Ṣètìlẹ́yìn fún Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Rẹ
1 Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ló ń jàǹfààní tó pọ̀ látinú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Lóṣù tó kọjá, a jíròrò ọ̀nà tí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ń gbà bójú tó iṣẹ́ tá a yàn fún un. Àmọ́ ìtìlẹ́yìn wo la lè ṣe fún un ká sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ara wa àtàwọn mìíràn láǹfààní?
2 Máa Pésẹ̀ Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀: Níwọ̀n bí àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ti máa ń mọ níwọ̀nba, ó ṣe pàtàkì kó o máa wà níbẹ̀. Fi sọ́kàn pé wàá máa pésẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìtìlẹ́yìn mìíràn tó o tún lè ṣe ni pé kí o máa tètè dé, nítorí ìyẹn á mú kó ṣeé ṣe fún alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìpàdé náà lọ́nà tó wà létòlétò.—1 Kọ́r. 14:40.
3 Àwọn Ìdáhùn Tó Ń Gbéni Ró: Ọ̀nà mìíràn tó o tún lè gbà ṣètìlẹ́yìn ni nípa mímúra sílẹ̀ dáadáa àti nípa dídáhùn lọ́nà tó ń gbéni ró. Àwọn ìdáhùn tó dá lórí kókó kan ṣoṣo ló sábà máa ń dára jù lọ, èyí sì tún máa ń fún àwọn mìíràn níṣìírí láti dáhùn. Má ṣe máa gbìyànjú láti dáhùn gbogbo kókó tó wà nínú ìpínrọ̀ kan. Bí kókó kan nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, ṣàjọpín ohun tó wà lọ́kàn rẹ náà pẹ̀lú àwọn ará nínú ìdáhùn rẹ láti mú kí ìjíròrò náà túbọ̀ lárinrin.—1 Pét. 4:10.
4 Bó o bá ní àǹfààní láti ka àwọn ìpínrọ̀ fún àǹfààní àwùjọ náà, sapá láti rí i pé ò ń ṣe iṣẹ́ tá a yàn fún ọ yìí dáadáa. Kíkàwé lọ́nà tó dára á mú kí ìpàdé náà túbọ̀ gbádùn mọ́ni.—1 Tím. 4:13.
5 Ìjẹ́rìí Àjẹ́pọ̀: A máa ń ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní ọ̀pọ̀ ibi tá a ti ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, ìtìlẹ́yìn tí ò ń ṣe fún àwọn ètò wọ̀nyí yóò ran alábòójútó náà lọ́wọ́ bó ti ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà. Máa wo àwọn ìṣètò wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àǹfààní tó o ní láti túbọ̀ sún mọ́ àwọn arákùnrin rẹ àti láti fún wọn ní ìṣírí.
6 Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Pápá: Fífi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ sílẹ̀ ní gbàrà tí oṣù bá ti parí tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn láti ṣètìlẹ́yìn fún alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. O lè fi ìròyìn rẹ lé òun fúnra rẹ̀ lọ́wọ́ tàbí kó o fi sínú àpótí tó wà fún ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Akọ̀wé lè lo àpótí yìí láti fi ṣàkójọ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá tí àwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ti gbà jọ.
7 Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ pẹ̀lú alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ kò ṣàì lérè nínú o. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà yóò ‘wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí o fi hàn.’—Fílí. 4:23.