Ǹjẹ́ A Lè Mọ Ọlọ́run?
“A kò lè mọ Ọlọ́run.” —Philo, láti ìlú Alẹkisáńdíríà, onímọ̀ ọgbọ́n orí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.
“[Ọlọ́run] kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” —Sọ́ọ̀lù ará Tásù, nígbà tó ń bá àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí sọ̀rọ̀ ní ìlú Áténì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.
ÈWO ló bá èrò rẹ mu nínú gbólóhùn méjèèjì yìí? Ọ̀pọ̀ ló rí i pé ọ̀rọ̀ tí Sọ́ọ̀lù ará Tásù, tá a tún ń pè ní àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tuni lára, ó sì tuni nínú. (Ìṣe 17:26, 27) Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ bí irú èyí ló wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Jésù gba àdúrà kan tó fi dá wa lójú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lè mọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì rí ìbùkún gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀.—Jòhánù 17:3.
Àmọ́ ṣá o, èrò àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí bíi Philo yàtọ̀ sí èyí. Wọ́n sọ pé kò sí béèyàn ṣe lè mọ Ọlọ́run, torí pé àwámáàrídìí ni. Èwo ni ká wá gbà gbọ́ báyìí?
Bíbélì sọ ní kedere pé àwọn nǹkan kan wà nípa Ọlọ́run tó ṣòro fún àwa èèyàn láti lóyè. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà tí Ọlọ́run ti wà, bí òye rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó àti bí ọgbọ́n rẹ̀ ṣe pọ̀ tó jẹ́ àwámáàrídìí fún àwa èèyàn. Wọ́n kọjá òye ẹ̀dá. Ṣùgbọ́n, àwọn nǹkan yìí kò ní ká má mọ Ọlọ́run. Kódà, ríronú nípa àwọn nǹkan yìí máa jẹ́ ká “sún mọ́ Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:8) Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí a kò lè mọ̀ nípa Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, a ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a lè mọ̀ nípa Ọlọ́run.
Kí Ni Àwọn Ohun Tí A Kò Lè Mọ̀ Nípa Ọlọ́run?
ỌLỌ́RUN WÀ TÍTÍ LÁÉ: Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run ti wà “láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 90:2) Lédè míì, Ọlọ́rùn kò ní ìbẹ̀rẹ̀ kò sì ní lópin. Lójú àwa èèyàn “àwọn ọdún rẹ̀ ré kọjá àwárí ní iye.”—Jóòbù 36:26.
Àǹfààní tó máa ṣe ẹ́: Ọlọ́run ṣèlérí pé tó o bá mọ òun, wàá ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 17:3) Ká ni Ọlọ́run kò ní wà títí láé, ṣé ó máa lè ṣèlérí pé òun máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun? “Ọba ayérayé” nìkan ló lè ṣe irú ìlérí bẹ́ẹ̀, kó sì mú un ṣẹ.—1 Tímótì 1:17.
BÍ ÒYE ỌLỌ́RUN ṢE JINLẸ̀ TÓ: Bíbélì kọ́ wa pé “kò sí àwárí òye” Ọlọ́run, torí pé ìrònú rẹ̀ ju ti àwa èèyàn lọ fíìfíì. (Aísáyà 40:28; 55:9) Abájọ tí Bíbélì fi béèrè pé: “Ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà, kí ó lè fún un ní ìtọ́ni?”—1 Kọ́ríńtì 2:16.
Àǹfààní tó máa ṣe ẹ́: Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń gbà lẹ́ẹ̀kan náà. (Sáàmù 65:2) Kódà, ó máa ń mọ̀ bí ẹyẹ ológoṣẹ́ kan bá jábọ́ sílẹ̀. Ṣé ohun tí Ọlọ́run ń rò á wá pọ̀ débi tí kò fi ní rí tiwa rò, tí kó sì ní gbọ́ àdúrà wa? Rárá o, torí pé òye Ọlọ́run jinlẹ̀ gan-an. Láfikún sí i, lójú Ọlọ́run a “níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”—Mátíù 10:29, 31.
ÀWỌN IṢẸ́ ỌLỌ́RUN: Bíbélì kọ́ wa pé àwa èèyàn kò lè “rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.” (Oníwàásù 3:11) Torí náà, a ò lè mọ gbogbo nǹkan nípa Ọlọ́run láéláé. Kódà, ọgbọ́n tí Ọlọ́run fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ “ré kọjá àwákàn.” (Róòmù 11:33) Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run múra tán láti fi ọ̀nà rẹ̀ han àwọn tó bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Ámósì 3:7.
