ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 24
Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kó O Borí Gbogbo Ìrònú Tí Kò Bá Ìmọ̀ Ọlọ́run Mu!
“À ń borí àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga tí kò bá ìmọ̀ Ọlọ́run mu.”—2 KỌ́R. 10:5.
ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Ìkìlọ̀ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ kìlọ̀ fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín.’ (Róòmù 12:2) Kí nìdí tó fi fún wọn nírú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará yẹn ti ya ara wọn sí mímọ́, tí Jèhófà sì ti fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yàn wọ́n?—Róòmù 1:7.
2-3. Kí ni Sátánì ń ṣe kó lè kẹ̀yìn wa sí Jèhófà? Báwo la ṣe lè fa àwọn nǹkan tó ti “fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” tu lọ́kàn wa?
2 Pọ́ọ̀lù kíyè sí i pé àwọn Kristẹni kan ti fàyè gba èròkerò àti ọgbọ́n orí èèyàn tó kúnnú ayé Sátánì, ìdí nìyẹn tó fi kọ̀wé sí wọn. (Éfé. 4:17-19) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni yẹn lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. Sátánì tó jẹ́ ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ń wá bó ṣe máa mú ká kẹ̀yìn sí Jèhófà, onírúurú ọgbọ́n ló sì ń dá. Bí àpẹẹrẹ, tó bá kíyè sí pé a lẹ́mìí ìgbéraga tàbí pé a fẹ́ di gbajúmọ̀, ó lè lò ó láti dẹkùn mú wa. Ó sì tún lè lo àṣà ìbílẹ̀ wa, bá a ṣe kàwé tó àti ibi tá a gbé dàgbà láti mú ká máa ronú bíi tiẹ̀.
3 Ṣé ó ṣeé ṣe láti fa àwọn nǹkan tó ti “fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” tu lọ́kàn wa? (2 Kọ́r. 10:4) Ẹ kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, ó ní: “À ń borí àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga tí kò bá ìmọ̀ Ọlọ́run mu, a sì ń mú gbogbo ìrònú lẹ́rú kí ó lè ṣègbọràn sí Kristi.” (2 Kọ́r. 10:5) Ó ṣe kedere nígbà náà pé lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, a lè borí èrò tí kò tọ́ ká sì yí ìwà wa pa dà. Bí aporó ṣe lè pa oró májèlé bẹ́ẹ̀ náà ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè mú ká borí ìwà burúkú tó ti mọ́ wa lára nínú ayé Sátánì yìí.
Ẹ YÍ “ÈRÒ INÚ YÍN PA DÀ”
4. Ìyípadà wo ni ọ̀pọ̀ wa ṣe nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?
4 Ó ṣeé ṣe ká rántí àwọn ìyípadà tá a ṣe nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tá a sì ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ọ̀pọ̀ lára wa ló jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò tọ́. (1 Kọ́r. 6:9-11) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìwà burúkú yẹn!
5. Ìgbésẹ̀ méjì wo ni Róòmù 12:2 rọ̀ wá pé ká gbé?
5 Àmọ́ o, a ò gbọ́dọ̀ dẹra nù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tá à ń hù ká tó ṣèrìbọmi, síbẹ̀ ó yẹ ká túbọ̀ wà lójúfò ká sì yẹra fún ohunkóhun táá mú ká pa dà sẹ́yìn. Kí la lè ṣe tíyẹn ò fi ní ṣẹlẹ̀? Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín, àmọ́ ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà.’ (Róòmù 12:2) Ẹsẹ yìí fi hàn pé ìgbésẹ̀ méjì kan wà tá a gbọ́dọ̀ gbé. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí ayé èṣù yìí “máa darí” wa. Èkejì, a gbọ́dọ̀ “para dà,” ní ti pé ká yí bá a ṣe ń ronú pa dà.
6. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 12:43-45?
