dára ká bi ara wa pé: Ta ni aládùúgbò wa ní tòótọ́? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa?
TA NI ALÁDÙÚGBÒ WA NÍ TÒÓTỌ́?
3, 4. (a) Àpèjúwe wo ni Jésù fi dáhùn ìbéèrè náà pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi”? (b) Báwo ni ará Samáríà náà ṣe ṣèrànwọ́ fún ọkùnrin tí àwọn ọlọ́ṣà bọ́ láṣọ, tí wọ́n lù, tí wọ́n sì fi sílẹ̀ láìkú tán? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
3 A lè máa rò pé ẹni tó ń gbé nítòsí wa, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́, tó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ ni aládùúgbò wa. (Òwe 27:10) Ṣùgbọ́n ronú lórí ohun tí Jésù sọ nígbà tí ọkùnrin kan tó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Jésù wá dá a lóhùn nípa sísọ ìtàn ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere. (Ka Lúùkù 10:29-37.) A lè retí pé nígbà tí àlùfáà kan àti ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì rí ọkùnrin kan tí àwọn ọlọ́ṣà bọ́ láṣọ, tí wọ́n lù, tí wọ́n sì fi sílẹ̀ láìkú tán, ńṣe ló yẹ kí wọ́n hùwà tó fi hàn pé aládùúgbò rere ni wọ́n. Àmọ́, wọ́n kọjá lára rẹ̀ láìṣe ìrànlọ́wọ́ kankan fún un. Ará Samáríà kan ló wá ran ọkùnrin náà lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn Júù kórìíra àwọn ará Samáríà yìí gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún Òfin Mósè.—Jòh. 4:9.
4 Kí wá ni ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere náà ṣe láti ran ọkùnrin náà lọ́wọ́? Ó da òróró àti wáìnì sí ojú ọgbẹ́ ọkùnrin tí wọ́n ṣe léṣe náà kí ojú ọgbẹ́ rẹ̀ bàa lè san. Ó fún olùtọ́jú ilé èrò náà ní owó dínárì méjì, ìyẹn sì jẹ́ owó iṣẹ́ ọjọ́ méjì gbáko. (Mát. 20:2) Torí náà, ó rọrùn láti rí ẹni tó jẹ́ aládùúgbò rere fún ọkùnrin tí wọ́n ṣe léṣe náà. Ó dájú pé àpèjúwe tí Jésù ṣe yìí kọ́ wa pé ká máa ṣàánú fún àwọn aládùúgbò wa ká sì máa fìfẹ́ hàn sí wọn.
5. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn nígbà ìjábá kan tó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí?
5 Ó sábà máa ń ṣòro láti rí àwọn aláàánú èèyàn tí wọ́n dà bí ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere náà. Ó sì túbọ̀ ń ṣòro, pàápàá jù lọ ní àwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” lílekoko yìí táwọn èèyàn ti di aláìní ìfẹ́ni àdánidá, òǹrorò àti aláìní ìfẹ́ ohun rere. (2 Tím. 3:1-3) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ipò lílekoko lè wáyé nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Hurricane Sandy jà ní ìlú New York City lọ́wọ́ ìparí oṣù October ní ọdún 2012. Ní apá ibì kan tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ tó pọ̀, ojú pọ́n àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ torí pé ìjì náà ti ba iná mànàmáná wọn, ohun tó lè múlé móoru àtàwọn nǹkan kòṣeémánìí mìíràn jẹ́. Láìka gbogbo ìyẹn sí, ńṣe làwọn jàǹdùkú bẹ̀rẹ̀ sí í jí ẹrù àwọn èèyàn náà kó. Ní àdúgbò yẹn kan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ètò kan tó mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ran ara wọn àtàwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ohun tó sì ń mú káwọn Kristẹni máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wọn. Àwọn ọ̀nà míì wo la lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa?
BÁ A ṢE LÈ FI HÀN PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ ALÁDÙÚGBÒ WA
6. Báwo la ṣe ń tipasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù wa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa?
6 Ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọ̀nà tá à ń gbà ṣe èyí ni pé a máa ń sapá láti mú kí àwọn èèyàn rí “ìtùnú [gbà] láti inú Ìwé Mímọ́.” (Róòmù 15:4) Kò sí iyè méjì pé aládùúgbò rere la jẹ́ bá a ṣe ń fi Bíbélì wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí. (Mát. 24:14) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó wá látọ̀dọ̀ “Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìrètí”!—Róòmù 15:13.
