“Nísinsìnyí Ẹ Jẹ́ Ènìyàn Ọlọ́run”
“Ẹ kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run.”—1 PÉT. 2:10.
1, 2. Ìyípadà wo ló wáyé ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni? Àwọn wo ló wà lára àwọn èèyàn tí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
MÁNIGBÀGBÉ ni Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni jẹ́ nínú ìtàn àwọn èèyàn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé. Ìyípadà kan tó kàmàmà wáyé. Lọ́jọ́ yẹn, Jèhófà tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ mú orílẹ̀-èdè tuntun kan jáde, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí tàbí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16) Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ látọjọ́ Ábúráhámù tí àwọn tó jẹ́ ọkùnrin láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run kò ní máa dádọ̀dọ́ mọ́ láti fi hàn pé àwọn jẹ́ èèyàn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè tuntun náà ni pé: “Ìdádọ̀dọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ti ọkàn-àyà nípasẹ̀ ẹ̀mí.”—Róòmù 2:29.
2 Àwọn tó kọ́kọ́ wà lára orílẹ̀-èdè tuntun tó jẹ́ ti Ọlọ́run yìí ni àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọgọ́rùn-ún ó lé díẹ̀ míì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi tí gbogbo wọn kóra jọ sínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 1:12-15) Àwọn yìí ni Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ lé lórí, tó mú kí wọ́n di àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí bí. (Róòmù 8:15, 16; 2 Kọ́r. 1:21) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé májẹ̀mú tuntun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, Kristi ló ṣe alárinà rẹ̀ ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. (Lúùkù 22:20; ka Hébérù 9:15.) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn wá di ara orílẹ̀-èdè tuntun tó jẹ́ ti Jèhófà, ìyẹn àwọn èèyàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn. Ẹ̀mí mímọ́ mú kí wọ́n lè wàásù ní àwọn èdè táwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tó wá sí Jerúsálẹ́mù ń sọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni wọ́n ti wá ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ tàbí Pẹ́ńtíkọ́sì táwọn Júù máa ń ṣe. Àwọn èèyàn náà gbọ́, wọ́n sì lóye “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” tí àwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí bí yìí wàásù fún wọn lédè wọn.—Ìṣe 2:1-11.
ÀWỌN ÈÈYÀN TÍ ỌLỌ́RUN ṢẸ̀ṢẸ̀ YÀN
3-5. (a) Kí ni Pétérù sọ fún àwọn Júù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì? (b) Àwọn ìgbésẹ̀ wo ní wọ́n gbé tẹ̀ léra tó mú kí orílẹ̀-èdè tuntun tó jẹ́ ti Jèhófà yìí gbòòrò sí i ní àwọn ọdún mélòó kan tí Ọlọ́run dá a sílẹ̀?
3 Àpọ́sítélì Pétérù ni Jèhófà lò pé kó múpò iwájú láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe kí wọ́n lè di ara orílẹ̀-èdè tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà, ìyẹn ìjọ Kristẹni. Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, Pétérù fi ìgboyà sọ fún àwọn Júù pé wọ́n gbọ́dọ̀ gba Jésù gbọ́ nítorí pé “Ọlọ́run fi ṣe Olúwa àti Kristi,” ìyẹn ẹni tí wọ́n “kàn mọ́ òpó igi.” Nígbà tí àwọn èrò tó pé jọ náà béèrè ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, Pétérù dáhùn pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́.” (Ìṣe 2:22, 23, 36-38) Lọ́jọ́ yẹn, èèyàn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ló dara pọ̀ mọ́ àwọn tó wà nínú orílẹ̀-èdè tuntun náà, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Ìṣe 2:41) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, iṣẹ́ ìwàásù táwọn àpọ́sítélì náà ń fi ìtara ṣe mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn máa pọ̀ sí i. (Ìṣe 6:7) Nípa bẹ́ẹ̀, orílẹ̀-èdè tuntun náà ń gbòòrò sí i.
4 Nígbà tó yá, wọ́n mú iṣẹ́ ìwàásù náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Samáríà, iṣẹ́ náà sì yọrí sí rere. Fílípì ajíhìnrere ṣèrìbọmi fún ọ̀pọ̀ nínú wọn, àmọ́ wọn ò rí ẹ̀mí mímọ́ gbà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní Jerúsálẹ́mù rán àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù sí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni ní Samáríà. Àwọn àpọ́sítélì náà “gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.” (Ìṣe 8:5, 6, 14-17) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ará Samáríà yẹn náà di àwọn tá a fi ẹ̀mí yàn, wọ́n sì di ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí.