6 Ìyípadà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ kọjá ohun tó kàn hàn sójú táyé. Ó kan gbogbo apá ìgbésí ayé wa. (Wo àpótí náà, “Ṣé Lóòótọ́ Ni Mo Para Dà àbí Mò Ń Díbọ́n?”) A gbọ́dọ̀ yí èrò inú wa pa dà, ìyẹn ni pé ká ṣe ìyípadà nínú bá a ṣe ń ronú, bí nǹkan ṣe ń rí lára wa títí kan ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan. Torí náà, ó yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bi ara ẹ̀ pé, ‘Ṣé àwọn ìyípadà tí mò ń ṣe dénú mi àbí ojú ayé lásán ni mò ń ṣe?’ Ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì gan-an, ó sì yẹ ká wá ìdáhùn sí i. Jésù sọ ohun tó yẹ ká ṣe nínú Mátíù 12:43-45. (Kà á.) Ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú àwọn ẹsẹ yìí jẹ́ ká rí kókó pàtàkì kan, ìyẹn ni pé ká gbé èròkerò kúrò lọ́kàn nìkan ò tó, a tún gbọ́dọ̀ fi èrò tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu kún ọkàn wa.
Ẹ “DI TUNTUN NÍNÚ AGBÁRA TÓ Ń DARÍ ÌRÒNÚ YÍN”
7. Báwo la ṣe lè yí irú ẹni tá a jẹ́ nínú pa dà?
7 Àmọ́ ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn yí èrò rẹ̀ tàbí irú ẹni tó jẹ́ nínú pa dà? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú yín, kí ẹ sì gbé ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfé. 4:23, 24) Torí náà, ó ṣeé ṣe kéèyàn yí irú ẹni tó jẹ́ nínú pa dà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. Ó kọjá ká kàn gbé èròkerò kúrò lọ́kàn tàbí ká kàn sọ pé a ò ní hùwà burúkú mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gba pé ká yí “agbára tó ń darí ìrònú” wa pa dà. Ìyẹn béèrè pé ká ṣe ìyípadà nínú ohun tí ọkàn wa ń fà sí, bá a ṣe ń ronú àtohun tó ń sún wa ṣe nǹkan. Kì í ṣe ohun tá a máa ṣe lẹ́ẹ̀kan tá a sì máa dúró, ohun tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe nígbà gbogbo ni.
8-9. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan ṣe jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká yí irú ẹni tá a jẹ́ nínú pa dà?
8 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ oníjàgídíjàgan. Tẹ́lẹ̀, kò lè ṣe kó má mutí yó, ó sì máa ń bá àwọn èèyàn jà. Àmọ́ nígbà tó yá, ó jáwọ́, ó sì ṣèrìbọmi. Ìyẹn mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ládùúgbò rẹ̀ tẹ́tí sí ìwàásù. Àmọ́ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ohun kan tí kò retí ṣẹlẹ̀ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan. Ọkùnrin kan tó ti mutí yó wá sí ilé rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jà rẹ̀. Arákùnrin yìí ò kọ́kọ́ dá a lóhùn, àmọ́ nígbà tí ọkùnrin náà tàbùkù sí orúkọ Jèhófà, ara rẹ̀ ò gbà á mọ́. Ló bá bọ́ síta, ó sì lu ọkùnrin náà lálùbolẹ̀. Kí lẹ rò pé ó fà á tí arákùnrin yìí fi ṣe bẹ́ẹ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti mú kó máa yẹra fún ohun tó lè fa ìjà, síbẹ̀ kò tíì yí agbára tó ń darí ìrònú rẹ̀ pa dà. Lédè míì, kò tíì yí irú ẹni tó jẹ́ nínú pa dà.
9 Síbẹ̀, arákùnrin yìí sapá láti borí ìwà rẹ̀. (Òwe 24:16) Àwọn alàgbà ràn án lọ́wọ́, ó sì ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ. Nígbà tó yá, ó tẹ̀ síwájú, ó sì di alàgbà. Àmọ́ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, irú ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀ níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọkùnrin kan tó ti mutí yó fẹ́ lu ọ̀kan lára àwọn alàgbà. Kí wá ni arákùnrin yìí ṣe? Dípò tó fi máa bá ọkùnrin náà jà, ṣe ló fi ohùn pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀, ó pẹ̀tù sí i nínú, lẹ́yìn náà ó mú un délé. Kí ló mú kí arákùnrin yìí hùwà pẹ̀lẹ́? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé arákùnrin wa ti yí agbára tó ń darí ìrònú rẹ̀ pa dà. Ó ti yí irú ẹni tó jẹ́ nínú pa dà, ó wá para dà dẹni tó jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti onírẹ̀lẹ̀. Ìyẹn sì mú ìyìn àti ògo bá Jèhófà.
10. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè yí irú ẹni tá a jẹ́ nínú pa dà?
10 A ò lè ṣe àwọn ìyípadà yìí ní ọ̀sán kan òru kan, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣàdédé wáyé. Ó gba pé ká sapá gan-an fún ọ̀pọ̀ ọdún. (2 Pét. 1:5) Ó kọjá ká kàn sọ pé ọjọ́ pẹ́ tá a ti wà “nínu òtítọ́.” Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yí irú ẹni tá a jẹ́ nínú pa dà. Àwọn nǹkan wo ló máa jẹ́ ká lè ṣe àwọn ìyípadà yìí? Ẹ jẹ́ ká jíròrò díẹ̀ lára wọn.
BÁ A ṢE LÈ YÍ AGBÁRA TÓ Ń DARÍ ÌRÒNÚ WA PA DÀ
11. Báwo ni àdúrà ṣe máa mú ká yí agbára tó ń darí ìrònú wa pa dà?
11 Àdúrà ni ohun àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì. Ó ṣe pàtàkì pé ká gbàdúrà bíi ti onísáàmù pé: “Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sí inú mi, èyí tó fìdí múlẹ̀.” (Sm. 51:10) Àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ gbà pé ó yẹ ká yí ìrònú wa pa dà ká sì bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́, ṣé ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́? Ẹ jẹ́ ká wo ìlérí tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì alágídí nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì, ó ní: “Èmi yóò mú kí ọkàn wọn ṣọ̀kan, màá sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn . . . màá sì fún wọn ní ọkàn ẹran, [ìyẹn, ọkàn tó ń jẹ́ kí Ọlọ́run darí òun].” (Ìsík. 11:19; àlàyé ìsàlẹ̀) Jèhófà ṣe tán láti ran àwọn èèyàn yẹn lọ́wọ́, ó sì dájú pé á ran àwa náà lọ́wọ́.
12-13. (a) Bó ṣe wà nínú Sáàmù 119:59, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣàṣàrò lé lórí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara rẹ?
12 Ohun pàtàkì kejì ni pé ká máa ṣàṣàrò. Ó yẹ ká máa fara balẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì rí i pé à ń ṣàṣàrò ká lè mọ àwọn ìyípadà tó yẹ ká ṣe nínú èrò àti ìṣe wa. (Ka Sáàmù 119:59; Héb. 4:12; Jém. 1:25) Ó yẹ ká kíyè sí i bóyá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí ohun táwọn èèyàn ń gbé lárugẹ. Ó ṣe pàtàkì ká mọ ibi tá a kù sí, ká gbà pé lóòótọ́ la kù síbẹ̀, ká sì sapá gidigidi láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa.
13 Bí àpẹẹrẹ, bi ara rẹ pé: ‘Nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, ṣé mi ò kì í jowú tàbí ṣe ìlara àwọn míì?’ (1 Pét. 2:1) ‘Ṣé mi ò kì í gbéra ga nítorí ibi tí mo dàgbà sí, bí mo ṣe kàwé tó tàbí torí bí mo ṣe lówó tó?’ (Òwe 16:5) ‘Ṣé mi ò kì í fojú pa àwọn míì rẹ́ torí pé wọn ò ní àwọn nǹkan tí mo ní tàbí torí ìlú tí wọ́n ti wá?’ (Jém. 2:2-4) ‘Ṣé àwọn nǹkan tí ayé Sátánì ń gbé lárugẹ kò máa wọ̀ mí lójú?’ (1 Jòh. 2:15-17) ‘Ṣé àwọn fíìmù tàbí géèmù tó ní ìṣekúṣe àti ìwà ipá ló máa ń wù mí?’ (Sm. 97:10; 101:3; Émọ́sì 5:15) Tá a bá lè wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, ó ṣeé ṣe ká rí àwọn ibi tó ti yẹ ká ṣàtúnṣe. Tá a bá sapá láti fa àwọn nǹkan tó ti “fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” tu lọ́kàn wa, àá múnú Jèhófà Baba wa ọ̀run dùn.—Sm. 19:14.
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọgbọ́n yan àwọn tá à ń bá ṣọ̀rẹ́?
