Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Yí Èrò Rẹ Pa Dà?
ÀWỌN ọ̀dọ́ mélòó kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni fẹ́ lọ wo fíìmù. Wọ́n gbọ́ pé àwọn ọmọ ilé ìwé àwọn gbádùn fí ìmù yẹn gan-an. Nígbà tí wọ́n dé gbọ̀ngàn tí wọ́n á ti wo fí ìmù náà, wọ́n lọ wo àwòrán tí wọ́n fi polówó fíìmù náà, wọ́n rí oríṣiríṣi àwọn ohun ìjà àti àwọn obìnrin tó wọ aṣọ tó ṣí ara sílẹ̀. Kí ni wọ́n máa ṣe? Ṣé wọ́n á wọnú gbọ̀ngàn yẹn, kí wọ́n sì wo fíìmù náà?
Ipò tí àwọn ọ̀dọ́ yìí bá ara wọn jẹ́ ká mọ̀ pé a máa ń ní láti ṣe àwọn ìpinnu tó lè ní ipa rere tàbí búburú lórí ipò tẹ̀mí wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Nígbà míì, o lè pinnu pé o fẹ́ ṣe nǹkan kan, àmọ́ nígbà tí o rò ó sọ́tùn-ún rò ó sósì, o yí èrò rẹ pa dà. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé o ò lè dá ìpinnu ṣe àbí bó o ṣe yí èrò rẹ pa dà yẹn gan-an ló tọ̀nà?
ÌGBÀ TÍ KÒ YẸ Kó O Yí Èrò Rẹ Pa Dà
Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló mú ká ya ara wa sí mímọ́ fún un, ká sì ṣèrìbọmi. Ó wù wá tọkàntọkàn láti máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Àmọ́, Sátánì Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá wa ti pinnu láti ba ìwà títọ́ wa jẹ́. (Ìṣí. 12:17) A ti pinnu pé a máa sin Jèhófà àti pé a ó máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. Ẹ ò rí i pé kò ní dáa rárá tá a bá lọ yí èrò wa pa dà lẹ́yìn tá a ti ya ara wa sí mímọ́ sí Jèhófà. Ẹ̀mí wa lè lọ sí i!
Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ọdún [2,600] sẹ́yìn, Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ṣe ère gàgàrà oníwúrà kan, ó sì pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn wólẹ̀ fún ère náà, kí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀. Ṣe ni wọ́n máa ju ẹnikẹ́ni tí kò bá jọ́sìn ère náà sínú iná ìléru. Àmọ́, àwọn mẹ́ta kan tí wọ́n ń sin Jèhófà, ìyẹn Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kò tẹrí ba fún ère náà. Torí náà, wọ́n jù wọ́n sínú iná ìléru. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kó wọn yọ lọ́nà ìyanu nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, àwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹn múra tán láti kú dípò kí wọ́n yí ìpinnu wọn láti máa jọ́sìn Ọlọ́run pa dà.—Dán. 3:1-27.
Ẹlòmíì ni wòlíì Dáníẹ́lì, kò jáwọ́ láti máa gbàdúrà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n halẹ̀ mọ́ ọn pé wọ́n máa jù ú sínú ihò kìnnìún. Ó ń bá a nìṣó láti máa gbàdúrà sí Jèhófà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń ṣe. Dáníẹ́lì kò yí ìpinnu rẹ̀ láti máa sin Jèhófà pa dà. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi kó wòlíì náà yọ ní “àtẹ́sẹ̀ àwọn kìnnìún.”—Dán. 6:1-27.
Lóde òní, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wọn ṣẹ. Ní iléèwé kan ní ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn ọmọ iléèwé kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ láti kí àsíá orílẹ̀-èdè níbi ayẹyẹ kan tí iléèwé wọn ṣe. Wọ́n halẹ̀ mọ́ wọn pé wọ́n máa lé wọn kúrò níléèwé tí wọn ò bá kí àsíá náà bí àwọn ọmọ iléèwé tó kù ṣe ń ṣe. Láìpẹ́ sígbà yẹn, alákòóso ètò ẹ̀kọ́ wá sílùú wọn, ó sì bá àwọn kan lára àwọn ọmọléèwé tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀. Àwọn ọmọ náà ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ láìbẹ̀rù. Látìgbà yẹn, wọn ò tún bá wọn fa wàhálà lórí ọ̀ràn yẹn mọ́. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin yìí ń lọ síléèwé láìsì pé wọ́n ń halẹ̀ mọ́ wọn pé kí wọ́n ṣe ohun tó máa ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.
Jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Joseph. Ìyàwó rẹ̀ ní àrùn jẹjẹrẹ, ó sì kú lójijì. Ohun tí Arákùnrin Joseph fẹ́ lórí ọ̀ràn ààtò ìsìnkú ni àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ bá a fẹ́. Àmọ́, àwọn mọ̀lẹ́bí ìyàwó rẹ̀ ò sí nínú òtítọ́, torí náà, wọ́n fẹ́ mú àwọn àṣà kan wọnú ètò ìsìnkú náà, títí kan àwọn ààtò ìsìnkú tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. Arákùnrin Joseph sọ pé: “Nígbà tí wọ́n rí i pé mi ò yí èrò mi pa dà, wọ́n gbìyànjú láti yí àwọn ọmọ mi lérò pa dà, àmọ́ àwọn ọmọ mi dúró lórí ìpinnu wọn. Wọ́n tún fẹ́ ṣe àìsùn òkú nílé mi, àmọ́ mo sọ fún pé tí wọ́n bá ní dandan làwọn máa ṣe é, kò ní jẹ́ nílé mi. Wọ́n mọ̀ pé ìyẹn ò bá ohun tí mo gbà gbọ́ mu, wọ́n sì mọ̀ pé kò bá ohun tí ìyàwó mi gbà gbọ́ mu kó tó kú. Torí náà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ atótónu wọ́n lọ ṣe é níbòmíràn.
“Mo bẹ Jèhófà lákòókò tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ mí yìí pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí ìdílé mi má bàa rú òfin rẹ̀. Ó gbọ́ àdúrà mi, ó sì jẹ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ láìka wàhálà àwọn mọ̀lẹ́bí sí.” Arákùnrin Joseph àtàwọn ọmọ rẹ̀ kò rò ó rárá pé káwọn yí èrò wọn pa dà lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn wọn sí Jèhófà.
ÌGBÀ TÍ O LÈ Yí Èrò Rẹ Pa Dà
Láìpẹ́ lẹ́yìn Ìrékọjá ní ọdún 32 Sànmánì Kristẹni, obìnrin ará Foníṣíà ti Síríà kan lọ bá Jésù Kristi ní àgbègbè Sídónì. Ó ń bẹ Jésù léraléra pé kó lé ẹ̀mí èṣù tó wà lára ọmọbìnrin òun jáde. Jésù ò kọ́kọ́ dá a lóhùn. Ó wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “A kò rán mi jáde sí ẹnikẹ́ni bí kò ṣe sí àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù.” Nígbà tó ń bẹ Jésù ṣáá, Jésù sọ pé: “Kò tọ́ kí a mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, kí a sì sọ ọ́ sí àwọn ajá kéékèèké.” Èsì tó fún Jésù fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa; ṣùgbọ́n àwọn ajá kéékèèké ní ti gidi máa ń jẹ nínú èérún tí ń jábọ́ láti orí tábìlì àwọn ọ̀gá wọn.” Jésù ṣe ohun tó fẹ́ fún un, ó mú ọmọbìnrin rẹ̀ lára dá.—Mát. 15:21-28.
Ohun tí Jésù ṣe yìí fi hàn pé ó fìwà jọ Jèhófà. Torí pé Jèhófà múra tán láti yí èrò rẹ̀ pa dà nígbà tí ipò nǹkan bá gbà bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ńṣe ni Ọlọ́run fẹ́ pa orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì run nígbà tí wọ́n ṣe ère ọmọ wúrà, àmọ́ ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Mósè, Ó sì yí ohun tó fẹ́ ṣe pa dà.—Ẹ́kís. 32:7-14.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà fìwà jọ Jèhófà àti Jésù. Nígbà kan Pọ́ọ̀lù wò ó pé kò yẹ kí Jòhánù Máàkù tẹ̀ lé àwọn lọ sí ìrìn àjò míṣọ́nnárì mọ́, torí pé Máàkù fi Pọ́ọ̀lù àti Bánábà àwọn tó kù sílẹ̀, ó sì pa dà sílé nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tí wọ́n lọ. Àmọ́, nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù rí i pé ó wu Máàkù láti ṣiṣẹ́ sìn àti pé ó máa wúlò gan-an. Torí náà, Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Mú Máàkù, kí o sì mú un wá pẹ̀lú rẹ, nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.”—2 Tím. 4:11.
Àwa ńkọ́? A lè fi hàn pé a fìwà jọ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, aláàánú àti onísùúrù, a lè rí i pé ó yẹ ká yí èrò wa pa dà. Bí àpẹẹrẹ, a lè yí irú ojú tí a fi ń wo àwọn èèyàn pa dà. Ẹni pípé ni Jèhófà àti Jésù, àmọ́ aláìpé làwa. Torí náà, bí Jèhófà àti Jésù bá ṣe tán láti yí èrò wọn pa dà, ṣé kò yẹ káwa náà máa ro nǹkan kan mọ́ àwọn èèyàn lára ká sì torí ìyẹn yí èrò wa pa dà nípa wọn?
