“Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Kí O sì Máa Ṣe Rere”
‘Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, máa ṣe rere kí o sì máa fi ìṣòtítọ́ báni lò.’—SM. 37:3.
1. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà fi jíǹkí àwa èèyàn?
JÈHÓFÀ fi ọ̀pọ̀ nǹkan jíǹkí àwa èèyàn. Ó fún wa lágbára láti ronú ká lè yanjú ìṣòro ká sì wéèwé ohun tá a máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. (Òwe 2:11) Ó tún fún wa lágbára láti ṣe ohun tá a wéèwé, ká sì rí i pé a ṣàṣeyọrí. (Fílí. 2:13) Yàtọ̀ síyẹn, ó fún wa ní ẹ̀rí ọkàn tó ń jẹ́ ká mọ ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Ẹ̀rí ọkàn yìí ló máa ń kìlọ̀ fún wa tá a bá fẹ́ ṣìwà hù, ó sì máa ń dá wa lẹ́bi ká lè ṣàtúnṣe tá a bá ṣàṣìṣe.—Róòmù 2:15.
2. Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa lo àwọn nǹkan tó fi jíǹkí wa?
2 Jèhófà fẹ́ ká lo àwọn nǹkan tó fi jíǹkí wa yìí bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọ̀ pé inú wa máa dùn gan-an tá a bá ń lo àwọn ẹ̀bùn náà bó ṣe tọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà rọ̀ wá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká máa lo ẹ̀bùn tó fún wa lọ́nà tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” Ó tún rọ̀ wá pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.” (Òwe 21:5; Oníw. 9:10) Bákan náà, Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì rọ̀ wá pé: “Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” Ó tún sọ pé: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Gál. 6:10; 1 Pét. 4:10) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Jèhófà fẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti múnú ara wa àtàwọn míì dùn.
3. Àwọn nǹkan wo làwa èèyàn ò lè ṣe?
3 Síbẹ̀, Jèhófà mọ̀ pé àwọn nǹkan kan wà tá ò lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kò sóhun tá a lè ṣe tá a fi lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ikú àti àìpé tá a jogún. Yàtọ̀ síyẹn, a ò lè darí ìgbésí ayé àwọn míì, torí pé gbogbo wa la lómìnira láti ṣe ohun tá a fẹ́. (1 Ọba 8:46) Bákan náà, bó ti wù ká gbọ́n tó tàbí ká nírìírí tó, ìkókó la ṣì jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà.—Aísá. 55:9.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Ipò yòówù ká wà, ó yẹ ká jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà, ká gbà pé á ràn wá lọ́wọ́ àti pé á bá wa ṣe ohun tá ò lè dá ṣe. Síbẹ̀, ó yẹ káwa náà sapá, ká ṣe ohun tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro tá a bá ní, ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́. (Ka Sáàmù 37:3.) Lédè míì, ó yẹ ká ‘gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì máa ṣe rere’ àti pé ó yẹ ká “máa fi ìṣòtítọ́ báni lò.” Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò nípa bí Nóà, Dáfídì, àtàwọn míì tó fòótọ́ ọkàn sin Ọlọ́run ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. A máa rí bí wọ́n ṣe fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí wọ́n lè ṣe àti ohun tí wọn ò lè ṣe. Lẹ́yìn náà, a máa wo ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́.
KÍ LA LÈ ṢE NÍNÚ AYÉ BÚBURÚ YÌÍ?
5. Báwo ni nǹkan ṣe rí nígbà ayé Nóà?
5 Nígbà ayé Nóà, àwọn èèyàn máa ń hùwà ipá gan-an, wọ́n sì máa ń ṣe ìṣekúṣe. (Jẹ́n. 6:4, 9-13) Ó dá Nóà lójú pé Jèhófà máa pa gbogbo àwọn ẹni ibi ìgbà yẹn run. Síbẹ̀, ńṣe làwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn ba Nóà lọ́kàn jẹ́. Bó ti wù kó rí, Nóà mọ̀ pé àwọn nǹkan kan wà tóun ò lè ṣe, àwọn nǹkan míì sì wà tóun lè ṣe.