7. Kí ni Ìlànà Pàtàkì náà? Ìbùkún wo la máa rí gbà tá a bá fi í sílò?
7 Máa fi Ìlànà Pàtàkì náà sílò. Nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Orí Òkè ló ti mẹ́nu kan Ìlànà Pàtàkì náà, èyí táwọn kan ń pè ní Òfin Oníwúrà. Ó ní: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn; ní tòótọ́, èyí ni ohun tí Òfin àti àwọn Wòlíì túmọ̀ sí.” (Mát. 7:12) Tá a bá ń tẹ̀ lé ohun tí Jésù sọ yìí nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn, ó fi hàn pé à ń fi ẹ̀kọ́ tó wà nínú “Òfin,” sílò (ìyẹn àwọn àkọsílẹ̀ tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sí Diutarónómì) àtèyí tó wà nínú “àwọn Wòlíì,” (ìyẹn ìwé táwọn wòlíì kọ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù). Ó ṣe kedere látinú ohun tí àwọn ìwé yìí sọ pé Ọlọ́run máa ń bù kún fún àwọn tó bá fìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ nípasẹ̀ Aísáyà pé: “Ẹ pa ìdájọ́ òdodo mọ́, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí í ṣe òdodo . . . Aláyọ̀ ni ẹni . . . tí ń ṣe èyí.” (Aísá. 56:1, 2) Ó dájú pé Jèhófà ń bù kún wa torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa, a sì ń ṣe ohun tó tọ́ sí wọn.
8. Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa, kí ló sì lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?
8 Nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ. Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ, kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé: Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mát. 5:43-45) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ ohun tó jọ èyí nígbà tó wí pé: “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu.” (Róòmù 12:20; Òwe 25:21) Bí Òfin Mósè ṣe sọ, béèyàn bá rí i tí ẹran ẹni tó múni lọ́tàá ṣubú tó sì wà lábẹ́ ẹrù tí ó gbé, èèyàn gbọ́dọ̀ tú irú ẹran bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. (Ẹ́kís. 23:5) Bí àwọn tó jẹ́ ọ̀tá ara wọn tẹ́lẹ̀ bá ran ara wọn lọ́wọ́ lọ́nà yìí, ó ṣeé ṣe kí wọ́n di ọ̀rẹ́ ara wọn. Torí pé àwa Kristẹni máa ń fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, inú ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń bá wa ṣọ̀tá tẹ́lẹ̀ ti wá rọ̀. Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó tí àwọn tó mú wa lọ́tàá, tó fi mọ́ àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wa lójú méjèèjì, bá wá sínú òtítọ́ torí pé a fìfẹ́ hàn sí wọn!
9. Kí ni Jésù sọ nípa bá a ṣe lè máa wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa?
9 “Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Héb. 12:14) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ò yọ àwọn ará wa sílẹ̀. Torí ó sọ pé: “Bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” (Mát. 5:23, 24) Ọlọ́run máa bù kún wa tá a bá ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ará wa, tá a sì ń tètè ṣe ohun táá mú kí àlàáfíà jọba láàárín wa.
10. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ alárìíwísí?
10 Má ṣe jẹ́ alárìíwísí. Jésù sọ pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́; àti òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n fún yín. Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ? Tàbí báwo ni ìwọ ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Yọ̀ǹda fún mi láti yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú rẹ’; nígbà tí, wò ó! igi ìrólé kan ń bẹ nínú ojú ìwọ fúnra rẹ? Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì ríran kedere ní ti bí o ṣe lè yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.” (Mát. 7:1-5) Ẹ ò rí i pé àpèjúwe yẹn bá a mú gan-an. Ó sì jẹ́ ọ̀nà tí Jésù ń gbà sọ fún wa pé kò yẹ́ ká jẹ́ arítẹni-mọ̀-ọ́n-wí tó ń fi àpáàdì jàn-ànràn bo tiẹ̀ mọ́lẹ̀!
Ọ̀NÀ TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀ TÁ A LÈ GBÀ FÌFẸ́ HÀN SÍ ÀWỌN ALÁDÙÚGBÒ WA
11, 12. Ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo la lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa?
11 Ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kan wà tá a fẹ́ gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. Bíi ti Jésù, àwa náà ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 8:1) Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:19, 20) Bá a ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ yẹn, à ń sapá láti ran àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè kúrò lójú ọ̀nà fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò tó lọ sínú ìparun kí wọ́n sì bọ́ sójú ọ̀nà híhá tó lọ sínú ìyè. (Mát. 7:13, 14) Ó dájú pé Jèhófà máa ń bù kún irú ìsapá bẹ́ẹ̀.