5 Ní ọdún 36 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run tún lo Pétérù láti mú kí àwọn míì dara pọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè tuntun náà, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tó wàásù fún Kọ̀nílíù tó jẹ́ ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù àtàwọn ẹbí pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Ìṣe 10:22, 24, 34, 35) Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí Pétérù ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ . . . , ẹ̀mí mímọ́ bà lé gbogbo àwọn [tí kì í ṣe Júù] tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Àwọn olùṣòtítọ́ tí wọ́n bá Pétérù wá, tí wọ́n jẹ́ àwọn tí ó dádọ̀dọ́, sì ṣe kàyéfì, nítorí pé ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ ni a ń tú jáde sórí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú.” (Ìṣe 10:44, 45) Nípa bẹ́ẹ̀, àǹfààní ti wá ṣí sílẹ̀ fún àwọn Kèfèrí tí kò dádọ̀dọ́ láti di ara orílẹ̀-èdè tuntun náà, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí.
“ÀWỌN ÈNÌYÀN KAN FÚN ORÚKỌ RẸ̀”
6, 7. Àwọn nǹkan wo làwọn tó jẹ́ ara orílẹ̀-èdè tuntun náà ṣe tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ [Jèhófà]”? Báwo ni ibi tí wọ́n ṣe àwọn nǹkan náà dé ṣe gbòòrò tó?
6 Ní ìpàdé kan tí ìgbìmọ̀ olùdarí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni, Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn náà sọ pé: “Símíónì [Pétérù] ti ṣèròyìn ní kínníkínní bí Ọlọ́run ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.” (Ìṣe 15:14) Àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù ni àwọn èèyàn tí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn láti máa jẹ́ orúkọ rẹ̀. (Róòmù 11:25, 26a) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Pétérù sọ pé: “Ẹ kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run.” Pétérù sọ iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wọn, ó ní: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá’ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pét. 2:9, 10) Wọ́n ní láti máa kéde ìyìn Ẹni tí wọ́n ń ṣojú fún, kí wọ́n sì máa yin orúkọ rẹ̀ lógo lójú gbogbo èèyàn. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹlẹ́rìí onígboyà fún Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.
7 Bó ṣe rí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tara, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà pe àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí ní “àwọn ènìyàn tí mo ti ṣẹ̀dá fún ara mi, kí wọ́n lè máa ròyìn ìyìn mi lẹ́sẹẹsẹ.” (Aísá. 43:21) Bí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe ń túdìí àṣírí àwọn ọlọ́run èké táwọn èèyàn ń jọ́sìn nígbà yẹn, ńṣe ni wọ́n ń fìgboyà jẹ́ kí aráyé mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. (1 Tẹs. 1:9) Wọ́n ń jẹ́rìí nípa Jèhófà àti Jésù “ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8; Kól. 1:23.
8. Ìkìlọ̀ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?
8 Lára “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ [Jèhófà]” ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sì jẹ́ onígboyà. Ìgbà kan wà tó dúró níwájú àwọn kèfèrí onímọ̀ ọgbọ́n orí, tó fìgboyà jẹ́rìí fún wọn pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ, ó sọ pé, “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹni yìí ti jẹ́, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 17:18, 23-25) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi máa parí ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta, ó kìlọ̀ fún àwọn èèyàn tá a fi orúkọ Ọlọ́run pè, ó ní: “Mo mọ̀ pé lẹ́yìn lílọ mi, àwọn aninilára ìkookò yóò wọlé wá sáàárín yín, wọn kì yóò sì fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo, àti pé láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:29, 30) Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi máa parí, ìpẹ̀yìndà tá a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí ti búrẹ́kẹ́.—1 Jòh. 2:18, 19.
9. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí Bíbélì pè ní “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ [Jèhófà]” lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì?
