Máa Fi Ìtara Wàásù Nìṣó
IṢẸ́ wíwàásù ìhìn rere ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù tí à ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé ńṣe ni Ọlọ́run bu kún wa bá a ṣe láǹfààní láti kópa nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn fáwọn aṣáájú-ọ̀nà àti àwọn akéde láti máa fi ìtara bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn nìṣó.
Agbára káká ni àwọn akéde kan fi máa ń rẹ́ni wàásù fún tí wọ́n bá lọ wàásù láti ilé dé ilé. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ládùúgbò tí wọ́n ti lọ wàásù lè máà sí nílé. Tí wọ́n bá tún jàjà rí ẹni wàásù fún, ẹni náà lè má kọbi ara sí i tàbí kó má tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ rárá. Àwọn akéde míì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó tóbi gan-an tó sì ń méso jáde, àmọ́ wọ́n ń ṣàníyàn pé àwọn ò ní lè wàásù fún gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀. Ní ti àwọn akéde kan, wọ́n ti rẹ̀wẹ̀sì torí pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń retí pé òpin máa dé.
Ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń dojú kọ ìṣòro tó lè mú kí iná ìtara wọn máa jó rẹ̀yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu. Torí kò sí ìkankan nínú wa tó máa retí pé ó máa rọrùn láti polongo òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń mú káwọn èèyàn rí ìyè nínú ayé tí Sátánì “ẹni burúkú náà” ń ṣàkóso yìí.—1 Jòh. 5:19.
Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìṣòro yòówù kó o ní bó o ti ń polongo ìhìn rere náà, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí rẹ̀. Àmọ́, kí lo lè ṣe tí ìtara tó o ní fún iṣẹ́ ìwàásù kò fi ní jó rẹ̀yìn? Jẹ́ ká gbé àwọn àbá díẹ̀ yẹ̀ wò.
MÁA RAN ÀWỌN AKÉDE TUNTUN LỌ́WỌ́
Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń ṣèrìbọmi tí wọ́n sì ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi, o máa mọrírì rẹ̀ gan-an tí àwọn tó ti ṣèrìbọmi tipẹ́ bá ràn ẹ́ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Tó o bá sì ti di akéde Ìjọba Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó máa dáa tó o bá ń dá àwọn akéde tuntun lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, wàá sì láyọ̀ pé o ṣe bẹ́ẹ̀.
Jésù mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun gba ìtọ́sọ́nà kí wọ́n lè di òjíṣẹ́ tó dáńgájíá, torí náà ó fi bí wọ́n á ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà hàn wọ́n. (Lúùkù 8:1) Bákan náà lónìí, ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́ àwọn mìíràn káwọn náà lè di òjíṣẹ́ tó dáńgájíá.
Kò yẹ ká kàn rò pé tí akéde tuntun kan bá ṣáà ti ń lọ sóde ẹ̀rí ó máa mọ bó ṣe yẹ kó máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ fúnra rẹ̀. Akéde náà nílò ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ olùkọ́ tí ó jẹ́ onínúure àti onífẹ̀ẹ́. Lára ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí akéde tuntun yìí nílò ni bó ṣe máa (1) múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí ó lè lò sílẹ̀ kó sì fi dánra wò, (2) bó ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú onílé tàbí ẹni kan tó ń kọjá lọ, (3) bó ṣe máa fi ìwé ìròyìn lọni, (4) bó ṣe máa ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ àti (5) bó ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tí akéde tuntun yìí bá ń fiyè sí bí akéde tó ti ní ìrírí ṣe ń kọ́ni lóde ẹ̀rí tí ó sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ó máa ṣe é láǹfààní gan-an. (Lúùkù 6:40) Akéde tuntun náà máa mọrírì rẹ̀ tó bá ń rẹ́ni tẹ́tí sí i tó sì ń ràn án lọ́wọ́ nígbà tó bá nílò rẹ̀. Á sì tún ṣe é láǹfààní tá a bá ń gbóríyìn fún un tí a sì ń fún un ní ìmọ̀ràn tó máa ràn án lọ́wọ́ lóde ẹ̀rí.—Oníw. 4:9, 10.