12 Bíi ti Jésù, à ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí àìní wọn nípa tẹ̀mí lè máa jẹ wọ́n lọ́kàn. (Mát. 5:3) Tá a bá ti rí àwọn tó ṣe tán láti gbọ́rọ̀ wa, a máa ń ṣe ipa tiwa láti mú kí wọ́n gbọ́ “ìhìn rere Ọlọ́run.” (Róòmù 1:1) Ńṣe ni àwọn tó bá tẹ́tí gbọ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run máa ń pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ Jésù Kristi. (2 Kọ́r. 5:18, 19) Torí náà, bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere, ńṣe là ń fi hàn lọ́nà tó ṣe pàtàkì gan-an pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa.
13. Báwo ló ṣe ń rí lára rẹ pé ò ń lọ́wọ́ nínú pípolongo Ìjọba Ọlọ́run?
13 Bá a ṣe ń ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó jáfáfá, inú wa ń dùn pé à ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti máa fi àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run ṣèwà hù. Èyí lè mú kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà pátápátá. (1 Kọ́r. 6:9-11) Inú wa ń dùn gan-an láti rí bí Ọlọ́run ṣe ń ran àwọn ‘tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun’ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ kí wọ́n sì wá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (Ìṣe 13:48) Ọ̀pọ̀ lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ló jẹ́ pé ìdùnnú ti dípò àìnírètí fún wọn, ìgbọ́kànlé nínú Baba wa ọ̀run sì ti dípò àníyàn ṣíṣe. Ẹ sì wo bí inú wa ṣe máa ń dùn tó nígbà tí àwọn ẹni tuntun bá ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí! Ṣé ìwọ náà gbà pé, gẹ́gẹ́ bí olùpolongo Ìjọba Ọlọ́run, ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún wa láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa lọ́nà pàtàkì yìí?
Ọ̀NÀ TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ KÁ GBÀ MÁA FÌFẸ́ HÀN
14. Lọ́rọ̀ ara rẹ, sọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí ìwé 1 Kọ́ríńtì 13:4-8 sọ nípa ìfẹ́.
14 Tá a bá ń fi àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìfẹ́ sílò nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wa, a máa yẹra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro, a máa láyọ̀, ìbùkún Ọlọ́run á sì jẹ́ tiwa. (Ka 1 Kọ́ríńtì 13:4-8.) Ní ṣókí, ẹ jẹ́ ká ṣe àyẹ̀wò ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìfẹ́ ká sì rí bá a ṣe lè fi àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò nínú àjọṣe wa pẹ̀lú aládùúgbò wa.
15. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìpamọ́ra ká sì tún máa fi inúure hàn? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa jowú ká sì máa fọ́nnu?
15 “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere.” Bí Ọlọ́run ṣe máa ń fi ìpamọ́ra, tàbí sùúrù àti inúure hàn nínú bó ṣe ń bá àwa èèyàn aláìpé lò, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kí àwa náà máa ní sùúrù ká sì tún máa fi inúure hàn nígbà táwọn míì bá ṣe àṣìṣe, tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí tí wọ́n bá tiẹ̀ hùwà tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn. “Ìfẹ́ kì í jowú,” torí náà tá a bá ní ojúlówó ìfẹ́ a ò ní máa ṣojú kòkòrò sí ohun ìní àwọn ẹlòmíì tàbí àǹfààní tí wọ́n ní nínú ìjọ. Síwájú sí i, tá a bá ní ìfẹ́, a ò ní máa fọ́nnu, ìgbéraga ò sì ní wọ̀ wá lẹ́wù. Ó ṣe tán, “ojú ìrera àti ọkàn-àyà ìṣefọ́nńté, fìtílà àwọn ẹni burúkú, ẹ̀ṣẹ̀ ni.”—Òwe 21:4.
16, 17. Báwo la ṣe lè máa hùwà tó bá ọ̀rọ̀ inú 1 Kọ́ríńtì 13:5, 6 mu?
16 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa, a ó máa hùwà sí wọn lọ́nà tó bójú mu. A ò ní máa purọ́ fún wọn, a ò ní máa jà wọ́n lólè, a ò sì ní í ṣe ohunkóhun mìíràn tó máa mú ká rú òfin Jèhófà ká sì tẹ àwọn ìlànà rẹ̀ lójú. Ìfẹ́ ò tún ní jẹ́ ká máa mójú tó ire ara wa nìkan, kàkà bẹ́ẹ̀, a ó máa ṣe ohun tó fi hàn pé ọ̀ràn àwọn èèyàn jẹ wá lógún.—Fílí. 2:4.