6, 7. (a) Kí làwọn nǹkan tí Nóà ò lè ṣe? (b) Báwo ni ọ̀rọ̀ wa ṣe jọ ti Nóà?
6 Ohun tí Nóà ò lè ṣe: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nóà fìtara kéde ìparun tó ń bọ̀, síbẹ̀ kò lè fipá mú àwọn èèyàn burúkú yẹn láti yí pa dà, kò sì lè mú kí Ìkún-omi náà dé ṣáájú ìgbà tí Ọlọ́run ní lọ́kàn. Ohun tí Nóà lè ṣe ni pé kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa pa àwọn èèyàn burúkú run bó ṣe ṣèlérí, àti pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní àsìkò tó ní lọ́kàn.—Jẹ́n. 6:17.
7 Àwọn èèyàn burúkú ló kúnnú ayé lónìí, a sì mọ̀ pé Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa pa wọ́n run. (1 Jòh. 2:17) Ohun kan ni pé a ò lè fipá mú àwọn èèyàn pé kí wọ́n yí pa dà lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ‘ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.’ A sì mọ̀ pé kò sóhun tá a lè ṣe láti mú kí “ìpọ́njú ńlá” dé ṣáájú àsìkò tí Ọlọ́run ní lọ́kàn. (Mát. 24:14, 21) Bíi ti Nóà, ó ṣe pàtàkì pé káwa náà nígbàgbọ́ tó lágbára, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa tó dá sọ́rọ̀ náà. (Sm. 37:10, 11) Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní jẹ́ kí ọjọ́ tó ní lọ́kàn láti pa ayé búburú yìí run lé ọjọ́ kan.—Háb. 2:3.
8. Báwo ni Nóà ṣe tẹra mọ́ àwọn nǹkan tó lè ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
8 Ohun tí Nóà lè ṣe: Kàkà kí Nóà káwọ́ gbera torí àwọn nǹkan tí kò lè ṣe, ńṣe ló tẹra mọ́ àwọn nǹkan tó lè ṣe. Bíbélì pè é ní “oníwàásù òdodo” torí pé ó fìtara kéde ìparun tó máa dé bá ayé ìgbà yẹn. (2 Pét. 2:5) Ó dájú pé iṣẹ́ ìwàásù yẹn mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára. Yàtọ̀ sí pé ó wàásù, ó tún fi tọkàntara ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un pé kó kan ọkọ̀ áàkì.—Ka Hébérù 11:7.
9. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nóà?
9 Bíi ti Nóà, àwa náà máa ń sapá láti ṣe púpọ̀ nínú iṣẹ́ Olúwa. (1 Kọ́r. 15:58) Bí àpẹẹrẹ, a máa ń kọ́ àwọn ibi tá a ti ń jọ́sìn, a sì máa ń bójú tó wọn. A máa ń yọ̀ǹda ara wa láwọn àpéjọ wa, a sì tún máa ń ṣe onírúurú iṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa àti ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa ń lo ara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, torí a mọ̀ pé ó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ìlérí Ọlọ́run túbọ̀ dájú. Ohun tí arábìnrin kan sọ ni pé: “Tá a bá ń sọ fáwọn míì nípa àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run, a máa ń kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ wọn ò ní ìrètí kankan, wọn ò sì gbà pé ìṣòro àwọn lè yanjú.” Láìsí àní-àní, bá a ṣe ń wàásù ń mú ká túbọ̀ nírètí pé ọjọ́ ọ̀la máa dáa, ó sì tún ń mú ká máa bá eré ìje ìyè náà nìṣó.—1 Kọ́r. 9:24.
TÁ A BÁ ṢÀṢÌṢE
10. Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì.
