Ẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Nígbà Gbogbo!
“Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà.”—SM. 62:8.
1-3. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
ÀWỌN èèyàn ń fojú àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi rí màbo ní ìlú Róòmù, wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé àwọn ló dáná sun ìlú Róòmù ní ọdún 64 Sànmánì Kristẹni àti pé wọ́n kórìíra àwọn èèyàn. Torí náà, àkókò yẹn ò fararọ rárá fẹ́ni tó bá jẹ́ Kristẹni. Ká sọ pé ìwọ náà jẹ́ Kristẹni nígbà yẹn, ojoojúmọ́ làyà rẹ á máa já pé wọ́n lè jù ẹ́ sẹ́wọ̀n kí wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹranko ti fa àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ kan ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ tàbí kí wọ́n kàn wọ́n mọ́gi kí wọ́n sì dáná sun wọ́n lóòyẹ̀ kí wọ́n lè fi iná tó ń jó náà ríran lálẹ́.
2 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò tí nǹkan ò rọgbọ yìí ni wọ́n ju àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì ní ìlú Róòmù. Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni míì máa wá ràn án lọ́wọ́? Pọ́ọ̀lù lè kọ́kọ́ máa rò pé bóyá lẹni kẹ́ni máa rí tòun rò torí ó sọ fún Tímótì pé: “Nínú ìgbèjà mi àkọ́kọ́, kò sí ẹnì kankan tí ó wá síhà ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n gbogbo wọn ṣá mi tì—kí ó má ṣe di kíkà sí wọn lọ́rùn.” Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù gbà pé òun ṣì rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Ó sọ pé: “Ṣùgbọ́n Olúwa dúró lẹ́bàá mi, ó sì fi agbára sínú mi.” Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, Jésù Olúwa fún Pọ́ọ̀lù ní agbára tó nílò. Báwo sì ni ìrànwọ́ yẹn ṣe wúlò tó? Kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ: “A sì dá mi nídè kúrò lẹ́nu kìnnìún.”—2 Tím. 4:16, 17.a
3 Ó dájú pé ìgbàgbọ́ Pọ́ọ̀lù á túbọ̀ lágbára sí i bó ṣe ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yẹn, á sì jẹ́ kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa fún òun lókun láti fara da àwọn àdánwò tí òun ń kojú àti àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó wáyé lọ́jọ́ iwájú. Abájọ tó fi sọ pé: “Olúwa yóò dá mi nídè lọ́wọ́ gbogbo iṣẹ́ burúkú.” (2 Tím. 4:18) Pọ́ọ̀lù ti wá mọ̀ pé tí kò bá tiẹ̀ sí nǹkan kan táwọn èèyàn lè ṣe, ó dájú pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ á ṣèrànwọ́!
ÀǸFÀÀNÍ TÓ MÁA JẸ́ KÁ “GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ”
4, 5. (a) Ibo lo ti lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà nígbàkigbà? (b) Báwo lo ṣe lè mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára?
4 Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bí i pé ìwọ nìkan lo ń fàyà rán ìṣòro rẹ? Ó lè jẹ́ ìṣòro àìníṣẹ́lọ́wọ́, àwọn tó ń fúngun mọ́ ẹ ní ilé ìwé, àìlera tàbí àwọn ohun míì ló ń kó ìdààmú bá ẹ. Bóyá o tiẹ̀ bẹ àwọn kan pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́, àmọ́ ṣe ni wọ́n já ẹ kulẹ̀ torí agbára wọn kò gbé e. Ká sòótọ́, àwọn ìṣòro kan wà tágbára ẹ̀dá èèyàn kò ká. Ní irú àwọn àkókò yìí, ṣé ìmọ̀ràn tí kò wúlò ni Bíbélì fún wa nígbà tó sọ pé ká “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà”? (Òwe 3:5, 6) Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn yẹn nítumọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ó nítumọ̀! Ó dájú hán-únhán-ún pé Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ Bíbélì ló sì fi hàn bẹ́ẹ̀.
5 Nítorí náà, dípò kó o máa bínú tó bá jọ pé kò sẹ́ni tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ńṣe ni kó o máa wò ó pé àǹfààní nìyẹn jẹ́ fún ẹ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní kíkún, kí ìwọ alára lè rí i bó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó. Èyí á jẹ́ kó o túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, á sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀.