14 Ohun pàtàkì kẹta ni pé ká yan àwọn èèyàn gidi lọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ lè nípa lórí wa, ó ṣe tán wọ́n máa ń sọ pé fi ọ̀rẹ́ rẹ hàn mí, kí n lè sọ irú ẹni tó o jẹ́. (Òwe 13:20) Èrò ayé Sátánì ni ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn tá a jọ wà nílé ìwé sábà máa ń gbé lárugẹ. Àmọ́, àwọn ọ̀rẹ́ gidi ló wà nínú ìjọ wa. Torí náà, inú ìjọ la ti lè rí àwọn táá mú kó máa wù wá “láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere.”—Héb. 10:24, 25, àlàyé ìsàlẹ̀.
“Ẹ FẸSẸ̀ MÚLẸ̀ NÍNÚ ÌGBÀGBỌ́”
15-16. Kí ni Sátánì ń ṣe láti yí èrò wa pa dà?
15 Àmọ́, ó yẹ ká máa rántí pé gbogbo ọ̀nà ni Sátánì ń wá láti yí wa lérò pa dà. Onírúurú èrò òdì ló sì ń lò ká má bàa fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
16 Ìbéèrè kan náà tí Sátánì bi Éfà lọ́jọ́sí náà ló ṣì ń dọ́gbọ́n bi àwa náà, ó béèrè lọ́wọ́ Éfà pé: “Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé . . . ?” (Jẹ́n. 3:1) Nínú ayé èṣù yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń béèrè àwọn ìbéèrè tó lè mú ká ṣiyèméjì, bíi: ‘Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé kò dáa kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin tàbí kí obìnrin máa fẹ́ obìnrin? Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àti Kérésìmesì? Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run yín sọ pé kẹ́ ẹ má ṣe gba ẹ̀jẹ̀ tẹ́ ẹ bá ń ṣàìsàn? Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run ìfẹ́ máa sọ pé kẹ́ ẹ má ṣe kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn yín torí pé wọ́n yọ wọ́n lẹ́gbẹ́?’
17. Kí ló yẹ ká ṣe táwọn ìbéèrè tó lè mú ká ṣiyèméjì bá ń wá sí wa lọ́kàn, kí ni Kólósè 2:6, 7 sọ pé ìyẹn máa yọrí sí?
17 Ó yẹ kí ohun tá a gbà gbọ́ dá wa lójú. Ìdí sì ni pé tá ò bá wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó lè mú ká ṣiyèméjì, kò ní pẹ́ tá a fi máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì. Tá ò bá ṣọ́ra, èrò òdì lè gbilẹ̀ lọ́kàn wa, kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa sì rì. Kí ló yẹ ká ṣe kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká mú èrò wa bá ti Ọlọ́run mu, ìyẹn á jẹ́ ká lè fúnra wa ṣàwárí “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, a ò ní ṣiyèméjì rárá nípa àwọn òtítọ́ tá a ti kọ́ nínú Bíbélì. Á sì túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlànà Jèhófà ló yẹ ká máa tẹ̀ lé. Ìyẹn á jẹ́ ká dà bí igi tí gbòǹgbò rẹ̀ fìdí múlẹ̀ dáadáa, àá sì “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.”—Ka Kólósè 2:6, 7.
18. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tí ayé Sátánì kò fi ní kéèràn ràn wá?
18 Àwa fúnra wa la máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, kò sí ẹlòmíì tó lè bá wa ṣe é. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú wa. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ó ṣe pàtàkì ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo, ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa lẹ́mìí mímọ́ rẹ̀. Bákan náà, ká máa ṣàṣàrò, ká sì máa ṣàyẹ̀wò ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká yan àwọn èèyàn gidi lọ́rẹ̀ẹ́, ìyẹn àwọn táá mú ká máa ronú ká sì máa hùwà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ayé Sátánì kò ní kéèràn ràn wá, àá sì borí “àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga tí kò bá ìmọ̀ Ọlọ́run mu.”—2 Kọ́r. 10:5.
ORIN 50 Àdúrà Ìyàsímímọ́ Mi
a Ibi tá a dàgbà sí, àṣà ìbílẹ̀ wa àti bá a ṣe kàwé tó lè nípa rere tàbí búburú lórí bá a ṣe ń ronú. Kódà, ó ṣeé ṣe ká kíyè sí i pé àwọn ìwà kan tí kò dáa ti di bárakú fún wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè yí àwọn ìwà tí kò tọ́ tó ti mọ́ wa lára pa dà.