10 Jèhófà pe Ọba Dáfídì ní “ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà [òun] lọ́rùn.” (Ìṣe 13:22) Ìdí sì ni pé Dáfídì jẹ́ olóòótọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà kan wà tó dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo. Ó bá Bátí-ṣébà ṣe panṣágà. Kò fi mọ síbẹ̀, ó tún wá bó ṣe máa bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀, ló bá ṣètò bí wọ́n ṣe máa pa Ùráyà tó jẹ́ ọkọ obìnrin náà lójú ogun, ó sì kọ́ ọ sínú lẹ́tà. Kódà, Ùráyà fúnra rẹ̀ ni Dáfídì fi lẹ́tà náà rán! (2 Sám. 11:1-21) Àmọ́ nígbà tó yá, àṣírí Dáfídì tú. (Máàkù 4:22) Kí wá ni Dáfídì ṣe nígbà tí àṣírí tú?
11, 12. (a) Kí ni Dáfídì ò lè ṣe lẹ́yìn tó dẹ́ṣẹ̀? (b) Tá a bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ló dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣe fún wa?
11 Ohun tí Dáfídì ò lè ṣe: Dáfídì ò lè dáwọ́ aago pa dà sẹ́yìn. Bákan náà, kò sóhun tó lè ṣe tí kò fi ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. Kódà, á ṣì máa bá àwọn kan lára ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yí jálẹ̀ ọjọ́ ayé rẹ̀. (2 Sám. 12:10-12, 14) Torí náà, ó gba pé kí Dáfídì nígbàgbọ́. Ó ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé tóun bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà máa dárí ji òun, á sì ran òun lọ́wọ́ láti fara da ìyà ẹ̀ṣẹ̀ òun.
12 Torí pé a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe. Àwọn àṣìṣe kan wúwo ju àwọn míì lọ, ó sì lè má rọrùn fún wa láti yí ọwọ́ aago pa dà sẹ́yìn. Ó lè jẹ́ pé ṣe làá máa bá ìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà yí. (Gál. 6:7) Àmọ́, a gbà pé Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé tá a bá ronú pìwà dà, òun á dúró tì wá nígbà ìṣòro, kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àfọwọ́fà wa ni.—Ka Aísáyà 1:18, 19; Ìṣe 3:19.
13. Báwo ni Dáfídì ṣe pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?
13 Ohun tí Dáfídì lè ṣe: Dáfídì jẹ́ kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọ̀nà kan tó gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó gba ìbáwí tí Jèhófà fún un nípasẹ̀ wòlíì Nátánì. (2 Sám. 12:13) Dáfídì tún gbàdúrà sí Jèhófà, ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ Jèhófà pé kó fi ojú rere hàn sí òun. (Sm. 51:1-17) Kàkà kí Dáfídì kárísọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ńṣe ló kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tó ṣe, kò sì dán irú ẹ̀ wò mọ́. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Dáfídì kú, Jèhófà ò sì gbàgbé àwọn ohun rere tó ṣe.—Héb. 11:32-34.
14. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Dáfídì ṣe?
14 Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Dáfídì ṣe? Tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo, ó yẹ ká ronú pìwà dà, ká sì bẹ Jèhófà tọkàntọkàn pé kó dárí jì wá. (1 Jòh. 1:9) Bákan náà, ó yẹ ká lọ bá àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́, ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Ka Jákọ́bù 5:14-16.) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dárí jì wá àti pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa dà ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Lẹ́yìn náà, ó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe wa, ká máa bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lọ, ká sì nírètí pé ọ̀la máa dáa.—Héb. 12:12, 13.
NÍGBÀ TÁWỌN NǸKAN MÍÌ BÁ ṢẸLẸ̀ SÍ WA
15. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Hánà?
15 Àwa náà lè ronú kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà míì láyé àtijọ́ tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, kò sí ohun tí Hánà lè ṣe sí ìṣòro àìrọ́mọbí tó ní. Àmọ́, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa tu òun nínú, torí náà ó máa ń gbàdúrà tọkàntọkàn, ó sì ń bá ìjọsìn rẹ̀ nìṣó ní àgọ́ ìjọsìn. (1 Sám. 1:9-11) Àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn fún wa. Táwa náà bá ní ìṣòro àìlera tàbí ìṣòro míì tó kọjá agbára wa, ó yẹ ká kó gbogbo ìṣòro náà fún Jèhófà, ká sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ó máa tọ́jú wa. (1 Pét. 5:6, 7) Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká sapá láti máa wá sí ìpàdé déédéé, ká sì máa kópa nínú àwọn apá ìjọsìn míì.—Héb. 10:24, 25.