Ó ṢE PÀTÀKÌ KÁ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ TÁ A BÁ MÁA NÍ ÀJỌṢE PẸ̀LÚ RẸ̀
6. Kí nìdí tó fi sábà máa ń ṣòro láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tí a bá wà nínú ìṣòro?
6 Ǹjẹ́ o lè gbàdúrà sí Jèhófà nípa ìṣòro kan tó ń kó ìdààmú bá ẹ, kí ọkàn ẹ sì wá balẹ̀ lẹ́yìn náà, torí o mọ̀ pé o ti ṣe ohun tó yẹ kó o ṣe nípa ọ̀ràn náà àti pé Jèhófà máa yanjú èyí tó kù? Bẹ́ẹ̀ ni, o lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Sáàmù 62:8; 1 Pétérù 5:7.) Ó yẹ kó o kọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó ṣe pàtàkì tí o bá fẹ́ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Síbẹ̀, ó lè ṣòro nígbà míì láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa pèsè ohun tó o nílò. Kí nìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà lójú ẹsẹ̀.—Sm. 13:1, 2; 74:10; 89:46; 90:13; Háb. 1:2.
7. Kí nìdí tí Jèhófà kì í dáhùn gbogbo àdúrà wa lójú ẹsẹ̀?
7 Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àdúrà wa ni Jèhófà máa ń dáhùn lójú ẹsẹ̀? Má gbàgbé pé Ọlọ́run fi àjọṣe àwa àti òun wé àjọṣe tó máa ń wà láàárín ọmọ àti baba. (Sm. 103:13) Bí àpẹẹrẹ, ọmọ kan ò le retí pé kí òbí òun fún òun ní gbogbo nǹkan tí òun bá ṣáà ti béèrè tàbí kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Nígbà míì ọmọdé lè béèrè ohun kan torí ó kàn wù ú. Àwọn nǹkan míì sì máa gba pé kí ọmọ náà ṣe sùúrù díẹ̀ títí ó fi máa tó àkókò lójú òbí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọmọ náà lè béèrè nǹkan míì tó lè ṣe ìpalára fún un tàbí kó ṣàkóbá fún àwọn ẹlòmíì. Síwájú sí i, tó bá jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ ni òbí kan máa ń fún ọmọ rẹ̀ ní gbogbo ohun tó bá béèrè, a jẹ́ pé òbí náà ti di ẹrú ọmọ náà nìyẹn, ọmọ náà sì ti di ọ̀gá. Bákan náà, Jèhófà lè rí i pé ohun tó máa ṣe wá láǹfààní jù ni pé kí àkókò díẹ̀ kọjá kó tó dáhùn àwọn àdúrà kan. Òun ló láṣẹ láti ṣèpinnu yẹn torí pé òun ní Ẹlẹ́dàá wa tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, Ọ̀gá tó nífẹ̀ẹ́ wa àti Baba wa ọ̀run. Tó bá jẹ́ pé gbogbo nǹkan tá à ń béèrè náà ni Jèhófà ń ṣe fún wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ìyẹn lè sọ àjọṣe tó yẹ kó wà láàárín wa dìdàkudà.—Fi wé Aísáyà 29:16; 45:9.
8. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ó mọ ibi tí agbára wá mọ?
8 Nǹkan míì ni pé, Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ. (Sm. 103:14) Nítorí náà, kò retí pé ká máa dá fara da àwọn ìṣòro wa, àmọ́ ó ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ torí òun ni baba wa. Òótọ́ ni pé, ìgbà míì máa ń wà tó máa ń ṣe wá bíi pé agbára wa ti pin. Àmọ́ Jèhófà ṣèlérí pé òun kò ní jẹ́ kí ìyà tó ju agbára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ jẹ wọ́n. Ó dájú pé ó máa “ṣe ọ̀nà àbájáde.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:13.) Nítorí náà, kò sí àní-àní pé Jèhófà mọ̀ wá lóòótọ́, ó mọ ibi tí agbára wa mọ.
9. Kí ló yẹ ká ṣe tí a ò bá rí ìtura lójú ẹsẹ̀ lẹ́yìn tí a gbàdúrà?
9 Tá ò bá rí ìtura lójú ẹsẹ̀ lẹ́yìn tá a gbàdúrà, ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù, ká máa wojú Ẹni tó mọ ìgbà tó dára jù lọ láti ràn wá lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ó wu Ọlọ́run gan-an láti ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ ó ń mú sùúrù dìgbà tó dáa jù láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún fífi ojú rere hàn sí yín, nítorí náà, yóò dìde láti fi àánú hàn sí yín. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́ [òdodo]. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.”—Aísá. 30:18.
“LẸ́NU KÌNNÌÚN”
10-12. (a) Kí ló lè mú kí nǹkan nira gan-an fún Kristẹni kan tó ń tọ́jú ẹnì kan nínú ìdílé tí àìsàn tó le koko ń bá fínra? (b) Báwo ni àjọṣe ẹnì kan àti Jèhófà ṣe máa sunwọ̀n sí i tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e nígbà tí nǹkan bá nira? Ṣàpèjúwe.
