BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
Mo ti lè ran àwọn míì lọ́wọ́ báyìí
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI 1981
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI GUATEMALA
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀ ÌYÀ JẸ MÍ NÍ KÉKERÉ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Ìlú àdádó kan tó ń jẹ́ Acul ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Guatemala ni wọ́n bí mi sí. Ẹ̀yà Ixil ni wá, ìyẹn ẹ̀yà kan tó ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ àwọn Maya. Mo gbọ́ èdè Sípáníìṣì, mo sì tún gbọ́ èdè ìbílẹ̀ mi dáadáa. Àsìkò tí wọ́n ń ja ogun abẹ́lé ní orílẹ̀-èdè Guatemala ni wọ́n bí mi, ọdún mẹ́rìndínlógójì [36] sì ni wọ́n fi ja ogun náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ìlú wa ló bógun yẹn lọ.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin, ẹ̀gbọ́n mi tó jẹ́ ọmọ ọdún méje ń fi bọ́ǹbù kékeré kan ṣeré, àfi gbàù! Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ẹ̀gbọ́n mi kú, ojú mi méjèèjì sì fọ́. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, wọ́n mú mi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn afọ́jú ní Guatemala City, ibẹ̀ ni mo ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń ka ìwé àwọn afọ́jú. Àmọ́, ó yà mí lẹ́nu pé àwọn olùkọ́ wa kò gbà mí láyè láti máa bá àwọn ẹlẹgbẹ́ mi sọ̀rọ̀, àwọn ẹlẹgbẹ́ mi pàápàá sì máa ń yẹra fún mi. Èyí mú kí n dá wà kí n sì máa fojú sọ́nà fún oṣù méjì nínú ọdún tí màá lọ lò pẹ̀lú ìyá mi nílé. Ìyá ni ìyá mi torí onínúure ni, ó sì fẹ́ràn mi púpọ̀. Ó dùn mí pé nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, ìyá mi kú. Ńṣe ló dàbí pé ẹnì kan ṣoṣo tó rí tèmi rò láyé yìí ló ti lọ yẹn, èyí sì mú kí ọkàn mi gbọgbẹ́ gan-an.
Ọmọ ọdún mọ́kànlá ni mí nígbà tí mo pa dà sílé, mo sì ń gbé pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n mi kan àti ìdílé rẹ̀. Ọmọ bàbá kan náà ni wá, àmọ́ ìyá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló bí wa. Kí n sòótọ́ ó gbìyànjú, torí o tọ́jú mi, ó sì fún mi láwọn nǹkan tí mo nílò. Àmọ́, kò sẹ́ni tó lè pẹ̀tù sọ́kàn mi tó ti gbọgbẹ́. Nígbà míì, màá sọ fún Ọlọ́run pé: “Kí ló dé tí ìyá mi fi kú? Kí ló dé tójú mi fi fọ́?” Àwọn kan sọ fún mi pé Ọlọ́run ló jẹ́ kí n ko àwọn àgbákò yẹn. Ìyẹn mú kí n gbà pé ọ̀dájú ni Ọlọ́run, kò sì rí ti ẹnikẹ́ni rò. Ó ṣe mí bíi kí n pa ara mi, àmọ́ ohun kan tí kò jẹ́ kí n ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, mi ò rí ọ̀nà gbé e gbà.
Torí pé mo fọ́ lójú, àwọn èèyàn máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì máa ń fìtínà mi. Kódà, àwọn kan máa ń fipá bá mi ṣèṣekúṣe. Àmọ́, mi ò fẹjọ́ sun ẹnikẹ́ni torí mo gbà pé kò sẹ́ni tó rí tèmi rò. Àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ bá mi sọ̀rọ̀, èmi náà kì í sì í dá sẹ́ni kẹ́ni. Mo máa ń fẹ́ dá wà, èyí sì máa ń jẹ́ kí n soríkọ́, mi ò sì fọkàn tán ẹnikẹ́ni.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ mi níléèwé lákòókò oúnjẹ ọ̀sán. Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ wa tó káàánú mi ló ní kí wọ́n wá bá mi. Wọ́n sọ àwọn ìlérí Ọlọ́run fún mi pé àwọn òkú máa jíǹde àti pé àwọn afọ́jú ṣì máa ríran. (Aísáyà 35:5; Jòhánù 5:28, 29) Mo nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n kọ́ mi, àmọ́ ó ṣòro fún mi láti bá wọn sọ̀rọ̀ torí kò mọ́ mi lára láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò kì í túra ká, wọn kò dẹ́kun wíwá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì fi sùúrù kọ mi ní àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Àwọn tọkọtaya yìí máa ń rin ìrìn kìlómítà mẹ́wàá gba orí àwọn òkè ńlá kí wọ́n tó dé ibi tí mò ń gbé.