17 A kì í tètè tán ojúlówó ìfẹ́ ní sùúrù, kì í sì í “kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe,” bíi pé kéèyàn ní ìwé kan tó ń kọ àkọsílẹ̀ sí táwọn èèyàn bá ti ṣe ohun tó dùn ún. (1 Tẹs. 5:15) Tá a bá ń di kùnrùngbùn, a ò lè múnú Ọlọ́run dùn. Ńṣe lọ̀rọ̀ wa á dà bí ìgbà téèyàn da epo bẹtiróò sínú iná tó ń kú lọ, ìyẹn sì lè pa àwa àti àwọn míì lára. (Léf. 19:18) Ìfẹ́ ń mú ká máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́, ṣùgbọ́n kò ní jẹ́ ká “yọ̀ lórí àìṣòdodo,” bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé wọ́n ṣàìdáa sí ẹnì kan tó kórìíra wa tàbí wọ́n yàn án jẹ.—Ka Òwe 24:17, 18.
18. Kí ni 1 Kọ́ríńtì 13:7, 8 fi kọ́ wa nípa ìfẹ́?
18 Tún wo ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ síwájú sí i nípa ìfẹ́. Ó sọ pé ìfẹ́ “a máa mú ohun gbogbo mọ́ra.” Bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá àmọ́ tó tọrọ àforíjì, ìfẹ́ á mú ká dárí jì í. Ìfẹ́ “a máa gba ohun gbogbo gbọ́,” ìyẹn ohun gbogbo tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń mú ká mọyì àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà. Ìfẹ́ “a máa retí ohun gbogbo” tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì ó sì máa ń mú ká lè sọ ìdí tá a fi nírètí fún àwọn míì. (1 Pét. 3:15) Bákan náà, a máa ń gbàdúrà a sì máa ń retí pé Ọlọ́run á kó wa yọ tá a bá bára wa nínú àwọn ipò lílekoko. Ìfẹ́ “a máa fara da ohun gbogbo,” ì báà jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn ṣẹ̀ wá ni o, ì báà jẹ́ inúnibíni, tàbí àwọn àdánwò mìíràn. Síwájú sí i, “ìfẹ́ kì í kùnà láé.” Ìdí ni pé títí láé fáàbàdà làwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn á máa fìfẹ́ hàn.
MÁA NÍFẸ̀Ẹ́ ALÁDÙÚGBÒ RẸ GẸ́GẸ́ BÍ ARA RẸ
19, 20. Ìtọ́ni inú Ìwé Mímọ́ wo láá mú ká máa bá a nìṣó láti fi ìfẹ́ hàn sí aládùúgbò wa?
19 Tá a bá ń fi ìtọ́ni inú Bíbélì sílò, àá lè máa bá a nìṣó láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn aládùúgbò wa. Gbogbo èèyàn ló yẹ ká máa fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí, kì í wulẹ̀ ṣe kìkì àwọn tá a jọ wá látinú ẹ̀yà kan náà. Ó tún yẹ ká rántí pé Jésù sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mát. 22:39) Ọlọ́run àti Kristi retí pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. Tá ò bá mọ ohun tó yẹ ká ṣe nínú ọ̀ràn kan tó da àwa àti aládùúgbò wa pọ̀, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa rí ìbùkún Jèhófà gbà, ó sì máa mú ká le máa ṣe ohun tó fi ìfẹ́ hàn.—Róòmù 8:26, 27.
20 “Ọba òfin” ni Bíbélì pe àṣẹ tó sọ pé ká fẹ́ràn aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa. (Ják. 2:8) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti mẹ́nu kan àwọn àṣẹ kan tó wà nínú Òfin Mósè, ó sọ pé: “Àṣẹ mìíràn yòówù kí ó wà, ni a ṣàkópọ̀ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yìí, èyíinì ni, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Ìfẹ́ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí aládùúgbò ẹni; nítorí náà, ìfẹ́ ni ìmúṣẹ òfin.” (Róòmù 13:8-10) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa.
21, 22. Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa?
21 Bá a ṣe ń ṣàṣàrò lórí ìdí tó fi yẹ ká máa fi ìfẹ́ hàn sí àwọn aládùúgbò wa, ó dára ká máa ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé Bàbá òun ‘ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.’ (Mát. 5:43-45) Ó yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sí àwọn aládùúgbò wa, yálà wọ́n jẹ́ olódodo tàbí aláìṣòdodo. Bí a ṣe sọ ṣáájú, ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn ni pé ká máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. Ẹ sì wo àǹfààní tí wọ́n máa rí tí wọ́n bá mọrírì ìhìn rere tọkàntọkàn tí wọ́n sì wá sínú òtítọ́!
22 Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa. Onírúurú ọ̀nà ló sì tún wà tá a lè gbà fìfẹ́ hàn sí àwọn aládùúgbò wa. Tá a bá ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò wa, ńṣe là ń fi hàn pé a mọyì ohun tí Jésù sọ lórí kókó pàtàkì yìí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, à ń mú inú Jèhófà, Baba wa ọ̀run dùn.