10 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, nígbà tí nǹkan bá nira gan-an fún ẹ, ó lè ṣe ẹ́ bíi pé o ti sún mọ́ ẹnu kìnnìún tàbí pé o tiẹ̀ wà “lẹ́nu kìnnìún.” Irú àwọn àkókò yìí ló ṣòro jù lọ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, síbẹ̀ àkókò yìí ló ṣe pàtàkì jù lọ pé kó o gbẹ́kẹ̀ lé e. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ò ń tọ́jú mọ̀lẹ́bí rẹ kan tó ń ṣàìsàn tó le koko. Bóyá o tiẹ̀ ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ọgbọ́n àti okun.b Lẹ́yìn tó o ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, ǹjẹ́ ọkàn rẹ̀ ò ní balẹ̀ torí o mọ̀ pé ojú Jèhófà ń bẹ lára rẹ àti pé ó máa jẹ́ kó o lè fi ìṣòtítọ́ fara da ìṣòro náà?—Sm. 32:8.
11 Àmọ́ nígbà míì, ohun tó ṣẹlẹ̀ lè mú kó jọ pé Jèhófà kò ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹnu àwọn dókítà lè má kò lórí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà tọ́jú àìsàn náà. Tàbí kí àwọn mọ̀lẹ́bí tó o rò pé wọ́n máa tù ẹ́ nínú mú kí nǹkan túbọ̀ nira fún ẹ. Máa wojú Jèhófà pé kó fún ẹ lókun. Túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Ka 1 Sámúẹ́lì 30:3, 6.) Nígbà tí ìtura bá dé wàá rí i pé àjọṣe ìwọ àti Jèhófà á lágbára sí i.
12 Lindac rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn ọdún mélòó kan tó fi tọ́jú àwọn òbí rẹ̀ tó ń ṣàìsàn láwọn ọdún tí wọ́n lò kẹ́yìn kí wọ́n tó kú. Ó sọ pé: “Lákòókò yẹn nǹkan ò rọrùn rárá fún èmi, ọkọ mi àti àbúrò mi, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni a ò mọ ohun tó yẹ ká ṣe. Nígbà míì ó máa ń tojú sú wa. Àmọ́ ní báyìí tá a bá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ńṣe la máa ń rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa. Kódà nígbà tó tiẹ̀ dà bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ, ó fún wa lókun, ó sì pèsè ohun tí a nílò.”
13. Báwo ni bí arábìnrin kan ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tó kó ìdààmú bá a?
13 Tí a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, èyí tún máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da àjálù. Nígbà tí ọkọ Rhonda tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, ó tún gbọ́ pé àbúrò rẹ̀ ọkùnrin ní àìsàn tó ń ba awọ àti iṣan ara jẹ́ ìyẹn àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí kan tó ń jẹ́ lupus. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, ìyàwó àbúrò rẹ̀ kú. Nígbà tí Rhonda rí i pé òun ti ń gbé ìṣòro náà kúrò lọ́kàn, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí ìyá rẹ̀ kú. Kí ló jẹ́ kí Rhonda lè fara dà á? Ó sọ pé: “Mo máa ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, kódà tí mo bá fẹ ṣe àwọn ìpinnu tí ò tó nǹkan pàápàá. Ìyẹn ti jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni gidi. Ó ti jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà ló yẹ kí n gbára lé dípò kí n máa gbára lé òye tèmi tàbí àwọn ẹ̀lòmíì. Ó dá mi lójú pé ó ràn mí lọ́wọ́ lóòótọ́, ó pèsè gbogbo ohun tí mo nílò. Ìyẹn sì ti jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe ń bá Jèhófà rìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.”
14. Ìgbẹ́kẹ̀lé wo ni Kristẹni olóòótọ́ kan tí a yọ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lẹ́gbẹ́ lè ní?
14 Àpẹẹrẹ míì rèé. Ká sọ pé wọ́n yọ mọ̀lẹ́bí rẹ kan lẹ́gbẹ́. Àwọn ohun tí o kọ́ nínú Bíbélì sì ti jẹ́ kó o mọ bó ṣe yẹ kó o ṣe sí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́. (1 Kọ́r. 5:11; 2 Jòh. 10) Síbẹ̀, ìpinnu tó bá Ìwé Mímọ́ mu náà lè nira fún ẹ, kódà o lè má fara mọ́ ọn.d Ṣé wàá gbẹ́kẹ̀ lé Baba wa ọ̀run pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣègbọràn sí ìtọ́ni Bíbélì nípa àwọn tá a bá yọ lẹ́gbẹ́? Ǹjẹ́ o wá rí i pé àǹfààní nìyẹn jẹ́ fún ẹ láti mú kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà lágbára sí i, kó o sì túbọ̀ sún mọ́ ọn?
