ÌJÍRÒRÒ LÁÀÁRÍN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ÀTI ẸNÌ KAN
Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀?—APÁ 2
Ìjíròrò tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Kọ́lá pa dà lọ sí ilé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Tádé.
ÀTÚNYẸ̀WÒ RÁŃPẸ́ NÍPA ÀLÁ NEBUKADINÉSÁRÌ
Kọ́lá: Ojú ẹ rèé, Tádé. Báwo ni nǹkan? Mo máa ń gbádùn ìjíròrò Bíbélì tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.a
Tádé: Àlàáfíà ni, ẹ ṣeun.
Kọ́lá: Inú mi dùn pé àlàáfíà ni mo bá ẹ. Níjelòó tí mo wá, a sọ̀rọ̀ nípa ìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà gbọ́ pé ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀.b Níjọ́ yẹn, a rí ẹ̀rí pàtàkì kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì orí 4. Ṣé o ṣì rántí ohun tó wà níbẹ̀?
Tádé: Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ àlá tí Nebukadinésárì Ọba lá nípa igi ńlá kan.
Kọ́lá: Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Nínú àlá náà, Nebukadinésárì rí igi ràgàjì kan tó ga dé ọ̀run. Ó wá gbọ́ tí ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàṣẹ pé kí wọ́n gé igi náà lulẹ̀, àmọ́ kí wọ́n fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀ nínú ilẹ̀. Lẹ́yìn “ìgbà méje,” igi náà yóò tún hù pa dà.c A tún jíròrò bí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe pín sọ́nà méjì. Ṣé o rántí ìmúṣẹ àkọ́kọ́?
Tádé: Bẹ́ẹ̀ ni, Nebukadinésárì fúnra rẹ̀ ló kọ́kọ́ sẹ sí lára, nígbà tí orí rẹ̀ dà rú fún ọdún méje, àbí?
Kọ́lá: Bẹ́ẹ̀ ni. Ìṣàkóso Nebukadinésárì dáwọ́ dúró nígbà tí orí rẹ̀ dà rú. Àmọ́ nínú ìmúṣẹ kejì tó gbòòrò, ìṣàkóso Ọlọ́run máa dáwọ́ dúró fún ìgbà méje. Bá a sì ṣe jíròrò ní ọjọ́sí, ìgbà méje náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jerúsálẹ́mù pa run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Látìgbà yẹn ni kò ti sí ọba lórí ilẹ̀ ayé tó ṣojú fún Jèhófà láti ṣàkóso àwọn èèyàn rẹ̀. Àmọ́ lópin ìgbà méje náà, Ọlọ́run máa yan Ọba tuntun kan láti ọ̀run tó máa ṣàkóso àwọn èèyàn rẹ̀. Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé, òpin ìgbà méje náà ló máa jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ Ìṣàkóso Ọlọ́run tó máa tọ̀run wá. A ti mọ àkókò tí ìgbà méje náà bẹ̀rẹ̀. Tá a bá lè mọ bí ìgbà méje náà ṣe gùn tó, àá lè mọ ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ gan-an. Mi ò mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ mi yé ẹ?
Tádé: Bẹ́ẹ̀ ni, kódà àtúnyẹ̀wò yìí ti jẹ́ kí n rántí àwọn nǹkan tá a jíròrò gbẹ̀yìn.
Kọ́lá: Ó dáa náà, jẹ́ ká wá wo bí ìgbà méje náà ṣe gùn tó. Èmi náà ṣẹ̀ṣẹ̀ tún kókó yìí kà ni kí n lè rántí ohun tó wà níbẹ̀ dáadáa. Àmọ́ màá gbìyànjú láti ṣàlàyé rẹ̀ fún ẹ.
Tádé: Kò burú.
ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN BẸ̀RẸ̀ NÍGBÀ TÍ ÌGBÀ MÉJE NÁÀ PARÍ
Kọ́lá: Nínú ìmúṣẹ àkọ́kọ́ tó ṣẹ sí Nebukadinésárì lára, ìgbà méje náà dúró fún ọdún méje. Àmọ́ nínú ìmúṣẹ kejì tó tan mọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ìgbà méje náà máa gùn ju ọdún méje lọ.
Tádé: Kí nìdí tẹ́ ẹ fi sọ bẹ́ẹ̀?
Kọ́lá: Rántí pé ìgbà méje náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jerúsálẹ́mù pa run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Tá a bá ka ọdún méje látìgbà yẹn, á mú wa dé ọdún 600 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ kò sóhun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún yẹn tó tan mọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Bá a sì ṣe sọ ní ọjọ́sí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ pé ìgbà méje náà ò tíì parí.
Tádé: Òótọ́ ló sọ bẹ́ẹ̀, mo ṣẹ̀ẹ̀ rántí ni.
Kọ́lá: Torí náà, ìgbà méje yẹn kì í kàn-án ṣe ọdún méje lásán, àmọ́ ó dúró fún àkókò tó gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Tádé: Báwo wá ló ṣe gùn tó?