9 Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, ìpẹ̀yìndà náà gbòde kan, èyí wá mú kí onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì sú yọ. Dípò kí àwọn Kristẹni apẹ̀yìndà yìí jẹ́ “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ [Jèhófà],” ṣe ni wọ́n tiẹ̀ yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ láti èdè kan sí òmíràn. Wọ́n mú àṣà àwọn abọ̀rìṣà wọnú ẹ̀sìn wọn, wọ́n sì tipasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ èké wọn, àwọn ogun tí wọ́n pè ní ogun mímọ́ àti ìṣekúṣe wọn tàbùkù sí Ọlọ́run. Nítorí ìdí yìí, ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ni àwọn tó ń fòótọ́ sin Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé kò fi ju kéréje lọ. Yàtọ̀ síyẹn, a ò ṣètò wọn láti jẹ́ “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀.”
ỌLỌ́RUN TÚN ÀWỌN ÈÈYÀN RẸ̀ BÍ
10, 11. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jésù sọ nínú àkàwé àlìkámà àti èpò? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ inú àkàwé Jésù ṣe ṣẹ lẹ́yìn ọdún 1914, kí ló sì yọrí sí?
10 Nínú àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti èpò, ó sàsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tá a fi wé òru, èyí tí ìpẹ̀yìndà mú kó wáyé. Ó sọ pé “nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn,” Èṣù á gbin èpò sínú pápá tí Ọmọ ènìyàn gbin irúgbìn àlìkámà sí. Irúgbìn méjèèjì yìí á dàgbà pọ̀ títí di “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Jésù ṣàlàyé pé “irúgbìn àtàtà” ṣàpẹẹrẹ “àwọn ọmọ ìjọba náà” nígbà tí “àwọn èpò” ṣàpẹẹrẹ “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà.” Lákòókò òpin, Ọmọ ènìyàn máa rán “àwọn akárúgbìn,” ìyẹn àwọn áńgẹ́lì, pé kí wọ́n ya àwọn tá a fi wé èpò kúrò lára àlìkámà. Wọ́n á sì kó àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run jọ. (Mát. 13:24-30, 36-43) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ inú àkàwé yìí ṣe ṣẹ, báwo ló sì ṣe kan níní tí Jèhófà ní àwọn èèyàn lórí ilẹ̀ ayé?
11 Ọdún 1914 ni “ìparí ètò àwọn nǹkan” bẹ̀rẹ̀. Nígbà ogun tó bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún yẹn, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ “àwọn ọmọ ìjọba náà” kò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ, wọ́n sì wà nínú ìgbèkùn tẹ̀mí lábẹ́ Bábílónì Ńlá. Lọ́dún 1919, Jèhófà dá wọn nídè, ó sì mú kí ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn àti “àwọn èpò,” ìyẹn àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà, hàn kedere. Ó kó “àwọn ọmọ Ìjọba náà” jọ pọ̀ sí àwùjọ kan, ìyẹn sì mú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ, tó sọ pé: “A ha lè bí ilẹ̀ kan pẹ̀lú ìrora ìrọbí ní ọjọ́ kan? Tàbí kẹ̀, a ha lè bí orílẹ̀-èdè kan ní ìgbà kan? Nítorí pé Síónì ti wọnú ìrora ìrọbí, ó sì ti bí àwọn ọmọ rẹ̀.” (Aísá. 66:8) Síónì, ìyẹn àpapọ̀ àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà bí àwọn ọmọ rẹ̀ tá a fẹ̀mí yàn, ó sì ṣètò wọn láti di orílẹ̀-èdè kan.
12. Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ [Jèhófà]” lóde òní?
12 Bíi tàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ “àwọn ọmọ Ìjọba náà” ní láti jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà. (Ka Aísáyà 43:1, 10, 11.) Nítorí náà, wọ́n á dá yàtọ̀ torí pé wọ́n ń hùwà tó yẹ Kristẹni, wọ́n sì ń wàásù “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run . . . láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:14; Fílí. 2:15) Lọ́nà yìí, wọ́n ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀, àní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn, wá sí òdodo lọ́dọ̀ Jèhófà.—Ka Dáníẹ́lì 12:3.
“ÀWA YÓÒ BÁ YÍN LỌ”
13, 14. Kí ni àwọn tí kì í ṣe Ísírẹ́lì tẹ̀mí gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè jọ́sìn Jèhófà kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ sìn ín lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà? Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Bíbélì sọ nípa èyí?
13 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé ní Ísírẹ́lì ayé àtijọ́, ó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè láti jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tí Jèhófà bá dá májẹ̀mú. (1 Ọba 8:41-43) Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, àwọn tí kì í ṣe ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí gbọ́dọ̀ dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n jẹ́ “àwọn ọmọ Ìjọba náà,” ìyẹn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a fẹ̀mí yàn.
