Máa Ní Ìbẹ̀rù Jèhófà Lọ́kàn Lọ́jọ́ Gbogbo
1 “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n.” (Sm. 111:10) Ó ń sún wa láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ó sì ń jẹ́ ká yẹra fún ohun búburú. (Òwe 16:6) Ìbẹ̀rù yìí jẹ́ níní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá wa, èyí sì ń jẹ́ ká yẹra fún mímú un bínú àti ṣíṣe àìgbọràn sí i. Nǹkan tó yẹ kí á kọ́, kí á sì máa ṣe lọ́jọ́ gbogbo ni.—Òwe 8:13.
2 Lójoojúmọ́, ẹ̀mí ayé Sátánì máa ń fẹ́ fagbára mú wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀. (Éfé. 6:11, 12) Ẹran ara wa aláìpé jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ohun búburú ló sì máa ń fẹ́ ṣe. (Gál. 5:17) Nítorí náà, láti ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà, láti jẹ́ aláyọ̀, kí a sì jèrè ìyè, a gbọ́dọ̀ máa ní ìbẹ̀rù rẹ̀ lọ́kàn lọ́jọ́ gbogbo.—Diu. 10:12, 13.
3 Ní Hébérù 10:24, 25, a ṣí wa létí pé kí a máa pé jọ pọ̀ kí a lè máa fún ara wa níṣìírí “pàápàá jù lọ” ní àkókò tí à ń gbé yìí. Lílọ sí ìpàdé déédéé ṣe kókó bí a óò bá la àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí já. Ṣíṣàìfẹ́ mú Ọlọ́run bínú ló ń jẹ́ ká máa lọ sí àwọn ìpàdé, ó sì ń jẹ́ ká máa mọrírì ète wọn. Àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń wo kíkópa nínú àwọn ìpàdé Kristẹni gẹ́gẹ́ bí àǹfààní ṣíṣeyebíye.
4 Ṣíṣègbọràn sí àṣẹ náà pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba náà tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí a ń gbà fi hàn pé a ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 10:42) Ìdí pàtàkì kan tí a fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kọ́ ìbẹ̀rù Jèhófà kí wọ́n sì máa ṣe ohun tí ó fẹ́. A ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí a bá ń ṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò, tí a ń sakun láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, tí a sì ń fi gbogbo àṣẹ Ọlọ́run kọ́ àwọn ẹlòmíràn. A ń tipa báyìí fi ìbẹ̀rù Jèhófà àti ìfẹ́ fún aládùúgbò wa hàn.—Mát. 22:37-39.
5 Àwọn tí kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn kì í fi ìmọrírì hàn fún àwọn nǹkan tẹ̀mí, wọ́n sì máa ń gba afẹ́fẹ́ ayé yìí tí ń ṣekú pani sínú tàbí kí wọ́n ní èrò ti ayé. (Éfé. 2:2) Ǹjẹ́ kí a pinnu délẹ̀délẹ̀ pé a óò máa “ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run . . . pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.” (Héb. 12:28) A óò tipa báyìí gba ìbùkún tí àwọn tó ní ìbẹ̀rù Jèhófà lọ́kàn lọ́jọ́ gbogbo máa ń gbà.