15. Kí nìdí tí Ádámù fi ṣàìgbọràn sí àṣẹ Jèhófà nínú ọgbà Édẹ́nì?
15 Ní báyìí, ronú díẹ̀ nípa Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ náà. Ǹjẹ́ Ádámù rò pé òun lè ṣàìgbọràn sí Jèhófà kí òun sì máa wà láàyè nìṣó? Rárá, torí Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé “a kò tan Ádámù jẹ.” (1 Tím. 2:14) Kí ló wá mú kó ṣàìgbọràn? Ó ní láti jẹ́ pé ìfẹ́ tó ní fún ìyàwó rẹ̀ ló kó sí i lórí, ìyẹn ló sì mú kó jẹ èso tí Éfà fún un. Ó ṣègbọràn sí ohùn ìyàwó rẹ̀ dípò Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.—Jẹ́n. 3:6, 17.
16. Ta ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́ jù lọ, kí sì nìdí?
16 Ǹjẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ádámù fi hàn pé kò yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wa tọkàntọkàn? Rárá o! Àmọ́, Jèhófà ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́ jù lọ. (Ka Mátíù 22:37, 38.) Èyí ló máa ṣe àwọn mọ̀lẹ́bí wa láǹfààní jù lọ, bóyá wọ́n ń sin Jèhófà àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Nígbà náà, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ fún Jèhófà máa lágbára sí i, kó o sì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e. Tó bá sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ mọ̀lẹ́bí rẹ kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ṣì ń kó ìdààmú bá ẹ, sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún Jèhófà nínú àdúrà.e (Róòmù 12:12; Fílí. 4:6, 7) Jẹ́ kí ìṣòro tó ń kó ìdààmú bá ẹ yìí mú kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ dán mọ́rán, kó sì jẹ́ ẹni gidi sí ẹ. Èyí á jẹ́ kó o lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa jẹ́ kí ọ̀ràn náà já sí ibi tó dáa.
BÁ A ṢE Ń RETÍ OHUN TÍ JÈHÓFÀ MÁA ṢE
17. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà tá a bá ń kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà?
17 Kí nìdí tí Jèhófà fi dá Pọ́ọ̀lù “nídè kúrò lẹ́nu kìnnìún”? Ó sọ pé: “Nípasẹ̀ mi, kí a lè ṣàṣeparí ìwàásù náà ní kíkún àti kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lè gbọ́ ọ.” (2 Tím. 4:17) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, tá a bá ń kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù, a jẹ́ pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa fi gbogbo nǹkan mìíràn tó ṣe pàtàkì “kún un fún” wa. (Mát. 6:33) À ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, torí náà a ti ‘fi ìhìn rere sí ìkáwọ́’ wa, Jèhófà sì kà wá sí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ̀. (1 Tẹs. 2:4; 1 Kọ́r. 3:9) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ó máa jẹ́ ká lè ṣe sùúrù dìgbà tí Jèhófà máa mú ìtura wá.
18. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí a sì tún jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ dán mọ́rán sí i?
18 Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká lo àkókò tá a wà yìí láti mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run dán mọ́rán sí i. Bí ohunkóhun bá mú ká máa ṣàníyàn, ẹ jẹ́ ká lo àǹfààní náà láti sún mọ́ Jèhófà sí i. Tí a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tí à ń gbàdúrà láìdabọ̀, tí à sì tún tẹra mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó lè kó wa yọ nínú àwọn ìṣòro ti lọ́ọ́lọ́ọ́ tó fi mọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ká sì gbà pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.
a Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé a dá òun nídè “lẹ́nu kìnnìún,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹnu kìnnìún gangan ló ti yè bọ́ tàbí kó jẹ́ pé ṣe ló kàn fi ṣe àpẹẹrẹ.
b Ọ̀pọ̀ àpilẹ̀kọ ni a ti tẹ̀ jáde láti ran àwọn Kristẹni tó ń ṣàìsàn àtàwọn tó ń tọ́jú wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè fara dà á. Wo Jí! February 8, 1994; February 8, 1997; June 8, 2000; àti February 8, 2001 ojú ìwé 15 sí 23.
c A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
d Wo àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tí Ìyọlẹ́gbẹ́ Fi Jẹ́ Ìpèsè Onífẹ̀ẹ́,” èyí tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí.
e A ti tẹ àwọn àpilẹ̀kọ kan jáde tó máa jẹ́ kí àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lè fara dà á nígbà tí mọ̀lẹ́bí wọn kan bá fi Jèhófà sílẹ̀. Wo Ilé Ìṣọ́ September 1, 2006 ojú ìwé 17 sí 21, January 15, 2007 ojú ìwé 17 sí 20.