Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ṣé àlááfíà ṣì máa wà láyé?
Kí ni ìdáhùn rẹ?
Bẹ́ẹ̀ ni
Bẹ́ẹ̀ kọ́
Kò dá mi lójú
Ohun tí Bíbélì sọ
Nígbà tí Jésù Kristi bá ń ṣàkóso, ‘ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà yóò wà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́,’ àní títí láé.—Sáàmù 72:7.
Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?
Àwọn èèyàn burúkú kò ní sí mọ́ láyé, àwọn èèyàn rere máa “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.
Ọlọ́run máa mú gbogbo ogun kúrò pátápátá.—Sáàmù 46:8, 9.
Ṣé ó ṣeé ṣe ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀ báyìí?
Èrò àwọn kan ni pé . . . kò ṣeé ṣe káwa èèyàn ní ìfọ̀kànbalẹ̀ torí pé ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ ló kún inú ayé. Kí lèrò rẹ?
Ohun tí Bíbélì sọ
Lónìí, àwọn tó sún mọ́ Ọlọ́run máa ń ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—Fílípì 4:6, 7.
Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?
Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fòpin sí ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ, òun á sì sọ “ohun gbogbo di tuntun.”—Ìṣípayá 21:4, 5.
A máa ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tá a bá sapá láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.—Mátíù 5:3.