16. Kí làwọn òbí lè rí kọ́ lára Sámúẹ́lì?
16 Àwọn òbí tí ọmọ wọn ti fi Jèhófà sílẹ̀ lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Sámúẹ́lì. Àwọn ọmọ Sámúẹ́lì ò ṣe ìfẹ́ Jèhófà, Sámúẹ́lì ò sì lè fipá mú àwọn ọmọ rẹ̀ tó ti dàgbà yìí pé kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run tó kọ́ wọn. (1 Sám. 8:1-3) Ńṣe ló fi ọ̀rọ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́. Síbẹ̀, Sámúẹ́lì kò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run yingin, ó sì ṣe ohun tó múnú Jèhófà, Baba rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Lónìí, àwọn òbí Kristẹni kan ti bá ara wọn nírú ipò bẹ́ẹ̀. Ó dá wọn lójú pé Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà bíi ti bàbá tó wà nínú àkàwé ọmọ onínàákúnàá. (Lúùkù 15:20) Síbẹ̀, àwọn òbí náà gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà torí èyí lè mú kí ọmọ náà ronú, kó sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.
17. Kí la rí kọ́ lára opó aláìní náà?
17 Tún ronú nípa opó aláìní tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀. (Ka Lúùkù 21:1-4.) Kò sóhun tó lè ṣe sí ìwà jẹgúdújẹrá táwọn èèyàn ń hù nínú tẹ́ńpìlì. (Mát. 21:12, 13) Bákan náà, kò jọ pé ó lè lówó ju bó ṣe wà lọ. Síbẹ̀, tinútinú ló fi fi “ẹyọ owó kéékèèké méjì” ṣe ọrẹ, owó yìí sì ni “gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní.” Obìnrin olóòótọ́ yìí fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó mọ̀ pé tóun bá fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú láyé òun, Jèhófà máa pèsè nǹkan tóun nílò. Èyí ló mú kí opó náà máa ṣe ọrẹ fún ìjọsìn Ọlọ́run. Ó dá àwa náà lójú pé tá a bá ń fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú láyé wa, Jèhófà máa rí i dájú pé a ò ṣaláìní ohunkóhun.—Mát. 6:33.
18. Sọ àpẹẹrẹ ìránṣẹ́ Jèhófà kan tó gbára lé Jèhófà.
18 Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa tó jẹ́ olóòótọ́ lóde òní ló ti fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tí wọ́n sì tún gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Malcolm tó jẹ́ olóòótọ́ títí tó fi kú lọ́dún 2015. Ọ̀pọ̀ ọdún ni òun àtìyàwó rẹ̀ fi sin Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wọn. Ó sọ pé: “Ayé yìí ti dojú rú, kò sì sẹ́ni tó mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́la, ṣùgbọ́n, Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e.” Arákùnrin Malcolm fi kún un pé: “Kéèyàn gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kóun lè máa kó ipa tó jọjú kóun sì máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ débi tó bá ṣeé ṣe dé. Kéèyàn máa pọkàn pọ̀ sórí ohun tó lè ṣe, kì í ṣe ohun tí kò lè ṣe.”a
19. (a) Kí nìdí tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2017 fi bá a mu wẹ́kú? (b) Báwo lo ṣe máa fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2017 sílò nígbèésí ayé rẹ?
19 Bí ayé yìí ṣe túbọ̀ ń burú sí i, a mọ̀ pé nǹkan á túbọ̀ máa nira. (2 Tím. 3:1, 13) Torí náà, ju ti ìgbàkigbà rí lọ, ó yẹ ká pinnu pé a ò ní jẹ́ káwọn ìṣòro ayé yìí mú ká dẹwọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ. Ẹ ò rí i pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2017 bá a mu wẹ́kú, ó sọ pé: “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere”!—Sm. 37:3.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2017: “Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Kí O sì Máa Ṣe Rere”—Sm. 37:3
a Wo Ilé Ìṣọ́, October 15, 2013, ojú ìwé 17 sí 20.