Kọ́lá: Ìwé Ìṣípayá jẹ́ ká mọ bí ìgbà méje náà ṣe gùn tó, torí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú rẹ̀ tan mọ́ ohun tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì. Ìwé Ìṣípayá sọ pé ìgbà mẹ́ta àtààbọ̀ jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́.d Torí náà, ìgbà méje máa jẹ́ ìlọ́po méjì ìgbà mẹ́ta àtààbọ̀, èyí á fún wa ní ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọjọ́. Ǹjẹ́ àlàyé mi ń yé ẹ?
Tádé: Ó ń yé mi, àmọ́ mi ò rí bí èyí ṣe fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọdún 1914.
Kọ́lá: Ó dáa, jẹ́ ká wá so àwọn ọ̀rọ̀ náà pọ̀. Nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan, ọjọ́ kan sábà máa ń dúró fún ọdún kan.e Tá a bá lo ìlànà ọjọ́ kan fún ọdún kan, ìgbà méje náà máa jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọdún. Tá a bá wá ka ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọdún láti 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, á mú wa dé ọdún 1914.f Bá a ṣe mọ̀ pé ọdún 1914 ni ìgbà méje náà dópin nìyẹn, àkókò yẹn ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí jọba gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Kó o sì máa wò ó, láti ọdún 1914 ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tí ń ṣẹlẹ̀ láyé yìí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò jẹ́ àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.
Tádé: Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo nìyẹn?
Kọ́lá: Jésù sọ díẹ̀ nínú ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í jọba lọ́run. Àkọsílẹ̀ yẹn wà nínú ìwé Mátíù 24:7, ó ní: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.” Wàá rí i pé àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀, wà lára ohun tí Jésù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn. Mo mọ̀ pé ìwọ náà á gbà pẹ̀lú mi pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ń han aráyé léèmọ̀ láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn báyìí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Tádé: Òótọ́ pọ́ńbélé nìyẹn.
Kọ́lá: Nínú ẹsẹ yẹn kan náà, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun á máa jà nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ogun tí ìwé Ìṣípayá sọ kì í kàn-án ṣe ogun abẹ́lé lásán, àmọ́ ogun kan tó máa kárí ayé lákòókò òpin.g Ǹjẹ́ o rántí ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní jà?
Tádé: Ọdún 1914 ni, ọdún yẹn kọ́ lẹ sọ pé Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í jọba! Ó ga o, mí ò tiẹ̀ rò ó bẹ́ẹ̀ rí rárá.
Kọ́lá: Tá a bá ronú lórí àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbà méje àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn tó wà nínú Bíbélì, àá rí i pé gbogbo ẹ bára jọ. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọdún 1914 àti pé, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ ní ọdún yẹn.h
Tádé: Gbogbo ohun tẹ́ ẹ ṣàlàyé yìí ṣì rí bákan lójú mi.
Kọ́lá: Ọ̀rọ̀ ẹ yé mi dáadáa. Bí mo ṣe sọ níjelòó, ó pẹ́ díẹ̀ kí èmi náà tó lóye gbogbo àlàyé yẹn. Síbẹ̀, mo mọ̀ pé déwọ̀n ayé kan, ìjíròrò wa tí jẹ́ kó o rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé ìgbàgbọ́ wa karí Ìwé Mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò mẹ́nu kan ọdún 1914.
Tádé: Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ yín tiẹ̀ máa ń jọ mí lójú, gbogbo ohun tẹ́ ẹ bá sọ ni ẹ máa ń fi Bíbélì tì lẹ́yìn. Ọ̀rọ̀ yìí kàn fẹ́ lọ́jú díẹ̀ ni. Kí ló dé tí Ọlọ́run ò kúkú fi sọ nínú Bíbélì ní tààràtà pé ọdún 1914 ni Jésù máa bẹ̀rẹ̀ sí jọba lọ́run?
Kọ́lá: Ìbéèrè yẹn dáa gan-an. Kódà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tí Bíbélì ò fi gbogbo ẹnu ṣàlàyé tán. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ fi máa ń béèrè pé, kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí wọ́n kọ Bíbélì lọ́nà tó máa gba ìsapá kéèyàn tó lè lóye rẹ̀? Ṣé ká wá jíròrò ìbéèrè yẹn nígbà míì tí mo bá wá.
Tádé: Màá fẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ṣé àwọn ẹ̀kọ Bíbélì kan máa ń ṣe ìwọ náà ní kàyéfì? Ǹjẹ́ ó fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ àti bí ìjọsìn wa ṣe rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́tìkọ̀ láti bi ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa rẹ̀. Inú onítọ̀hùn á dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń jíròrò Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn lọ́fẹ̀ẹ́.
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà Àti Ẹnì Kan—Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀?—Apá 1” nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 2014.
c Wo Dáníẹ́lì 4:23-25.
d Wo Ìṣípayá 12:6, 14.
f Wo àtẹ náà, “Igi Inú Àlá Nebukadinésárì.”
g Wo Ìṣípayá 6:4.
h Wo orí 9 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.