Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 11
Orin 183
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn kan nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ November 15 lọni. Ṣàlàyé bí a ṣe ń rí owó láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé tí à ń ṣe.—Wo ojú ìwé 2 nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn Jí!
15 min: Àwọn Alátìlẹyìn Ìjọsìn Tòótọ́—Láyé Ọjọ́un àti Lóde Òní. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 1, 2002, ojú ìwé 26 sí 30.
20 min: “Ṣètìlẹ́yìn fún Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Rẹ.”a Alàgbà kan tó jẹ́ alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ni kó bójú tó o. Nígbà tí o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, fi àlàyé kún un látinú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 70. Gbóríyìn fún àwọn ará fún àwọn ọ̀nà kan pàtó tí wọ́n ń gbà ṣètìlẹ́yìn fún ìṣètò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, lẹ́yìn náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pe àfiyèsí sí àwọn àgbègbè èyíkéyìí tí wọ́n ti nílò ìtẹ̀síwájú.
Orin 114 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 18
Orin 78
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Jíròrò àpótí náà “Àwọn Ìsọfúnni Tó Dára Gan-an Láti Kà!”
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé tí alàgbà kan tó dáńgájíá yóò sọ.
25 min: “Ẹ̀yin Olórí Ìdílé—Ẹ Jẹ́ Kí Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Máa Bá A Lọ Láìdáwọ́dúró Nínú Ìdílé Yín.” Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí tá a gbé ka ìpínrọ̀ 1 sí 3, jíròrò ìpínrọ̀ 4 sí 13 pẹ̀lú àwùjọ. Bí àyè bá ṣe wà sí, ka ìpínrọ̀ 7, 8, 11, àti 12. Fọ̀rọ̀ wá òbí kan tàbí méjì lẹ́nu wò. Kí ló ti ran ìdílé wọn lọ́wọ́ láti ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó gún régé fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí? Àwọn ìsapá wo ni wọ́n ti ṣe nítorí èyí? Àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n ti gbà jàǹfààní? Fi àlàyé ṣókí tó o mú látinú ìpínrọ̀ 14 kádìí ìjíròrò náà.
Orin 31 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 25
Orin 16
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Tọkọtaya kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lóde ẹ̀rí ṣàṣefihàn ọ̀nà tá a lè gbà lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi ìwé ìròyìn December 1 àti December 8 lọni. Ọkọ fi Ilé Ìṣọ́ lọni, ìyàwó sì fi Jí! lọni.
15 min: “Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Mọ Òtítọ́ Nípa Jésù.”b Fi àlàyé kún un látinú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 278. Rọ gbogbo àwọn ará láti mú ìwé náà dání wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ fún ìjíròrò apá náà, “Ilé Ẹ̀kọ́ Kan Tó Ń Mú Wa Gbára Dì fún Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nígbèésí Ayé.”
20 min: “Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn sí ‘Àwọn Ọmọdékùnrin Aláìníbaba.’” Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ta lórí ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ọmọdékùnrin àti àwọn ọmọdébìnrin tí wọ́n jẹ́ aláìníbaba, èyí tá a gbé ka ìpínrọ̀ 1. Tẹnu mọ́ àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí àwọn mìíràn lè gbà pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3 àti 4, fi àlàyé díẹ̀ kún un látinú Jí! October 8, 1995, ojú ìwé 8 àti 9.
Orin 142 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 2
Orin 213
8 min: Àwọn Ìfilọ̀ Ìjọ. Rán gbogbo àwọn ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn fún oṣù November sílẹ̀. Ní ṣókí, gbé ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tá a lè lò nígbà tá a bá ń fi ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ lọni yẹ̀ wò.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1995, ojú ìwé 8.
12 min: Àwọn Ìṣòro Tó Ń Kojú Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ. Alàgbà kan fọ̀rọ̀ wá òbí kan tàbí méjì tó ń dá tọ́mọ (tàbí àwọn tí ọkọ wọn tàbí aya wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí) lẹ́nu wò, láti mọ bí wọ́n ṣe ń kojú àwọn ìṣòro tó so mọ́ títọ́ àwọn ọmọ wọn, fífún wọn níbàáwí, àti títọ́ wọn sọ́nà nípa tẹ̀mí. Báwo ni wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ ìdílé síbẹ̀ tí wọ́n tún ń wá sí àwọn ìpàdé tí wọ́n sì ń jáde òde ẹ̀rí déédéé? Sọ àwọn àbá díẹ̀ tó wà nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 104 sí 110. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ ní ojú ìwé 113 sí 115, mẹ́nu kan àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ táwọn mìíràn lè gbà ṣèrànwọ́.
25 min: Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Mú Wa Gbára Dì fún Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nígbèésí Ayé. Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ jíròrò ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú àwùjọ. Jíròrò rẹ̀ lọ́nà tí yóò mú kí àwọn ará túbọ̀ máa fi ìháragàgà retí ilé ẹ̀kọ́ náà, èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní January. Pe àfiyèsí sí àwọn apá kan pàtó nínú “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2003,” èyí tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2002. Sọ àwọn ohun tá a nílò láti dara pọ̀ mọ́ ilé ẹ̀kọ náà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé rẹ̀ nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ní ojú ìwé 282, kí o sì rọ àwọn tí kò bá tíì forúkọ sílẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá ti tóótun.
Orin 127 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.