14 Àwọn wòlíì ìgbàanì méjì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn á ṣe máa wọlé wá ní ọjọ́ ìkẹyìn yìí kí wọ́n lè máa sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀. Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’ Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde lọ, ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò sì jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù.” (Aísá. 2:2, 3) Lọ́nà kan náà, wòlíì Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá yóò sì wá ní ti tòótọ́ láti wá Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Jerúsálẹ́mù àti láti tu Jèhófà lójú.” Ó ṣàpèjúwe wọn pé wọ́n jẹ́ “ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” tí wọ́n di aṣọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí mú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, tí wọ́n sì ń sọ pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”—Sek. 8:20-23.
15. Ọ̀nà wo ni “àwọn àgùntàn mìíràn” gbà ń “bá” àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí “lọ”?
15 “Àwọn àgùntàn mìíràn” ń “bá” àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí “lọ” ní ti pé wọ́n ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Máàkù 13:10) Wọ́n di ara àwọn èèyàn Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró, wọ́n wá jọ di “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” náà Kristi Jésù.—Ka Jòhánù 10:14-16.
WÀÁ RÍ ÀÀBÒ LỌ́DỌ̀ ÀWỌN ÈÈYÀN JÈHÓFÀ
16. Báwo ni Jèhófà ṣe máa mú apá tó kẹ́yìn “ìpọ́njú ńlá” wá?
16 Lẹ́yìn ìparun Bábílónì Ńlá, Sátánì máa fi gbogbo agbára rẹ̀ kọ lu àwa èèyàn Jèhófà, nígbà yẹn a máa ní láti fi ara wa sábẹ́ ààbò tí Jèhófà máa pèsè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Torí pé ìkọlù yìí ló máa yọrí sí apá tó kẹ́yìn “ìpọ́njú ńlá,” Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa ṣe ohun táá ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìkọlù náà, òun ló sì máa pinnu ìgbà tó máa bẹ̀rẹ̀. (Mát. 24:21; Ìsík. 38:2-4) Nígbà yẹn, Gọ́ọ̀gù máa kọ lu “àwọn ènìyàn kan tí a kó jọpọ̀ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè,” ìyẹn àwọn èèyàn Jèhófà. (Ìsík. 38:10-12) Ìkọlù yẹn ló máa jẹ́ àmì pé àkókò ti tó tí Jèhófà máa mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí Gọ́ọ̀gù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Jèhófà máa mú kí aráyé mọ̀ pé Òun ni ọba aláṣẹ, á sì ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́, torí ó sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò . . . sọ ara mi di mímọ̀ lójú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè; wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”—Ìsík. 38:18-23.
17, 18. (a) Ìtọ́ni wo làwọn èèyàn Jèhófà máa gbà nígbà tí Gọ́ọ̀gù bá kọ lù wọ́n? (b) Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dáàbò bò wá, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
17 Nígbà tí Gọ́ọ̀gù bá bẹ̀rẹ̀ ìkọlù rẹ̀, Jèhófà máa sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Lọ, ènìyàn mi, wọnú yàrá rẹ ti inú lọ́hùn-ún, kí o sì ti ilẹ̀kùn rẹ mọ́ ara rẹ. Fi ara rẹ pa mọ́ fún kìkì ìṣẹ́jú kan títí ìdálẹ́bi yóò fi ré kọjá.” (Aísá. 26:20) Ní irú àsìkò pàtàkì yẹn, Jèhófà máa fún wa láwọn ìtọ́ni tó ń gbẹ̀mí là, ó sì ṣeé kí ‘yàrá ti inú lọ́hùn-ún’ jẹ mọ́ àwọn ìjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́.
18 Torí náà, tá a bá fẹ́ wà lábẹ́ ààbò tí Jèhófà máa pèsè nígbà ìpọ́njú ńlá, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jèhófà ní àwọn èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn àwọn èèyàn tó ṣètò ní ìjọ-ìjọ. A gbọ́dọ̀ máa wà pẹ̀lú àwọn èèyàn Jèhófà nìṣó, ká sì rí i pé à ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tá a wà déédéé. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fi gbogbo ọkàn wa sọ bí onísáàmù náà ti sọ pé: “Ìgbàlà jẹ́ ti Jèhófà. Ìbùkún rẹ wà lára àwọn ènìyàn rẹ.”—Sm. 3:8.