Ǹjẹ́ O “Fẹ́” Láti Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́?
1 Jésù bìkítà gan-an nípa àwọn èèyàn. Nígbà tí adẹ́tẹ̀ kan bẹ̀ ẹ́ pé kó ran òun lọ́wọ́, ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó fi kan ọkùnrin náà, ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” (Máàkù 1:40-42) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fara wé Jésù nípa ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?
2 Àwọn Olùfìfẹ́hàn: Gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ló ń kópa nínú ríran àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́wọ́ láti di olùjọ́sìn Jèhófà. Nígbà táwọn ẹni tuntun bá wá sí ìpàdé, kí wọn dáadáa kó o lè dojúlùmọ̀ wọn. Wá àwọn ọ̀nà láti fún wọn níṣìírí. Gbóríyìn fún wọn fún àwọn ìbéèrè tí wọ́n dáhùn nínú ìpàdé. Yìn wọ́n nítorí bí wọ́n ṣe ń sapá láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó ṣeé ṣe fún wọn láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ láàárín ìjọ.
3 Àwọn Onígbàgbọ́ Ẹlẹgbẹ́ Wa: Ní pàtàkì, ó yẹ ká ṣèrànwọ́ fún “àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́,” a sì lè ṣe èyí ní onírúurú ọ̀nà. (Gál. 6:10) Àìsàn ń bá ọ̀pọ̀ àwọn ará fínra. Bó o bá bẹ̀ wọ́n wò láti fún wọn níṣìírí, o lè jẹ́ kí wọ́n gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbámúṣé, o sì tún lè ṣèrànwọ́ fún wọn nípa tara láwọn ọ̀nà mìíràn pẹ̀lú. Àwọn kan lè máa fàyà rán àwọn ìṣòro ńlá mìíràn nínú ìgbésí ayé wọn. Fi hàn pé o bìkítà fún wọn nípa fífara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn kó o sì gbé wọn ró. (1 Tẹ́s. 5:14) Ó yẹ ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà bákan náà, bí wọ́n ti ń ṣe ojúṣe wọn. (Héb. 13:17) Bá a bá ní ẹ̀mí ìmúratán láti ṣèrànwọ́, a ó lè “di àrànṣe afúnnilókun” fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa.—Kól. 4:11.
4 Àwọn Tá A Jọ Wà Nínú Ìdílé: A tún ní láti sapá ká lè fara wé ọ̀nà tí Jésù gbà bìkítà fáwọn èèyàn, pàápàá nínú ìdílé tiwa. Àníyàn àtọkànwá táwọn òbí ní fún àwọn ọmọ wọn ló ń sún wọn láti “máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Àwọn ọmọ lè ṣe ipa tiwọn nípa rírí i pé àwọ́n ti wà ní ìmúrasílẹ̀ ṣáájú àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, ìpàdé ìjọ àti iṣẹ́ ìsìn pápá. Àwọn ọmọ tó ti dàgbà lè fi irú ẹ̀mí ìyọ́nú tí Jésù ní hàn nípa ṣíṣèrànwọ́ fáwọn òbí wọn tìfẹ́tìfẹ́, kí wọ́n lè kojú àwọn ìṣòro tí ọjọ́ ogbó ń mú wá. Láwọn ọ̀nà wọ̀nyí àtàwọn mìíràn, gbogbo wa lè “máa fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe ìwà hù nínú agbo ilé” wa.—1 Tím. 5:4.
5 Bá a bá fara wé Jésù nípa ṣíṣèrànwọ́ fáwọn ẹlòmíràn, a ó lè mú kí ìṣòro àwọn èèyàn dín kù, a ó sì lè mú kí ìdílé wa àti ìjọ sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a óò bọlá fún Jèhófà, “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.”—2 Kọ́r. 1:3.