MÁA BÁ ẸNI TÍ Ẹ JỌ ṢIṢẸ́ LÓDE Ẹ̀RÍ SỌ̀RỌ̀
O lè ti sapá gan-an kó o lè wàásù fáwọn èèyàn lóde ẹ̀rí, àmọ́ nígbà míì, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, ó lè jẹ́ ẹni tí ẹ jọ wàásù lẹ jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa. Má gbàgbé pé “méjìméjì” ni Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde. (Lúùkù 10:1) Bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, wọ́n ń gbé ara wọn ró, wọn sì ń fún ara wọn ní ìṣírí. Torí náà, àǹfààní ńlá la ní bí a ti ń ní “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” pẹ̀lú àwọn ará wa tí a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.—Róòmù 1:12.
Àwọn nǹkan wo lẹ lè jọ sọ? Ǹjẹ́ èyíkéyìí nínú yín ní ìrírí kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí tó máa fún ẹnì kejì níṣìírí? Ǹjẹ́ o rí kókó pàtàkì kan nígbà tí ò ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí nígbà ìjọsìn ìdílé? Ǹjẹ́ o gbọ́ nǹkan kan ní ìpàdé tó fún ẹ níṣìírí? Nígbà míì, ẹni tí ẹ jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí lè máà jẹ́ ẹni tí o sábà máa ń bá ṣiṣẹ́. Ǹjẹ́ o mọ bí ó ṣe rí òtítọ́? Kí ló mú kó dá ẹni náà lójú pé inú ètò Ọlọ́run ni a wà yìí? Àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wo ló ti ní tàbí ìrírí wo ló ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀? Ìwọ náà lè sọ àwọn ìrírí tó o ní. Tó o bá bá ẹnì kan ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, àǹfààní ni ìyẹn jẹ́ fún yín láti “gbé ara yín ró lẹ́nì kìíní-kejì” láìka ohun tí ẹ bá pàdé lóde ẹ̀rí sí.—1 Tẹs. 5:11.
JẸ́ KÓ MỌ́ Ẹ LÁRA LÁTI MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ DÉÉDÉÉ
Tó o bá fẹ́ máa fi ìtara bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ nìṣó, ó ṣe pàtàkì kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti tẹ ìsọfúnni jáde nípa oríṣiríṣi àkòrí. (Mát. 24:45) Torí náà, tó o bá fẹ́ máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé, àwọn àkòrí tó o lè fi ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ pọ̀ lọ jàra. Jẹ́ ká gbé kókó kan yẹ̀ wò tí o lè fi ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́. Kókó náà ni: Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì? Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16 mẹ́nu kan àwọn ìdí díẹ̀.
Tó o bá gbé àwọn kókó tó wà nínú àpótí yìí yẹ̀ wò, á mú kó o máa fi ìtara wàásù nìṣó. Nígbà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, o ò ṣe ṣèwádìí sí i kó o lè rí àwọn ìdí míì tí iṣẹ́ ìwàásù fi ṣe pàtàkì? Lẹ́yìn ìyẹn kó o wá ṣàṣàrò lórí àwọn ìdí yìí àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tì í lẹ́yìn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ máa fi ìtara wàásù.
MÚRA TÁN LÁTI LO ÀWỌN ÀBÁ TÍ ÈTÒ ỌLỌ́RUN Ń FÚN WA
Ètò Ọlọ́run máa ń fún wa ní àwọn àbá tá a lè lò tó máa mú ká sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, a lè fi lẹ́tà wàásù, a lè fi tẹlifóònù wàásù, a lè wàásù lójú pópó tàbí láwọn ibòmíì, a lè wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà àti láwọn àgbègbè táwọn èèyàn ti ń ṣe okòwò. A tún lè ṣètò láti lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé.
Ǹjẹ́ o múra tán láti gbìyànjú àwọn àbá yìí wò? Ǹjẹ́ o ti lo èyíkéyìí nínú wọn? Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti gbìyànjú àwọn àbá yìí ti rí i pé ó yọrí sí rere. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mẹ́ta yẹ̀ wò.
Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ dá lórí àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ kan nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó sọ nípa bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ April pinnu pé òun máa lo àbá yìí. Ó sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ mẹ́ta lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Ó yà á lẹ́nu pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ́n tiẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé, inú arábìnrin yìí dùn gan-an.