Tá a bá ń ronú nípa àwọn àfojúsùn tẹ̀mí, ó lè jẹ́ pé ohun tó dá a jù ká ṣe ni pé ká yí èrò wa pa dà. Àwọn kan tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì ti ṣe díẹ̀ tí wọ́n ti ń wá sípàdé lè máa fi ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìrìbọmi falẹ̀. Tàbí káwọn ará kan máa lọ́ tìkọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n láǹfààní láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i lọ́nà yìí. Kì í sì í wu àwọn arákùnrin kan rárá láti nàgà fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. (1 Tím. 3:1) Ǹjẹ́ èyíkéyìí nínú àwọn ohun tá a sọ yìí kan ìwọ náà? Jèhófà ké sí ọ tìfẹ́tìfẹ́ pé kó o wá tọ́ àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí wò. Torí náà, o ò ṣe yí èrò rẹ pa dà, kí ìwọ náà lè ní irú ayọ̀ téèyàn máa ń ní tó o bá yọ̀ǹda ara rẹ fún Jèhófà tó o sì ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?
Nígbà tí Arábìnrin Ella ń sọ nípa iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ní ẹ̀ka ọ́fí ìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Áfíríkà, ó sọ pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ dé Bẹ́tẹ́lì, mi ò mọ̀ bóyá mo máa pẹ́. Ó wù mí kí n sin Jèhófà tọkàntọkàn, àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ ìdílé mi gan-an. Àárò àwọn ará ilé mi sọ mí gan-an! Àmọ́, ẹni tá a jọ ń gbé yàrá ní Bẹ́tẹ́lì gbà mí níyànjú, torí náà mo pinnu láti dúró. Lẹ́yìn tí mo lo ọdún mẹ́wàá ní Bẹ́tẹ́lì, mo wò ó pé mo fẹ́ máa wà ní Bẹ́tẹ́lì títí lọ, kí n lè máa ṣiṣẹ́ sin àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi.”
ÌGBÀ TÓ DI DANDAN Kí O Yí Èrò Rẹ Pa Dà
Ǹjẹ́ o rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kéènì nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í jowú àbúrò rẹ̀ tó sì ń bínú kíkankíkan? Ọlọ́run sọ fún ọkùnrin tí inú ń bí yìí pé tí ó bá ṣe rere òun máa ṣe ojúure sí i. Ọlọ́run kìlọ̀ fún Kéènì pé kó kápá ẹ̀ṣẹ̀ tó “lúgọ sí ẹnu ọ̀nà” dè é. Kéènì lè yí ìwà àti èrò rẹ̀ pa dà, àmọ́ ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ kọ etí dídi sí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún un. Ó ṣeni láàánú pé Kéènì pa àbúrò rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di apààyàn àkọ́kọ́!—Jẹ́n. 4:2-8.
Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ùsáyà Ọba. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀, ó ń ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà, ó sì ń wá Ọlọ́run nígbà gbogbo. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé bí Ùsáyà ṣe di onígbèéraga, ó ba orúkọ rere tó ní jẹ́. Ìgbà kan wà tó lọ sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe àlùfáà. Ǹjẹ́ ó yí èrò rẹ̀ pa dà nígbà táwọn àlùfáà kìlọ̀ fún un pé kó má ṣe hùwà ìkùgbù yìí? Rárá o, kò gbọ́. Ńṣe ni Ùsáyà “kún fún ìhónú,” kò sì gba ìkìlọ̀ tí wọ́n fún un. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mú kí ẹ̀tẹ̀ yọ sí i lára.—2 Kíró. 26:3-5, 16-20.
Ó ṣe kedere báyìí pé, àwọn ìgbà kan wà tó máa gba pé ká yí èrò wa pa dà pátápátá. Àpẹẹrẹ òde òní kan rèé. Joachim ṣèrìbọmi lọ́dún 1955, àmọ́ wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ lọ́dún 1978. Lẹ́yìn ohun tó lé ní ogún ọdún, ó ronú pìwà dà, wọ́n sì gbà á pa dà sínú ìjọ. Alàgbà kan bi í láìpẹ́ yìí pé kí nídìí tó fi jẹ́ kó pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ kó tó kọ̀wé béèrè pé kí wọ́n gba òun pa dà. Joachim dáhùn pé: “Inú ń bí mi, mo sì tún ń gbéra ga. Ó ń dùn mí gan-an pé mo jẹ́ kó pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ kí n tó pa dà. Nígbà tí wọ́n yọ mí lẹ́gbẹ́ mo mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.” Joachim ní láti yí èrò rẹ̀ pa dà kó sì ronú pìwà dà.
A lè bá ara wa ní ipò tí ó máa gba pé ká yí èrò wa pa dà, ká sì yí ìwà wa pa dà. Ǹjẹ́ ká múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀ kí Jèhófà lè ṣe ojú rere sí wa.—Sm. 34:8.