Ìgbà tí Ọlọ́run ti wà, bí òye rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó àti bí ọgbọ́n rẹ̀ ṣe pọ̀ tó jẹ́ àwámáàrídìí fún àwa èèyàn
Àǹfààní tó máa ṣe ẹ́: Tó o bá ń ka Bíbélì tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, gbogbo ìgbà ni wàá máa rí ohun tuntun kọ́ nípa Ọlọ́run àti bó ṣe máa ń ṣe nǹkan. Èyí fi hàn pé kò sígbà tí a kò ní rí ohun táá jẹ́ ká sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run.
Ohun Tí A Lè Mọ̀
Ti pé a ò lè lóye àwọn nǹkan kan nípa Ọlọ́run kò túmọ̀ sí pé a kò lè mọ Ọlọ́run rárá. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká túbọ̀ mọ Ọlọ́run. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò:
ORÚKỌ ỌLỌ́RUN: Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run fún ara rẹ̀ ní orúkọ. Ó sọ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” Orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Bíbélì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà. Kò tún sí orúkọ míì tó fara hàn tó bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì.—Aísáyà 42:8.
Àǹfààní tó máa ṣe ẹ́: Nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù gbà, ó ní: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Ṣé ìwọ náà lè lo orúkọ Ọlọ́run nínú àdúrà rẹ? Jèhófà máa gba àwọn tó ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ là.—Róòmù 10:13.
IBI TÍ ỌLỌ́RUN Ń GBÉ: Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run àti ayé. Ayé ni ibi tí àwa èèyàn ń gbé. Ọ̀run jẹ́ ibi tí ojú àwa èèyàn kò lè tó, ibẹ̀ sì làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wà. (Jòhánù 8:23; 1 Kọ́ríńtì 15:44) Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run” sábà máa ń tọ́ka sí ibi tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, ìyẹn àwọn ańgẹ́lì ń gbé. “Ọ̀run” yẹn náà ni ibi tí Ẹlẹ́dàá ń gbé.—1 Àwọn Ọba 8:43.
Àǹfààní tó máa ṣe ẹ́: Wàá túbọ̀ mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Ẹlẹ́dàá wa kì í ṣe agbára àìrí kan tó máa ń wà níbi gbogbo. Ẹni gidi ni Jèhófà, ó sì ní ibi tó ń gbé. Síbẹ̀, ‘kò sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú rẹ̀.’—Hébérù 4:13.
IRÚ ẸNI TÍ ỌLỌ́RUN JẸ́: Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run ní àwọn ìwà tó dáa. “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Kì í purọ́. (Títù 1:2) Kì í ṣe ojúsàájú, ó jẹ́ aláàánú àti oníyọ̀ọ́nú, kì í sì í tètè bínú. (Ẹ́kísódù 34:6; Ìṣe 10:34) Ohun tó sì máa ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu ni pé, ó wu Ẹlẹ́dàá wa láti jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.—Sáàmù 25:14.
Àǹfààní tó máa ṣe ẹ́: Ìwọ náà lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Jákọ́bù 2:23) Bó o sì ṣe ń mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, wàá túbọ̀ lóye àwọn ìtàn inú Bíbélì.
‘WÁ ỌLỌ́RUN’
Bíbélì jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ lọ́nà tó ṣe kedere. Ẹlẹ́dàá kì í ṣe ẹni tí kò ṣe é mọ̀, kódà ó fẹ́ ká mọ òun. Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Bí ìwọ bá wá a, yóò jẹ́ kí o rí òun.” (1 Kíróníkà 28:9) Tó o bá ka Bíbélì tó o sì ronú lórí àwọn ìtàn inú rẹ̀, wàá mọ Ọlọ́run. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run ‘yóò sún mọ́ ẹ.’—Jákọ́bù 4:8.
O wá lè máa ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, nígbà tó jẹ́ pé mi ò lè mọ gbogbo nǹkan nípa rẹ̀?’ Wo àpẹẹrẹ yìí: Ṣé ó pọn dandan kí ẹnì kan ní ìmọ̀ ìṣègùn kó tó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ dókítà? Rárá o! Ẹni tó jẹ́ ọ̀rẹ́ dókítà lè má mọ̀ nípa ìṣègùn rárá. Síbẹ̀, wọ́n ṣì lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí ọ̀rẹ́ dókítà yìí mọ àwọn ohun tí dókítà náà fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́. Bákan náà, tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ìyẹn sì lohun tó ṣe pàtàkì tó o bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
Bíbélì ò kàn sọ̀rọ̀ lóréfèé nípa irú ẹni tí Ẹlẹ́dàá wa jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tá a nílò láti mọ Ọlọ́run. Ṣé wàá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà Ọlọ́run? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé wọn lọ́fẹ̀ẹ́. A rọ̀ ẹ́ pé kó o kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbègbè rẹ tàbí kó o lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn www.jw.org/yo.