Àpẹẹrẹ kejì ni ti àbá tí ètò Ọlọ́run fún wa pé ká máa fi ìwé ìròyìn lọni. A rọ̀ wá pé ká wá àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àwọn àpilẹ̀kọ pàtó kan nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Alábòójútó àyíká kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé nígbà tí àpilẹ̀kọ kan jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! nípa táyà mọ́tò, òun lọ sí àwọn ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta táyà láwọn àdúgbò kan, òun sì fún àwọn máníjà tó wà ní ṣọ́ọ̀bù náà ní ìwé ìròyìn yìí. Òun àti ìyàwó rẹ̀ mú ẹ̀dà ìwé ìròyìn Jí! lédè Gẹ̀ẹ́sì tó sọ̀rọ̀ nípa dókítà àti aláìsàn lọ sí ilé ìwòsàn tí ó ju ọgọ́rùn-ún lọ ní àyíká tí wọ́n ti ń sìn. Alábòójútó àyíká náà sọ pé: “Àwọn ibi tí a lọ yìí tún jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe, kí wọ́n sì tún mọ àwọn ìtẹ̀jáde wa. Tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn sọ̀rọ̀ dáadáa, ó máa ń mú kó rọrùn fún wa láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn.”
Àpẹẹrẹ kẹta dá lórí àbá tí ètò Ọlọ́run fún wa pé ká máa fi tẹlifóònù wàásù. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Judy kọ lẹ́tà sí orílé-iṣẹ́ wa, ó ní òun mọrírì bí wọ́n ṣe rọ̀ wá pé ká máa fi tẹlifóònù wàásù. Ó sọ pé oríṣiríṣi àìsàn ló ń ṣe màmá òun tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86], àmọ́ ó máa ń wàásù fáwọn èèyàn lórí tẹlifóònù, kódà ó ń kọ́ obìnrin ẹni ọdún méjìléláàádọ́rùn-ún [92] kan lẹ́kọ̀ọ́ lórí tẹlifóònù. Ohun tó ń ṣe yìí fún un láǹfààní láti kópa nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́, èyí sì ń fún un láyọ̀ gan-an.
Àwọn àbá tó máa ń wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a lè lò lóde ẹ̀rí gbéṣẹ́ gan-an ni. Torí náà, máa lò wọ́n. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa láyọ̀, wàá sì lè máa fi ìtara bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ nìṣó.
NÍ ÀFOJÚSÙN TÍ ỌWỌ́ RẸ LÈ TẸ̀
Kì í ṣe iye ìwé tí a fi síta tàbí iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń darí tàbí iye èèyàn tí a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fi di ìránṣẹ́ Jèhófà la fi ń díwọ̀n àṣeyọrí tí a ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ó ṣe tán, yàtọ̀ sí ìyàwó Nóà, àwọn ọmọ rẹ̀ àtàwọn ìyàwó wọn, èèyàn mélòó ni ó tún wàásù fún tí wọ́n sì di ìránṣẹ́ Jèhófà? Síbẹ̀ a lè sọ pé Nóà ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Torí náà, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kí á máa fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà.—1 Kọ́r. 4:2.
Ọ̀pọ̀ àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ló ti rí i pé táwọn bá fẹ́ máa fi ìtara wàásù nìṣó àfi káwọn ní àfojúsùn tí ọwọ́ àwọn lè tẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àfojúsùn yìí? Àwọn àbá kan wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé yìí.
O lè bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, kó sì yọrí sí rere. Tí ọwọ́ rẹ bá tẹ àwọn àfojúsùn rẹ, ọkàn rẹ máa balẹ̀ pé o ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeyọrí, wàá sì láyọ̀ pé ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti wàásù ìhìn rere náà.
Lóòótọ́ o, a lè kojú ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan wà tó o lè ṣe táá jẹ́ kó o lè máa fi ìtara polongo Ìjọba Ọlọ́run. Máa gbádùn pàṣípààrọ̀ ìṣírí pẹ̀lú ẹni tí ẹ jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, máa lo àwọn àbá tí ẹrú olóòótọ́ ń fún wa kó o sì ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, má gbàgbé pé bó o ṣe ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni Ọlọ́run fún ẹ láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Aísá. 43:10) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé wàá máa láyọ̀ tó o bá ń fi ìtara wàásù nìṣó!