Ẹ̀gbọ́n mi sọ fún mi pé àwọn tọkọtaya yìí máa ń múra dáadáa, àmọ́ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ. Síbẹ̀, wọ́n fẹ́ràn mi, wọ́n sì máa ń ra ẹ̀bùn wá fún mi. Mo mọ̀ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ nìkan ló lè nífẹ̀ẹ́ èèyàn báyìí.
Ìwé àwọn afọ́jú tó dá lórí Bíbélì ni mo fi kẹ́kọ̀ọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo lóye gbogbo ohun tí mò ń kọ́, síbẹ̀ àwọn nǹkan kan wà tó ṣòro fún mi láti fara mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣòro fún mi láti gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi àti pé àwọn ẹlòmíì náà fẹ́ràn mi. Mo mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi fúngbà díẹ̀, síbẹ̀ mi ò rí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá onífẹ̀ẹ́.a
Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kí n tún ìrònú mi ṣe. Bí àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run máa ń káàánú àwọn tí ìyà ń jẹ. Nígbà kan tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń jìyà, Ọlọ́run sọ pé: ‘Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi níṣẹ̀ẹ́ . . . mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.’ (Ẹ́kísódù 3:7) Nígbà tí mo rí i pé aláàánú ni Jèhófà, èyí sún mi láti fẹ́ fayé mi sìn ín. Ní ọdún 1998, mo ṣèrìbọmi, mo sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Lẹ́yìn ọdún kan tí mo ṣèrìbọmi, mo bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n ṣètò fún àwọn afọ́jú nítòsí ìlú Escuintla. Alàgbà kan nínú ìjọ mi rí wàhálà tí mò ń ṣe kí n tó lè dé ìpàdé torí ibi tí mò ń gbé jìnnà. Kí n tó lè dé ìpàdé, màá ní láti gun orí òkè táwọn tọkọtaya tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ máa ń gùn, kí n sòótọ́, kò rọrùn rárá. Alàgbà yìí wá bá mi ṣètò láti máa gbé ọ̀dọ̀ ìdílé Ẹlẹ́rìí kan tó wà nílùú Escuintla. Ìdílé yìí gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì bá mi ṣọ̀nà bí màá ṣe máa dé ìpàdé. Títí di báyìí, ńṣe ni wọ́n ń tọ́jú mi bíi pé ara ìdílé wọn ni mo jẹ́.
Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni àwọn ara nínú ìjọ ti gbà fìfẹ́ tòótọ́ hàn sí mi. Gbogbo èyí jẹ́ kó dá mi lójú pé lóòótọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ Kristẹni tòótọ́.—Jòhánù 13:34, 35.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Mi ò ro ara mi pin mọ́, mo sì ní ìrètí. Mo ti rí nǹkan gidi fayé mi ṣe. Mo sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi àkókò tó pọ̀ wàásù. Kàkà kí n máa dárò nípa àìlera mi, mo gbájú mọ́ bí màá ṣe ran àwọn míì lọ́wọ́ láti mọ àwọn òtítọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú Bíbélì. Mo tún láǹfààní láti jẹ́ alàgbà nínú ìjọ ti mo wà, mo sì máa ń sọ àwọn àsọyé tó dá lórí Bíbélì fáwọn ara ìjọ. Mo tún ti láǹfààní láti sọ àsọyé ní àwọn àpéjọ àgbègbè níbi tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn máa ń wá.
Lọ́dún 2010, mo kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ (tá à ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run báyìí) tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè El Salvador. Ilé ẹ̀kọ́ yìí ti mú kí n gbara dì láti bójú tó àwọn ojúṣe mi nínú ìjọ dáadáa. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ti jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run kà mí sí, ó sì fẹ́ràn mi, àti pé ó lè lo ẹnikẹ́ni fún iṣẹ́ rẹ̀.
Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Nísìnyí, mo lè fi gbogbo ẹnu sọ pé mò ń láyọ̀. Tẹ́lẹ̀, mi ò ronú pé mo lè wúlò fún ẹnikẹ́ni, àmọ́ ní báyìí mo ti wá lè ran àwọn míì lọ́wọ́.
a Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi, wo orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.