Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 13
Orin 152
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù November sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ November 15 àti Jí! October-December. Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, fi hàn báwọn ará ṣe lè fún ẹni tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn lésì, tó wá sọ pé ‘Mo ti dojúlùmọ̀ iṣẹ́ yín dáadáa’—Wo ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 12.
20 min: Àwọn Òjíṣẹ́ Tó Ń Wàásù Ìhìn Rere. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 77 sí àkòrí tó wà lójú ìwé 83.
15 min: “Ẹ Má Ṣe Ṣojo Síbẹ̀, Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà.”a Fi àlàyé kún un látinú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 252 àti 253 lábẹ́ àkòrí náà “Ìgbà Tó Yẹ Kí O Juwọ́ Sílẹ̀” tá a fi lẹ́tà wínníwínní kọ.
Orin 39 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 20
Orin 132
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí ní December. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní kí àwùjọ sọ ohun tó wù wọ́n nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ kí wọ́n sì sọ ìrírí tó tayọ tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n lò ó. Sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá fún lílo ìwé náà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005. Lo ọ̀kan lára àwọn àbá náà tàbí òmíràn tó bá máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé náà.
Orin 203 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 27
Orin 111
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù November sílẹ̀. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́.
15 min: Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Ń Jùmọ̀ Kọ́lé fún Ìyìn Rẹ̀. Kí alàgbà kan sọ ọ́ bí àsọyé tó dá lórí Ilé Ìṣọ́, November 1, 2006, ojú ìwé 17 sí 21.
20 min: “Mímúra Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Ìròyìn Sílẹ̀.”b Fi àṣefihàn oníṣẹ̀ẹ́jú-mẹ́ta kún un nínú èyí táwọn akéde méjì, tó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ tọkọtaya, ti yan ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá lójú ìwé 4 fún Ilé Ìṣọ́ December 1, kí wọ́n pinnu bí wọ́n ṣe máa lò ó, kí wọ́n sí sọ ọ́ lọ́rọ̀ ara wọn. Lẹ́yìn ìyẹn, kí wọ́n tẹ̀ lé àwọn àbá tá a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán yìí láti fi múra bí wọ́n ṣe máa lo àpilẹ̀kọ mìíràn tí wọ́n mọ̀ pé ó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn mu, kí wọ́n sì ṣe àṣefihàn rẹ̀.
Orin 120 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 4
Orin 155
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: “Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!”c Gba àwọn ará níyànjú láti máa lo àwọn nǹkan bí àpótí, àwòrán àti àtẹ ìsọfúnni tó wà nínú ìwé náà láti fi kún òye wọn. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, ẹ fi ẹsẹ Bíbélì tá a jíròrò ṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ yẹn.
20 min: Bíbélì Ni Kó O Máa Lò Nígbà Tó O Bá Ń Dáhùn Ìbéèrè. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ August 15, 2002, ojú ìwé 17 àti 18 lábẹ́ àkòrí náà “Fífi Ìfẹ́ Hàn Sáwọn Òtítọ́ Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn.” Ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí gbogbo ìbéèrè náà níkọ̀ọ̀kan. Jẹ́ kí akéde kan ṣe àṣefihàn bó ṣe lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni (Orí 16, ìpínrọ̀ 6 sí 10) láti dáhùn ìbéèrè, tí ìdáhùn náà sì dá lórí Ìwé Mímọ́, nígbà tí ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ béèrè pé, “Kí nìdí tí o kì í fi í ṣayẹyẹ Kérésìmesì?”
Orin 168 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.